Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Kémi Àtẹni Tá a Jọ Ń Fẹ́ra Fira Wa Sílẹ̀?

Ṣé Kémi Àtẹni Tá a Jọ Ń Fẹ́ra Fira Wa Sílẹ̀?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Kémi Àtẹni Tá a Jọ Ń Fẹ́ra Fira Wa Sílẹ̀?

“Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tá a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, àwa méjèèjì rí i pé ó ti lọ wà pa jù. A máa ń sọ pé èkùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà, àfi bíi pé kò sóhun tó lè yẹ̀ ẹ́.”—Jessica. a

“Ìfẹ́ bọ̀bọ́ yẹn ti kó sí mi lórí, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta sí mi ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà! Ó wù mí kí n ní ọ̀rẹ́kùnrin kan tó dàgbà táá máa tọ́jú mi.”—Carol.

Nígbà tó yá, Jessica àti Carol fi ọ̀rẹ́kùnrin wọn sílẹ̀. Kí nìdí? Kí ló ń ṣe wọ́n tí wọ́n fi ní láti fi irú àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyẹn sílẹ̀?

Ó TI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan báyìí tẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín. Nígbà tẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀, lójú ẹ, ó dà bíi pé “kò sóhun tó máa yà yín.” b Nígbà míì gan-an, o máa ń ronú lórí bí ìfẹ́ ṣe ń pa yín bí ọtí nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ní báyìí èrò rẹ ti yàtọ̀. Ṣó yẹ kó o mọ́kàn kúrò lórí ohun tó ò ń rò báyìí? Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ó yẹ kẹ́ ẹ fira yín sílẹ̀?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o ò gbọ́dọ̀ tanra ẹ o, torí pé béèyàn ò bá kọbi ara sáwọn àmì tó fi hàn pé ìṣòro wà nínú àjọṣe kan, ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ò ka àmì ìkìlọ̀ ọkọ̀ sí. Bọ́rọ̀ àjọṣe ṣe rí náà nìyẹn, bó ò bá kọbi ara sí ìṣòro tó yọjú, kò ní lọ fúnra ẹ̀, á wulẹ̀ máa burú sí i ni. Àwọn àmì wo ló lè fi hàn pé àjọṣe kan léwu, tó yẹ kó o kọbi ara sí?

Bí ìfẹ́ bá tètè kó sí i yín lórí. Ó léwu tí ìfẹ́ bá tètè kó sí i yín lórí. Carol sọ pé: “A máa ń bára wa sọ̀rọ̀ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti tẹlifóònù. Sísọ̀rọ̀ láwọn ọ̀nà yìí máa ń jẹ́ kẹ́ni méjì tètè mọwọ́ ara wọn ju kéèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú lọ!” Má ṣe kánjú, ṣe ni kó o yáa fara balẹ̀ kẹ́ ẹ lè mọ ara yín dáadáa. Kò yẹ kí àjọṣe dà bí ọṣẹ tó hó kùṣùkùṣù tó wá dá wáí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó dà bí òdòdó rírẹwà tó rọra ń dàgbà díẹ̀díẹ̀.

Ó lágídí, ó sì máa ń wọ́ mi nílẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ana sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni ọ̀rẹ́kùnrin mi máa ń wọ́ mi nílẹ̀, síbẹ̀ mo máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá ni.” Ó tún sọ pé, “Mo fàyè gba ohun tí mi ò ronú pé mo lè fàyè gbà láyé mi!” Bíbélì dẹ́bi fún “ọ̀rọ̀ èébú.” (Éfésù 4:31) Ọ̀rọ̀ tó ń wọ́ èèyàn nílẹ̀ ò yẹ nínú àjọṣe onífẹ̀ẹ́, èèyàn ì báà tiẹ̀ sọ ọ́ lọ́nà jẹ́jẹ́ pàápàá.—Òwe 12:18.

Inú ẹ̀ le. Ìwé Òwe 17:27 sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ . . . tutù ní ẹ̀mí.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Erin rí i pé ọ̀rẹ́kùnrin òun kì í ṣe onínú tútù. Ó ní, “Bá a bá ní èdèkòyédè, ńṣe ló máa ń tì mí dà nù, tí màá sì fara pa.” Bíbélì sọ fáwọn Kristẹni pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú . . . kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Ó dájú pé ẹni tí ò ní ìkóra-ẹni-níjàánu ò tíì yẹ lẹ́ni tó ń kọ ẹnu ìfẹ́ sí obìnrin.—2 Tímótì 3:1, 3, 5.

