Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Káàbọ̀ Sínú Ètò Jèhófà”

“Káàbọ̀ Sínú Ètò Jèhófà”

“Káàbọ̀ Sínú Ètò Jèhófà”

Ó ti ṣe díẹ̀ tí ìdílé kan ti ń dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Finland, wọ́n sì ti dojú kọ àtakò níwá lẹ́yìn. Àwọn èèyàn máa ń kìlọ̀ fún wọn pé, “Wọ́n á kàn gbowó yín ni.” Àwọn míì tiẹ̀ sọ pé, “Ilé yín á lọ sí i.” Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé iná ṣẹ́ yọ lóru ọjọ́ kan báyìí tó sì jó ibi tí wọ́n gbé ẹ̀rọ tó ń múlé móoru sí. Àdánù ńlá gbáà nìyẹn jẹ́ níbi títutù rinrin tí wọ́n ń gbé níhà àríwá ilẹ̀ ayé.

Owó ìbánigbófò ò ká àwọn ohun èlò tí wọ́n máa fi tún ibi tó jó náà kọ́. Ṣe ló dà bíi pé ohun táwọn kan sọ ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí iná yẹn jó. Baálé ilé náà rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó mí kanlẹ̀, ó sì sọ pé: “Ó ti wá kàn wá ku báyìí o.” Síbẹ̀, òun àti ìyàwó rẹ̀ ò yí ìpinnu wọn láti ṣèrìbọmi padà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré ló kù sígbà yẹn.

Ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ rí i pé àǹfààní lèyí jẹ́ fáwọn láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòhánù 3:18) Kíá làwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ sì ṣètò bí wọ́n á ṣe tún ilé náà kọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Finland fún wọn ní ìmọ̀ràn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí bí wọ́n á ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n ya àwòrán ohun tí wọ́n fẹ́ kọ́, wọ́n gbàṣẹ ìkọ́lé lọ́dọ̀ ìjọba, wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun èlò ìkọ́lé tí wọ́n máa nílò, wọ́n sì fìwé ké sáwọn tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn fúnṣẹ́.

Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ iná ọ̀hún, iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Lọ́jọ́ Wednesday kan báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà wó èyí tí iná jó kù lára ilé náà palẹ̀. Lọ́jọ́ Friday, àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti àwọn ìjọ mìíràn wá kún wọn lọ́wọ́, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà. Nígbà tí baálé ilé tí wọ́n ń ràn lọ́wọ́ yìí ń lọ sígboro, ó bá òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó wà ládùúgbò náà pàdé. Òṣìṣẹ́ ìjọba yìí bi í léèrè bóyá ó ti da tapólì bo orí òrùlé ilé tó jó ná kí òjò má bàa rọ̀ lé e lórí. Pẹ̀lú ara yíyá ló fi dá a lóhùn pé: “Rárá o, mi ò wulẹ̀ da tapólì bò ó, àmọ́ èèyàn ọgbọ̀n ló wà lórí òrùlé náà báyìí!”

Lọ́jọ́ Sátidé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n pàdé níbi ilé kíkọ́ náà, tí inú wọn sì ń dùn yùngbà nítorí àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣèrànlọ́wọ́. Aládùúgbò wọn kan tóun pẹ̀lú bá wọn fọwọ́ kún ilé kíkọ́ náà ṣàlàyé pé: “Ìwòyí alẹ́ àná rèé tí mò ń ronú nípa bí ẹ̀yin èèyàn yìí ṣe yàtọ̀ tó! Ẹ máa ń bójú tó ara yín, ẹ sì tún máa ń ran ara yín lọ́wọ́ gan-an ni.”

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ni iṣẹ́ náà parí. Ilé tuntun tí wọ́n kọ́ náà ló pa àwọn ẹlẹ́tanú tí wọ́n ń ṣèkìlọ̀ èké fún ìdílé náà lẹ́nu mọ́. Alàgbà ìjọ kan rántí ìgbà tí òun àti baálé ilé náà dúró síwájú ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ tán náà, ó sọ pé: “Inú mi dùn ara mi sì yá gágá láti fọwọ́ kọ́ arákùnrin wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi náà lọ́rùn tí mo sì sọ pé, ‘Káàbọ̀ sínú ètò Jèhófà.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ibi tó jóná

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ìgbà tí wọ́n ń tún ibi tó jóná kọ́ rèé