Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Kí N Bo Àṣírí Ọ̀rẹ́ Mi?

Ṣé Kí N Bo Àṣírí Ọ̀rẹ́ Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Kí N Bo Àṣírí Ọ̀rẹ́ Mi?

“Kò rọrùn rárá, torí pé ọ̀rẹ́ mi àtàtà lẹni tá à ń wí yìí.”—James. a

“Níbẹ̀rẹ̀ kò rọrùn rárá, àwọn ọ̀rẹ́ mi ò tiẹ̀ gba tèmi mọ́, torí pé mo kọ̀ láti bo àṣírí wọn.”—Ann.

BÍBÉLÌ sọ pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) Ǹjẹ́ o nírú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣeyebíye lo ní.

Àmọ́, bí ọ̀rẹ́ ẹ tó jẹ́ Kristẹni bá hùwà tí kò tọ́ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe tó o bá ní ọ̀rẹ́ kan tó ń ṣèṣekúṣe, tó ń mu ọtí àmujù, tó ń lo oògùn olóró tàbí tó hu àwọn ìwà kan tó burú jáì? (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 1 Tímótì 1:9, 10) Kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣé wàá sọ àwọn nǹkan tí kò dáa tó ń ṣe fún un? Ṣé àwọn òbí rẹ lo máa sọ fún àbí àwọn òbí ọ̀rẹ́ rẹ? Àbí àwọn alàgbà ìjọ lo máa sọ fún? b Tó o bá lọ fẹjọ́ ẹ̀ sùn ṣé kò ní fa ìjà láàárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ? Àbí ó máa dáa kó o kúkú dákẹ́?

Ṣé Kí N Sọ àbí Kí N Má Sọ?

Kò sẹ́ni tí kò lè ṣàṣìṣe. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì làwọn kan dá. Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn míì “ṣi ẹsẹ̀ gbé,” tí wọn ò bá sì tètè ṣàtúnṣe, ó lè yọrí sí àwọn ìṣòro mìíràn. (Gálátíà 6:1) Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan yẹ̀ wò.

◼ Àṣírí tú sí Susan, ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni, lọ́wọ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tóun náà jẹ́ Kristẹni ní ìkànnì kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi tó kó àwọn àwòrán oníhòòhò àtàwọn orin tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sí.

․․․․․

Rò ó wò ná: Kí ni wàá ṣe tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Susan? Ṣé wàá ṣe nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà? Àbí ohun tí wàá sọ ni pé kò séyìí tó kàn ẹ́ nípa ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ kó sórí ìkànnì rẹ̀? Tí Susan bá wá bá ẹ pé kó o gba òun nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí lo máa sọ fún un?

Ohun tí Susan ṣe: Lẹ́yìn tí Susan ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, ó pinnu pé òun á lọ sọ fáwọn òbí ọ̀rẹ́ òun. Susan sọ pé: “Ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí nígbà tí mo fẹ́ lọ, torí pé àwọn òbí ọ̀rẹ́ mi pẹ̀lú ṣèèyàn gan-an ni. Kò rọrùn fún mi rárá láti sọ fún wọn, bí mo ṣe bú sẹ́kún nìyẹn.”

Kí lèrò ẹ? Ǹjẹ́ ohun tí Susan ṣe yìí dáa? Àbí o rò pé ì bá dáa kó má sọ fẹ́nì kankan?

Àwọn kókó díẹ̀ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ronú lórí ọ̀ràn yìí rèé:

Kí ló yẹ kí ọ̀rẹ́ àtàtà ṣe? Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Tẹ́nì kan bá ń ṣe ohun tí kò bá àwọn ìlànà Bíbélì mu, ‘inú wàhálà’ lẹni náà wà, yálà ó mọ̀ tàbí kò mọ̀. Òótọ́ ni pé kò dáa kéèyàn jẹ́ “olódodo àṣelékè” nípa sísọ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan di bàbàrà. Àmọ́ ọ̀rẹ́ àtàtà kò ní ṣàì sọ̀rọ̀ tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá hùwà tí kò bá ti Kristẹni mu. (Oníwàásù 7:16) Kì í ṣohun tó dáa pé kéèyàn kàn mójú kúrò nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.—Léfítíkù 5:1.

