Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Alẹ́ Tó Yẹ Ká Rántí

Alẹ́ Tó Yẹ Ká Rántí

Alẹ́ Tó Yẹ Ká Rántí

A ké sí ẹ láti wá lọ́jọ́ Thursday April 9, 2009

Ní alẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù Kristi kú, ó fi ètò Ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀. Ó lo wáìnì àti àkàrà aláìwú gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ ó sì pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tayọ̀tayọ̀ ké sí ẹ pé kó o dara pọ̀ mọ́ wa láti pa àṣẹ Jésù yìí mọ́, ká jọ ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó máa ń wáyé lọ́dọọdún. Jọ̀wọ́ bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ kó o lè mọ ibi tá a ti máa ṣe é, ọjọ́ tá a máa ṣe é àti aago tó máa bẹ̀rẹ̀.