Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fàwọn Ìṣòro Rẹ Jẹ Ẹ́ Níyà?

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fàwọn Ìṣòro Rẹ Jẹ Ẹ́ Níyà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fàwọn Ìṣòro Rẹ Jẹ Ẹ́ Níyà?

“Nígbà tí obìnrin kan, tó jẹ́ ẹni ọdún bíi márùndínlọ́gọ́ta, mọ̀ pé òun ti lárùn jẹjẹrẹ, ó sọ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé ẹ̀san ló ń ké lórí mi yìí.” Nígbà tó ń ronú lórí ohun tí kò dáa tó ṣe lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó ronú pé: “Ó ní láti jẹ́ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni Ọlọ́run fi ń jẹ mí yìí.”

NÍGBÀ ìṣòro, ọ̀pọ̀ máa ń rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ àwọn torí àwọn nǹkan tí ò dáa táwọn ti ṣe. Bí ọ̀pọ̀ ìṣòro bá sì dé bá wọn, a lè gbọ́ tí wọ́n á máa dárò pé: “Áà, ó ṣe jẹ́ èmi? Kí ni mo ṣe tí èyí fi tọ́ sí mi?” Ṣó yẹ ká máa rò pé Ọlọ́run ló ń fi àwọn ìṣòro wa jẹ wá níyà? Ṣé lóòótọ́ ni pé Ọlọ́run ló ń fàwọn ìṣòro wa jẹ wá níyà?

Àwọn Tó Fòótọ́ Sin Ọlọ́run Náà Níṣòro

Ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù. Ọ̀sán kan òru kan ló pàdánù ọrọ̀ tó ní. Lẹ́yìn náà ni ìjì líle pa àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí àìsàn burúkú kan fi kọlu Jóòbù fúnra ẹ̀. (Jóòbù 1:13-19; 2:7, 8) Àwọn àjálù burúkú yẹn mú kí Jóòbù figbe ta pé: “Ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.” (Jóòbù 19:21, Bíbélì Mímọ́) Bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, Jóòbù rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ òun.

Àmọ́, kí ìṣòro tó dé bá Jóòbù, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti sọ nípa Jóòbù pé ó jẹ́ “ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” (Jóòbù 1:8) Gbogbo ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé Ọlọ́run mọ irú ẹni tí Jóòbù jẹ́ yìí mú kó ṣe kedere pé Òun kọ́ ló ń pọ́n ọn lójú.

Bíbélì sọ nípa àwọn tó fòótọ́ sin Ọlọ́run, síbẹ̀ tí wọ́n níṣòro. Láìka bí Jósẹ́fù ṣe fòótọ́

sin Ọlọ́run sí, ó fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún nígbà tí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 39:10-20; 40:15) Tímótì pẹ̀lú fòótọ́ sin Ọlọ́run, síbẹ̀ ‘àìsàn ṣe é lemọ́lemọ́.’ (1 Tímótì 5:23) Jésù Kristi ò dẹ́ṣẹ̀ rí, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣe é bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú kó tó kú ikú oró. (1 Pétérù 2:21-24) Torí náà, àṣìṣe ló jẹ́ tá a bá ń rò pé torí pé inú Ọlọ́run ò dùn sí wa la ṣe ń níṣòro. Àmọ́ ta wá lẹni tó ń fa ìṣòro bá wa tí kì í bá ṣe Ọlọ́run?

Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro

Bíbélì fi hàn pé Sátánì Èṣù ló fa ìṣòro Jóòbù. (Jóòbù 1:7-12; 2:3-8) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ló ń fa àwọn ìṣòro wa lónìí nígbà tó sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Torí pé Sátánì ni “olùṣàkóso ayé yìí,” ó ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ nínú ìwà ibi tó ti yọrí sí ìjìyà àti ìrora ọkàn tó kọjá sísọ.—Jòhánù 12:31; Sáàmù 37:12, 14. a

Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká tètè máa sọ pé Èṣù ló ń fa gbogbo ìṣòro tá a bá ní. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún, a máa ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání, tó sì máa ń kó wa sínú ìṣòro. (Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ọkùnrin kan tí kì í jẹun dáadáa, tí kì í sì í sinmi dáadáa, bí ohun tó ń ṣe yìí bá sọ ọ́ di aláìlera, ṣẹ́ Èṣù ló yẹ kó dá lẹ́bi? Rárá o, ìyà ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání tó ṣe ló ń jẹ. (Gálátíà 6:7) Ńṣe nirú ipò yìí bá òwe Bíbélì kan mu tó sọ pé: “Ìwà-òmùgọ̀ eniyan . . . mu ìparun ba ọ̀nà ara rẹ̀.”—Òwe 19:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Paríparì rẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí ò bára dé tó ń ṣẹlẹ̀ jẹ́ nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníwàásù 9:11) Wo ẹnì kan tí òjò ńlá ká mọ́ ojú ọ̀nà. Ibi tó bá dúró sí nígbà tójò náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ló máa pinnu bóyá ìwọ̀nba lòjò tó máa pa á tàbí ńṣe ló máa tutù jìngbìnnì. Bákan náà, láwọn “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, ipò tí ò dáa lè tètè yọrí sí ọ̀pọ̀ ìṣòro fún wa. (2 Tímótì 3:1-5) Àmọ́, àkókò àti ibi tá a bá wà ló sábà máa ń pinnu bí ipa tó máa ní lórí wa ṣe máa pọ̀ tó, a ò sì ní lè ṣe ohun tó pọ̀ nípa ẹ̀, ìyẹn bá a bá tiẹ̀ lè ṣe ohunkóhun rárá. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé títí láé lojú á máa pọ́n wa?

Gbogbo Ìpọ́njú Máa Tó Dópin

Inú wa dùn pé Jèhófà Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìpọ́njú. (Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 1:3; 21:3, 4) Àmọ́ títí dìgbà yẹn, Jèhófà fi hàn pé òun bìkítà fún wa lóòótọ́ bó ṣe ń fún wa ní “ìtọ́ni” àti “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́” ká bàa lè máa fara da àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra, bá a ti ń fojú sọ́nà fáwọn ohun rere tó ń bọ̀. (Róòmù 15:4; 1 Pétérù 5:7) Nígbà yẹn, àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lójú Ọlọ́run á máa gbé títí láé nínú ayé tuntun, ohunkóhun ò sì ní pọ́n wọn lójú mọ́.—Sáàmù 37:29, 37.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ta Ni Sátánì? Ṣó Wà Lóòótọ́?” nínú Jí! April–June 2007

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ṣáwọn èèyàn burúkú nìkan lojú máa ń pọ́n?—Jóòbù 1:8.

◼ Ṣé Èṣù ló yẹ ká máa di ẹ̀bi gbogbo ìṣòro wa rù?—Gálátíà 6:7.

◼ Ṣé títí láé ni ìpọ́njú á máa wà?—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

“Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11