Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Mẹ́fà Tó Lè Mú Káyé Yẹni

Ohun Mẹ́fà Tó Lè Mú Káyé Yẹni

Ohun Mẹ́fà Tó Lè Mú Káyé Yẹni

ẸNÍ bá gbé ayé ẹ̀ lọ́nà tó dára jù lọ la lè sọ pé ayé yẹ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì ní láti jẹ́ ẹni tó ń fàwọn ìlànà Ọlọ́run sílò tó sì ń fayé ẹ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run torí ẹ̀ dá wa. Bíbélì sọ pé èèyàn tó bá ń gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀, á “dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”Sáàmù 1:3.

Bẹ́ẹ̀ ni, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé tá a sì ń ṣe àṣìṣe, ayé ṣì lè yẹ wá! Ṣé inú ẹ dùn láti gbọ́ bẹ́ẹ̀? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà mẹ́fà tá a gbé karí Bíbélì yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ káyé bàa lè yẹ ìwọ náà, kó o lè rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé ọgbọ́n Ọlọ́run làwọn ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi ń kọ́ni.—Jákọ́bù 3:17.

1 Máa Fojú Tó Tọ́ Wo Owó

“Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:10) Kì í ṣe owó, èyí tí gbogbo wa nílò láti gbọ́ bùkátà ìdílé wa ni Bíbélì sọ pé kò dáa, bí kò ṣe ìfẹ́ owó. Ká sòótọ́, ńṣe ni irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń sọ owó di ọ̀gá, tàbí ọlọ́run ẹni.

Gẹ́gẹ́ báa ṣe rí i nínú èyí àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, gbogbo àwọn tó bá rò pé lílépa ọrọ̀ ló lè mú káyé yẹ àwọn wulẹ̀ ń sáré lé ẹ̀fúùfù lásán ni. Yàtọ̀ sí pé wọ́n á rí ìjákulẹ̀, wọ́n á tún fa ọ̀pọ̀ ìrora sórí ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn èèyàn bá ń fi gbogbo ara lépa ọrọ̀, wọ́n sábà máa ń fi àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn dí i. Àwọn míì kì í sùn nítorí iṣẹ́ tàbí nítorí àníyàn àti ìdààmú ọkàn. Oníwàásù 5:12 sọ pé: ‘Dídùn ni oorun oníṣẹ́, ì báà jẹ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀: ṣùgbọ́n ìtẹ́lọ́rùn ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.’—Bibeli Mimọ.

Kì í wulẹ̀ ṣe pé owó jẹ́ òǹrorò ọ̀gá nìkan ni, àmọ́ ó tún kún fún ẹ̀tàn. Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” (Máàkù 4:19) Èyí tó túmọ̀ sí pé ó lè dà bíi pé owó máa ń fúnni láyọ̀, àmọ́ kì í fúnni láyọ̀ tòótọ́. Èèyàn á wulẹ̀ máa fẹ́ láti lówó púpọ̀ sí i ni. Bíbélì The New English Bible sọ pé: “Ẹni tó bá fẹ́ owó, owó kì yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn.”—Oníwàásù 5:10.

Ní kúkúrú, ẹní bá nífẹ̀ẹ́ owó máa para ẹ̀ láyò gbẹ̀yìn ni, ọwọ́ ẹ̀ lè má tẹ owó tó ń wá, owó tó rí lè máà tó o, tàbí kó tiẹ̀ fipá wá a. (Òwe 28:20) Àwọn nǹkan tó máa ń mú káyé yẹni ní tòótọ́ ni ìwà ọ̀làwọ́, ẹ̀mí ìdáríjì, ìwà mímọ́, ìfẹ́ àti àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.

