O Lè Túbọ̀ Máa Rántí Nǹkan!
O Lè Túbọ̀ Máa Rántí Nǹkan!
“Rírántí nǹkan máa ń mú kí nǹkan gbádùn mọ́ni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a ò ní mọbi tá a wà, ńṣe la ó máa dà bí àjèjì sí ara wa lójoojúmọ́. Lọ́jọ́ gbogbo, tòní ò ní jọ tàná, a ò ní rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, a ò sì ní mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.”—ÌWÉ “MYSTERIES OF THE MIND.”
KÍ NÌDÍ tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù táwọn ẹyẹ kan ti tọ́jú àwọn kóró èso pa mọ́ de ìgbà òtútù wọ́n ṣì máa ń rántí ibi tí wọ́n tọ́jú ẹ̀ sí? Kí ló fà á táwọn ọ̀kẹ́rẹ́ fi máa ń rántí ibi tí wọ́n bo èkùrọ́ mọ́, nígbà tó jẹ́ pé àwa èèyàn lè fi kọ́kọ́rọ́ síbì kan, ká má sì rántí ibi tá a fi sí láàárín wákàtí kan péré? Kò sírọ́ ńbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wa la máa ń gbàgbé nǹkan. Àmọ́, bá a ṣe jẹ́ aláìpé tó yìí, ọpọlọ wa ṣì ní agbára kíkàmàmà láti kẹ́kọ̀ọ́ ká sì rántí nǹkan. Ohun tó lè mú ká túbọ̀ máa rántí nǹkan ni pé ká máa lo ọpọlọ wa dáadáa.
Bí Ọpọlọ Ṣe Lágbára Tó
Ọpọlọ èèyàn wúwo tó nǹkan bí ìwọ̀n ẹ̀kún omi agolo mílíìkì márùn-ún, ó sì tóbi tó ọsàn kékeré. Síbẹ̀, ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù àwọn ohun tín-tìn-tín ló wà nínú ọpọlọ, gbogbo wọn ló sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lọ́nà tó díjú tó sì ṣàrà ọ̀tọ̀. Kódà, ọ̀kan lára àwọn ohun tín-tìn-tín yìí lè bá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ohun tín-tìn-tín mìíràn ṣiṣẹ́. Bí gbogbo wọn ṣe so kọ́ra yìí mú kí ọpọlọ wa lágbára láti ṣiṣẹ́ lórí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni kó sì tọ́jú ọ̀pọ̀ ìsọfúnni pa mọ́. Ohun tó sábà máa ń ṣòro ni pé kéèyàn rántí àwọn ìsọfúnni kan lásìkò tó bá nílò rẹ̀. Àwọn kan tètè máa ń rántí nǹkan gan-an, kódà àwọn tí wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ kàwé tàbí tí wọn ò kàwé rárá.
Bí àpẹẹrẹ, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, àwọn asọ̀tàn kan tí wọn ò kàwé lè sọ orúkọ àtìrandíran èèyàn tó ti gbé lábúlé wọn. Àwọn asọ̀tàn yìí ran òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà, Alex Haley, lọ́wọ́ láti ṣèwádìí ìtàn ìran mẹ́fà nínú ìlà ìdílé rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Gáḿbíà. Ọ̀gbẹ́ni Alex Haley yìí ló gba ẹ̀bùn Pulitzer lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lórí ìwé rẹ̀ tó ní àkọlé náà, Roots. Ọ̀gbẹ́ni Haley sọ pé: “Mo gbóṣùbà fáwọn asọ̀tàn ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn tá a máa ń sọ nípa wọn lónìí pé, bí asọ̀tàn ilẹ̀ Áfíríkà kan bá kú, ńṣe lo dà bí ìgbà tí ibi ìkówèésí kan jó kanlẹ̀.”
Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ gbajúgbajà olùdarí orin aláré ará Ítálì kan tó ń jẹ́ Arturo Toscanini, táwọn èèyàn gbà pé ó jẹ́ olùdarí orin aláré tó mòye nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n pè é ní pàjáwìrì láti wá darí orin náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ríran dáadáa, ó darí gbogbo orin aláré náà, ìyẹn Aida, láìwòwé!
Itú táwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí pa lè yani lẹ́nu gan-an. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló lè rántí ọ̀pọ̀
nǹkan ju bí wọ́n ṣe rò lọ. Ṣó o fẹ́ túbọ̀ máa rántí nǹkan dáadáa?Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Túbọ̀ Máa Rántí Nǹkan
Ìpele mẹ́ta ni bí ọpọlọ ṣe ń gba ìsọfúnni pín sí: gbígba ìsọfúnni wọlé, títọ́jú ìsọfúnni pa mọ́ àti rírántí. Béèyàn bá ti nímọ̀lára nǹkan, ọpọlọ á gbà á wọlé. Lẹ́yìn náà ló máa tọ́jú ìsọfúnni náà pa mọ́, kó bàa lè rántí tó bá yá. Bí ọ̀kan lára àwọn ìpele mẹ́ta yìí bá daṣẹ́ sílẹ̀, lèèyàn máa ń gbàgbé nǹkan.
Onírúurú ọ̀nà ni rírántí nǹkan pín sí, lára wọn ni ìmọ̀lára ojú ẹsẹ̀, ìrántí fún ìgbà díẹ̀ àti ìrántí fún ìgbà pípẹ́. