Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Ẹni Tí Mò Ń Fẹ́ Bá Fi Mí Sílẹ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Ẹni Tí Mò Ń Fẹ́ Bá Fi Mí Sílẹ̀?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Ẹni Tí Mò Ń Fẹ́ Bá Fi Mí Sílẹ̀?

“Ọdún karùn-ún rèé tá a ti ń bá ọ̀rẹ́ wa bọ̀, a sì ti ń fẹ́ra wa fún oṣù mẹ́fà. Nígbà tí kò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́, ó ṣòro fún un láti sọ fún mi. Àfi bí kò ṣe dá sí mi mọ́. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú mi. Ìbànújẹ́ wá dorí mi kodò. Mo wá ń bi ara mi pé, ‘Kí lẹ̀ṣẹ̀ mi gan-an?’”—Rachel. a

ÌBÀNÚJẸ́ lè dípò ayọ̀ fún ẹ bẹ́ni tó ò ń fẹ́ bá fi ẹ́ sílẹ̀. Wo àpẹẹrẹ Jeff àti Susan tí wọ́n fẹ́ra wọn fún ọdún méjì. Láàárín àkókò yẹn, ọ̀rọ̀ wọ́n wọ̀ gan-an. Ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú ni Jeff máa ń kọ lẹ́tà látorí tẹlifóònù ránṣẹ́ sí Susan pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó tún máa ń fún un lẹ́bùn látìgbàdégbà, láti fi hàn pé gbogbo ìgbà ló wà lọ́kàn òun. Susan sọ pé: “Jeff máa ń sapá láti fetí sí mi, ó sì máa ń lóye mi. Ó máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé mo tóbi lọ́wọ́ òun.”

Ká tó wí ká tó fọ̀, Jeff àti Susan ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó wọn àti ibi tí wọ́n máa gbé lẹ́yìn tí wọ́n bá fẹ́ra. Jeff tiẹ̀ béèrè irú òrùka tó máa bá Susan lọ́wọ́ mu. Àmọ́ lójijì ni Jeff já Susan sílẹ̀! Ọ̀rọ̀ náà ba Susan lọ́kàn jẹ́ gan-an. Ńṣe ló wà bí aláìsí, débi pé gbogbo nǹkan tojú sú u. Ó ní: “Ọkàn mi ò pa pọ̀ mọ́, ara mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ yá gágá.” b

Ìdí Tó Fi Máa Ń Dunni

Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Susan yìí bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé, ‘Bó bá jẹ́ ìwọ ni, ṣé wà á lè bọ́ nínú ẹ̀dùn ọkàn náà báyìí?’ (Sáàmù 38:6) Kò sẹ́ni tírú ẹ̀ á ṣẹlẹ̀ sí tí kò ní bara jẹ́. Ó lè jẹ́ pé fífi tẹ́ni tó ò ń fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀ ni ìṣòro tó le jù lọ tó o tíì fara dà rí. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé tẹ́ni téèyàn ń fẹ́ bá fini sílẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà tó pani sáyé. Kódà inú ẹ lè bà jẹ́ gan-an táá fi dà bíi pé àwọn ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, irú bíi:

Rírò pé irọ́ ni. ‘Kò kàn lè parí bẹ́ẹ̀ yẹn. Èrò ẹ̀ máa tó yí pa dà.’

Ìbínú. ‘Báwo ló ṣe máa ṣe irú nǹkan yìí sí mi? Mi ò ní gbà!’

Ìdààmú ọkàn. ‘Mo tẹ́. Kò sẹ́ni tó máa dẹnu ìfẹ́ kọ mí mọ́.’

Gbígba kámú. ‘Mo máa tó gbàgbé ẹ̀. Ó dùn mí o, àmọ́ mo ti ń gbé e kúrò lọ́kàn.’

Ohun tó fini lọ́kàn balẹ̀ ni pé, o gba kámú lórí ọ̀ràn náà. Ìgbà tẹ́ ẹ ti bẹ̀rẹ̀ àti ibi tẹ́ ẹ ti bá ọ̀rọ̀ yín dé ló máa pinnu bó ṣe máa yá tó láti gba kámú. Àmọ́, ní báyìí ná, báwo lo ṣe lè fara da ìdààmú ọkàn tó o ní?

Má Rẹ̀wẹ̀sì

Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́rọ̀ yìí rí pé, Bí ẹkún pẹ́ dalẹ́, ayọ̀ ń bọ̀ lówùúrọ̀. Ọ̀rọ̀ yìí lè má tù ẹ́ nínú nígbà tẹ́ni tó ò ń fẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ́ sílẹ̀. Ìdí ni pé irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ kì í yanjú lójú ẹsẹ̀. Bí àpẹẹrẹ: Bí ọ̀bẹ bá gé ẹ lọ́wọ́, ó máa jinná tó bá yá o, àmọ́ á ṣì máa dùn ẹ́ gan-an báyìí. O ní láti dá ẹ̀jẹ̀ tó ń tibẹ̀ jáde, kó o sì wá nǹkan lò, kára lè tù ẹ́. O tún gbọ́dọ̀ bójú tó o kí kòkòrò àrùn má bàa wọ̀ ọ́. Bọ́rọ̀ ìdààmú ọkàn náà ṣe rí nìyẹn. Ní báyìí, ó ń dùn ẹ́ gan-an. Àmọ́, àwọn nǹkan tó o lè ṣe wà, tí ìrora náà á fi dín kù, tí ìbànújẹ́ ò fi ní borí ẹ. Bó bá yá, ọ̀rọ̀ náà á tán ńlẹ̀, àmọ́ báwo lo ṣe lè ṣe ipa tìẹ? Gbìyànjú àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Má pa ẹkún mọ́ra. Kò burú tó o bá sunkún nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé “ìgbà sísunkún” àti “ìgbà pípohùnréré ẹkún” wà. (Oníwàásù 3:1, 4) Tó o bá sunkún, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o rìndìn. Dáfídì tó tiẹ̀ jẹ́ jagunjagun tó nígboyà sọ nígbà kan tí ìdààmú ọkàn bá a pé: “Láti òru mọ́jú ni mo ń mú kí àga ìrọ̀gbọ̀kú mi rin gbingbin; omijé mi ni mo fi ń mú kí àga ìnàyìn mi kún àkúnwọ́sílẹ̀.”—Sáàmù 6:6.

