Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ebi Lè Tán Láyé?

Ǹjẹ́ Ebi Lè Tán Láyé?

Ǹjẹ́ Ebi Lè Tán Láyé?

WO BÓ ṣe máa rí lára bàbá kan tí kì í fọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀ ṣeré, tó bá rí i pé wọn ò róúnjẹ jẹ kánú. Ó máa dùn ún dé ìsàlẹ̀ ikùn rẹ̀ gan-an ni. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ náà ṣe ń rí lára obí tó jẹ́ èèyàn nìyẹn, ronú nípa bó ṣe máa rí lára Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ tó wà lọ́run. Kò sí ohun tó ṣókùnkùn sí i nípa ìyà tó ń jẹ ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí ò lè jẹun kánú.

Pẹ̀lú èròǹgbà rere táráyé ní láti pèsè oúnjẹ fáwọn tébi ń pa láyé níbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlélógún yìí, ṣe ni ìṣòro ebi ń pọ̀ sí i. Àmọ́, Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà, lágbára láti wá nǹkan ṣe láti gbá ebi wọlẹ̀ pátápátá, ó sì máa ṣe é. Báwo la ṣe mọ̀?

Bíbélì ṣàlàyé pé nígbà tí Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà sínú ọgbà Édẹ́nì, ó fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti lè wà láìléwu, nínú ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n á sì máa jẹ àjẹyó. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Mo ti fi gbogbo ewéko tí ń mú irúgbìn jáde fún yín, èyí tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ni pé kí wọ́n “kún ilẹ̀ ayé” kí gbogbo onírúurú èèyàn sì ní ànító àti àníṣẹ́kù ohun rere láti jẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 29.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn tí wọ́n sì pàdánù ojú rere rẹ̀, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ìran èèyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò tíì yí padà. Bíbélì sọ pé Jèhófà ni “Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa,” ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló sì wà nínú Bíbélì pé ó máa mú gbogbo ìṣòro tó ń mú kí oúnjẹ wọ́n kúrò.—Sáàmù 146:7.

Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bi í léèrè nípa àmì tàbí ẹ̀rí táá fi hàn pé ó máa gbé Ìjọba rẹ̀ táá máa bójú tó ọ̀ràn ayé yìí kalẹ̀, Jésù to àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìyẹn lẹ́sẹẹsẹ. Ọ̀kan lára wọn ni “àìtó oúnjẹ.” Tá a bá yẹ ọ̀rọ̀ Jésù yẹn wò kínníkínní, á dá wa lójú pé ìyà tó ń jẹ aráyé kò ní pẹ́ dópin. aMátíù, orí 24.

Sáàmù 72:16 sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Párádísè tí Ọlọ́run máa tó gbé kalẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” Láyé àtijọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ọkà máa ń lalẹ̀ hù láwọn àfonífojì ni. Àmọ́ nígbà tí ìbùkún tí asọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ bá dé, téèyàn bá gbin oúnjẹ sí ilẹ̀ tó ti ṣá pátápátá tó sì ti gbẹ tí kò sì ní ọ̀rá kankan, ìyẹn níbi tí nǹkan kò ti lè hù báyìí, ńṣe ló máa so jìngbìnnì. Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nípa Bíbélì sọ pé: “Nígbà ìjọba Mèsáyà, ṣe ló máa dà bíi pé ọkà so sí tọ̀tún tòsì lọ bẹẹrẹbẹ tàbí kó dà bí ìgbà téèyàn bá gbin ọkà sórí òkè títí tó fi dé téńté orí ẹ̀, tó wá rí bíi pé gbogbo ilẹ̀ ayé ló kún fún ọkà tí pòròpórò rẹ̀ ti tó kórè, tó wá ń mì láálo láálo.”

Àbí ẹ ò rí ìyàtọ̀ ńlá gbáà tó wà láàárín ọjọ́ iwájú tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ àtohun tójú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń rí lónìí! Ìyàtọ̀ náà ga, lọ́jọ́ iwájú tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wa, “ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”—Sáàmù 67:6.

Bó o bá fẹ́ kọ́wọ́ rẹ àti tàwọn tó o fẹ́ràn tẹ àwọn ìbùkún yìí àtàwọn míì tó ń múnú ẹni dùn, èyí tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀, má ṣàfira, tètè tọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ lọ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó bá sún mọ́ ọ jù lọ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìjíròrò lórí bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣe nímùúṣẹ wà ní orí kọkànlá ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]