Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rí Ohun Tá À Ń Wá

A Rí Ohun Tá À Ń Wá

A Rí Ohun Tá À Ń Wá

Gẹ́gẹ́ bí Bert Tallman ṣe sọ ọ́

Inú mi máa ń dùn tí mo bá rántí ìgbà tí mo wà lọ́mọdé ní ìpínlẹ̀ Alberta, lórílẹ̀-èdè Kánádà ní àgbègbè kan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fáwọn Íńdíà tó jẹ́ ará Amẹ́ríkà tí wọ́n ń gbé níbẹ̀. Ibi tá à ń gbé ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ibi àpáta àti Adágún Louise rírẹwà tó wà níbẹ̀.

ỌMỌ mẹ́sàn-án làwọn òbí wa bí, ọkùnrin méje, obìnrin méjì. Ilé màmá màmá wa lèmi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi, àtàwọn àbúrò mi sábà máa ń wà. Màmá àgbà jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, wọ́n sì kọ́ wa láwọn àṣà ìbílẹ̀ wa tó ti wà tipẹ́, kí wọ́n tó bí wa. A kọ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣa àgbáyun lóko, bí wọ́n ṣe ń gbọ́únjẹ ìbílẹ̀, a sì máa ń ṣọ̀gbìn nínú ọgbà. Iṣẹ́ apẹja ni bàbá ìyá mi àti bàbá mi ń ṣe, wọ́n sì máa ń mú mi dání. A máa ń pa ẹtu àtàwọn ẹran tó tóbi bí ẹfọ̀n jẹ tàbí ká lo awọ wọn. Òṣìṣẹ́ kára làwọn òbí wa, wọ́n sì sapá gidigidi láti mú kí ilé tù wá lára. Mo gbádùn ibi tá a gbé yẹn gan-an ni.

Àmọ́, gbogbo nǹkan yí pa dà bírí nígbà tí màmá àgbà kú lọ́dún 1963. Ọmọ ọdún márùn-ún ni mí nígbà yẹn, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì tojú sú mi gan-an. Kò sóhun tí wọ́n sọ tó tù mí nínú. Kódà, bí mo ṣe kéré tó nígbà yẹn, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Bí Ẹlẹ́dàá bá wà, ibo gan-an ló wà? Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń kú?’ Nígbà míì, mo máa ń kédàárò torí pé nǹkan tojú sú mi. Báwọn òbí mi bá béèrè pé kí ló ń ṣe mi, ńṣe ni mo kàn máa ń sọ fún wọn pé orí ló ń fọ́ mi.

Mo Ráwọn Òyìnbó

Kí màmá àgbà tó kú, a kì í fi bẹ́ẹ̀ ráwọn òyìnbó. Nígbàkigbà tá a bá sì rí wọn, mo máa ń gbọ́ táwọn èèyàn máa ń bú wọn pé: “Ẹ ò rí i, Èṣù bèlèké, oníwọra, ọ̀dájú. Èèyànkéèyàn gbáà ni wọ́n.” Wọ́n ní kí n máa ṣọ́ra fáwọn òyìnbó, pé ẹlẹ̀tàn ni wọ́n, wọn ò sì ṣeé fọkàn tán. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara mi wà lọ́nà láti rí wọn, síbẹ̀, mo máa ń ṣọ́ra, torí pé àwọn òyìnbó tó wà ládùúgbò wa máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ wa láìdáa.