Kò fẹ́ kẹ́nì kankan mọ̀ sí àjọṣe wa. Angela sọ pé, “Ọ̀rẹ́kùnrin mi ò fẹ́ kẹ́nì kankan mọ̀ pé à ń fẹ́ra. Ó tiẹ̀ bínú nígbà tí dádì mi mọ̀!” Lóòótọ́, ó lè nídìí pàtàkì kan táwọn tó ń fẹ́ra wọn fi lè sọ pé àwọn ò fẹ́ kẹ́nì kankan mọ̀ pé àwọn ń fẹ́ra. Àmọ́, ó léwu béèyàn bá kọ̀ láti sọ fáwọn tó yẹ kí wọ́n mọ̀.

Kò ní in lọ́kàn láti gbé mi sílé. Ọwọ́ pàtàkì làwọn Kristẹni fi mú ọ̀ràn ìfẹ́sọ́nà, torí pé ó máa ń ran ọkùnrin àti obìnrin lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá àwọn á gbéra wọn sílé. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kẹ́ ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra ìgbéyàwó nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ pàdé. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ni kì í gbé ẹni tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ sọ́nà sílé. Lẹ́sẹ̀ kan náà, èèyàn ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà tó bá mọ̀ pé òun ò tíì ṣe tán láti ṣègbéyàwó.

Dákú dájí ni àjọṣe wa. Ìwé Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà.” Kò túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà náà lẹ ó máa gbà fúnra yín o! Àmọ́ àjọṣe tó ń dá kú dá jí lè fi hàn pé ohun kan wà tó yẹ kí wọ́n ṣiṣẹ́ lé lórí gẹ́gẹ́ bí Ana ṣe wá mọ̀. Ó sọ pé, “Gbogbo ìgbà tí mo dá àjọṣe mi pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin mi dúró ni mo máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀! Màá wá pa dà lọ, màá sì tún bẹ̀rẹ̀ àjọṣe tó jẹ́ pé ì bá sàn kí n jáwọ́ nínú ẹ̀.”

Ó ń rọ̀ mí pé ká bára wa sùn. “Bó o bá nífẹ̀ẹ́ mi, wàá ṣe é.” “Ó yẹ ká ti wọnú ara wa jù báyìí lọ.” “Kò sọ́rọ̀ ńbẹ̀ bá ò bá tíì bára wa sùn.” Irú ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn táwọn ọmọkùnrin máa ń sọ nìyí kí wọ́n lè bá àwọn ọmọbìnrin sùn. Ìwé Jákọ́bù 3:17 sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà.” Ọ̀rẹ́kùnrin tó níwà rere, tó sì fara mọ́ ìpinnu rere tó o ṣe nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ lo yẹ ẹ́. Má gbàgbàkugbà láyè!

Wọ́n ti kìlọ̀ fún mi nípa ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Gba ìmọ̀ràn, kó o lè ṣàṣeyọrí; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wàá kùnà.” (Òwe 15:22, Today’s English Version) Jessica sọ pé: “O ò lè kọtí ikún sóhun táwọn ìdílé rẹ tàbí ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ ti jọ wà tipẹ́ bá sọ bíwọ náà ò ṣe ní fẹ́ láti ṣàì kọbi ara sí iyè méjì tó o bá ní nípa àjọṣe náà. Torí bó o bá ṣe ń kọtí ikún sóhun táwọn èèyàn bá sọ tó nìṣòro rẹ á ṣe máa pọ̀ sí i tó.”

Àwọn ohun tá a sọ lókè yìí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àmì tó lè fi hàn pé ìṣòro wà nínú àjọṣe kan. c Bó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, báwo ni ọ̀rẹ́kùnrin rẹ ti ń ṣe sí nínú àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn yìí? Kọ àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó máa kọ ẹ́ lóminú nípa ọ̀rẹ́kùnrin rẹ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Bó O Bá Fẹ́ Fi Í Sílẹ̀

Bó o bá rí i pé á dáa kó o fi í sílẹ̀ ńkọ́? Ọ̀nà wo lo máa gbé e gbà? Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà tó o lè gbé e gbà, àmọ́ fàwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí sọ́kàn.

Lo ìgboyà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Trina sọ pé, “Mo ti gbára lé ọ̀rẹ́kùnrin mi jù débi tí ẹ̀rù fi ń bà mí láti fi í sílẹ̀.” Ó gba ìgboyà láti sọ̀rọ̀ téèyàn bá fẹ́ fòpin sí àjọṣe kan. Àmọ́, ó ṣàǹfààní bó o bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ. (Òwe 22:3) Èyí á fún ẹ láǹfààní láti gbé ohun tó ò fẹ́ àtohun tó o fẹ́ kalẹ̀ nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú ẹni tó o máa fẹ́ sọ́nà àti nígbà tó o bá ṣègbéyàwó.