2 Jẹ́ Ọ̀làwọ́

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lè láyọ̀ bó bá ń fúnni lẹ́bùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹní bá jẹ́ ọ̀làwọ́ á máa láyọ̀ ní gbogbo ìgbà. Àmọ́ ṣá o, oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn lè gbà jẹ́ ọ̀làwọ́. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ, táwọn èèyàn sì máa ń mọrírì jù lọ ni pé kéèyàn máa fara ṣiṣẹ́ fáwọn ẹlòmíì.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àgbéyẹ̀wò tó dá lórí àìmọtara-ẹni nìkan, ayọ̀ àti ìlera, Ọ̀jọ̀gbọ́n Stephen G. Post sọ pé àwọn tó bá jẹ́ aláìmọtara-ẹni nìkan tí wọ́n sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ sábà máa ń pẹ́ láyé, nǹkan máa ń sunwọ̀n sí i fún wọn, ara wọn máa ń le, èrò inú wọn máa ń yè kooro, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ sorí kọ́.

Síwájú sí i, àwọn tó bá lawọ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní kì í pàdánù ohunkóhun. Òwe 11:25 sọ pé: “Ẹni tí ó . . . ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.” Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, àwọn èèyàn máa ń mọyì àwọn tó bá jẹ́ ọ̀làwọ́ gan-an, wọ́n sì máa ń nífẹ̀ẹ́ wọn, bí wọn ò bá retí àti rí ohunkóhun gbà pa dà; àmọ́ Ọlọ́run ló nífẹ̀ẹ́ wọn tó sì mọyì wọn jù lọ.—Hébérù 13:16.

3 Máa Dárí Jini ní Fàlàlà

“Ẹ máa . . . dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13) Lóde òní, àwọn èèyàn kì í sábà fẹ́ láti dárí ji àwọn ẹlòmíì; wọ́n máa ń yàn láti gbẹ̀san dípò kí wọ́n fi àánú hàn. Kí nìyẹn máa ń yọrí sí? Wọ́n máa ń gbéra wọn ṣépè, wọ́n sì máa ń ta jàǹbá fúnra wọn.

Ìpalára náà lè má mọ síbẹ̀. Ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn The Gazette ti ìlú Montreal, lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Nínú ìwádìí kan tó dá lórí ẹgbẹ̀tàlélógún [4,600] èèyàn tó wà láàárín ọmọ ọdún méjìdínlógún sí ọgbọ̀n ọdún, wọ́n rí i pé béèyàn bá ṣe jẹ́ òǹrorò sí, bó bá ṣe ń ní ìjákulẹ̀ sí, tó sì jẹ́ òṣónú sí”, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀dọ̀fóró onítọ̀hún á ṣe máa bà jẹ́ sí. Kódà, díẹ̀ lára àwọn ìpalára tí wọ́n máa ń ṣe fúnni ju tẹni tó ń mu sìgá lọ! Kì í wulẹ̀ ṣe pé dídárí jini máa ń mú kí okùn ọ̀rẹ́ túbọ̀ yi nìkan ni, àmọ́ ó tún máa ń mú kí ìlera jí pépé!

Báwo lo ṣe lè túbọ̀ máa dárí jini? Kọ́kọ́ mọ irú ẹni tó o jẹ́ dáadáa. Ṣé ìwọ náà kì í múnú bí àwọn èèyàn nígbà míì? Ṣó sì máa ń dùn mọ́ ẹ bí wọ́n bá dárí jì ẹ́? Kí wá ló dé tíwọ náà ò máa fi àánú hàn sáwọn ẹlòmíì? (Mátíù 18:21-35) Lọ́nà yìí, ó tún ṣe pàtàkì pé kó o máa kó ara ẹ níjàánu. Bínú bá ń bí ẹ “ka oókan títí dóríi ẹẹ́wàá” tàbí kó o wá ọ̀nà míì tí ìbínú ẹ á fi rọlẹ̀. Kó o sì jẹ́ kó yé ẹ pé ìkóra-ẹni-níjàánu kì í ṣe ìwà òmùgọ̀. Òwe 16:32 sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.” Pé ó “sàn ju alágbára ńlá” fi hàn pé àṣeyọrí ńlá gbáà ló ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

