Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Oúnjẹ Bá Lọ Tán Pẹ́nrẹ́n

Bí Oúnjẹ Bá Lọ Tán Pẹ́nrẹ́n

Bí Oúnjẹ Bá Lọ Tán Pẹ́nrẹ́n

NÍ ÀWỌN apá ibì kan lágbàáyé, àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńlá gbà pé irè oko ò lè tán lọ́jà tàbí níbikíbi tí wọ́n ti ń tà á, èrò wọn sì tún ni pé kò ní wọ́n ju ohun táwọn lè rà lọ. Nígbà tí oúnjẹ bá ń wọ̀lú déédéé, àwọn tó ń jẹ ẹ́ lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe ń kó o wọ̀lú. Àmọ́, bí nǹkan ò bá fara rọ, àwọn èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ọ̀nà tí wọ́n á gbà máa róúnjẹ rà. Bí ohun kan bá sì jàjà lọ ṣẹlẹ̀, tó di pé wọn ò róúnjẹ kó wọ̀lú déédéé mọ́, ohun táá tẹ̀yìn ẹ̀ yọ á burú jọjọ.

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan tí ọrọ̀ ajé ti dojú rú ní Àríwá Áfíríkà. Nígbà tí ìjọba dáwọ́ owó ìrànwọ́ tí wọ́n ń san fáwọn àgbẹ̀ lórí oúnjẹ dúró, lọ́sàn-án kan òru kan lowó búrẹ́dì di ìlọ́po méjì iye tó wà tẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ tínú ń bí fọ́n sígboro láti fẹ̀hónú hàn, bí wọ́n ṣe ń fọ́ wíńdò àwọn ṣọ́ọ̀bù ni wọ́n ń já wọ àwọn ilé ìfowópamọ́ àti ilé ìfìwéránṣẹ́. Orílẹ̀-èdè náà dà rú látòkèdélẹ̀, ìyẹn ló mú kí ìjọba ṣe ìkéde kọ́lọ́mọ-kìlọ̀-fọ́mọ. Ìròyìn sọ pé níbi táwọn agbófinró ti ń gbìyànjú àtipaná rògbòdìyàn náà, wọ́n da ìbọn bo àwọn tó ń wọ́de, ọgọ́fà èèyàn ni wọ́n sì pa.

Tóúnjẹ ò bá wọ̀lú dáadáa láwọn orílẹ̀-èdè tí ètò ọrọ̀ ajé ti ń lọ déédéé pàápàá, wàhálà lè bẹ́ sílẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lóṣù September ọdún 2000 nìyẹn. Àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn lórí bí wọ́n ṣe fowó lé owó epo rọ̀bì dí gbogbo ọ̀nà táwọn ọkọ̀ elépo máa ń gbà jáde láti ibi tí wọ́n ti ń fọ epo, wọn ò sì ráàyè gbé epo wọ̀lú. Láàárín ọjọ́ mélòó kan, epo pẹtiróòlù gbẹ láwọn ilé epo, kò sì sépo táwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtàwọn ọkọ̀ akẹ́rù á fi rìn, bí kò ṣe sí ọkọ̀ tí wọ́n á fi kó oúnjẹ wọ̀lú nìyẹn o. Jákèjádò orílẹ̀-èdè yẹn, kò sí ọjà olóókan lórí àtẹ láwọn ilé ìtajà àtàwọn ṣọ́ọ̀bù, láwọn tó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá nílò ọjà ni wọ́n tó máa ń gbà á.

Onírúurú ìṣòro tó rọ̀ mọ́ kíkó oúnjẹ wọ̀lú ló wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ìwé kan tó ń jẹ́ Feeding the Cities, tí àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn Food and Agriculture Organization of the United Nations gbé jáde sọ pé, lára àwọn nǹkan tó ń fa àwọn ìṣòro náà ni ọ̀dá, ètò ọrọ̀ ajé tí ò lọ déédéé, ìgboro tó ń dà rú àti ogun. Ìwé náà sọ pé tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, “wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ la ó máa rí i pé gbogbo nǹkan ò ní máa lọ déédéé, òkùtà á sì máa bá gbogbo ètò tó jẹ mọ́ kíkó oúnjẹ wọ̀lú.” Ó tún wá fi kún un pé: “Táwọn nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà dé ibi tó pọ̀ tàbí kó máà pẹ́ tó fi máa kásẹ̀ nílẹ̀, àwọn aláìní ló sábà máa ń jìyà rẹ̀.”

Àwọn tó ń ṣàrúnkúnná ọ̀rọ̀ sọ pé bérò ṣe ń yára pọ̀ sí i ṣáá láwọn ìlú ńláńlá yìí máa dá “ìṣòro ńlá sílẹ̀” fáwọn tó ń ta oúnjẹ àtàwọn tó ń kó o wọ̀lú. Wọ́n fojú dá a pé tó bá fi máa di ọdún 2007, ìdajì àwọn tó ń gbé láyé láá máa gbé láwọn ìlú ńláńlá. Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ, “tó bá yá, kíkó tá à ń kó oúnjẹ tó dáa tí kò sì wọ́nwó lọ sọ́dọ̀ [àwọn tó ń gbé nínú ìlú ńlá] á mú kí nǹkan nira débi pé á ṣòro láti kó oúnjẹ dé gbogbo ibi tó yẹ.”

Ọ̀ràn ńlá tó yẹ kó o fún láfiyèsí pàtàkì ni ọ̀ràn bí wàá ṣe máa róúnjẹ rà lọ́jà. Torí náà, báwo la ṣe lè fọkàn balẹ̀ tó lórí ọ̀ràn kíkó oúnjẹ wọ̀lú? Kí ló dé táwọn ọ̀mọ̀ràn ń bẹ̀rù pé tó bá yá wọ́n lè má róúnjẹ kó wọ̀lú mọ́? Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ tẹ́nikẹ́ni ò ní máa ṣàníyàn mọ́ lórí bí oúnjẹ ọ̀sán á ṣe máa bá tàárọ̀ nínú?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn tó ń kó ṣọ́ọ̀bù nígbà ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ

[Credit Line]

BETAH/SIPA