Kété lẹ́yìn tí màmá àgbà kú, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí àmujù, ìyẹn sì mú káwọn ọdún wọ̀nyẹn jẹ́ ìgbà tí inú mi bà jẹ́ jù lọ láyé mi. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, àwọn ẹlẹ́sìn Mormon méjì wá sílé wa. Ó dà bíi pé èèyàn rere ni wọ́n. Àwọn òbí mi gbà pé kí n dara pọ̀ mọ́ ètò ìyípadà kan táwọn ẹlẹ́sìn yìí ń ṣe. Bí mo ṣe lóye ètò yẹn ni pé wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ Ìbílẹ̀ máa gbé pẹ̀lú àwọn òyìnbó kí wọ́n lè dà bíi tiwọn. Nítorí ipò táwọn òbí mi wà, wọ́n rò pé ó kúkú sàn kí n lọ máa gbé lọ́dọ̀ ìdílé míì. Ẹ̀rù bà mí, ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá mi, torí pé àwọn òbí mi ti sọ fún mi pé àwọn òyìnbó ò ṣeé fọkàn tán. Mi ò fẹ́ lọ rárá, mo sì ta ọgbọ́n tí mi ò fi ní lọ. Níkẹyìn, mo gbà láti lọ nígbà táwọn òbí mi fi dá mi lójú pé èmi àtẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin la jọ ń lọ.

Àmọ́, nígbà tá a dé ìlú Vancouver, lágbègbè British Columbia, wọ́n pín èmi àti ẹ̀gbọ́n mi níyà, wọ́n sì mú mi lọ síbi tó jìnnà tó ọgọ́rùn-ún [100] kìlómítà! Èyí mú kí ọkàn mi dàrú gidigidi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdílé tí mò ń gbé lọ́dọ̀ wọn ṣèèyàn gan-an, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bà mí lọ́kàn jẹ́, ẹ̀rù sì bà mí gidigidi. Oṣù mẹ́wàá lẹ́yìn náà mo pa dà sílé.

Mo Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ nílé nígbà tí mo pa dà, inú mi dùn pé mo pa dà délé. Nígbà tí mo pé nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá, àwọn òbí mi ò mutí mọ́. Ìyẹn tù mí lára, àmọ́, mo ti ń hùwàkiwà, torí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mo sì máa ń mutí. Àwọn òbí mi sọ pé kí n máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò míì, irú bíi fífi akọ màlúù díje, mo sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Ojo èèyàn ò lè ṣe irú eré ìdíje yìí. Mo lè fọwọ́ kan di okùn tí wọ́n lọ́ mọ́ ara akọ màlúù yìí mú, kí n sì gùn ún fún ìṣẹ́jú àáyá mẹ́jọ, láì ṣubú.

Mi ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nígbà táwọn àgbààgbà ìlú mú mi wọnú ẹ̀sìn Ìbílẹ̀. Inú mi dùn gan-an sí èyí, torí pé mi ò tiẹ̀ fìgbà kan gbádùn ẹ̀sìn àwọn òyìnbó. Mo gbà pé ó ṣeé ṣe kí inúure àti àìṣègbè wà nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ àwọn èèyàn wa, èyí tí kò sí nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tó ń pera wọn ní Kristẹni. Ara máa ń tù mí tí mo bá wà láàárín àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ wa, torí pé mo máa ń gbádùn àwọn àwàdà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín tẹbí tọ̀rẹ́.

Láàárín àkókò yẹn náà ni mo gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe fojú àwọn èèyàn wa rí màbo fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo gbọ́ pé àwọn òyìnbó tan àrùn kálẹ̀ láàárín wa, wọ́n sì tún pa gbogbo ẹfọ̀n tá a máa ń rí pa jẹ́, tá a sì tún ń rí tà. Kódà, ńṣe ni Ọ̀gágun R. I. Dodge, tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí máa ń sọ pé: “Ẹ pa gbogbo ẹfọ̀n tẹ́ ẹ bá rí dà nù. Torí pé, bẹ́ ẹ bá pa ẹfọ̀n kan, Íńdíà ará Amẹ́ríkà kan lẹ pa yẹn.” Mo mọ̀ pé ìwà táwọn òyìnbó hù yìí jẹ́ káwọn èèyàn wa rí ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, tí kò sì lè rọ́nà gbé e gbà.