Tó bá jẹ́ pé òbí ni ẹ́ ńkọ́? Bi ara rẹ pé: ‘Bí ọmọ mi ọkùnrin tàbí obìnrin bá ní ìkànnì kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi tó kó àwòrán àti orin tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sí, ṣé á wù mí kí n mọ̀ nípa rẹ̀? Báwo ló ṣe máa rí lára mi tí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin mi bá ní ọ̀rẹ́ kan tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà tí kò sì sọ fún mi?’

Tó bá kan òfin Ọlọrun ńkọ́? Tọ́rọ̀ bá dà báyìí, kì í ṣe àkókò nìyí láti dákẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, èyí tó wà nínú Bíbélì nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tó o bá ṣe ohun tó tọ́, wàá mú inú Ẹlẹ́dàá rẹ dùn. (Òwe 27:11) Bákan náà, inú  á dùn torí o mọ̀ pé, ní tòdodo, ohun to máa ṣàǹfààní fún ọ̀rẹ́ ẹ lo ṣe yẹn.—Ìsíkíẹ́lì 33:8.

“Ìgbà Sísọ̀rọ̀”

Bíbélì sọ pé: “Ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) Ìgbà míì máa ń wà táwọn ọmọdé kì í mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Bí ọ̀rẹ́ wọn kan bá ṣe nǹkan tí kò dáa, ohun tí wọ́n máa ń sọ ni pé: ‘Mi ò fẹ́ kó ọ̀rẹ́ mi sí wàhálà’ tàbí ‘mi ò fẹ́ kí èmi àtọ̀rẹ́ mi jà.’ Tó bá jẹ́ pé àwọn kókó méjì yìí nìkan lohun tó ṣe pàtàkì láti ronú lé lórí, ohun tó o máa ṣe kò le rárá, ṣe ni kó o ‘dákẹ́ jẹ́ẹ́.’

Àmọ́, bó o bá ṣe ń dàgbà sí i, wàá túbọ̀ máa lo òye nínú irú àwọn ọ̀ràn báwọ̀nyí. O mọ̀ pé ọ̀rẹ́ rẹ ti kó sí wàhálà, ó sì nílò ìrànlọ́wọ́, ìwọ náà lo sì lè ràn án lọ́wọ́. Kí wá lo lè ṣe tó o bá gbọ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan ṣe ohun kan tí kò bá òfin tàbí àwọn ìlànà Bíbélì mu?

Ohun tó o máa kọ́kọ́ ṣe ni pé, kó o ṣèwádìí bóyá òótọ́ lohun tó o gbọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àhesọ lásán ni. (Òwe 14:15) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Katie sọ pé: “Nígbà kan, ọ̀rẹ́ mi kan bẹ̀rẹ̀ sí í parọ́ mọ́ mi, àwọn tó sún mọ́ mi sì rò pé òótọ́ lohun tó ń sọ. Ẹ̀rù bà mí, torí pé kò sẹ́ni tó jẹ́ gbà mí gbọ́!” Bíbélì sọ pé Jésù kò ní “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ Bíbélì Contemporary English Version ṣe sọ ọ́, “kò ní . . . fetí sí àhesọ.” (Aísáyà 11:3) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Má ṣe yára gbà pé òótọ́ ni gbogbo ohun tó o gbọ́. Gbìyànjú kó o ṣèwádìí bóyá òótọ́ lohun tó o gbọ́. Jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ ẹnì kan yẹ̀ wò.

◼ Ẹni tó ń jẹ́ James tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí gbọ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan lo oògùn olóró lágbo àríyá kan.

Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni James kí ni wàá ṣe? Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá òótọ́ lohun tó o gbọ́ nípa ọ̀rẹ́ rẹ?

․․․․․

Ohun tí James ṣe. James kọ́kọ́ ṣe bí ẹni pé òun ò tíì gbọ́ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó wá sọ pé: “Lẹ́yìn náà, ẹ̀rí ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. Mo mọ̀ pé níbi tọ́rọ̀ dé yìí, àfi kí n bá ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀.”

Kí lèrò ẹ? Tó o bá gbọ́ pé ẹnì kan hùwà tí kò bá ìlànà Kristẹni mu, àwọn àǹfààní wo ló lè wà níbẹ̀ tó o bá kọ́kọ́ bá onítọ̀hún sọ ohun tó o gbọ́ nípa rẹ̀?

․․․․․

Tó bá ṣòro fún ẹ láti bá onítọ̀hún sọ ohun tó o gbọ́ nípa rẹ̀, nǹkan míì wo lo lè ṣe?

