Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kí Ọkọ Tàbí Aya Má Dalẹ̀ Ara Wọn?

Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kí Ọkọ Tàbí Aya Má Dalẹ̀ Ara Wọn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kí Ọkọ Tàbí Aya Má Dalẹ̀ Ara Wọn?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ gbọ́ pé ọkọ tàbí aya lójú síta. Bọ́rọ̀ ṣe rí lójú àwọn èèyàn yìí bá Bíbélì mu, ó ní: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.” —Hébérù 13:4.

ṢÉ OHUN tá à ń sọ ni pé, bí tọkọtaya kan ò bá ṣáà ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹlòmíì, wọn ò dalẹ̀ ara wọn nìyẹn? Bí baálé ilé tàbi ìyàwó ilé bá ń fọkàn ronú pé òun ń bá obìnrin tàbí ọkùnrin míì lò pọ̀ ńkọ́? Bí ọkọ tàbí aya bá ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú obìnrin tàbí ọkùnrin míì, ṣé wọ́n ń “dalẹ̀ ara wọn” náà nìyẹn?

Ṣó Léwu Kéèyàn Máa Fọkàn Ronú Pé Òun Ń Bá Ẹlòmíì Lò Pọ̀?

Apá tó bá ìwà ẹ̀dá mu tó sì ṣe pàtàkì ni Bíbélì ka ìbálòpọ̀ sí fún tọkọtaya; ó máa ń fún wọn ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Òwe 5:18, 19) Àmọ́, lóde òní ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi gbà gbọ́ pé kò sóhun tó burú nínú kí ọkọ tàbí aya máa fọkàn ronú pé àwọn ń bá ẹlòmíì lò pọ̀. Ṣé kò séwu nínú irú àfọkànrò bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, béèyàn ò bá ṣáà ti ṣàgbèrè?

Ẹní bá ń gbé irú èrò bẹ́ẹ̀ sọ́pọlọ wulẹ̀ ń wá bó ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn ni. Irú ìfẹ́ ìmọtara-ẹni bẹ́ẹ̀ ò sì bá ìmọ̀ràn tí Bíbélì fáwọn lọ́kọláya mu. Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìbálòpọ̀ rèé: “Aya kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀; bákan náà, pẹ̀lú, ọkọ kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n aya rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:4) Bí ọkọ tàbí aya bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí, kò ní sọ ìbálòpọ̀ di ọ̀nà táá máa gbà tẹ́ ìfẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn, lẹ́yìn tó bá ti fọkàn ronu pé òun ń bá ẹlòmíì lò pọ̀. Èyí á sì jẹ́ káwọn méjèèjì máa túbọ̀ láyọ̀.—Ìṣe 20:35; Fílípì 2:4.

Bí ẹni tó ń fọkàn ronú pé òun ń bá ẹlòmíì tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya òun lò pọ̀ bá láǹfààní àtiṣe ohun tó ń gbé sọ́pọlọ, ó máa ba ọkọ tàbí aya rẹ̀ lọ́kàn jẹ́ gidigidi. Béèyàn bá ń gbé èrò pé òun ń bá ẹlòmíì lò pọ̀ sọ́pọlọ, ṣó máa rọrùn fún un láti tètè ṣe àgbèrè? Ó dájú pé bó ṣe máa rí gan-an nìyẹn. Bíbélì ṣàlàyé pé ohun téèyàn bá ń rò lọ́kàn lèèyàn máa ń hù níwà. Ó ní: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 1:14, 15.

Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Bí o kì í bá gbé èròkerò tó lè mú ẹ ṣàgbèrè sọ́pọlọ, wàá máa fi ìṣọ́ “ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ” mìmì kan ò sì ní mi ìgbéyàwó rẹ.—Òwe 4:23.

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Dalẹ̀ Ara Yín Nípa Ríro Èròkerò?

Bí ìgbéyàwó bá máa tọ́jọ́, àfi kí tọkọtaya ní “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe” fún ara wọn. (Orin Sólómọ́nì 8:6; Òwe 5:15-18) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú kẹ́ni tó ti ṣègbéyàwó ní obìnrin tàbí ọkùnrin lọ́rẹ̀ẹ́, ọkọ tàbí aya ẹ̀ ló yẹ kó máa gba àkókò àti àfiyèsí ẹ̀ jù lọ, èrò nípa ẹ̀ náà ló sì yẹ kó máa gbà á lọ́kàn. Bí tọkọtaya bá jẹ́ kí àjọṣe èyíkéyìí gba ẹ̀tọ́ ọkọ tàbí aya wọn mọ́ wọn lọ́wọ́, bí ẹní dalẹ̀ ara wọn ni, bí ò tiẹ̀ la ìbálòpọ̀ lọ. a

Báwo nirú àjọṣe bẹ́ẹ̀ ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀? Ó lè jọ pé ọkùnrin tàbí obìnrin kan fà ẹ́ mọ́ra ju ọkọ tàbí aya ẹ lọ, ó sì lè jẹ́ pé ó ní ìgbatẹnirò jù ú lọ. Bó o bá ń wà pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀ níbi iṣẹ́ tàbí níbi àríyá, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀ àṣírí, tó fi mọ́ àwọn ìṣòro tàbí ìjákulẹ̀ tó ò ń bá pàdé nínú ìgbéyàwó rẹ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, á di pé kó o máa wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. Bó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ lójúkojú tàbí lórí fóònù, tó o sì ń kọ lẹ́tà sí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àṣírí ara ẹ fún un. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tó yẹ kó mọ sáàárín tọkọtaya, kò sì yẹ kí wọ́n máa tú irú “ọ̀rọ̀ àṣírí” bẹ́ẹ̀ síta.—Òwe 25:9.