4 Máa Tẹ̀ Lé Ìlànà Ọlọ́run

“Àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 19:8) Ká sọ ọ́ ní ṣókí, àwọn ìlànà Ọlọ́run dáa fún wa, wọ́n ń dáàbò bò wá, wọ́n ń jẹ́ ká ronú lọ́nà tó tọ́, wọ́n sì ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ń pa wá mọ́ kúrò nínú àwọn ìwà tó lè pani lára bíi lílo oògùn olóró, ìmutípara, ìṣekúṣe àti wíwo àwòrán oníhòòhò. (2 Kọ́ríńtì 7:1; Kólósè 3:5) Ìpalára tó lè tìdí èyí wá lè jẹ́ ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, àìfọkàntánni, kí ìdílé dàrú, kí ìdààmú ọkàn báni, òkùnrùn, ó sì tún lè fa ikú àìtọ́jọ́.

Àmọ́ ní tàwọn tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, wọ́n máa ń ní àjọṣe tó dáa àtèyí tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn èèyàn, wọ́n máa ń mọyì ara wọn, wọ́n sì máa ń ní àlááfíà ọkàn. Nínú Aísáyà 48:17, 18, Ọlọ́run sọ pé òun ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” Ó wá fi kún un pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tó dára jù lọ ni Ẹlẹ́dàá wa ń fẹ́ fún wa. Ó ń fẹ́ ká máa “tọ ọ̀nà” tó máa mú káyé yẹ wá ní tòótọ́.

5 Ní Ìfẹ́ Àìmọtara-Ẹni Nìkan

“Ìfẹ́ a máa gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 8:1) Báwo layé ì bá ṣe rí bí kò bá sí ìfẹ́? Ńṣe ni ìgbésí ayé á rí ráuràu téèyàn ò sì ní láyọ̀! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Bí . . . èmi kò [bá] ní ìfẹ́ [fáwọn ẹlòmíì], èmi kò jámọ́ nǹkan kan. . . . èmi kò ní èrè rárá.”—1 Kọ́ríńtì 13:2, 3.

Irú ìfẹ́ tí Bíbélì ń sọ níbí yìí kì í ṣe ti ìbálòpọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn náà láyè tiẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìfẹ́ tó sàn jù, tó máa ń wà pẹ́ títí, tá a gbé karí àwọn ìlànà Ọlọ́run. a (Mátíù 22:37-39) Ìfẹ́ yìí kì í ṣe ìfẹ́ ojú lásán tó máa ń mú kéèyàn rí tọwọ́ ẹlòmíì gbà, ìfẹ́ àtọkànwá tó máa ń mú kéèyàn ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì ni. Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé ìfẹ́ yìí máa ń ní sùúrù ó sì máa ń hùwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í sì í gbéra ga. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn fẹ́ láti ṣe ohun tó máa ṣàǹfààní fáwọn ẹlòmíì, kì í sì í tètè bínú, àmọ́ ó máa ń dárí jini. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń gbéni ró. Síwájú sí i, ó máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, pàápàá àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé kan náà.—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.

Ọ̀nà táwọn òbí lè gbà fìfẹ́ hàn ni pé kí wọ́n máa fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn, kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n mọ irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù àti bí wọ́n á ṣe máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Irú àwọn ọmọ tá a bá tọ́ dàgbà lọ́nà yìí ò ní máa dààmú, ilé ò ní máa lé wọn sá, wọ́n á mọ̀ pé àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ àwọn ní tòótọ́ wọ́n sì mọyì àwọn.—Éfésù 5:33–6:4; Kólósè 3:20.