Fi ro ara rẹ wò. Ká ní ìwọ ni ọ̀rẹ́kùnrin rẹ fẹ́ fi sílẹ̀, ọ̀nà wo lo máa fẹ́ kó gbé e gbà? (Mátíù 7:12) Ó dájú pé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ kọjá ẹni tó o kàn máa kọ ímeèlì tàbí lẹ́tà orí tẹlifóònù alágbèéká sí tàbí kó o kàn pè é sórí tẹlifóònù pé, “Tóò, mi ò ṣe mọ́ o!”

Wá ibi àti àkókò tó yẹ. Ṣó yẹ kẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ lójúkojú ni tàbí látorí tẹlifóònù? Ṣé lẹ́tà ló yẹ kó o kọ ni àbí kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀? Bọ́rọ̀ náà bá ṣe wáyé ló máa pinnu ohun tó o máa ṣe. O ò gbọ́dọ̀ lọ pàdé rẹ̀ níbikíbi tó máa fi ẹ́ sínú ewu o, kò sì ní bọ́gbọ́n mu kó jẹ́ ibi táwọn èèyàn ò sí, tí ìwà pálapàla ti lè ṣẹlẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 4:3.

Sọ bọ́rọ̀ ṣe rí. Sọ ohun tó jẹ́ kó o rò pé ó yẹ kẹ́ ẹ fira yín sílẹ̀. Bó o bá ronú pé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ ò ṣe ẹ́ dáadáa, jẹ́ kó mọ̀. Má ṣe mẹin-mẹin. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi sọ pé, “Gbogbo ìgbà lo máa ń wọ́ mi ńlẹ̀,” sọ pé, “Ńṣe lò ń wọ́ mi nílẹ̀ bó o bá ń . . . ”

Kíwọ náà múra tán láti fetí sílẹ̀. Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tí ò yé ẹ dáadáa nínú ọ̀ràn náà? Má ṣe jẹ́ kó fọ̀rọ̀ dídùn tàn ẹ́ jẹ, àmọ́ na sùúrù sí i, kó o sì gbé àwọn ẹ̀rí tóun náà ní yẹ̀ wò. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Bíbélì gba àwọn Kristẹni ni pé, kí wọ́n “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, [kí wọ́n sì] lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ àwọn tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí gan-an kọ́ nìyí.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin ni àpilẹ̀kọ yìí dá lé lórí, síbẹ̀, tọkùnrin tobìnrin làwọn ìlànà tó wà níbẹ̀ kàn.

c Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Jí! July–September 2007, ojú ìwé 18 sí 20.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kọ àwọn nǹkan tó o kà sí pàtàkì lára ẹni tó o fẹ́ fẹ́ sórí ìlà yìí. ․․․․․

◼ Àwọn ìwà wo lo ò fẹ́ lára ẹni tó o fẹ́ fẹ́? ․․․․․

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

ẸNI TÓ O BÁ FẸ́ FẸ́ GBỌ́DỌ̀ . . .

□ ní irú ìgbàgbọ́ tó o ní.—1 Kọ́ríńtì 7:39.

□ fara mọ́ ìpinnu rere tó o ṣe nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:18.

□ jẹ́ ẹni tó ń gba tìẹ àti tàwọn ẹlòmíì rò.—Fílípì 2:4.

lórúkọ rere.—Fílípì 2:20.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

ṢỌ́RA FÚN Ọ̀RẸ́KÙNRIN RẸ BÓ BÁ JẸ́ PÉ . . .

tara ẹ̀ nìkan ló mọ̀.

gbogbo ìgbà lohun tó ń ṣe máa ń mú kó o rò pó o jẹ̀bi, pé ọ̀dẹ̀ ni ẹ́, tàbí pé o ò já mọ́ nǹkan kan.

kì í jẹ́ kó o ráyè fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ àti ìdílé ẹ.

gbogbo ìgbà ló máa ń fẹ́ mọ ibi tó o wà.

ó máa ń fẹ̀sùn kàn ẹ́ pé o máa ń báwọn míì tage, láìjẹ́ pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀.

ó máa ń halẹ̀ mọ́ ẹ, ó sì máa ń fòté lé àwọn ohun tó fẹ́ kó o ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Béèyàn ò bá kọbi ara sáwọn àmì tó fi hàn pé ìṣòro wà nínú àjọṣe kan, ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ò ka àmì ìkìlọ̀ ọkọ̀ sí

WO EPO ỌKỌ̀