Tọ́jú ara ẹ. Bí àròdùn bá ti tán ẹ lókun, bó o bá ń ṣeré ìmárale, tó o sì ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ara ẹ á pa dà bọ̀ sípò. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní.”—1 Tímótì 4:8.

Báwo ló ṣe yẹ kí ìlera ara ẹ sunwọ̀n sí i?

․․․․․

Wá nǹkan ṣe. Máa ṣe àwọn nǹkan táá máa múnú ẹ dùn. Àkókò yìí gan-an ni kò sì yẹ kó o máa dá wà. (Òwe 18:1) Bó o bá ń bá àwọn tí ọ̀rọ̀ ẹ jẹ lógún kẹ́gbẹ́, wàá máa rí nǹkan tó dáa ronú lè lórí.

Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe?

․․․․․

Sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Ọlọ́run. Èyí lè má rọrùn. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi bí ẹni tí wọ́n ń fẹ́ bá já wọn sílẹ̀. Wọ́n máa ń sọ pé, ‘bí mo ṣe gbàdúrà tó kí n lè ẹni tí màá fẹ́, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ náà rèé!’ (Sáàmù 10:1) Ṣó tiẹ̀ bójú mu pé ká sọ Ọlọ́run di alárinà tó ń bá tọkùnrin tobìnrin wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́? Kò yẹ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká dá Ọlọ́run lẹ́bi nígbà tẹ́ni téèyàn ń fẹ́ bá lóun ò ṣe mọ́. Ohun tó dá wa lójú nípa Jèhófà ni pé: “Ó bìkítà fún [wa].” (1 Pétérù 5:7) Torí náà, sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún un. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

Àwọn nǹkan pàtó wo lo lè sọ fún Jèhófà nínú àdúrà rẹ bó o ṣe ń fara da ìbànújẹ́ torí pé ẹni tó ò ń fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀?

․․․․․

Tún Èrò Pa

Lẹ́yìn tí ohun gbogbo bá ti pa dà bọ̀ sípò, wá pa dà ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àjọṣe rẹ tó kọjá. Bó o bá ti ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa dáa kó o ṣàkọsílẹ̀ ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Ǹjẹ́ ó sọ ìdí tó fi fi ẹ́ sílẹ̀ fún ẹ? Bó bá sọ ọ́, kọ ọ́ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí, bó ò tiẹ̀ fara mọ́ ọn.

․․․․․

◼ Àwọn nǹkan wo lo tún rò pé ó lè fà á?

․․․․․

Bó o bá ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ nǹkan kan wà tó yẹ kó o ti ṣe kí nǹkan yìí máa bàa ṣẹlẹ̀? Bó bá wà, kí ni?

․․․․․

Ǹjẹ́ o ti rí ohunkóhun kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí táá jẹ́ kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i, tàbí kí ọ̀nà tó o gbà ń wo nǹkan gbé pẹ́ẹ́lí sí i?

․․․․․

Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí wàá fẹ́ ṣe lọ́nà tó yàtọ̀ tó o bá tún ń fẹ́ ẹlòmíì?

․․․․․

Òótọ́ ni pé, bó o ṣe fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra rí kọ́ ló rí yìí. Àmọ́, má gbàgbé pé: Bí ìjì bá ń jà, tójò sì ń rọ̀, ó rọrùn láti máa wò ó bíi pé ìjì nàá ò ní rọlẹ̀ àti pé òjò náà ò ní dá bọ̀rọ̀, àmọ́ bó bá yá, òjò á dá, ojú ọjọ́ á sì mọ́lẹ̀ kedere. Bọ́rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe rí náà nìyẹn. Nígbà tó yá, ìdààmú ọkàn wọn kásẹ̀ nílẹ̀, ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́kàn kúrò níbẹ̀. Bó pẹ́ bó yá, ìwọ náà á lè gbọ́kàn kúrò níbẹ̀!

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin làwọn tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, síbẹ̀ àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀ kan àwọn ọkùnrin náà.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kí lo rí kọ́ nípa ara ẹ látinú ọ̀rọ̀ ìwọ àtẹni tó fi ẹ́ sílẹ̀?

◼ Kí lo rí kọ́ nípa ọkùnrin tàbí obìnrin nínú àpilẹ̀kọ yìí?

◼ Ta lo lè fọ̀rọ̀ lọ̀ bí ìdààmú ọkàn bá bá ẹ torí pé ẹni tó ò ń fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

ÀBÁ

Susan tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ó sì ń mú un kiri kó bàa lè máa kà á nígbà tó bá tún ronú kan ohun tó ṣẹlẹ̀. Ìwọ náà lè fẹ́ láti lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ yìí lọ́nà yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bí ẹni tó ò ń fẹ́ bá fi ẹ́ sílẹ̀, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tó o fara pa, ó máa dùn ẹ́ o, àmọ́ ó máa jinná tó bá yá