Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Dáa Kí Wọ́n Máa Fi Iná Sun Òkú Èèyàn?

Ṣó Dáa Kí Wọ́n Máa Fi Iná Sun Òkú Èèyàn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Dáa Kí Wọ́n Máa Fi Iná Sun Òkú Èèyàn?

Èrò àwọn kan ni pé fífi iná sun òkú èèyàn títí táá fi di eérú kò fi ọ̀wọ̀ hàn fún òkú náà àti ìrántí rẹ̀. Wọ́n sọ pé, ‘àṣà àwọn abọ̀rìṣà ni, torí náà gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ yẹra fún un.’ Àwọn kan gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ọ̀nà tó bójú mu láti palẹ̀ òkú mọ́. Kí lèrò tìẹ lórí ọ̀ràn yìí?

LÁYÉ ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa sin òkú. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù sin Sárà, aya rẹ̀, sínú ihò àpáta. Bákan náà, inú sàréè kan tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta ni wọ́n gbé òkú Jésù sí. (Jẹ́nẹ́sísì 23:9; Mátíù 27:60) Ǹjẹ́ Bíbélì sọ pé sísin òkú nìkan ni ọ̀nà tó bójú mu láti palẹ̀ òkú mọ́? Ṣó tiẹ̀ sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò fọwọ́ sí fífi iná sun òkú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti palẹ̀ òkú mọ́?

Ṣé Ẹ̀rí Wà Pé Ọlọ́run Ò Fọwọ́ sí Fífi Iná Sun Òkú?

Béèyàn bá kàn ka àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì, ó lè dà bíi pé òkú àwọn tí kò rí ojú rere Ọlọ́run ni wọ́n máa ń fi iná sun. Bí àpẹẹrẹ, Òfin Mósè sọ pé bí ọmọbìnrin ọ̀kan lára àwọn àlùfáà Jèhófà bá di aṣẹ́wó, ńṣe ni kí wọ́n “fi iná sun ọmọbìnrin náà” lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa á. (Léfítíkù 20:10; 21:9) Bákan náà, nígbà tí Ákánì àti ìdílé rẹ̀ ṣàìgbọràn, tí èyí sì mú kí ìlú Áì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù sọ Ákánì àti ìdílé rẹ̀ lókùúta pa, wọ́n sì “fi iná sun wọ́n.” (Jóṣúà 7:25) Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé bí wọ́n ṣe máa ń ṣe òkú àwọn tó bá kú ikú ẹ̀sín rèé, àti pé bí wọ́n ṣe fi iná sun òkú àwọn aṣebi yìí fi hàn pé wọn ò sin òkú wọn lọ́nà ẹ̀yẹ.

Síwájú sí i, nígbà tí Jòsáyà Ọba fẹ́ mú ìbọ̀rìṣà kúrò ní Júdà, ó fọ́ àwọn ibi tí wọ́n sin òkú àwọn àlùfáà tí wọ́n máa ń rúbọ sí òrìṣà Báálì sí, ó sì sun egungun wọn lórí pẹpẹ. (2 Kíróníkà 34:4, 5) Ǹjẹ́ àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé Ọlọ́run ò fojúure wo àwọn òkú tí wọ́n fi iná sun? Bíbélì sọ ohun míì tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá.

Nígbà táwọn Filísínì ṣẹ́gun Sọ́ọ̀lù, ọba Ísírẹ́lì lójú ogun, wọn ò fọ̀wọ̀ hàn fún òkú Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta rárá, wọ́n de òkú wọn mọ́ ara ògiri ìlú náà ní Bẹti-ṣánì. Àmọ́, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé Jabẹṣi-gílíádì gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe ṣe òkú Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yìí, wọ́n tú àwọn òkú náà lára ògiri, wọ́n sì sun wọ́n, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá sin àwọn egungun wọn. (1 Sámúẹ́lì 31:2, 8-13) Béèyàn bá kọ́kọ́ ka ìtàn yìí, ó lè dà bíi pé ohun tó fi hàn ni pé fífi iná sun òkú kò dáa. Ó ṣe tán, èèyàn kéèyàn ni Sọ́ọ̀lù, ó bá Dáfídì tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà jà kò sì rí ojú rere Ọlọ́run títí tó fi kú.

