Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí N Ní Ọ̀rẹ́ Míì?

Ṣó Yẹ Kí N Ní Ọ̀rẹ́ Míì?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣó Yẹ Kí N Ní Ọ̀rẹ́ Míì?

“Bínú bá ń bí mi, ó máa ń wù mí kí n rẹ́ni sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún. Bínú mi ò bá dùn, ó máa ń wù mí kí n rẹ́ni tù mí nínú. Bínú mi bá ń dùn, ó máa ń wù mí kí n rẹni bá mi yọ̀. Ní tèmi, ọ̀rẹ́ ṣe kókó.”—Brittany.

WỌ́N máa ń sọ pé ọmọdé nílò alábàáṣeré, àmọ́ àgbàlagbà nílò ọ̀rẹ́. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú méjèèjì?

Eré nìkan ló máa ń pa àwọn alábàáṣeré pọ̀.

Àwọn ọ̀rẹ́ máa ń mọyì ara wọn.

Síwájú sí i, Bíbélì sọ pé “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Èyí ṣàlàyé ohun tí ọ̀rẹ́ lè ṣe àmọ́ téèyàn ò lè rí níbi téèyàn ti ń lọ ṣeré!

Òtítọ́: Bó o ṣe ń dàgbà, o nílò ọ̀rẹ́ tó

(1) Ní àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra.

(2) Ń gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì.

(3) Máa ní ipa rere lórí ẹ.

Ìbéèrè: Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ọ̀rẹ́ rẹ ní àwọn ohun tá a sọ yìí? Jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.

Èkíní Àwọn Ànímọ́ Tó Fani Mọ́ra

Ohun tó yẹ kó o mọ̀. Kì í ṣe gbogbo ọ̀rẹ́ ló ní ànímọ́ tá a fi lè pè wọ́n ní ọ̀rẹ́ tòótọ́. Bíbélì pàápàá sọ pé “àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wà tí wọ́n nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” (Òwe 18:24) Ìyẹn lè dà bí àsọdùn. Àmọ́ gbé èyí yẹ̀ wò: Ǹjẹ́ o ní “ọ̀rẹ́” tó ti rẹ́ ẹ jẹ rí? Èyí tó ń sọ ohun tí ò dáa nípa ẹ lẹ́yìn ẹ ńkọ́? Irú àwọn nǹkan báyìí lè mú kó o má fọkàn tán ọ̀rẹ́ mọ́. a Bó bá dọ̀rọ̀ ká lọ́rẹ̀ẹ́, máa fi sọ́kàn pé, iye ọ̀rẹ́ tó o ní kọ́ ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kí ìwọ̀nba ọ̀rẹ́ tó o bá ní jẹ́ ojúlówó!

Ohun tó o lè ṣe. Àwọn tó ní ànímọ́ tó ṣeé fara wé ni kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

“Gbogbo èèyàn ló máa ń sọ ohun tó dáa nípa Fiona ọ̀rẹ́ mi. Mo fẹ́ káwọn èèyàn máa sọ ohun tó dáa nípa èmi náà. Ó wù mí kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ tèmi náà ní rere. Ìyẹn wù mí gan-an ni.”—Yvette, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17].

Gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò.

1. Ka Gálátíà 5:22, 23.

2. Wá bi ara ẹ pé, ‘Ṣáwọn ọ̀rẹ́ mi láwọn ànímọ́ tó para pọ̀ di “èso ti ẹ̀mí”?’

3. Kọ orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí. Kó o wá kọ ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ orúkọ ẹ̀.

Orúkọ Ìwà

․․․․․ ․․․․․

․․․․․ ․․․․․

․․․․․ ․․․․․

Àkíyèsí: Bó bá jẹ́ pé ìwà tí ò dáa ló ń wá sí ẹ lọ́kàn nípa wọn, ó lè jẹ́ àkókò nìyí láti wá àwọn ọ̀rẹ́ míì!

