Wàhálà Tó Wà Nínú Kíkó Oúnjẹ Wọnú Ìlú Ńláńlá
Wàhálà Tó Wà Nínú Kíkó Oúnjẹ Wọnú Ìlú Ńláńlá
“Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni láti pèsè oúnjẹ tó máa tó bọ́ àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ìlú ńláńlá láyé, wàhálà ọ̀hún sì ń pọ̀ sí i ni débi tó fi pọn dandan pé káwọn ilé iṣẹ́ oúnjẹ, àwọn ọlọ́kọ̀, àwọn alájàpá àti ogunlọ́gọ̀ àwọn aláròóbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀.” —JACQUES DIOUF, OLÙDARÍ ÀGBÀ FÚN ÀJỌ FOOD AND AGRICULTURE ORGANIZATION OF THE UNITED NATIONS, LÓ SỌ̀RỌ̀ YÌÍ.
KÓDÀ, àwọn tó mọ̀ nípa bí oúnjẹ ṣe ń wọ̀lú sọ pé àtirí oúnjẹ táá máa tó àwọn tó ń gbé nílùú ńláńlá jẹ láìsọsẹ̀ máa tó di “olórí ìṣòro tó ń kojú ọmọnìyàn” ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí.
Àwọn kan sọ pé ká tó lè fọkàn balẹ̀ lórí oúnjẹ, “gbogbo ìgbà ni gbogbo èèyàn pátá gbọ́dọ̀ máa rí oúnjẹ tó tó jẹ débi tára wọn á fi lè máa gbé kánkán.” Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, oúnjẹ tó wà láyé lápapọ̀ tó láti bọ́ gbogbo aráyé, ìyẹn bí wọ́n bá ń pín in fún kálukú ní ìwọ̀n tó nílò. Àmọ́, ohun tá a rí báyìí ni pé òjìlélẹ́gbẹ̀rin mílíọ̀nù [840,000,000] èèyàn ni kì í róúnjẹ gidi jẹ sùn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń gbé ní ìlú ńláńlá. Wo díẹ̀ lára ẹ̀ka tí ìṣòro náà pín sí.
Kékeré Kọ́ Loúnjẹ Tí Wọ́n Ń Jẹ Nílùú Térò Pọ̀ Sí
Bí èrò ṣe ń pọ̀ sí i láwọn ìlú ńláńlá, ṣe ni wọ́n ń kọ́ ilé àti iléeṣẹ́ sórí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn tẹ́lẹ̀ létí àwọn ìlú náà, wọ́n sì tún la ọ̀nà síbẹ̀. Bó ṣe di pé ilẹ̀ tí wọ́n lè fi dáko oúnjẹ táwọn ará ìlú á jẹ túbọ̀ ń jìnnà sáwọn ìlú ọ̀hún nìyẹn. Wọn kì í sábà gbin oúnjẹ sáàárín ìlú ńláńlá, tá a bá sì rí ibi tí wọ́n gbìn ín sí, ìwọ̀nba ni. Àwọn ìlú kéékèèké tó wà lọ́nà jíjìn ni wọ́n sì ti ń lọ gbé ẹran wá. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ojú ọ̀nà táwọn irè oko ń gbà wọnú ìlú ò dáa. Èyí sì máa ń mú kó gba àkókò púpọ̀ sí i láti gbé oúnjẹ wọ̀lú, ọ̀pọ̀ nínú oúnjẹ ọ̀hún láá ti bàjẹ́ lójú ọ̀nà, ìyẹn á sì wá mú kó túbọ̀ gbówó lórí nígbà tó bá fi máa dé ọ̀dọ̀ àwọn tó máa rà á, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọ̀pọ̀ wọn ni ò rí já jẹ.
