Kí Ló Ń Fa Ìṣòro Àìrílégbé?
Kí Ló Ń Fa Ìṣòro Àìrílégbé?
ÀJỌ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé: “Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn tí kò rílé gbé káàkiri àgbáyé.” Bí wọ́n bá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, nígbà náà, a jẹ́ pé nínú bí ọgọ́ta èèyàn, ẹnì kan ni kò rílé tó dáa gbé! Síbẹ̀, ó ṣòro láti sọ ohun tó ń fa ìṣòro ọ̀hún gan-an. Kí nìdí tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀?
Níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ káàkiri àgbáyé, ohun táwọn èèyàn kà sí àìrílégbé yàtọ̀ síra. Ní ti àwọn tó sì ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìṣòro ọ̀hún, ọ̀nà tí wọ́n ń gbé àyẹ̀wò wọn gbà, àti ohun tí wọ́n ní lọ́kàn pẹ̀lú àyẹ̀wò tí wọ́n ń ṣe, máa ń nípa lórí ohun tí wọ́n kà sí àìrílégbé. Kò sì sí bí ohun tí wọ́n kà sí àìrílégbé ò ṣe ní hàn nínú ìṣirò tí wọ́n bá gbé jáde. Nítorí náà, ó ṣòro láti mọ iye àwọn tí kò rílé gbé, ìyẹn bá a bá tiẹ̀ lè mọ̀ ọ́n rárá.
Ìwé kan tó dá lórí ọgbọ́n téèyàn lè dá sí ìṣòro àìrílégbé, Strategies to Combat Homelessness, tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó ń rí sí ọ̀ràn ilégbèé fáwọn tí kò nílé lórí, ìyẹn United Nations Centre for Human Settlements, tẹ̀ jáde ṣàlàyé pé ohun tó ń jẹ́ àìrílégbé ni kéèyàn “máà ní ilé tó yẹ ọmọlúwàbí láti máa gbé. Ìyẹn ni ipò èyíkéyìí tá a bá ṣáà ti lè kà sí èyí tí kò dáa tó” ládùúgbò tí wọ́n wà. A lè rí lára àwọn aláìrílégbé yìí tí wọ́n ń rìn káàkiri òpópónà tàbí tí wọ́n ń sùn nínú àwókù ilé tàbí àwọn ilé táwọn èèyàn ti pa tì, àwọn míì sì lè máa forí pa mọ́ sáwọn ilé elérò púpọ̀ táwọn afẹ́dàáfẹ́re kọ́. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn míì wà tí wọ́n á wulẹ̀ fìdí hẹ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Èyí ó wù ó jẹ́, ìwádìí kan náà fi hàn pé: “Bá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláìrílégbé, ó fi hàn pé onítọ̀hún wà nínú ipò kan, a sì ‘gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan’ fẹ́ni tó bá wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀.”
Wọ́n fojú bù ú pé lórílẹ̀-èdè Poland, táwọn èèyàn bí ogójì mílíọ̀nù ń gbé, ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000] tí kò nílé lórí. Kò sẹ́ni tó lè sọ bí wọ́n ṣe pọ̀ tó gan-an, torí pé kò síbì kan tí wọ́n ti ń gba orúkọ wọn sílẹ̀, àti pé ṣe ni wọ́n máa ń ṣí káàkiri. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé wọ́n á pọ̀ tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n!