Síwájú sí i, àwọn olórí ìjọba kan pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn tí wọ́n kó sòdí, ti sapá gidigidi láti ṣe àwọn àyípadà kan tí wọ́n á fi mú àwọn ọmọ ìbílẹ̀ wọnú àṣà Ìbílẹ̀ àwọn òyìnbó, torí pé ojú ẹni tó luko tí kò sì dá nǹkan kan mọ̀ làwọn òyìnbó fi ń wò wọ́n. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé gbogbo nǹkan nípa àwọn èèyàn wa ló gbọ́dọ̀ yí pa dà, títí kan àṣà ìbílẹ̀ wọn, ìgbàgbọ́ wọn, ìwà wọn àti èdè wọn, kí wọ́n bàa lè máa ṣe bí àwọn òyìnbó. Lórílẹ̀-èdè Kánádà, wọ́n tiẹ̀ máa ń hùwà àìdáa sáwọn ọmọ wa tí wọ́n ń gbé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ táwọn ẹlẹ́sìn ń bójú tó. Àwọn míì lára àwọn èèyàn wa bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkiwà bíi jíjoògùnyó, ìmukúmu, ìwà ipá, àti pípara ẹni, àwọn ìṣòro yìí ṣì ń bá a nìṣó láàárín àwọn èèyàn wa títí dòní olónìí.

Láti lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro yìí, àwọn èèyàn wa kan pa àwọn àṣà ìbílẹ̀ wa tì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sáwọn ọmọ wọn dípò èdè ìbílẹ̀ tiwọn, wọ́n sì gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ àwọn òyìnbó. Dípò káwọn òyìnbó náà fà wọ́n mọ́ra, ńṣe ni wọ́n ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, kódà, àwọn tó jẹ́ ọmọ Ìbílẹ̀ bíi tiwọn náà tún ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n máa ń bú wọn pé, wọ́n fojú jọ ọmọ ìbílẹ̀, àmọ́ wọ́n ń ṣe bí àwọn ọmọ òyìnbó.

Ó bani nínú jẹ́ láti máa rí báwọn èèyàn wa tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà ṣe ń jìyà lọ́pọ̀ ọ̀nà. Mò ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìdẹ̀ra máa dé bá àwọn èèyàn wa tí wọ́n ń gbé jákèjádò orílẹ̀-èdè Kánádà àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Mo Wá Ìdáhùn Lójú Méjèèjì

Nígbà tí mo ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo máa ń ronú pé kò sí bí mo ṣe lè dà bí àwọn òyìnbó, èrò àìtẹ́gbẹ́ yẹn sì máa ń mú kínú bí mi. Mo wá dìídì kórìíra àwọn òyìnbó gan-an. Àmọ́, àwọn òbí mi àti ẹ̀gbọ́n bàbá mi tó jẹ́ obìnrin rọ̀ mí pé kí n má ṣe ní èrò tí kò dáa, kí n má ṣe kórìíra, kí n má sì ṣe gbẹ̀san, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n lẹ́mìí ìdáríjì àti ìfẹ́, kí n má sì ṣe ka ẹ̀tanú táwọn èèyàn ń ṣe sí. Nígbà tó yá, mo wá mọ̀ pé àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fún mi yìí bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Bákan náà, ó ṣì wù mí láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ti ń jẹ mí lọ́kàn látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé. Mo tún máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tá a fi wà láyé àti ìdí tí ìwà ìrẹ́jẹ fi ń bá a nìṣó. Lójú tèmi, kò bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn kàn wà láàyè fúngbà díẹ̀ kó sì kú, èyí mú kí nǹkan tojú sú mi.

Nígbàkigbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti wá sílé wa, èmi ni wọ́n máa ń ní kí n lọ ṣílẹ̀kùn fún wọn. Ó dà bíi pé wọn kì í ṣe ẹ̀tanú, torí náà, mo máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé n kì í mọ bí mo ṣe máa gbé àwọn ìbéèrè mi kalẹ̀ bó ṣe yẹ, ìjíròrò wa ṣì máa ń lárinrin. Mo rántí ìgbà kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tó jẹ́ Íńdíà ará Amẹ́ríkà, ìyẹn John Brewster àti Harry Callihoo, wá sílé wa. A jọ sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn bá a ti ń rìn gba àfonífojì kan tó ní koríko. Mo gba ìwé kan lọ́wọ́ wọn, mo sì ti kà á dé ìdajì kó tó sọ nù.

