Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Láti ogún [20] ọdún sẹ́yìn, àwọn ìjábá tó ń wáyé kárí ayé ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́rin. Ó sì lé ní àádọ́talénígba [250] mílíọ̀nù èèyàn tó ń kàgbákò ẹ̀ lọ́dọọdún.ÌWÉ ÌRÒYÌN EL UNIVERSAL, ORÍLẸ̀-ÈDÈ MẸ́SÍKÒ.

“Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ìjì líle, tó sábà máa ń ṣọṣẹ́ láwọn ilẹ̀ tó wà lágbègbè òkun Pàsífíìkì ti gbá òbítíbitì pàǹtírí jọ.” Ibi táwọn pàǹtírí náà wà sì fẹ̀ tó gbogbo ilẹ̀ Ọsirélíà.ÌWÉ ÌRÒYÌN LA DÉPÊCHE DE TAHITI, ERÉKÙṢÙ TAHITI.

Bí wọ́n bá fẹ́ fi ohun ọ̀gbìn bí àgbàdo ṣe àádọ́ta [50] jálá epo tí ọkọ̀ akérò lè lò, àgbàdo tí wọ́n máa lò á pọ̀ débi pé ó máa wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́rin, èyí “tó lè bọ́ èèyàn kan ṣoṣo fún odindi ọdún kan!”—ÌWÉ ÌRÒYÌN GAZETA WYBORCZA, ORÍLẸ̀-ÈDÈ POLAND.

Wọ́n Ń Tẹ Ọ̀pọ̀ Bíbélì Lórílẹ̀-Èdè Ṣáínà

Ọ̀gbẹ́ni Ye Xiaowen tó jẹ́ ọ̀gá ní Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìsìn fún Ìpínlẹ̀, lórílẹ̀-èdè Ṣáínà sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Ṣáínà ti wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń tẹ Bíbélì tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé.” Ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé kan tó wà nílùú Nanjing tó jẹ́ olú ìlú Ẹkùn-Ìpínlẹ̀ Jiangsu, lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, ti tẹ odindi Bíbélì tó jẹ́ àádọ́ta [50] mílíọ̀nù. Ìwé ìròyìn orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ People’s Daily Online, sọ pé, “láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ẹ̀dà Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ jáde [nílé iṣẹ́ yìí] lọ́dọọdún.” Àwọn tó sì pera wọn ní Kristẹni nílùú Ṣáínà túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Àwọn Olè Ń Wá Àwọn Ère Ìsìn

Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Russky Newsweek sọ pé: “Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000] ṣọ́ọ̀ṣì táwọn olè ti lọ kó. Ó sì tó ọ̀kẹ́ méjì [40,000] àwọn ère tí wọ́n ròyìn fún Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Abẹ́lé Nílẹ̀ Rọ́ṣíà pé àwọn olè ti jí kó ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ní báyìí, ilé iṣẹ́ ìjọba náà ti bá Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe àdéhùn pé kí wọ́n fi àmì sára gbogbo ère ṣọ́ọ̀ṣì, débi pé bí wọ́n bá gbé àwọn ère náà sábẹ́ ìtànṣán lílágbára ni wọ́n máa tó lè rí àmì náà. Bí wọ́n bá wá ráwọn ère tí wọ́n jí náà, àmì yìí ló máa jẹ́ káwọn olùwádìí mọ ẹni tó ni wọ́n. Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé, Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Ilẹ̀ Moscow pẹ̀lú fara mọ́ ọgbọ́n tí wọ́n dá yìí, “torí pé àmì ti ‘ayé’ kò lè ṣèpalára kankan fáwọn ohun ìyanu tó wà lára àwọn ère náà.”

Ogun Ti Ba Àwọn Nǹkan Àlùmọ́nì Ilẹ̀ Áfíríkà Jẹ́

Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ International Herald Tribune sọ pé: “Láàárín ọdún 1990 sí 2005, orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún [23] nílẹ̀ Áfíríkà ló lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn tí àpapọ̀ iye owó tó bá a rìn tó nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] bílíọ̀nù owó dọ́là.” Bákan náà, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Làìbéríà, Ellen Johnson-Sirleaf sọ pé: “Owó tó ń bógun lọ nílẹ̀ Áfíríkà tó yanjú ìṣòro àrùn éèdì àti kòkòrò tó ń fà á, tàbí kí wọ́n fi bójú tó ìmọ̀ ẹ̀kọ́, omi, wọ́n sì lè lò ó fún ìtọ́jú àti ìgbógun ti àìsàn ibà àti ikọ́ ẹ̀gbẹ. Wọn ì bá fi owó náà kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ìwòsàn, ilé ìwé, kí wọ́n sì fi ṣe àwọn títì ọlọ́dà.” Ìwé ìròyìn yẹn parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “ká ní kò sí ogun ni, ibi tó láásìkí gan-an ni ilẹ̀ Áfíríkà ì bá jẹ́, dípò tó fi jẹ́ ibi tó tòṣì jù lọ lágbàáyé.”

Rírẹjú Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọkùnrin àti obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tí wọ́n ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [23,000] lọ fi hàn pé béèyàn bá ń rẹjú lọ́sàn-án, ó kéré tán lẹ́ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀, ó lè dín ewu àrùn ọkàn kù dé ìwọ̀n àyè kan. Ọ̀gbẹ́ni Dimitrios Trichopoulos, tó jẹ́ olùwádìí àti onímọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn, ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìlera Aráàlú ti Havard, Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà pé àìfararọ tó ti di bárakú àti másùnmáwo máa ń fa àrùn ọkàn. Ọ̀gbẹ́ni náà wá sọ pé, rírẹjú lọ́sàn-án lè dín másùnmáwo [àti] àrùn ọkàn kù.”