Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?

ÌWÉ gbédègbẹ́yọ̀ kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ìjímìjí, ìyẹn Encyclopedia of Early Christianity sọ pé: “Kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n bí Kristi.” Síbẹ̀, àìmọye èèyàn tó pera wọn ní Kristẹni kárí ayé ló ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù ní December 25. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjọ́ yìí kò sí nínú Bíbélì rárá. Ṣé oṣù December ni wọ́n bí Jésù lóòótọ́?

Òótọ́ ni pé Bíbélì kò sọ ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n bí Jésù, àmọ́ ẹ̀rí wà nínú Bíbélì pé kì í ṣe December 25 ni. Bákan náà, nínú àwọn ìwé mìíràn tó yàtọ̀ sí Bíbélì, a tún lè rí ìdí táwọn kan fi yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n ń ṣayẹyẹ ìbí Jésù.

Kí Nìdí Tí Kò Fi Lè Jẹ́ Pé December 25 Ni Wọ́n Bí Jésù?

Ìlú Jùdíà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n bí Jésù sí. Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé: “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú wà ní ìgbèríko kan náà, tí wọ́n ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.” (Lúùkù 2:4-8) Èyí kì í ṣohun tó ṣàjèjì. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ nígbà ayé Jésù, ìyẹn, Daily Life in the Time of Jesus sọ pé: “Ìta gbangba ni agbo ẹran máa ń wà ní àkókò tó pọ̀ jù lọ láàárín ọdún.” Àmọ́, ṣáwọn olùṣọ́ àgùntàn lè wà níta pẹ̀lú agbo ẹran wọn lóru ní December tó jẹ́ pé ńṣe ni ìta máa ń tutù nini? Ìwé yẹn tún sọ pé: “Abẹ́lé ni wọ́n máa ń wà nígbà òtútù. Kókó yìí nìkan ti tó láti fi mọ̀ pé ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ọdún Kérésìmesì, nígbà òtútù, kò lè tọ̀nà, níwọ̀n bí ìwé Ìhìn Rere ti sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà ní pápá lákòókò yẹn.”

Àlàyé mìíràn tún wà nínú Ìhìn Rere Lúùkù tó ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn. Ó sọ pé: “Ní ọjọ́ wọnnì àṣẹ àgbékalẹ̀ kan jáde lọ láti ọ̀dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pé kí gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé forúkọ sílẹ̀; (ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà Síríà;) gbogbo ènìyàn sì ń rin ìrìn àjò lọ láti forúkọ sílẹ̀, olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀.”—Lúùkù 2:1-3.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kí Ọ̀gọ́sítọ́sì bàa lè mọye èèyàn tó wà nílùú, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ mọye àwọn tá á máa sanwó orí àtàwọn tí wọ́n máa mú wọṣẹ́ ológun ló ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n lọ forúkọ sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò àtibímọ Màríà ti kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ó ṣègbọràn sí àṣẹ yìí, òun àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ jọ rìnrìn àjò tí ó tó àádọ́jọ [150] kìlómítà láti Násárétì lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Tiẹ̀ rò ó wò ná, ǹjẹ́ o rò pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí Ọ̀gọ́sítọ́sì tó jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ wá pàṣẹ pé káwọn èèyàn tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba Róòmù rìnrìn-àjò ọ̀nà gígún bẹ́ẹ̀ lásìkò òtútù nini?

Ó dùn mọ́ni pé ọ̀pọ̀ àwọn òpìtàn àtàwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ni kò gbà pé December 25 ni wọ́n bí Jésù. Ó dájú pé wàá rí ìsọfúnni lórí kókó yìí nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ èyíkéyìí tó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe jáde tí wọ́n pè ní Our Sunday Visitor’s Catholic Encyclopedia sọ pé: “Gbogbo èèyàn ló gbà pé kì í ṣe December 25 ni wọ́n bí Jésù.”

Ìdí Tí Wọ́n Fi Yan December 25

Lẹ́yìn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tí Jésù ti kú, àwọn kan yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n bí i. Kí nìdí? Ọ̀pọ̀ àwọn òpìtàn gbà pé àkókò táwọn abọ̀rìṣà ń ṣayẹyẹ ìbọ̀rìṣà làwọn kan sọ di ìgbà tí wọ́n ń ṣọdún Kérésìmesì ní ìrántí ìbí Jésù.

Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àlàyé kan táwọn èèyàn níbi gbogbo ń ṣe nípa December 25 ni pé dies solis invicti nati (‘ọjọ́ ìbí oòrùn tí a kò lè ṣẹ́gun’), làwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni sọ di ọjọ́ tí wọ́n ń ṣayẹyẹ ìbí Jésù. Ayẹyẹ ọjọ́ ìbí oòrùn yìí sì wọ́pọ̀ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, níbi tí wọ́n ti máa ń ṣayẹyẹ yíyọ oòrùn nígbà òtútù. Wọ́n máa ń fi sàmì sí ìbí oòrùn, ó tún jẹ́ àmì pé ìgbà òtútù ti ń kásẹ̀ nílẹ̀, àti pé ìgbà òjò àti ẹ̀ẹ̀rùn ti ń wọlé bọ̀.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Americana sọ pé: “Ìdí tí wọ́n fi yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ Kérésìmesì kò yé èèyàn dáadáa, àmọ́ àwọn kan gbà pé ńṣe ni wọ́n so ọjọ́ yẹn pọ̀ mọ́ ọjọ́ táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣàwọn ọdún kan lákòókò ayẹyẹ yíyọ oòrùn nígbà òtútù, ìyẹn lásìkò tí oòrùn bá ń wọlé bọ̀, tí wọ́n sì ń ṣayẹyẹ ‘ìpadàbọ̀ rẹ̀.‘ . . . Àwọn ara Róòmù tún máa ń ṣayẹyẹ kan tí wọ́n ń pè ní Saturnalia, (ìyẹn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń bọ Saturn, ọlọ́run nǹkan ọ̀gbìn, tí wọ́n sì fi ń rántí àkọ̀tun agbára oòrùn) ní àkókò kan náà yìí.” Nígbà ayẹyẹ yìí, àwọn abọ̀rìṣà yẹn máa ń bára wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n sì máa ń ṣàríyá aláriwo, tí wọ́n sì máa ń hùwà ẹhànnà. Abájọ tírú àwọn ìwà báwọ̀nyí fi máa ń wáyé lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá ń ṣọdún Kérésì lóde òní.

Ọ̀nà Tó Yẹ Ká Máa Gbà Bọlá fún Kristi

Àwọn kan sọ pé bá ò tiẹ̀ mọ ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n bí Jésù, ó ṣì yẹ káwọn Kristẹni máa ṣèrántí ọjọ́ tí wọ́n bí i. Èrò wọn ni pé, ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì téèyàn lè gbà bọlá fún Kristi, béèyàn bá ṣáà ti ń ṣe é tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ni ìbí Jésù jẹ́ nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì. Bíbélì sọ pé nígbà tí wọ́n bí Jésù, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sọ pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.” (Lúùkù 2:13, 14) Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé ká máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì pàṣẹ ní tààràtà pé ká máa ṣèrántí ikú Jésù. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún sì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe é. (Lúùkù 22:19) Èyí jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà bọlá fún Jésù.

Nígbà tó ku ọ̀la kí Jésù kú, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòhánù 15:14) Ó tún sọ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́.” (Jòhánù 14:15) Ká sòótọ́, kò sọ́nà míì tó dára jù téèyàn lè gbà bọlá fún Jésù Kristi ju pé kéèyàn mọ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé wọn.

KÍ LÈRO Ẹ?

◼ Kí nìdí tí kò fi lè jẹ́ pé oṣù December ni wọ́n bí Jésù?—Lúùkù 2:1-8.

◼ Kí ló ṣe pàtàkì ju ọjọ́ ìbí èèyàn lọ?—Oníwàásù 7:1.

◼ Ọ̀nà wo ló dára jù téèyàn lè gbà bọlá fún Jésù?—Jòhánù 14:15.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Bíbélì jẹ́rìí sí i pé oṣù December kọ́ ni wọ́n bí Jésù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ǹjẹ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn lè wà níta gbangba lóru pẹ̀lú agbo àgùntàn wọn nínú òtútù nini?

[Credit Line]

Todd Bolen/Bible Places.com