Mo Ki Ara Bọ Fífi Màlúù Díje

Mo máa ń lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà tó wà ládùúgbò wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo mọrírì àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí wọ́n máa ń fún mi, mi ò rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè mi nípa ìgbésí ayé. Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, mo kúrò nílé mo sì wá kára bọ fífi akọ màlúù díje. Mo máa ń mutí yó, mo sì máa ń lo oògùn olóró láwọn agbo àríyá tí mo máa ń lọ lẹ́yìn tí mo bá kúrò níbi ìdíje náà. Ẹ̀rí ọkàn mi máa ń dà mí láàmú, torí mo mọ̀ pé irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ kò dára, mo sì mọ̀ pé inú Ọlọ́run ò lè dùn sírú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀. Mo máa ń gbàdúrà sí Ẹlẹ́dàá pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́, kí n sì rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń jà gùdù lọ́kàn mi.

Lọ́dún 1978, nígbà tí mo wà nílùú Calgary, lórílẹ̀-èdè Kánádà, mo pàdé ọmọ Ìbílẹ̀ wa kan tó ń jẹ́ Rose. Ó jẹ́ apá kan ẹ̀yà tiwa àti apá kan ẹ̀ya Cree. Ọ̀rọ̀ àwa méjèèjì wọ̀, mo sì máa ń bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Àwa méjèèjì fẹ́ràn ara wa gan-an, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1979. A bímọ méjì, èyí obìnrin ń jẹ́ Carma, èyí ọkùnrin sì ń jẹ́ Jared. Olóòótọ́ èèyàn nìyàwó mi, ó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú mi, ó sì mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Lọ́jọ́ kan témi àtìyàwó mi pẹ̀lú àwọn ọmọ wa lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, mo rí ìwé kan tó ní àkọlé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. a Ohun tí mo kà níbẹ̀ jọ mí lójú, ó sì jọ pé ó bọ́gbọ́n mu. Àmọ́, nígbà tí mo kàwé náà débi tí òye àlàyé tó ṣe lórí Bíbélì fi bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi, mo rí i pé apá ibì kan nínú ìwé náà ti ya dà nù. Èmi àtìyàwó mi sapá gidigidi láti wá àwọn ojú ìwé tó ti ya náà, àmọ́, a ò rí wọn. Síbẹ̀, mo máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́.

A Lọ Sọ́dọ̀ Àlùfáà

Nígbà ìrúwé ọdún 1984, ìyàwó mi bí ọmọ wa kẹta, Kayla lorúkọ ẹ̀, ó sì rẹwà. Àmọ́, lóṣù méjì péré lẹ́yìn náà, àrùn ọkàn pa Kayla. Ìbànújẹ́ sorí wa kodò, mi ò sì mọ bí màá ṣe tu ìyàwó mi nínú. Ìyàwó mi ní tá a bá lọ sọ́dọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan tó wà ládùúgbò wa, a máa rí ìtùnú, ó sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè wa.

Nígbà tá a débẹ̀, a bi í pé, kí ló dé tí ọmọ wa jòjòló fi ní láti kú, àti pé ibo ló lọ gan-an? Àlùfáà náà fèsì pé, torí pé Ọlọ́run nílò áńgẹ́lì míì ló ṣe mú Kayla lọ. Mo wá ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi ní láti mú ọmọ wa lọ láti di áńgẹ́lì, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló jẹ́ Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé? Àǹfààní wo ni ọmọ jòjòló tí kò mọ nǹkankan fẹ́ ṣe fún un?’ Àlùfáà náà ò ṣí Bíbélì rárá. Nígbà tá a kúrò níbẹ̀, ńṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú wa.

