Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Ń Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Ìgbé Ayé Lọ́nà Tó Nítumọ̀

Ó Ń Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Ìgbé Ayé Lọ́nà Tó Nítumọ̀

Ó Ń Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Ìgbé Ayé Lọ́nà Tó Nítumọ̀

◼ Ìwé náà “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn” ti nípa rere lórí àwọn tó ti kà á. Obìnrin kan sọ pé: “Ó ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ Jésù dáadáa. Mo ti wá mọrírì ipa tó kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ní báyìí mo fẹ́ túbọ̀ máa gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀, kí n sì máa polongo ìhìn rere táráyé nílò gan-an báyìí.”

Bàbá kan sọ pé: “Ìwé náà ti jẹ́ kí n mọ bo ti ṣe pàtàkì tó pé kí n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀ fún wa . . . Ìwé yìí ti jẹ́ kí n ṣàṣàrò lórí àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́, sùúrù ńláǹlà, ìgbọ́ràn àti ìfaradà. Àwọn àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ tí ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe káàárẹ̀.”

Òǹkàwé míì sọ pé òun fara mọ́ ọ̀rọ̀ tó wà lẹ́yìn ìwé náà, èyí tó sọ pé: “Jésù Kristi ni afinimọ̀nà tí Ọlọ́run yàn láti fọ̀nà hàn ọmọ aráyé. . . . Ìwé yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jésù dáadáa, kó o lè máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.” Òǹkàwé náà wá sọ pé, “Ìwé yìí ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti nífẹ̀ẹ́ Jésù, ká gbà á gbọ́, ká máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu, ká sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

Ojú ìwé 192 ni ìwé Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn ní, mẹ́tàlá nínú àwọn ojú ìwé náà ní àwòrán mèremère, tó fi oríṣiríṣi nǹkan tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé hàn. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.