․․․․․

Ọ̀rẹ́ James yìí gbà pé òótọ́ lòun lo oògùn olóró lágbo àríyá. Àmọ́, ó bẹ James pé kó má sọ fẹ́nì kankan. Ohun tó tọ́ ni James fẹ́ ṣe. Bákan náà, ó fẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ṣe ohun tó tọ́. Ó wá sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ yìí pé òun fún un ní ọ̀sẹ̀ kan kó fi lọ jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà ìjọ rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun á lọ sọ fúnra òun.

Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí James ṣe yìí dára? Tó bá jẹ́ pó dáa, kí nìdí? Bí ò bá sì dáa, kí nìdí?

․․․․․

Ọ̀rẹ́ James kò lọ jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà, torí náà James lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà. Àmọ́, nígbà tó yá, ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí pe orí ara rẹ̀ wálé. Àwọn alàgbà ràn án lọ́wọ́ láti rí ìdí tó fi yẹ kó yí pa dà kó lè tún ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà.

Ṣé Kì Í Ṣe Pé Mo Ti Di Olófòófó?

Síbẹ̀, o lè máa bi ara rẹ pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé mo ti di olófòófó nìyẹn tí mo bá tú àṣírí ọ̀rẹ́ mi? Ǹjẹ́ kò kúkú ní dáa kí n ṣe bíi pé mi ò mọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà?’ Tó o bá bára ẹ̀ nírú ipò yìí, kí lo lè ṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó o mọ̀ pé ohun tó bá rọrùn láti ṣe kì í fìgbà gbogbo ṣàǹfààní, ohun tó bá sì ṣàǹfààní kì í sábà rọrùn láti ṣe. Ó gba pé kó o jẹ́ onígboyà kó o tó lè lọ sọ ìwà àìtọ́ tí ọ̀rẹ́ rẹ kan hù. O ò ṣe fọ̀rọ̀ náà lọ Ọlọ́run nínú àdúrà? Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n àti ìgboyà kó o lè ṣe ohun tó tọ́. Ó dájú pé yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Fílípì 4:6.

Ohun kejì ni pé, ronú lórí bó ṣe máa ṣe ọ̀rẹ́ rẹ láǹfààní tó o bá lọ sọ ohun tó ṣe. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: ká sọ pé ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ jọ ń rìn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kan lọ, lójijì ni ẹsẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ yọ̀ tó sì já sínú kòtò kan nísàlẹ̀. Kò sí àní-àní pé ọ̀rẹ́ rẹ yìí nílò ìrànlọ́wọ́. Àmọ́, kí ni wàá ṣe bí ìtìjú bá mú kó sọ fún ẹ pé kó o má ran òun lọ́wọ́, tó sì ní òun á gun òkè yẹn fúnra òun? Ṣé wàá kan fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí wàá sì jẹ kó fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu?

Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn, tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá ṣe ohun tí kò bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Ẹni náà lè sọ pé òun mọ bóun ṣe máa ṣe é tí àjọṣe òun á fi gún régé pa dà pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́ ńṣe lonítọ̀hún ń tan ara rẹ̀ jẹ. Òótọ́ ni pé ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe lè kó ìtìjú bá a. Àmọ́ tó o bá sọ fún ẹnì kan pé ọ̀rẹ́ rẹ yìí nílò ìrànlọ́wọ́, o lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là!—Jákọ́bù 5:15.

Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ẹ́ láti sọ̀rọ̀ nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá hùwà àìtọ́. Tó o bá ràn án lọ́wọ́, ńṣe lò ń fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run àti ọ̀rẹ́ rẹ pẹ̀lú. Ọjọ́ kan sì ń bọ̀ tí ọ̀rẹ́ rẹ yìí á wá dúpẹ́ oore tó o ṣe fún un.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ àwọn tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí gan-an kọ́ nìyí.

b Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn alàgbà máa ń ran àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa dà ní àjọse tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Jákọ́bù 5:14-16.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Báwo ni fífẹjọ́ ọ̀rẹ́ rẹ sùn nígbà tó bá hùwà àìtọ́ á ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ àtàtà ni ẹ́?

◼ Àwọn wo lo lè rántí nínú Bíbélì tí wọ́n kojú àdánwò, torí pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà? Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ lára wọn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá ti yà kúrò lọ́nà Kristẹni, ó yẹ kó o rí i dájú pé o ràn án lọ́wọ́