Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Kí Ni Kò Tọ̀nà Nínú Àwòrán Yìí?
Ka Jóṣúà 2:15-18; 6:15-21; 7:1, 20, 21. Wo àwòrán yìí. Àwọn nǹkan wo ni kò tọ̀nà nínú àwòrán náà? Kọ ìdáhùn rẹ sórí àwọn ìlà yìí.
1. ․․․․․
2. ․․․․․
3. ․․․․․
4. ․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká má máa mú nǹkan tí kì í ṣe tiwa?
Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí
Dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 14 Kí ni ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ ni lójú gbogbo èèyàn? Hébérù 13:․․․
OJÚ ÌWÉ 14 Lẹ́yìn tí ìfẹ́ ọkàn bá ti lóyún, kí ló máa ń bí? Jákọ́bù 1:․․․
Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Wòlíì?
Ka 2 Kíróníkà 18:1-19:3. Lẹ́yìn náà, dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
5. ․․․․․
Kí lorúkọ wòlíì tí Ọba Áhábù kórìíra?
6. ․․․․․
Kí nìdí tí Áhábù fi kórìíra wòlíì náà?
7. ․․․․․
Kí ni wòlíì náà sọ fún Áhábù, kí ni Áhábù sì ṣe?
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Ìgbà wo ló yẹ kó o lo ìgboyà bíi ti wòlíì yìí?
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ
1. Àwọn ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kọ lu ìlú náà.
2. Okùn tí Ráhábù so mọ́ fèrèsé kì í ṣe aláwọ̀ búlúù, aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ni.
3. Kì í ṣe ère ni Ákáánì jí, bí kò ṣe ẹ̀wù kan, wúrà gbọọrọ kan àti ṣékélì fàdákà.
4. Kì í ṣe alẹ́ ni wọ́n gbéjà kò wọ́n.
5. Mikáyà.
6. Ó kéde àwọn ìdájọ́ Jèhófà sórí Áhábù.
7. Pé Áhábù máa ṣubú lójú ogun. Áhábù ni kí wọ́n ju Mikáyà sí àtìmọ́lé.