Àwọn ìlú ńlá kan wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, térò pọ̀ sí bí omi tí wọn ò sì ní yé pọ̀ sí i. A retí pé tó bá fi máa di ọdún 2015, èrò tó wà ní ìlú Mumbai (tí wọ́n ń pè ní Bombay tẹ́lẹ̀) á ti di mílíọ̀nù méjìlélógún ó lé ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ti ìlú Delhi á ti di ogún mílíọ̀nù àti ọ̀kẹ́ márùnlélógójì, ti ìlú Mexico City á ti di ogún mílíọ̀nù àti ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, nígbà tí èrò tó wà ní ìlú São Paulo á sì ti di ogún mílíọ̀nù. Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé, lójoojúmọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ máa kó oúnjẹ tó pọ̀ tó èyí táá gba ẹgbẹ̀rún ọkọ̀ akóyọyọ wọnú àwọn ìlú ńláńlá térò inú wọn tó mílíọ̀nù mẹ́wàá, irú ìlú bẹ́ẹ̀ sì ni Manila tàbí Rio de Janeiro.
Iṣẹ́ kékeré kọ́ lèyí o, ṣe ló sì ń nira sí i, pàápàá láwọn ibi táwọn èèyàn ti ń yára pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ nílùú Lahore, lórílẹ̀-èdè Pakistan, wọ́n kàn ń bímọ bẹẹrẹbẹ ni, bíi mẹ́ta nínú ìdá ọgọ́rùn-
ún àwọn tó ń gbébẹ̀ ni wọ́n ń bí lọ́dọọdún. Kì í ṣèyẹn nìkan, bí omi làwọn èèyàn ń ya lọ síbẹ̀ látàwọn ìlú kéékèèké, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sọ pé yíya tí wọ́n ń ya lọ yìí ń kó wọn sínú ìdágìrì. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń ya lọ sáwọn ìlú ńlá tó ti kún jù tẹ́lẹ̀ lérò pé ìgbésí ayé á rọrùn díẹ̀ sí i fáwọn, àwọn á ríṣẹ́, àwọn á máa rí ọjà rà àwọn á sì máa ráwọn àǹfààní míì jẹ. Nítorí báwọn èèyàn ṣe ń ṣe báyìí rọ́ lọ sáwọn ìlú ńlá, a retí pé láìpẹ́ láìjìnnà, èrò ìlú Dhaka, lórílẹ̀-èdè Bangladesh á máa fi bíi mílíọ̀nù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ìdá méjì nínú mẹ́tà ìlú tó wà lórílẹ̀-èdè Ṣáínà ló jẹ́ ìlú kékeré, àmọ́ àwọn ìṣirò tí wọ́n fi wòye ọjọ́ iwájú fi hàn pé tó bá fi máa di ọdún 2025, á ti di kìkì ìlú elérò púpọ̀. Wọ́n retí pé ní àkókò kan náà yẹn, iye àwọn táá máa gbé láwọn ìlú ńlá lórílẹ̀-èdè Íńdíà á ti di ẹgbẹ̀ta mílíọ̀nù.Báwọn èèyàn ṣe ń tinú ìlú kéékèèké ya lọ sáwọn ìlú ńláńlá ń mú kí ìyípadà dé bá báwọn ìlú ṣe rí lápá ibi tó pọ̀ jù lọ láyé. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1960, tá a bá fi gbogbo àwọn tó ń gbé lápá Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà dá ọgọ́rùn-ún, mẹ́rìnlá péré nínú wọn ló ń gbé láwọn ìlú ńláńlá. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1997, wọ́n ti di ìdá méjì nínú márùn-ún, tó bá sì máa di ọdún 2020, wọ́n á ti lé ní ìdá mẹ́ta nínú márùn-ún. Láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìkángun ìlà oòrùn Áfíríkà, wọ́n retí pé tó bá fi máa di ọdún mẹ́wàá sígbà tá a wà yìí, àwọn tó wà níbẹ̀ á ti di ìlọ́po méjì. Wọ́n sì fojú bù ú pé láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá iye táwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà á fi pọ̀ sí i ló máa wáyé láàárín ìlú kéékèèké àti ìlú ńláńlá.