Ìkejì—Àwọn Ìlànà Bíbélì

Ohun tó yẹ kó o mọ̀. Bó o bá ń kánjú wá ọ̀rẹ́, àfàìmọ̀ lo ò ní kó ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) “Àwọn arìndìn” tá a sọ níbí yìí ò túmọ̀ sẹ́ni tí ò ní làákàyè o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí àwọn tí kò fetí sí ìkìlọ̀ tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu, irú àwọn tí kò yẹ kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́ nìyẹn!

Ohun tó o lè ṣe. Dípò tí wàá fi máa bá ẹni tó bá ṣáà ti gba tìẹ ṣọ̀rẹ́, ńṣe ni kó o yan ẹni tó o fẹ́. (Sáàmù 26:4) Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kó o máa ṣe ẹ̀tanú o. Ohun tá à ń sọ ni pé, bó o ṣe máa yan ẹni tó o fẹ́ bá ṣọ̀rẹ́ yìí fi hàn pé o lóye tó pọ̀ tó láti “rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Málákì 3:18.

Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ bó bá dọ̀rọ̀ ẹni tó máa gbà ní ‘àlejò nínú àgọ́ ẹ̀,’ kì í gba ẹnì kan ṣá láyè. (Sáàmù 15:1-5) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Máa gbé ìgbé ayé ẹ níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run, àwọn míì tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ sì lè torí ẹ̀ wá bá ẹ ṣọ̀rẹ́. Ẹ óò wá tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́!

“Mo dúpẹ́ pé àwọn òbí mi bá mi wá àwọn ọ̀rẹ́ tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run.”—Christopher, ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13].

Gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò.

Dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

◼ Ṣé ẹ̀rù máa ń bà mí nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi pé wọ́n lè mú kí n ṣe ohun tí mo mọ̀ pé kò dáa?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

◼ Ṣé mo máa ń lọ́ra láti fi àwọn ọ̀rẹ́ mi han àwọn òbí mi torí wọ́n lè sọ pé àwọn ò fẹ́ kí n máa bá wọn rìn?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Àkíyèsí: Bó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí, wá àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn tó jù ẹ́ lọ díẹ̀, àmọ́ tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run?

Ìkẹta—Ipa Rere

Ohun tó yẹ kó o mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Lauren sọ pé: “Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi máa ń gba tèmi níwọ̀n ìgbà tí mo bá ti lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n bá ní kí n ṣe. Èmi sì rèé, mi ò lẹ́ni tí mò ń bá rìn torí náà mo pinnu láti ṣe bíi tiwọn kí wọ́n lè gba tèmi.” Lauren rí i pé ńṣe lẹni tó bá gbà láti máa ṣe ohun táwọn kan fẹ́, á dà bí ọmọ ayò, wọ́n á sì máa tì í síbi tí wọ́n bá fẹ́. Ìwọ náà sì mọ̀ pé ìyẹn ò pọ́n ẹ lé!

Ohun tó o lè ṣe. Fòpin sí àjọṣe ẹ pẹ̀lú àwọn tó bá ń fipá mú ẹ pé kó o yí ìgbé ayé ẹ pa dà kó lè bá tiwọn mu. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú ẹ á dùn pé o ò gbàgbàkugbà, wà á sì lè tipa bẹ́ẹ̀ wá àwọn ọ̀rẹ́ táá ní ipa rere lórí ẹ.—Róòmù 12:2.

“Ẹnì kan tórí ẹ̀ tutù tó sì láàánú ni Clint ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, alábàárò gidi ló jẹ́ fún mi.”—Jason, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

Gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò.

