Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni?

Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni?

Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni?

Nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] ni tó ti di ògbóǹtagí akọrin, ó sì tún lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Díẹ̀ làwọn tó lókìkí tí wọ́n sì tún rí towó ṣe bíi tiẹ̀ nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé. Àmọ́, kò pẹ́ tí nǹkan fi bẹ̀rẹ̀ sí yíwọ́ fún un. Lẹ́yìn tí ìgbéyàwó ẹ̀ ti tú ká lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kì í wọ́n láwọn ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ń mu àmupara àtàwọn tó ń lo oògùn nílòkulò. Gbogbo nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí dojú rú fún un.

Ó BANI nínú jẹ́ pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́bìnrin yìí wọ́pọ̀ gan-an ni; nínú ìròyìn, ọ̀pọ̀ ìgbà là ń gbọ́ irú ìtàn tó bani lọ́kàn jẹ́ bẹ́ẹ̀ nípa àwọn gbajúgbajà. Kódà, láàárín àwọn oníṣòwò tí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara wọn, nǹkan ṣì máa ń nira fáwọn kan tó dà bíi pé wọ́n rọ́wọ́ mú lára wọn. Ìwé ìròyìn kan sọ nípa àwọn tí wọ́n rọ́wọ́ mú nínú ìṣòwò nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ní: “Fífẹ́ láti jẹ èrè àjẹpajúdé ń sọ àgbọ́kànlé àwọn èèyàn dòfo, ó ń ba ìdílé wọn jẹ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lo oògùn olóró láti fi pàrònú rẹ́ . . . Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó àjẹmọ́nú táwọn òṣìṣẹ́ báńkì kan ń gbà ní ìkóríta ìṣòwò tí wọ́n ń pè ní Wall Street nílùú Amẹ́ríkà mú kó dà bíi pé mìmì kan ò lè mì wọ́n, àwọn òṣìṣẹ́ míì wà táyé ti sú nítorí àtimókè, ipò táwọn míì bára wọn sì ti burú pátápátá.”

Àbí wíwá ayọ̀ àti àṣeyọrí síbi tí kò tọ́ ló fa irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀? Òótọ́ ni pé owó ò ṣeé bá ṣọ̀tá. Àmọ́, ṣó dìgbà tá a bá kó ọrọ̀ jọ káyé tó lè yẹ wá ni? Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Ṣáínà fi hàn pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tí owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ fi ìlọ́po méjì àtààbọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ipò nǹkan ò tìtorí ẹ̀ rọ àwọn èèyàn lọ́rùn.

Torí náà, a ò lè sọ pé ayé yẹ ẹnì kan nítorí irú iṣẹ́ tó ń ṣe, iye owó tó fi ra ilé tó ń gbé, ọkọ̀ tó ń gùn, tàbí irú aago tó ń lò. Ká tó lè sọ pé ayé yẹ ẹnì kan, ṣé kò yẹ ká wo bí ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe rí látòkè délẹ̀, ká wo àwọn ìlànà tó ń darí ìgbésí ayé ẹ̀, àti ohun tó ń gbélé ayé ṣe? Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè já fáfá kó sì lágbára, àmọ́ kó má mọ̀wàá hù, kó ya òṣónú kó má sì lọ́rẹ̀ẹ́ gidi. Ẹlòmíì lè lókìkí kó sì lọ́rọ̀, àmọ́ kó wo bí ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe rí, kó sì bi ara ẹ̀ pé, ‘Kí ni mò ń gbélé ayé ṣe gan-an? Kí ni gbogbo sá sókè sá sódò mi já sí?’

Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ìgbésí ayé àwọn táyé yẹ lóòótọ́ ti ní láti dá lórí àwọn ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, wọ́n ti ní láti ní àwọn ìlànà yíyè kooro tó ń darí wọn. Èyí tó máa mú kí ọkàn wọn balẹ̀, kí wọ́n mọyì ara wọn, káwọn èèyàn sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Wọ́n á tún ní ohun tí wọ́n fẹ́ fayé wọn ṣe ju kí wọ́n wulẹ̀ máa wá bí wọ́n á ṣe máa tẹ́ra wọn lọ́rùn. Irú ohun bẹ́ẹ̀ á mú kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀ kó sì tẹ́ wọn lọ́rùn. Àwọn kan lè béèrè pé: ‘Irú àwọn ìlànà wo nìyẹn?’ ‘Kí sì lohun tí wọ́n lè fẹ́ fayé wọn ṣe?’ Ṣé àwa fúnra wa lè rí ìdáhùn sí irú ìbéèrè wọ̀nyẹn, àbí a gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn lọ síbòmíì? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa tú iṣu àwọn ìbéèrè wọ̀nyí désàlẹ̀ ìkòkò.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

ÈRÒ ÒDÌ NÍPA OHUN TÓ Ń MÚ KÁYÉ YẸNI

Báwọn tó ń ṣèwádìí nípa ìṣègùn ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ eléré ìdárayá ni wọ́n túbọ̀ ń lo oògùn tó máa jẹ́ kí wọ́n lè gbégbá orókè lórí pápá bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oògùn náà lè pa wọ́n lára. Ìsọfúnni orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ Education Update ròyìn pé: “Nínú ìwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà tí wọ́n bi àwọn ọmọ kọ́lẹ́ẹ̀jì kan pé: ‘Bó o bá mọ̀ pé wàá gbégbá orókè tàbí kí wọ́n mú ẹ mọ́ àwọn tó máa ṣeré ìdárayá bó o bá ti lè lo oògùn aleṣan, tí wàá sì ṣàìsàn lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn náà, ṣó o ṣì máa gbà?,’ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló sọ pé àwọn á gbà. Nígbà tí wọ́n wá yí ìbéèrè náà pa dà pé ‘bó o bá mọ̀ pó o máa kú láàárín ọdún márùn-ún ńkọ́,’ o ju ìdajì lọ lára wọn tó sọ pé àwọn ṣì máa gbà.”