Àtifi kún oúnjẹ tó ń ti oko wá débi tá a ó fi
máa róúnjẹ bọ́ adúrú èrò tó pọ̀ báyìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ kékeré. Ó gba pé kí ẹgbàágbèje àgbẹ̀, àwọn tó ń di ẹrù sọ́kọ̀, àwọn ọlọ́kọ̀ ẹrù, àwọn oníṣòwò àtàwọn tó ń se oúnjẹ tà pawọ́ pọ̀, èyí á sì tún gba lílo ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ọkọ̀. Síbẹ̀, láwọn ibì kan, bí oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ láwọn ìlú ńláńlá ṣe ń pọ̀ sí i, ó túbọ̀ ń kọjá agbára àwọn ìlú tó wà nítòsí wọn láti pèsè oúnjẹ tí wọ́n nílò. Yàtọ̀ síyẹn, nínú èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìlú ńláńlá láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn nǹkan tí wọ́n nílò láti jẹ́ kóúnjẹ máa wọ̀lú, bí ètò ìrìnnà àtàwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú oúnjẹ sí, ọjà àti odò ẹran kò tó wọn lò mọ́.Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ni Òtòṣì
Ìṣòro tó wà nínú pípèsè oúnjẹ fún wọn láwọn ìlú térò ibẹ̀ ń pọ̀ sí i túbọ̀ máa ń díjú tí òtòṣì bá pọ̀ láwọn ìlú náà. Ó tó ìdajì, tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn tó ń gbénú àwọn ìlú ńláńlá bíi Dhaka, Freetown, Guatemala City, Èkó àti La Paz tí wọn ò rọ́wọ́ họrí.
Nígbà táwọn òǹwòye ń sọ̀rọ̀ nípa bí oúnjẹ á ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí, wọ́n sọ pé ọ̀tọ̀ ni kí oúnjẹ wà, ọ̀tọ̀ ni kí gbogbo èèyàn rí i jẹ. Oúnjẹ lè wà lọ́jà láwọn ìlú ńlá, àmọ́ ṣebí owó ni wọ́n á fi rà á, tí iye tí wọ́n ń dá a lé e bá kọjá agbára àwọn mẹ̀kúnnù tó wà nílùú ńkọ́? Wọ́n ti kíyè sí i pé bówó tó ń wọlé sápò àwọn kan tó ń gbé nílùú ńlá bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á ṣe máa táwọ́ sí oúnjẹ tó pọ̀ sí i tí wọ́n á sì máa jẹ oríṣiríṣi oúnjẹ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, káwọn tálákà tó wà láàárín ìlú wọ̀nyí tó lè rówó ra oúnjẹ tó máa tó wọn, ikun imú wọn tọ̀tún á fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ sí tòsì. Irú àwọn ìdílé tó tálákà báyìí lè ná ìdá mẹ́ta tàbí mẹ́rin nínú márùn-ún lára owó tó ń wọlé fún wọn lórí oúnjẹ nìkan.
Bóyá owó tí wọ́n ń ná lórí oúnjẹ ì bá dín kù ká ní wọ́n ń ra púpọ̀ lẹ́ẹ̀kan; àmọ́, ìyẹn ò lè ṣeé ṣe bówó ò bá tówó. Oúnjẹ tí wọ́n tiẹ̀ ń jẹ ní ọ̀pọ̀ ilé míì kò tó èyí tó yẹ kọ́mọ èèyàn máa jẹ, èyí sì ti mú kí àìjẹunrekánú máa bá wọn jà. Ọ̀kan lára irú ibi bẹ́ẹ̀ làwọn ìlú kan tó wà lápá gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà nílẹ̀ Áfíríkà, níbi tí àìjẹunrekánú ti “di ìṣòro tó gbalé gbòde.”
Àwọn tó ṣeé ṣe kí ìyà yìí jẹ jù làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti àwọn ìlú kéékèèké, tí ìgbésí ayé láwọn ìlú ńláńlá kò tíì mọ́ lára. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ làwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ṣì jẹ́ ọmọọṣẹ́ tó jẹ pé wọn kì í tètè rówó oṣù gbà torí bí owó ṣe ń tá ìjọba lọ́wọ́, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn arúgbó àtàwọn tára wọn ò le. Etí ìlú ni irú àwọn wọ̀nyí máa ń rí gbé, níbi tí kò ti sí àwọn ohun amáyédẹrùn bí iná mànàmáná, omi ẹ̀rọ, ọ̀nà tómi ẹ̀gbin ń gbà kọjá, ojú ọ̀nà àti ibi tí wọ́n lè dalẹ̀ sí. Àwọn ilé tí kò lágbára tàbí tó léwu làwọn èèyàn wọ̀nyí sì ń gbé. Ẹgbàágbèje èèyàn tó ń tiraka kọ́wọ́ tó tẹ́nu nínú irú ipò báyìí ni ebi lè tètè táwọ́ sí tí wàhálà kan bá ṣẹlẹ̀ tóúnjẹ ò sì wọ̀lú bó ṣe yẹ. Ọjà tó sún mọ́ etílé jù lọ sábà máa ń jìnnà sírú àwọn wọ̀nyí kò sì sí ohun tí wọ́n lè ṣe ju pé kí wọ́n máa fi owóbówó ra àṣàkù oúnjẹ lọ. Ojú àwọn wọ̀nyí mà ń rí nǹkan o.