Níwọ̀n bí ìṣòro àìrílégbé ti wọ́pọ̀ káàkiri, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó o mọ̀ wà lára àwọn tí kò rílé gbé. Ìṣòro àwọn aláìrílégbé lè mú ká máa bi ara wa ní
ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Kí ló fà á táwọn èèyàn wọ̀nyí ò fi ní ilé tó bójú mu? Báwo ni wọ́n ṣe ń rí bátiṣé? Ta ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́? Báwo sì lọjọ́ iwájú ṣe máa rí fáwọn aláìrílégbé?Àwọn Tí Kì Í Wọ́n Nílé Àwọn Aláìrílégbé
Àgbègbè kan tí wọ́n ń pè ní Harlem, nílùú New York City, níbi táwọn èèyàn ò ti rí já jẹ ni Sabrina, a ìyá kan tó ń dá tọ́mọ ń gbé. Ọmọ ọlọ́dún kẹrin ni nílé ìwé gíga, nígbà tó filé ìwé sílẹ̀. Ibì kan tí ìjọba ìbílẹ̀ kọ́ fáwọn tó ti pẹ́ tí wọn ò ti rílé gbé ni Sabrina àtàwọn ọmọ ẹ̀ kékeré mẹ́ta ń gbé. Ọmọ ọdún mẹ́wàá lèyí tó ṣàgbà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀, èyí tó pọwọ́ lé e jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta, èyí tó kéré jù lọ sì jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́wàá, gbogbo wọn ló sì jọ ń gbé nínú ilé oníyàrá kan náà. Àwọn tí ò bá ti níbi tí wọ́n lè forí pa mọ́ sí ni ìjọba ìbílẹ̀ máa ń kọ́ irú ilé bẹ́ẹ̀ fún.
Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni Sabrina fúnra rẹ̀ kó jáde nílé tí òun àti ìyá rẹ̀ ń gbé. Látìgbà náà ló sì ti ń gbé káàkiri; ó gbé pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọkùnrin, ó fìgbà kan wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan rẹ̀, nígbà tí nǹkan ò sì wá dára mọ́, ó kúkú kọjá lọ sílé tí ìjọba ìbílẹ̀ kọ́ fáwọn aláìrílégbé. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Mó máa ń di irun tà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ owó ìrànwọ́ tí ìjọba ń pèsè ni mo máa ń gbára lé jù lọ.”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Parents ṣe sọ, ibi tí ọ̀rọ̀ náà wá rọ́pá sí ni pé ìgbà tí Sabrina ríṣẹ́ atúnléṣe ní òtẹ́ẹ̀lì gan-an ni ìṣòro ẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, owó tó ń gbà ti pọ̀ ju tẹni tí ìjọba á tún máa ràn lọ́wọ́ lọ, àmọ́ owó ọ̀hún ò tó gbọ́ bùkátà owó ilé, oúnjẹ, aṣọ, ọkọ̀ àti ti ìtọ́jú ọmọ. Nítorí náà, ó ṣòro fún un láti máa sanwó ilé tó ń gbé, onílé rẹ̀ sì fẹ́ lé e jáde. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Sabrina fiṣẹ́ náà sílẹ̀ ó sì kọ́kọ́ fìgbà díẹ̀ gbé nínú ilé tí ìjọba kọ́ fún ìlò pàjáwìrì kó tó di pé iyàrá ṣí sílẹ̀ fún un níbi tó wà báyìí.
Sabrina sọ pé: “Nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fáwọn ọmọ mi. Àkọ́bí mi ti dán ilé ìwé mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò báyìí. Ó ti yẹ kó wà ní kíláàsì karùn-ún níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ó tún kíláàsì kan kà . . . Ńṣe là ń kó kiri.” Sabrina wà lára àwọn tó ń dúró de àǹfààní àtimáa gbé nínú ilé tí ìjọba ń san lára owó ẹ̀.