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, inú ìdílé kan tó máa ń fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù ni wọ́n ti tọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jack dàgbà. Lẹ́yìn tí Jack dẹni tó ń dá gbé, ó kọ lẹ́tà sáwọn òbí ẹ̀. Apá kan lẹ́tà náà kà báyìí pé: “Ohun tó máa ń wù mí nígbà gbogbo ni pé kí n máa tẹ̀ lé àṣẹ [Bíbélì] tó sọ pé: ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ . . . kí nǹkan sì lè máa lọ dáadáa fún ọ.’ (Diutarónómì 5:16) Ìlànà tí mò ń tẹ̀ lé yìí mú kí nǹkan máa lọ déédéé fún mi. Ìsinsìnyí gan-an ni mo sì túbọ̀ ń mọrírì ẹ̀ pé fífi tẹ́ ẹ fìfẹ́ tọ́ mi dàgbà ló fà á. Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tẹ́ ẹ ṣe láti wò mí dàgbà.” Bó o bá jẹ́ òbí, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ bó o bá rí irú lẹ́tà yìí gbà? Ǹjẹ́ kò ní mú kí ayọ̀ kún inú ọkàn rẹ̀?

Ìfẹ́ tó ń bá ìlànà ṣiṣẹ́ tún máa ń “yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́,” ìyẹn ni òtítọ́ nípa Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. (1 Kọ́ríńtì 13:6; Jòhánù 17:17) Àkàwé kan rèé: Tọkọtaya kan tó níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn pinnu láti jùmọ̀ ka ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Máàkù 10:9 pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀ [nínú ìgbéyàwó], kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” Ó wá di pé kí wọ́n yẹ ọkàn ara wọn wò báyìí. Ṣóòótọ́ ni wọ́n ń ‘yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́ Bíbélì’? Ṣé wọ́n á máa fojú wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́, bí Ọlọ́run ti ń ṣe? Ǹjẹ́ wọ́n múra tán láti sapá kí wọ́n bàa lè fìfẹ́ yanjú àwọn ìṣòro wọn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó wọn ò ní forí ṣánpọ́n, ayọ̀ á sì lè jẹ́ tiwọn.

6 Máa Jẹ́ Kí Ohun Tó O Ṣaláìní Nípa Tẹ̀mí Jẹ Ẹ́ Lọ́kàn

“Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Àwa èèyàn ò dà bí àwọn ẹranko, torí pé a mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ìyẹn la fi máa ń bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi, Kí ni Ọlọ́run tórí ẹ̀ dá ayé? Ṣé Ẹlẹ́dàá wà? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú? Ṣé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?

Kárí ayé, àìmọye èèyàn tó lọ́kàn rere ti rí i pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ìbéèrè tó gbẹ̀yìn kan ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé. Kí ló ní lọ́kàn láti ṣe? Ó fẹ́ kí ayé di Párádísè, káwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé. Sáàmù 37:29 sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”

Dájúdájú, ó wu Ẹlẹ́dàá wa pé káyé yẹ wá ju àádọ́rin [70] tàbí ọgọ́rin [80] ọdún lásán lọ. Ó fẹ́ káyé yẹ wá títí láé! Torí náà, àkókò tó yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá rẹ la wà yìí o. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bó o ṣe ń gba ìmọ̀ yẹn tó o sì ń fi ṣèwà hù nínú ayé rẹ, ìwọ náà á wá rí i pé “ìbùkún Jèhófà . . . ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní gbogbo ibi tí “ìfẹ́” ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí “Májẹ̀mú Tuntun,” ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·gaʹpe. Ìfẹ́ tó kan béèyàn ṣe ń hùwà ni a·gaʹpe. Ó jẹ́ ìfẹ́ tó máa ń mú kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ láti ran ẹlòmíì lọ́wọ́, kéèyàn tẹ̀ lé ìlànà, kó ṣiṣẹ́ bí iṣẹ́, kó sì máa hùwà ọmọlúwàbí. Àmọ́ a·gaʹpe kì í ṣe ìfẹ́ tí kò nímọ̀lára, ìfẹ́ ọlọ́yàyà ni, ó sì ń mára tuni.—1 Pétérù 1:22.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

ÀWỌN NǸKAN TÓ TÚN LÈ MÚ KÁYÉ YẸNI

Ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn. “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.”—Òwe 9:10.