Bí ara ẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

Ṣé mò ń yí ìmúra mi, bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tàbí bí mo ṣe ń ṣe nǹkan pa dà kí n lè tẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ́rùn?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ṣé mo ti ń lọ sáwọn ibi tí kò yẹ tí mi ó bá má lọ ká sọ pé kì í ṣe torí àwọn ọ̀rẹ́ mi?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Àkíyèsí: Bó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí, sọ fáwọn òbí ẹ tàbí kó o lọ sọ fún àgbàlagbà míì pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o tún lè sọ fún Kristẹni alàgbà kan pé kó fún ẹ nímọ̀ràn, kó o sì sọ fún un pé o fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ní ipa rere lórí ẹ.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lóòótọ́, kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe. (Róòmù 3:23) Torí náà, bí ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún ẹ bá dùn ẹ́, tó sì bẹ̀ ẹ́ tọkàntọkàn, má gbàgbé pé “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:8.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Àwọn ànímọ́ wo ló máa wù ẹ jù lọ pé kí ọ̀rẹ́ ẹ ní, kí sì nìdí?

◼ Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kó o ní kó o bàa lè jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Nígbà táwọn òbí mi sọ pé mi ò gbọ́dọ̀ bá àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi rìn mọ́, ní tèmi, àwọn tí wọ́n sọ yìí nìkan ló wù mí láti máa bá rìn. Àmọ́, kò sóhun tó burú nínú ìmọ̀ràn àwọn òbí mi, torí náà, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí gbé e yẹ̀ wò, mo rí i pé àwọn ọ̀rẹ́ gidi wà nítòsí mi.”—Cole.

“Ọ̀nà tó dáa jù lọ tí mo lè gbà mọ àwọn tó wà nínú ìjọ ni pé kí n máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ibẹ̀ ni mo ti dojúlùmọ̀ onírúurú èèyàn lọ́mọdé lágbà. Mo sì wá ń lo àkókò mi pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.”—Yvette.

“Mo gbàdúrà pé kí n lọ́rẹ̀ẹ́, àmọ́ mo wá rí i pé mi ò ṣe nǹkan kan láti wá wọn. Torí náà, èmi fúnra mi bẹ̀rẹ̀ sí báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípàdé. Kò sì pẹ́ tí mo fi ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ tuntun. Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lè sọ pé mi ò dá wà mọ́ látìgbà náà.”—Sam.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

GBÌYÀNJÚ ÀWỌN ÀBÁ YÌÍ

Bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè yan ọ̀rẹ́. Ní kí wọ́n sọ irú ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́. Ṣé wọ́n kábàámọ̀ nítorí irú àwọn tí wọ́n yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí? Ní kí wọ́n sọ ohun tó o lè ṣe tó ò fi ní kó sínú àwọn ìṣòro kan tí wọ́n bá pàdé.

Fi àwọn ọ̀rẹ́ ẹ han àwọn òbí ẹ. Tí kò bá yá ẹ lára láti ṣe bẹ́ẹ̀, á dáa kó o bi ara ẹ pé, ‘Kí ló fà á?’ Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ ń ṣe tó o mọ̀ pé àwọn òbí ẹ ò ní fọwọ́ sí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àfi kó o yáa mọ irú àwọn tó o máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

Ọ̀NÀ MẸ́TA TÓ O LÈ GBÀ NÍ Ọ̀RẸ́ ÀTÀTÀ

Máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ máa jẹ ẹ́ lógún.—Fílípì 2:4.

Máa dárí jini. Má retí pé káwọn ọ̀rẹ́ ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan láìsí àṣìṣe. “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”—Jákọ́bù 3:2.

Fún wọn lómìnira. Kò yẹ kó o máa fọ̀rọ̀ ẹ yọ wọ́n lẹ́nu nígbà gbogbo. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ á dúró tì ẹ́ nígbà tó o bá nílò wọn.—Oníwàásù 4:9, 10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Tó o bá gbà láti máa ṣe ohun táwọn kan fẹ́, kí wọ́n bàa lè máa gba tìẹ, ńṣe lo máa dà bí ọmọ ayò tí ẹni tó ń tayò lè tì síbi tó bá fẹ́