Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Wàá rí àwọn ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 13. Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.)

1. Ta ló ra hòrò Mákípẹ́là lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìnkú, àwọn mélòó sì ni Bíbélì sọ pé wọ́n sin síbẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 49:30-33; 50:13)

2. Nígbà táwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Dáfídì ń bá àwọn Filísínì jagun, kí nìdí tí wọ́n fi fi dandan lé e pé Dáfídì kò gbọ́dọ̀ bá àwọn lọ sógun mọ́? (2 Sámúẹ́lì 21:15-17)

3. Igi olóòórùn dídùn wo ló jẹ́ pé inú ìwé Orin Sólómọ́nì nìkan ló wà? (Orin Sólómọ́nì 1:14; 4:13; 7:11)

4. Kí ni Gídíónì lò kó bàa lè dá a lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á tipasẹ̀ rẹ̀ gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là? (Àwọn Onídàájọ́ 6:36-40)

5. Kí là ń pe ìkòkò bàbà ńlá táwọn àlùfáà máa ń wẹ̀ nínú rẹ̀, nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì? (2 Kíróníkà 4:6)

6. Èwo ló wúwo jù tó sì tún níye lórí jù lára ìwọ̀n táwọn Hébérù fi ń wọn owó? (Ẹ́sírà 8:26)

7. Kí ló bẹ́ sílẹ̀ lọ́run lẹ́yìn ìbí Ìjọba Ọlọ́run? (Ìṣípayá 12:7)

8. Ibo ni Jésù sọ pé yóò rọrùn jù fún ràkúnmí láti gbà kọjá “jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run”? (Mátíù 19:24)

9. Kí ni Jésù pe àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí nítorí pé wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? (Mátíù 15:14)

10. Ọba Síríà wo ló kó àwọn Júù kúrò ní Élátì tí í ṣe ìlú àwọn ará Jùdíà, èyí tó mú kí Áhásì Ọba ké gbàjarè pé kí ọba Ásíríà ran òun lọ́wọ́? (2 Àwọn Ọba 16:6, 7)

11. Èwo nínú àwọn ìyàwó Dáfídì Ọba ló bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ítíréámù fún un? (2 Sámúẹ́lì 3:5)

12. Nígbà tí Jósẹ́fù ní kí ìránṣẹ́ òun lépa àwọn arákùnrin òun kí wọ́n sì bá òun gba ife òun tó sọ nù wá, ibo ni wọ́n ti rí ife náà? (Jẹ́nẹ́sísì 44:12)

13. Àtọmọdọ́mọ Kálébù wo, tí Bíbélì fi èdè àbùkù ṣàpèjúwe pé ó le koko, ó burú, kò dára fún ohunkóhun rárá, ó sì jẹ́ òpònú ni Jèhófà kọlù tó sì kú? (1 Sámúẹ́lì 25:3, 17, 25, 36-38)

14. Ohun ìjà táwọn Hébérù sábà máa ń lò wo ni Fíníhásì fi gún Símírì àti Kọ́síbì ní àgúnyọ, tí òjòjò àrànkálẹ̀ tó pa ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ọmọ Ísírẹ́lì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù fi dáwọ́ dúró? (Númérì 25:6-15)

15. Àwọn ohun mẹ́rin wo ni Ágúrì rí i pé wọ́n jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún òun láti mọ̀? (Òwe 30:18, 19)

16. Kí ni Bíbélì lò láti fi ṣàpèjúwe àṣẹ táwọn òbí ní lórí àwọn ọmọ wọn? (Òwe 29:15)

17. Ohun èlò iṣẹ́ àgbẹ̀ wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń lò láti ro èpò dà nù? (Aísáyà 7:25)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Ábúráhámù. Èèyàn mẹ́fà: Sárà, Ábúráhámù, Ísákì, Rèbékà, Jékọ́bù àti Léà

2. Nítorí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, Iṣibi-bénóbù, tó jẹ́ ọ̀kan lára òmìrán àwọn Filísínì, sì ń wá bó ṣe máa ṣá a balẹ̀

3. Làálì

4. Ìṣùpọ̀ irun àgùntàn

5. “Òkun”

6. Tálẹ́ńtì

7. Ogun

8. “Ojú abẹ́rẹ́”

9. “Afọ́jú afinimọ̀nà”

10. Résínì

11. Ẹ́gílà

12. “Nínú àpò Bẹ́ńjámínì”

13. Nábálì

14. Aṣóró

15. “Ọ̀nà idì ní ojú ọ̀run, ọ̀nà ejò lórí àpáta, ọ̀nà ọkọ̀ òkun ní àárín òkun àti ọ̀nà abarapá ọkùnrin pẹ̀lú omidan”

16. Ọ̀pá

17. Ọkọ́