Ti Sabrina yìí tún wá sàn lára tàwọn tí ò rílé kankan gbé o. Síbẹ̀, gbogbo àwọn tí kò nílé lórí kọ́ ló gbà pé gbígbé táwọn ń gbé nínú ilé tí ìjọba kọ́ ló máa báwọn fòpin sí ìṣòro ìṣẹ́ àti òṣì. Ohun tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ran Àwùjọ Lọ́wọ́ Nílẹ̀ Poland sọ ni pé àwọn kan “máa ń bẹ̀rù àwọn ìlànà àti òfin tó máa ń wà nírú àwọn ilé bẹ́ẹ̀,” wọn kì í sì í gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń gbé nílé elérò púpọ̀ tí wọ́n kọ́ fáwọn aláìrílégbé gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́, wọn ò sì fẹ́ kí wọ́n máa mu ọtí líle tàbí kí wọ́n lo oògùn olóró. Gbogbo àwọn tó ń gbé níbẹ̀ kọ́ ni òfin yẹn tẹ́ lọ́rùn. Nítorí náà, ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ọdún, èèyàn lè ráwọn aláìrílégbé tí wọ́n ń sùn sí ibùdókọ̀ ojú irin, abẹ́ àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, yàrá abẹ́
ilẹ̀, orí bẹ́ǹṣì láwọn ibùdókọ̀, abẹ́ bíríìjì àti láwọn ibi tí wọ́n kọ́lé iṣẹ́ sí. Jákèjádò ayé la sì ń rí irú àwọn nǹkan báyìí tó ń ṣẹlẹ̀.Ìwé kan tó sọ nípa àìrílégbé la ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣeé ṣe kó máa fa ìṣòro àìrílégbé lórílẹ̀-èdè Poland lẹ́sẹẹsẹ. Lára àwọn nǹkan náà ni kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èèyàn, kéèyàn wọ gbèsè àtàwọn ìṣòro ìdílé. Kò sí ilé tó pọ̀ tó fáwọn àgbàlagbà, àwọn aláàbọ̀ ara àtàwọn tó ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìrílégbé máa ń ní ìdààmú ọpọlọ, àìlera tàbí ìṣòro sísọ nǹkan di bárakú, pàápàá jù lọ ọtí mímu. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn obìnrin tí kò rílé gbé ló sá kúrò nílé ọkọ, ńṣe ni wọ́n lé àwọn míì kúrò nínú ilé wọn, tàbí kí wọ́n ti ṣe aṣẹ́wó rí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo aláìrílégbé ló ní ohun tó ń bà wọ́n nínú jẹ́.
Àwọn Tó Bára Wọn Nípò Àìrílégbé
Ọ̀mọ̀wé Stanisława Golinowska, ògbógi nínú ìmọ̀ ìṣúnná owó àti àjọṣe ẹ̀dá, sọ pé: “[Lórílẹ̀-èdè Poland] níbí, kò sẹ́ni tó wù kó máà rí ilé gbé. . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, onírúurú ìkùnà nínú ìgbésí ayé ló ń fà á, èyí tó máa ń da àwọn èèyàn lọ́kàn rú títí débi tí ayé á fi sú wọn.” Ó dà bíi pé àwọn èèyàn tó sábà máa ń di aláìrílégbé làwọn tó jẹ́ pé, onírúurú nǹkan ló máa ń mú kó ṣòro fún wọn láti kojú ìṣòro tó ń bá wọn fínra. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà táwọn kan tẹ̀wọ̀n dé ni wọ́n rí i pé àwọn bàsèjẹ́ èèyàn ti fọ́lé àwọn. Ńṣe ni wọ́n lé àwọn míì jáde kúrò nílé. Ọ̀pọ̀ ló sì jẹ́ pé ìjábá ló sọ wọ́n dẹni tí ò nílé lórí mọ́. b
Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára àwọn aláìrílégbé tá a ṣèwádìí wọn lórílẹ̀-èdè Poland táwọn náà ti jùmọ̀ gbé pẹ̀lú ìdílé, aya, tàbí ọkọ wọn rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń ní ìṣòro ìdílé lemọ́lemọ́. Èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni wọ́n lé jáde kúrò nílé tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ní láti fi ilé sílẹ̀ tipátipá nígbà tí ìṣòro fẹ́ gbẹ̀mí wọn. Ìdá mẹ́rìnlá péré nínú ọgọ́rùn-ún làwọn tó dìídì pinnu pé àwọn á filé sílẹ̀.
