Kí Ni Ẹfolúṣọ̀n?
Kí Ni Ẹfolúṣọ̀n?
[Àpótí]
Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ẹfolúṣọ̀n” ni: “Ọ̀nà tí ohun kan gbà ń yí pa da.” Àmọ́ ṣá o, oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ń gbà lo ọ̀rọ̀ náà ẹfolúṣọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń lò ó láti fi ṣàlàyé bí àwọn ohun tí kò lẹ́mìí ṣe yí pa dà lọ́nà tó kàmàmà tó fi wá di pé ayé àtọ̀run wà. Wọ́n tún máa ń lò ó láti fi ṣàlàyé àwọn àyípadà kéékèèké tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ohun alààyè, tí ara ewéko àtàwọn ẹranko fi ń bá ibi tí wọ́n ń gbé mu. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà láti ṣàlàyé ni bí àwọn ohun alààyè ṣe wá látinú àwọn kẹ́míkà kan tó di àwọn nǹkan kéékèèké, táwọn nǹkan náà sì wá ń yíra pa dà lọ́nà èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ títí tó fi di àwọn ohun alààyè tó kàmàmà lóríṣiríṣi, tí àwa èèyàn sì jẹ́ èyí tó gbọ́n jù nínú àwọn ohun alààyè náà. Ìtumọ̀ tá a sọ kẹ́yìn yìí ni ti “ẹfolúṣọ̀n” inú àpilẹ̀kọ́ yìí.