Bọ́kàn ẹ bá ń fa sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ, tó o sì ń díbọ́n pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, ò ń tanra ẹ ni o! Jeremáyà 17:9 sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè.” Bó o bá jẹ́ kòríkòsùn pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin míì, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mò ń dára mi láre àbí mo máa ń ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí? Bí ọkọ tàbí aya mi bá gbọ́ ohun tá a jọ ń sọ, ṣé ara ẹ̀ máa gbà á? Báwo ló ṣe máa rí lára mi bí ọkọ tàbí aya mi bá ń bá ẹlòmíì ṣe irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀?’—Mátíù 7:12.

Bí tọkọtaya bá ń yan ọ̀rẹ́ èké, ìgbéyàwó wọn lè forí ṣánpọ́n, torí pé bọ́kàn wọn bá ti ń fa sí ẹlòmíì tí ọkàn onítọ̀hún náà sì ń fà sí wọn, wọ́n máa bára wọn lò pọ̀ kẹ́yìn ni. Ńṣe lọ̀rọ̀ náà rí bí ìkìlọ̀ Jésù pé: ‘Láti inú ọkàn-àyà ni panṣágà ti ń wá.’ (Mátíù 15:19) Àmọ́ ṣá o, bí wọn ò bá tiẹ̀ ṣe panṣágà, wàhálà tó máa dá sílẹ̀ lè burú débi pé wọ́n lè má gbẹ̀rí ara wọn jẹ́ mọ́. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Karen b sọ pé: “Nígbà tí àṣírí tú sí mi lọ́wọ́ pé ojoojúmọ́ ni Mark, ọkọ mi, ń bá obìnrin míì sọ̀rọ̀ ní bòókẹ́lẹ́ lórí fóònù, ọkàn mi gbọgbẹ́. Ó ṣòro fún mi láti gbà pé wọn ò tíì máa bára wọn sùn. Mi ò rò pé mo tún lè gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́ mọ́ láé.”

Bó o bá ní ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lọ́rẹ̀ẹ́, ṣe ni kó o lọ so ewé agbéjẹ́ẹ́ mọ́wọ́ o. Bí èròkerò bá wá sí ẹ lọ́kàn, má ṣàì kọbi ara sí i, má sì ṣe dára ẹ láre bí ọkàn ẹ bá ń dá ẹ lẹ́bi nípa irú àjọṣe bẹ́ẹ̀. Bó o bá rí i pé àjọṣe àárín ìwọ àti ẹlòmíì fẹ́ jin ìgbéyàwó ẹ lẹ́sẹ̀, tètè dín irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ kù tàbí kó o fòpin sí i. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.”—Òwe 22:3.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Ba Àárín Yín Jẹ́

Ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá wa ni pé kí ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tímọ́tímọ́ jù lọ láàárín èèyàn méjì. Ó sọ pé ọkọ àti aya “yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Bí wọ́n ṣe di ara kan yìí ò mọ sórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ o. Ó tún kan pé kí wọ́n máa gba tara wọn rò, ohun tó sì máa ń mú kí èyí ṣeé ṣe jù lọ ni pé kí wọ́n jẹ́ aláìmọ tara ẹni nìkan, kí wọ́n máa gbẹ̀rí ara wọn jẹ́, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn. (Òwe 31:11; Málákì 2:14, 15; Éfésù 5:28, 33) Bó o bá ń fi àwọn ìlànà wọ̀nyí sílò, kò ní jẹ́ kí èròkerò tàbí gbígbé ẹ̀tọ́ tó jẹ́ ti ọkọ tàbí aya ẹ fẹ́lòmíì ba ìgbéyàwó ẹ jẹ́.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká kíyè sí i pé, níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì yàtọ̀ sí ọkọ tàbí aya ẹni nìkan ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya kọ́ra wọn sílẹ̀.—Mátíù 19:9.

b Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ṣé ẹní bá ń fọkàn ronú pé òun ń bá obìnrin tàbí ọkùnrin míì lò pọ̀ lè ṣàgbèrè?—Jákọ́bù 1:14, 15.

◼ Ṣé jíjẹ́ kòríkòsùn pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin míì lè ba ìgbéyàwó ẹ jẹ́?—Jeremáyà 17:9; Mátíù 15:19.

◼ Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbéyàwó rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in?1 Kọ́ríńtì 7:4; 13:8; Éfésù 5:28, 33.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

“Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:28