Lẹ́yìn táwọn kan bá ti gbé fúngbà díẹ̀ nílé tí wọ́n kọ́ fáwọn aláìrílégbé, ó máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti dá gbọ́ bùkátà ara wọn lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n á sì lè wá ilé tí wọ́n á máa gbé. Àmọ́, àwọn kan wá wà tó jẹ́ pé ńṣe lọ̀ràn tiwọn túbọ̀ máa ń ṣòro yanjú. Lára ohun tó ń fà á tírú wọn fi máa ń dẹni tí ò ríbi gbé rárá ni ìdààmú ọpọlọ tàbí àìlera ara, ìlòkulò oògùn tàbí àmujù ọtí, ó sì lè jẹ́ nítorí pé iṣẹ́
kì í wù wọ́n ṣe, kí wọ́n máa ṣe àjàǹbàkù iṣẹ́, àìkàwé tó, tàbí kí oríṣiríṣi nǹkan tí ò dáa pé sí wọn lára. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, bí èèyàn mẹ́ta lára èèyàn mẹ́wàá tí ò nílé lórí ni kì í wọ́n nílé àwọn aláìrílégbé, bára wọn ò bá le, wọ́n á gbé wọn lọ sí ọsibítù, bí wọ́n bá ṣìwà hù, wọ́n á sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, bí wọ́n bá tẹ̀wọ̀n dé, wọ́n á tún gba ilé àwọn aláìrílégbé lọ. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé àwọn tó jẹ́ pé ìrànwọ́ tí wọ́n ń rí nílé àwọn aláìrílégbé yìí ni wọ́n gbára lé máa ń lò tó ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá lára owó àtàwọn nǹkan tí ìjọba yà sọ́tọ̀ nítorí ìṣòro àìrílégbé.Ṣé Lóòótọ́ Ni Wọ́n Ń Ran Àwọn Aláìrílégbé Lọ́wọ́?
Láwọn ilé kan tí wọ́n kọ́ fáwọn aláìrílégbé, wọ́n máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dẹni tó bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro àìrílégbé. Wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ ìjọba àti ìrànlọ́wọ́ owó láwọn ọ̀nà mìíràn, wọ́n lè bá wọn fi ẹsẹ̀ òfin tọ ọ̀ràn wọn, wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè wá àwọn aráalé wọn kàn, tàbí kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè kọ́ṣẹ́ ọwọ́. Ní ibùdó tí wọ́n kó àwọn ọ̀dọ́ tí kò rílé gbé sí nílùú London, wọ́n máa ń gbà wọ́n nímọ̀ràn lórí onírúurú oúnjẹ tó dáa fára, oúnjẹ gbígbọ́, béèyàn ṣe lè máa gbé ìgbé ayé táá mú kára ẹ̀ le dáadáa àti béèyàn ṣe lè ríṣẹ́. Ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fún wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n ka ara wọn kún, kóríyá ló jẹ́ fún wọn, irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lè dá dúró kí wọ́n bàa lè wá ibi tí wọ́n á máa gbé, kí wọ́n má sì ṣe jẹ́ kó bọ́ mọ́ àwọn lọ́wọ́. Dájúdájú, ó yẹ ká ṣọpẹ́ nítorí irú àwọn ìpèsè bẹ́ẹ̀.
Àmọ́ ṣá o, gbogbo ìgbà kọ́ làwọn aláìrílégbé ń rí irú ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n rò pé àwọn nílò jù lọ gbà nínú ilé tí wọ́n kọ́ fáwọn aláìnílélórí. Jacek, tó jẹ́ aláìrílégbé nílùú Warsaw, ṣàlàyé pé gbígbé téèyàn ń gbé níbẹ̀ kì í kọ́ni bí ìgbésí ayé ìta á ṣe mọ́ni lára. Ó lérò pé ṣíṣe táwọn tó wà níbẹ̀ ń ṣe wọlé wọ̀de, tí wọ́n sì jọ ń finú konú, á mú kí wọ́n dẹni tí “ìrònú wọn pọ̀n sọ́nà kan.” Ó sọ pé, “Ńṣe ni ilé tí wọ́n dé wa mọ́, tá ò sì mọ ohun tó ń lọ lẹ́yìn òde dà bí ìgbà tí wọ́n kó àwa àgbà jọ sílé àwọn ògo wẹẹrẹ.” Lójú tiẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ “ni ìrònú wọn ò já geere mọ́.”
Bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Poland ṣe fi hàn, dídáwà lohun tó máa ń dun àwọn aláìrílégbé lọ́kàn jù lọ. Nítorí ìṣòro àìrówóná àti àìrọ́wọ́mú láwùjọ, àwọn aláìrílégbé sábà máa ń wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àwọn míì máa ń fi ọtí pàrònú rẹ́. Jacek sọ pé: “Bí ọ̀pọ̀ lára wa bá ti rí i pé ipò wa ò lè yí padà mọ́, a ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì pé bóyá ni ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti mú kí ipò wa sunwọ̀n sí i.” Bí wọ́n ṣe rí, ipò òṣì wọn àti àìmọ ohun tí wọ́n lè ṣe, tó fi mọ́ bí wọn ò ṣe rílé gbé máa ń tì wọ́n lójú gan-an.