Àìbalẹ̀ Ọkàn àti Ẹ̀gbin Oúnjẹ
Ní ọ̀pọ̀ ibi, ó sábà máa ń wọ́pọ̀ pé kérò kàn ṣáà máa yára wọ́ jọ sí ìlú ńlá kan láìsí ètò, gbígbé wọn níbẹ̀ kò sì bófin mu. Ohun tó máa ń tẹ̀yìn irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yọ ni pé wọ́n á máa jẹ ẹ̀gbin mọ́ oúnjẹ, ìwà ọ̀daràn tó pọ̀ níbẹ̀ kò sì ní jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀. Ìwé kan tí àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ kọ, ìyẹn Feeding the Cities, sọ pé: “Lóòrèkóòrè làwọn alákòóso ìlú láwọn orílẹ̀-èdè tó
ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ń ṣe làálàá láti bójú tó èrò tó ń pọ̀ sí i láwọn ibi tí kò lè gba èrò tó pọ̀ tó iye àwọn tó ń gbébẹ̀.”Níbi tó pọ̀ jù nílẹ̀ Áfíríkà, wọn kì í ṣètò inú ọjà dáadáa, ṣe làwọn èèyàn kàn ṣáà máa ń kóra jọ síbẹ̀. Àwọn ọlọ́jà á kàn dédé gbé ọjà wọn kalẹ̀ níbi táwọn èèyàn bá ti fẹ́ rà á. Tí ibẹ̀ bá wá di ọjà tán, á di pé káwọn nǹkan amáyédẹrùn máà sí níbẹ̀.
Ní ìlú Colombo lórílẹ̀-èdè Sri Lanka, ibi táwọn ìsọ̀ tí wọ́n ti ń já ọjà lójú páálí àti lẹ́yọ lẹ́yọ wà ò dáa rárá, ńṣe lèrò sì máa ń rọ́ lu ara wọn níbẹ̀. Àwọn tó ń wa ọkọ̀ akẹ́rù máa ń ráhùn pé ọ̀pọ̀ wákàtí ló máa ń gba àwọn láti gbẹ́rù dé àárín ọjà, ogun sì ni káwọn tó lè ráàyè jáde. Àwọn ibi tí wọ́n ṣe fún ìgbọ́kọ̀sí, kíkó ẹrù àti jíjá ẹrù kò tó rárá.
Láwọn ibòmíì, kò sí àbójútó tó péye fún inú ọjà. Ibi tí wọ́n ti ń nájà dọ̀tí bí ilé póò, èyí sì ń mú kí ẹ̀gbin tó ń tara ohun alààyè wá àtèyí tó ń wá láti ibòmíì máa pọ̀ sí i, ó sì lè ṣèpalára fún wọn. Ẹnì kan tó jẹ́ aṣáájú àwùjọ nílùú kan lápá Gúúsù Éṣíà sọ pé: “Àwọn ìṣòro yìí ń pa kún ohun tó ń mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn túbọ̀ máa dẹnu kọlẹ̀.”
Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórí ẹran tí wọ́n ń tà ní ìlú kan lápá Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà fi hàn pé ìṣòro ńlá ni àìsí ìmọ́tótó tó péye lórí oúnjẹ àti àyíká ń mú wá. Níbi tá à ń sọ yìí, wọn ò róhun tó burú nínú kí wọ́n “lé ẹran sí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nínú eruku àti
omi ìdọ̀tí.” Kòkòrò bakitéríà kan tó ń jẹ́ salmonella wà nínú ìdá méjì nínú márùn-ún ẹran ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n kó síbẹ̀, ó sì wà nínú ìdá mẹ́ta nínú márùn-ún ẹran námà tó wà níbẹ̀, gbogbo námà tí wọ́n kó síbẹ̀ ló tún ní kòkòrò E. coli nínú. Àwọn ìdọ̀tí míì tí wọ́n tún rí nínú ẹ̀ ni èròjà olóró tó lè pani lára, bí òjé àti mẹ́kúrì.Láti lè yanjú ìṣòro oúnjẹ tí kò tó aráàlú jẹ àti bí kì í ṣe wọ̀lú déédéé, tàbí bí èyí tó ń wọ̀lú ò ṣe lágbẹ̀ẹ́kẹ̀lé, àwọn tó ń gbénú àwọn ìlú ńlá bí ìlú Kánò, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí, máa ń gbìyànjú láti dáko sí ilẹ̀ èyíkéyìí tẹ́nikẹ́ni ò bá ti lò. Bẹ́ẹ̀ sì rèé o, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn wọ̀nyí ni kò ní àṣẹ láti lo ilẹ̀ yẹn. Torí náà, wọ́n mọ̀ pé ìgbàkigbà ni wọ́n lè wá gba oko náà lọ́wọ́ wọn kí wọ́n sì ba gbogbo ohun tí wọ́n fòógùn ojú wọn gbìn jẹ́.
Ẹnì kan tó mọ̀ nípa ètò bóúnjẹ ṣe máa kárí ni Olivio Argenti, ó sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè. Ó sọ pé nígbà tóun lọ sí oko tó wà ní ìlú ńlá kan lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, òun rí i pé odò kan wà létí omi yẹn táwọn ará abúlé tó wà létí ìlú yẹn ń da ohun ẹlẹ́gbin sí. Omi yìí làwọn àgbẹ̀ ibẹ̀ máa ń fi wọ́n ewébẹ̀ wọn, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di àkùrọ̀ tí wọ́n kọ ebè sí. Argenti kọ̀wé pé: “Mo béèrè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ibẹ̀ bóyá wọ́n mọ ewu tó wà nínú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, wọ́n sì ní àwọn ò lè ṣe nǹkan kan lórí ìyẹn torí pé àwọn ò ní owó àtohun èlò táwọn lè fi tún nǹkan ṣe.” Ibi tí nǹkan ti rí báyìí pọ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.
Akitiyan Láti Bójú Tó Ìṣòro Ìlú Ńláńlá
Ó dà bíi pé àkààkàtán làwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n láwọn ìlú ńláńlá tó ń kún sí i yìí. Àwọn àjọ àgbáyé, àwọn elétò ìlú, àtàwọn alábòójútó ń ṣe ìwọ̀n tí wọ́n lè ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro náà. Lára ọgbọ́n tí wọ́n ń dá ni pé wọ́n rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa dáko láwọn ìlú kéékèèké, kí wọ́n sì mú kó ṣeé ṣe láti máa ti ibẹ̀ kó oúnjẹ wọ̀lú, kí wọ́n máa la ọ̀nà tuntun, kí wọ́n kọ́ ọjà àtàwọn odò ẹran. Wọ́n tún rí i pé àwọn ní láti máa rọ àwọn ará ìlú pé kí wọ́n máa kọ́ ilé tí wọ́n á máa kẹ́rù sí, kí wọ́n mú kó rọrùn sí i fáwọn àgbẹ̀ àtàwọn oníṣòwò àti àwọn