Yan àwọn ọ̀rẹ́ rere. “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.

Má ṣe máa mu àmupara. “Ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì.”—Òwe 23:21.

Má ṣe máa gbẹ̀san. “Má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.”—Róòmù 12:17.

Máa ṣiṣẹ́ kára. “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”—2 Tẹsalóníkà 3:10.

Máa fi Òfin Pàtàkì náà ṣèwà hù. Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.

Máa kó ahọ́n ẹ níjàánu. Ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere, kí ó kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu.”—1 Pétérù 3:10.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 8]

ÌFẸ́ A MÁA WONI SÀN

Dókítà kan tó tún jẹ òǹkọ̀wé, ìyẹn Dean Ornish, sọ pé: “Yálà ara wá yá tàbí à ń ṣàìsàn, inú wá bà jẹ́ tàbí à ń yọ̀, à ń jìyà tàbí a bọ́ lọ́wọ́ ìyà, gbogbo ẹ̀ sinmi lórí wíwà tàbí àìsí ìfẹ́ àti àjọṣe tó dán mọ́rán. Báwọn dókítà bá lè rí oògùn tó lè rọ́pò ìfẹ́ àti àjọṣe tó dán mọ́rán, gbogbo wọn lá fẹ́rẹ̀ẹ́ máa júwe ẹ̀ fáwọn tó ń gbàtọ́jú lọ́dọ̀ wọn. Bí dókítà kan ò bá ní kí aláìsàn lò ó, ẹ̀ṣẹ̀ ló dá yẹn.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ójú ìwé 9]

AYÉ PA DÀ YẸ MÍ LẸ́YÌN TÍ MO TI RÒ Ó PIN

Nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀ nílùú ìbílẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Milanko, tó ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń jẹ́ Balkan, ó wọṣẹ́ ológun. Torí pé ó láyà bíi kìnnìún, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń pè é ní Rambo, ìyẹn orúkọ gbajúmọ̀ òṣèré fíìmù kan tí wọ́n ti hùwà ipá. Àmọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, Milanko ò mọ èyí tí ì bá ṣe mọ́ torí ìwà ìbàjẹ́ àti àgàbàgebè tó rí nínú iṣẹ́ ológun. Ó kọ̀wé pé, “irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ yọrí sí ọ̀pọ̀ ìwàkiwà bíi mímu ọtí líle, mímu sìgá, lílo oògùn olóró, títa tẹ́tẹ́ àti bíbá tajá tẹran lò pọ̀. Gbogbo nǹkan tojú sú mi, mi ò sì mọ èwo gan-an ló yẹ kí n ṣe.”

Ní àkókò táyé nira fún Milanko yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Lẹ́yìn náà, nígbà tó lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin kan tó jẹ́ èèyàn àwọn òbí rẹ̀, ó rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Ohun tó kà nínú ìwé ìròyìn náà wù ú, kò sì pẹ́ tó fi gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òtítọ́ tó kọ́ látinú Bíbélì ràn án lọ́wọ́, ó láyọ̀ ayé ẹ̀ sì wá lójú. Ó sọ pé: “Ó sọ agbára mi dọ̀tun. Mo jáwọ́ nínú gbogbo ìwàkiwà tí mò ń hù, ìgbésí ayé mi yí pa dà, mo sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn tó mọ̀ mí ò pè mí ní Rambo mọ́, Bunny ni wọ́n ń pè mí, ìyẹn orúkọ ìnagijẹ ìgbà ọmọdé mi, torí pé mo ti wá di èèyàn jẹ́jẹ́.”