Ọ̀gbẹ́ni Francis Jẹ́gẹ́dẹ́, tó mọwá mẹ̀yìn báwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ tó, sọ pé: “Yálà àwọn ọmọ tó ń gbélé pákó nílùú Bombay [Mumbai] àti nílùú Calcutta là ń sọ ni o, tàbí àwọn ọmọ asùnta tó ń gbé lójú pópó nílùú London, tàbí àwọn ọmọ ajẹ̀gboro tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil, ohun tó dájú ni pé ìṣòro burúkú gbáà nìṣòro àìrílégbé, kò sì ṣeé máa ronú kan nítorí pé ó ń bani lọ́kàn jẹ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé kó ṣẹlẹ̀ síni. Ohun yòówù kó fa ọ̀ràn àìrílégbé, ìbéèrè tí kì í yé wá síni lọ́kàn ni pé, kí ló fà á tó jẹ́ pé nínú ayé tí ọrọ̀, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ẹ̀rọ pọ̀ sí yìí, ṣe ló dà bíi pé apá ò lè ká ìṣòro àìrílégbé?”
Ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn aláìrílégbé ló nílò ìrànlọ́wọ́, kì í wá ṣe ìrànlọ́wọ́ nípa tara nìkan, wọ́n tún nílò irú ìrànlọ́wọ́ tó lè tu ọkàn wọn lára tí kò sì ní gbé wọn lẹ́mìí sókè. Irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ lè fáwọn èèyàn lókun láti kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń pa kún ìṣòro àìrílégbé kí wọ́n sì borí àwọn ìṣòro náà. Ṣùgbọ́n ibo làwọn aláìrílégbé ti lè rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀? Ìrètí wo ló sì wà pé ọjọ́ kan á jọ́kan tí ìṣòro àìrílégbé ò ní sí mọ́?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.
b Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé ni ètò ìṣèlú tí kò fara rọ tàbí ogun ti sọ dẹni tó sá fi ilé sílẹ̀. Bó o bá fẹ́ kà nípa ìṣòro wọn, jọ̀wọ́ wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn olùwá-ibi-ìsádi nínú ìwé ìròyìn Jí! February 8, 2002.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ohun Tí Òṣì Paraku Ń Fà
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń gbé lójú pópó lórílẹ̀-èdè Íńdíà. Àwọn àfojúbù tí wọ́n ṣe nígbà kan rí fi hàn pé ó tó bí ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] èèyàn tó ń gbé níta gbalasa láàárín ilé méjì, nílùú Mumbai nìkan ṣoṣo. Gbogbo ilé wọn ò ju kí wọ́n ri igi mọ́lẹ̀, kí wọ́n da tapólì bò ó, kí wọ́n sì so tapólì náà mọ́ ara ilé míì tó wà ládùúgbò. Kí ló dé tó jẹ́ ibí yìí ni wọ́n ń gbé dípò kí wọ́n máa gbé níbi tílé olówó pọ́ọ́kú wà lẹ́bàá ẹ̀yìn odi ìlú? Ìdí ni pé lẹ́bàá ìgboro ìlú yìí ni wọ́n ti ń ta wóróbo, tí wọ́n ń kiri ọjà, tí wọ́n ń ti ọmọlanke, tí wọ́n sì ń ṣa nǹkan àlòkù kiri. Ìwé ìròyìn Strategies to Combat Homelessness sọ pé, “wọ́n ò rọ́gbọ́n míì dá sí i ni. Ipò òṣì ló sún wọn débi tí wọn ò fi lè náwó tó yẹ kí wọ́n fi jẹun sórí à ń háyà ilé.”