Àmọ́, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára àwọn tó kú pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù. Bí wọ́n ṣe ṣe òkú Sọ́ọ̀lù náà ni wọ́n ṣe ṣe ti Jónátánì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jónátánì kì í ṣèèyàn burúkú. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ló jẹ́ sí Dáfídì, ó sì máa ń gbèjà rẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nípa Jónátánì pé: “Ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀.” (1 Sámúẹ́lì 14:45) Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa ohun táwọn ará Jabẹṣi-gílíádì ṣe yìí, ó gbóríyìn fún wọn, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, ó ní: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí pé ẹ ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yìí sí olúwa yín, sí Sọ́ọ̀lù.” Ó hàn gbangba pé bí wọ́n ṣe fi iná sun òkú Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì yẹn kò kó ìdààmú ọkàn bá Dáfídì.—2 Sámúẹ́lì 2:4-6.

Kò Dí Àjíǹde Lọ́wọ́

Bíbélì kọ́ni ní kedere pé Jèhófà Ọlọ́run máa jí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti kú ní báyìí dìde. (Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 5:28, 29) Ohun tí ìwé Ìṣípayá tàbí Ìfihàn sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nígbà tó ń ṣàpèjúwe ìgbà táwọn òkú máa pa dà sí ìyè ni pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.” (Ìṣípayá 20:13) Èyí kì í sì í ṣe ohun bàbàrà fún Ọlọ́run Olódùmarè láti ṣe, ì báà jẹ́ pé wọ́n sin òkú ẹnì kan ni o, tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi iná sun ún, bóyá inú òkun ló kú sí ni o, tàbí ẹranko ẹhànnà kan ló jẹ ẹ́, tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé bọ́ǹbù ló pa onítọ̀hún pàápàá.

Bíbélì ò sọ ọ̀nà kan pàtó téèyàn gbọ́dọ̀ gbà palẹ̀ òkú mọ́. Jèhófà ò sì ka fífi iná sun òkú léèwọ̀. Àmọ́, ohun tó bójú mu ni pé ká sìnkú lọ́nà iyì àti ẹ̀yẹ.

Àmọ́ ṣá o, ohun kan tó lè nípa lórí ìpinnu téèyàn fẹ́ ṣe nípa ọ̀nà téèyàn máa gbà palẹ̀ òkú mọ́ sinmi lórí èrò àwọn èèyàn nípa àṣà ìsìnkú ládùúgbò ibi téèyàn ń gbé. Ó dájú pé àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bí àwọn aládùúgbò wọn nínú. Bákan náà, kò ní bójú mu láti lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tó lè fi hàn pé èèyàn gba àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké gbọ́, irú bí ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn. Yàtọ̀ sírú àwọn nǹkan báwọ̀nyí, ìpinnu èyíkéyìí tẹ́nì kan bá ṣe nípa bó ṣe fẹ́ kí wọ́n palẹ̀ òkú òun tàbí ti ẹlòmíràn mọ́ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni tàbí ti ìdílé.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wo ni Bíbélì sọ pé wọ́n fi iná sun òkú rẹ̀?—1 Sámúẹ́lì 31:2, 12.

◼ Kí ni Dáfídì ṣe fáwọn ọkùnrin tó sin òkú Sọ́ọ̀lù?—2 Sámúẹ́lì 2:4-6.

◼ Kí ló fi hàn pé fífi iná sun òkú ẹnì kan ò sọ pé kó má jíǹde?—Ìṣípayá 20:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Bíbélì ò sọ ọ̀nà kan pàtó téèyàn gbọ́dọ̀ gbà palẹ̀ òkú mọ́