Àdúrà Ló Gbé Wa Ró

Láàárọ̀ ọjọ́ Mọ́ńdè kan, ní November ọdún 1984, mo gbàdúrà fún àkókò gígùn, mo sì bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí ìgbé ayé mi túbọ̀ dára, kí n mọ ohun tó fa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, kí n sì mọ ìdí tá a fi wà láàyè. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn gan-an ni Diana Bellemy àti Karen Scott tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wa. Onínúure àti olóòótọ́ èèyàn ni wọ́n, wọ́n sì fìtara wàásù fún mi. Mo tẹ́tí sí wọn, mo gba Bíbélì àti ìwé kan tó ní àkọlé náà, Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, b mo sì gbà kóun àti ọkọ ẹ̀, Darryl, jọ pa dà wá lọ́sẹ̀ yẹn.

Lẹ́yìn tí wọ́n lọ tán ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ sí mi lọ́kàn pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà mi. Inú mi dùn débi pé mo ń lọ, mò ń bọ̀ nínú ilé, tí mo sì ń retí kí ìyàwó mi dé láti ibiṣẹ́, kí n lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Ẹnú yà mí nígbà tí ìyàwó mi sọ fún mi pé òun náà gbàdúrà títí lóru àná, tóun ń bẹ Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́ láti wá ìsìn tòótọ́ rí. Lọ́jọ́ Friday ọ̀sẹ̀ yẹn la ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àkọ́kọ́. Nígbà tó ṣe la gbọ́ pé lọ́jọ́ tí Karen àti Diana fi wá wàásù nílé wa yẹn, ṣe ni wọ́n ṣìnà ibí tí wọ́n ní lọ́kàn láti lọ wàásù. Àmọ́, bí wọ́n ṣe rí ilé wa báyìí, ó ṣe wọ́n bíi kí wọ́n wá wàásù níbẹ̀.

Mo Rí Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Mi!

Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó rú tẹbí tọ̀rẹ́ lójú, inú wọn ò sì dùn sí ìgbésẹ̀ tá a gbé yìí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ wa, wọ́n sọ pé ńṣe la kàn ń fayé wa tàfàlà, a ò sì lo ẹ̀bùn àti òye tá a ní lọ́nà tó tọ́. Àmọ́, a pinnu pé a ò ní kẹ̀yìn sí Ọ̀rẹ́ wa tuntun, ìyẹn Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà. Ó ṣe tán, a ti rí ohun tó ṣeyebíye, ìyẹn àwọn àgbàyanu òtítọ́ àtàwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 13:52) Èmi àtìyàwó mi ṣèrìbọmi, a sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní December, ọdún 1985. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa ti wá ń bọ̀wọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an báyìí, torí pé wọ́n rí i pé ìgbé ayé wa ti yí pa dà sí rere látìgbà tá a ti ṣèrìbọmi.

Dájúdájú, mo ti rí ohun tí mò ń wá! Ọ̀nà tó rọrùn tó sì bọ́gbọ́n mu ni Bíbélì gbà dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì-pàtàkì. Inú mi dùn nígbà tí mo mọ ìdí tá a fi wà láàyè, ìdí tá a fi ń kú, àti ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé a máa pa dà rí ọmọbìnrin wa Kayla, táá máa dàgbà ní àyíká tó dáa gan-an. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:4) Nígbà tó yá, mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó lè pa wá lára, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé pàtàkì lọ̀ràn ẹ̀mí, a ò sì gbọ́dọ̀ máa báwọn ẹlòmíì díje. (Gálátíà 5:26) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpinnu yẹn kò rọrùn fún mi rárá, mi ò fi akọ màlúù díje mọ́, kí n lè máa múnú Ọlọ́run dùn.