ọlọ́kọ̀ láti máa rówó yá, kí wọ́n sì ṣòfin tó máa múlẹ̀ lórí ọ̀ràn òwò àti ìmọ́tótó. Síbẹ̀, àwọn òǹwòye wòye pé pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí wọ́n ti ṣe, ọ̀pọ̀ ìjọba ni kò mọ bọ́ràn náà ṣe le tó, tí wọn ò sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti bójú tó ọ̀ràn náà. Kódà, láwọn ibi tí wọ́n bá ti ní àwọn ń bójú tó ọ̀ràn náà, kì í ságbára tó pọ̀ tó láti yanjú ẹ̀.Ìkìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ ti ń wáyé lórí báwọn ìṣòro tó ń kojú àwọn ìlú ńlá ṣe pọ̀ tó, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àjọ tó ń ṣèwádìí nípa ètò oúnjẹ kárí ayé, ìyẹn International Food Policy Research Institute, tó wà ní ìlú Washington, D.C. lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńláńlá á máa pọ̀ sí i ni, bẹ́ẹ̀ làwọn ìṣòro tó wà níbẹ̀ náà [ìyẹn ebi, àìjẹunrekánú, àti òṣì] á máa pọ̀ sí i, àfi tá a bá wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá báyìíbáyìí.” Janice Perlman ni ààrẹ ẹgbẹ́ Mega-Cities Project, ìyẹn ètò aláfọwọ́sowọ́pọ̀ kan tó wà jákèjádò ayé tó ń wá ojútùú sáwọn ìṣòro tó ń yọ àwọn ìlú ńlá lẹ́nu. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú àwọn ìlú ńlá tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, ó sọ pé: “Kò sí ètò kankan nílẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe máa bọ́ omilẹgbẹ èrò tó wà níbì kan tó ti kún fọ́fọ́ tí ìyà owó ń jẹ wọ́n, tí àyíká wọn ò yẹ ọmọ èèyàn, kò sì sílé tàbí iṣẹ́ tí wọ́n pèsè sílẹ̀ fáwọn wọ̀nyí. Èrò tó wà láwọn ìlú yìí ti pọ̀ ju àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ fún ìlò ọmọ èèyàn lọ.”
Àmọ́ ṣá o, a pàpà ní ìdì tá a fi lè retí pé ìṣòro kíkó oúnjẹ wọ̀lú àti pípín in káàkiri máa tó yanjú.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
ÈRÒ MÀ Ń PỌ̀ SÍ I LÁWỌN ÌLÚ ŃLÁŃLÁ
◼ Ní ọgbọ̀n ọdún sí àkókò tá a wà yìí, ó máa fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé láwọn ìlú ńláńlá lèrò tó bá pọ̀ sí i láyé á máa kóra jọ sí.
◼ Ìrètí wà pé tó bá fi máa di ọdún 2007, á ju ìlàjì àwọn èèyàn tó ń gbé láyé lọ táá máa gbé láwọn ìlú ńlá.
◼ Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé, iye àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńlá kárí ayé á máa fi bí ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i lọ́dọọdún; bó bá sì ń ṣe báyìí pọ̀ sí i, iye àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńláńlá á di ìlọ́po méjì tó bá fi máa tó ọdún méjìdínlógójì.
◼ A retí pé tó bá fi máa di ọdún 2015, àwọn ìlú táwọn tó ń gbénú wọn pọ̀ tó mílíọ̀nù márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ á ti kúrò ní mẹ́rìndínláàádọ́ta tó wà lọ́dún 2003, wọ́n á sì ti di mọ́kànlélọ́gọ́ta.
[Credit Line]
Orísun Ìsọfúnni: Ìwé World Urbanization Prospects—Àtúntẹ̀ ti 2003, ẹ̀ka tó ń rí sí ìkànìyàn lábẹ́ àjọ tó ń bójú tó ètò ọrọ̀ ajé àti ètò tó ń lọ láàárín ìlú, ìyẹn United Nations Department of Economic and Social Affairs, Population Division
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
DÍẸ̀ LÁRA OHUN TÍ KÌ Í JẸ́ KÓÚNJẸ WỌ̀LÚ BÓ ṢE YẸ ÀTI ÀTÚBỌ̀TÁN RẸ̀
◼ “Jákèjádò ayé la ti ń rí i pé tí oúnjẹ bá fi lè gbówó lórí lójijì, ṣe ló máa ń da ìlú rú, ó sì lè fa rúkèrúdò ìṣèlú.”—Jacques Diouf, olùdarí àgbà fún Àjọ Tó Ń Rí Sí Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, ló sọ̀rọ̀ yìí.