Tọkùnrin tobìnrin àtàwọn ọmọdé tí wọ́n ń gbé ní Ibùdókọ̀ Park tó wà nílùú Johannesburg, lórílẹ̀-èdè South Africa, tó ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbàá [2,300]. Wọ́n máa ń sùn sórí ibi táwọn èèyàn máa ń dúró sí wọkọ̀ ojú irin, orí àjákù aṣọ ibùsùn tàbí àjákù páálí ni wọ́n ń sùn. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ò níṣẹ́, wọ́n sì ti gbà pé bóyá làwọn lè ríṣẹ́ ṣe. Ibi tí kò níláárí bẹ́ẹ̀ náà ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń gbé káàkiri ìlú yẹn. Wọn ò lómi, wọn ò nílé ìgbọ̀nsẹ̀, wọn ò sì ní iná mànàmáná. Bó bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kòkòrò àrùn tètè máa ń ràn.
Ohun tó fà á tí àwùjọ èèyàn méjì yìí, àtàwọn míì tọ́rọ̀ wọn rí bẹ́ẹ̀, ò fi rílé gbé ò ṣòro láti lóye, òtòṣì paraku ni wọ́n.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ibi Táwùjọ Òde Òní Ti Kùnà
Ìwé Strategies to Combat Homelessness, tí àjọ tó ń rí sọ́ràn ibùgbé ẹ̀dá lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn United Nations Centre for Human Settlements, gbé jáde sọ àwọn ibi mélòó kan tí ètò tí wọ́n gbé kálẹ̀ láwùjọ, ètò ìṣèlú àti ètò ìṣúnná owó ti kùnà lórí ọ̀ràn pípèsè ibùgbé fún gbogbo èèyàn. Lára wọn nìwọ̀nyí:
● “Olórí ohun tó ṣì ń fa ìṣòro àìrílégbé ni pé ìjọba ò lè náwó tó pọ̀ tó débi táwọn èèyàn á fi lè máa gbé nínú ilé tó dáa tó.”
● “Òfin tí kò bójú mu àti ètò tí kò mọ́yán lórí lè . . . fa ìṣòro tí ò ní jẹ́ kí ilé tó wà kárí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó tòṣì.”
● “Àìrílégbé jẹ́ àmì pé wọn ò lo owó tí ìjọba ń ná lórí ilé gbígbé dáadáa lọ́nà tó fi máa kárí láwùjọ.”
● “Ohun tó máa ń fa àìrílégbé ni bí wọ́n ṣe máa ń ṣètò tó lè kó bá ọrọ̀ ajé, tó lè mú káwọn èèyàn máà rówó gbalé, tó lè mú kí ìlòkulò oògùn pọ̀ sí i, èyí tó lè fa ìlera àti ìdààmú ọpọlọ fáwọn tọ́ràn náà kàn jù . . . láwùjọ, láìfi ti ohun tó lè yọrí sí pè.”
● “Ó ti wá túbọ̀ ṣe pàtàkì báyìí pé kí ìdálẹ́kọ̀ọ́ máa gorí ìdálẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó ń tọ́jú àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n di aláìrílégbé. Àwọn èèyàn tí kò rílé gbé, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdé tó ń jẹ̀gboro, la gbọ́dọ̀ kà sí ẹni tó lè ran àwùjọ lọ́wọ́ lẹ́yìn ọ̀la, dípò tá a ó fi máa wò wọ́n bí adẹ́rùpọkọ̀.”
[Àwòrán]
Ìyá kan tó ń tọrọ owó àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò
[Credit Line]
© Fọ́tò tí Mark Henley/ Panos Pictures yà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ibùdókọ̀ ojú irin nibí yìí tẹ́lẹ̀, ṣe ni wọ́n sọ ọ́ di ilé elérò púpọ̀ fáwọn aláìrílégbé nílùú Pretoria, lórílẹ̀-èdè South Africa
[Credit Line]
© Fọ́tò tí Dieter Telemans/Panos Pictures yà
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Lápá òsì: © Fọ́tò tí Gerd Ludwig/Visum/Panos Pictures yà; tinú àkámọ́: © Fọ́tò tí Mikkel Ostergaard/Panos Pictures yà; lápá ọ̀tún: © Fọ́tò tí Mark Henley/Panos Pictures yà