Ìmọ̀ pípéye nínú Bíbélì ti sọ wá dòmìnira lọ́wọ́ àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tó ń da ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ wa láàmú, irú bíi pé béèyàn bá rí òwìwí nílé tàbí tí ajá bá ń gbó lákọlákọ, ó lè fa ikú ẹni kan nínú ìdílé. A ò tún gbà gbọ́ mọ́ pé àwọn ẹ̀mí àìrí kan tó wà nínú àwọn ohun abẹ̀mí tàbí àwọn ohun tí kò lẹ́mìí lè pa wá lára. (Sáàmù 56:4; Jòhánù 8:32) A ti wá mọyì àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá Jèhófà. Mo láwọn ọ̀rẹ́ tí mo lè pè ní arákùnrin àti arábìnrin mi, tí wọ́n wá látinú onírúurú orílẹ̀-èdè, wọ́n kà wá sí ìkan náà, a sì jùmọ̀ ń sìn Ọlọ́run pa pọ̀. (Ìṣe 10:34, 35) Ọ̀pọ̀ lára wọn ń sapá láti kọ́ àwọn àṣà Ìbílẹ̀ wa àtàwọn ohun tá a gbà gbọ́, wọ́n tún ń kọ́ èdè wa kí wọ́n bàa lè sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn lọ́nà tó ń wọni lọ́kàn.

Àgbègbè kan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fáwọn Íńdíà ará Amẹ́ríkà tí wọ́n ń gbé ní gúúsù Alberta, lórílẹ̀-èdè Kánádà ni ìdílé wa ń gbé, a sì ní ilé kẹ́jẹ́bú kan síbẹ̀. A ṣì máa ń gbádùn àwọn àṣà Ìbílẹ̀, títí kan àwọn oúnjẹ, orin àti ijó ìlú wa. A kì í bá wọn lọ́wọ́ sí àwọn ijó ìbílẹ̀ yẹn ní tààràtà, àmọ́ a máa ń wòran wọn nígbà tó bá bójú mu. Mo tún sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wa nípa àwọn nǹkan àjogúnbá wọn àtàwọn díẹ̀ lára àwọn èdè Ìbílẹ̀ wa. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ wa ní àwọn ànímọ́ tó dára gan-an, irú bí inúure, ìrẹ̀lẹ̀, ọ̀rọ̀ tẹbí tọ̀rẹ́ sì jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tún láájò àlejò, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, títí kan àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yà tọ̀. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣì máa ń wú mi lórí títí dòní.

Ohun tó ń múnú wa dùn jù lọ ni bá a ṣe ń lo àkókò wa, okun wa àtohun ìní wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀. Ọmọ wa Jared, yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí ìlú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Mo láǹfààní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú Ìjọ Macleod tí mò ń dara pọ̀ mọ́. Bákan náà, èmi, ìyàwó mi àti Carma ọmọ wa obìnrin, jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn tó máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti wàásù. Inú wa máa ń dùn gan-an pé à ń wàásù ní èdè ìbílẹ̀ wa. Inú wa máa ń dùn ṣìnkìn bá a ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń fetí sí òtítọ́ nípa Ẹlẹ́dàá àtohun tó fẹ́ ṣe.

Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíróníkà 28:9) Mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá, pé Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa bó ṣe ran èmi àti ìdílé mi lọ́wọ́ láti rí ohun tá à ń wá.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

‘Bí Ẹlẹ́dàá bá wà lóòótọ́, ibo ló wà? Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń kú?’

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

‘Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ wa ní àwọn ànímọ́ bí inúure àti ìrẹ̀lẹ̀’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Màmá màmá mi ló kọ́ mi láwọn àṣà ìbílẹ̀ wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Mo kara bọ fífi akọ màlúù díje

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àkànṣe ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “You Can Trust the Creator” wà lédè ìbílẹ̀ wa àtàwọn èdè míì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Inú mi ń dùn báyíì bí mo ṣe ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi, ìyàwó mi, àtàwọn ọmọ wa rèé