◼ Lọ́dún 1999, ìjì líle kan tí wọ́n ń pè ní Georges àtèyí tí wọ́n ń pè ní Mitch rọ́ lu àgbègbè Caribbean àti Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, ohun tó bà jẹ́ níbẹ̀ sì pọ̀ lọ bíi rẹ́rẹ, kò jẹ́ káwọn èèyàn ráàyè ṣe iṣẹ́ òòjọ́ wọn, ó sì fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ.
◼ Nígbà tí wọ́n fowó lé owó epo lórílẹ̀-èdè Ecuador lọ́dún 1999 àti lórílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2000, báwọn èèyàn ṣe ń fẹ̀hónú hàn ṣàkóbá tó kọjá sísọ fún ètò kíkó oúnjẹ wọ̀lú.
◼ Lára làlúrí tógun ń fà ni ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọ̀KAN RÈÉ LÁRA ÀRÀÁDỌ́TA Ọ̀KẸ́ ÈÈYÀN TÍ Ò RÓÚNJẸ JẸ
ABÚLÉ kan tí wọ́n tẹ̀ dó sórí ilẹ̀ onílẹ̀ (èyí tẹ́ ẹ̀ ń wò lókè yìí) ní ìkángun ìlú Lima, lórílẹ̀-èdè Peru, ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Consuelo àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tàlá ń gbé. Mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ẹ̀ ló lárùn ikọ́ fée. Ó sọ pé: “Orí òkè là ń gbé tẹ́lẹ̀, àfìgbà tó di alẹ́ ọjọ́ kan tí ẹgbàágbèje èrò tá a jọ wà ní abúlé yẹn ya lọ sáàárín ìlú. Èrò wa ni pé ‘tá a bá dé ìlú Lima, àwọn ọmọ wa á lè lọ sílé ìwé, a ó sì rówó ra bàtà fún wọn. Ayé á dára fún wọn jù báyìí lọ.’” Ni gbogbo ará abúlé yìí bá fi koríko hun ẹní, gbogbo wọ́n sì kọrí sọ́nà ìlú náà lóru ọjọ́ kan, wọ́n lọ kọ ilé koríko síbẹ̀. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn tó ṣí wá náà ti pọ̀ ju ohun tí ìjọba lè lé.
Ihò ńlá kan wà ní òrùlé ilé Consuelo, wọn ò sì rẹ́ ilẹ̀ ilé náà. Ó nawọ́ sí àwọn ohun ọ̀sìn tó ń jẹ̀ nínú ilé ẹ̀, ó ní: “Mò ń sin àwọn adìyẹ yìí kí n lè tà wọ́n fáwọn olówó ni. Mò ń wá owó tí màá fi ra bàtà fún ọmọbìnrin mi. Àmọ́, owó ọsibítù àti owó oògùn ni máà fi san báyìí.”
Gbogbo oúnjẹ tó wà nílé Consuelo kò ju àlùbọ́sà mélòó kan lọ. Iṣẹ́ wọ́n níbẹ̀ yẹn gan-an ni, obìnrin yìí ò sì lówó lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀, kódà kì í rówó ra omi déédéé. Kò sómi ẹ̀rọ nínú ilé ẹgẹrẹmìtì tó ń gbé, kò sì sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ níbẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Ìkòkò tá a fi ń ṣe póò nìyí. Tó bá sì dalẹ́, màá rán àwọn ọmọ kí wọ́n lọ wá ibì kan dà á sí. Kò sọ́gbọ́n míì tá a lè dá.”
Ọkọ Consuelo kì í sú já a, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló tiẹ̀ máa ń fojú kàn án. Kò tíì pé ọmọ ogójì ọdún, ó kàn lé lọ́gbọ̀n ọdún ni, ṣùgbọ́n ó ti gbó gan-an lójú. Òǹkọ̀wé kan tó fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò sọ pé: “Ojú ẹ̀ ò fani mọ́ra rárá, ńṣe ló hun jọ, tí ẹyinjú ẹ̀ kéré tó sì dúdú. Ẹní bá wo ojú ẹ̀ á mọ̀ pé kò ní ìrètí kankan.”
[Àwọn Credit Line]
Orísun Ìsọfúnni: Ìwé In Context
AP Photo/Silvia Izquierdo
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“ṢÉ KÍ N KÓ LỌ SÍLÙÚ ÀBÍ KÍ N MÁÀ LỌ?”
ÓYẸ kẹ́ni tó bá ń gbèrò àtikó lọ sílùú ńlá rò ó dáadáa kó tó kọrí síbẹ̀ o. Ìwé Feeding the Cities tí Àjọ Tó Ń Rí Sí Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè tẹ̀ jáde sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó máa ń gbé àwọn èèyàn lọ sí ìlú ńlá ni ìrètí pé ayé á túbọ̀ dẹrùn fáwọn tí àwọn bá fi wé àǹfààní díẹ̀díẹ̀ tó wà ní ìlú kékeré.” Àmọ́ ṣá o, “nǹkan lè má tètè rọrùn fún wọn, kódà ìdẹ̀rùn ọ̀hún lè máà bá ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.”
Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ló máa ń dojú kọ àwọn tó ti ìlú kékeré lọ sí ìlú ńlá níbi tí wọn ò ti mọ ojú ilẹ̀ dáadáa. Lára irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ni àìrílégbé, àìríṣẹ́ṣe àti ìṣẹ́ tó burú ju tibi tí wọ́n ti wá lọ. Torí náà, tó o bá ń gbèrò àtikó lọ sí ìlú ńlá, ṣó dá ọ lójú pé wàá lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ níbẹ̀? Téèyàn bá tiẹ̀ máa rí iṣẹ́ láwọn ìlú ńlá, owó táṣẹ́rẹ́ báyìí ni wọ́n á máa san fún un. Ṣé ti pé o gbọ́dọ̀ lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ kọ́wọ́ tó lè tẹ́nu kò ní mú kí ìwọ tàbí àwọn aráalé ẹ pa àwọn nǹkan tó o gbà pó ṣe pàtàkì tì?—Mátíù 28:19, 20; Hébérù 10:24, 25.
Àwọn òbí kan ti kó lọ sí ìlú ńlá tí wọ́n sì fi aya àtọmọ sílẹ̀ nílé. Ṣéyẹn bọ́gbọ́n mu ṣá? Ẹ̀tọ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí ni láti bójú tó àtijẹ àtimu àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n tó bá di pé gbogbo ìdílé ò sí lójú kan náà, báwo ni wọ́n á ṣe jẹ́ agbọ̀ràndùn fáwọn ọmọ wọn, tí wọn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n jìnnà sí Ọlọ́run? (1 Tímótì 5:8) Ṣé á ṣeé ṣe fáwọn bàbá láti lè máa tọ́ àwọn ọmọ wọn “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà?” (Éfésù 6:4) Bí tọkọtaya bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ṣé kò lè sún wọn sínú ìdẹwò láti ṣèṣekúṣe?—1 Kọ́ríńtì 7:5.
Olúkúlùkù ló máa pinnu bóyá kóun lọ sí ìlú ńlá àbí kóun má lọ o. Àmọ́, kí Kristẹni kan tó ṣe irú ìpinnu yẹn, ó dáa kó yẹ gbogbo ọ̀ràn tó wé mọ́ ọn wò dáadáa kó sì gbàdúrà pé kí Jèhófà fòun mọ̀nà.—Lúùkù 14:28.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ojú làwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńláńlá ń rọ́ bí wọ́n ṣe ń gbé nínú ẹ̀gbin àti nínú sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ̀
Íńdíà
Niger
Mẹ́síkò
Bangladesh
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nínú àwọn ìdílé tí nǹkan ò ti dán mọ́rán láwọn ìlú ńlá, dandan ni káwọn ọmọdé pàápàá ṣiṣẹ́
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Íńdíà: © Fọ́tò tí Mark Henley/Panos Pictures yà; Niger: © Olivio Argenti; Mẹ́síkò: © Fọ́tò tí Aubrey Wade/Panos Pictures yà; Bangladesh: © Fọ́tò tí Heldur Netocny/ Panos Pictures yà; fọ́tò tìsàlẹ̀: © Fọ́tò tí Jean-Leo Dugast/Panos Pictures yà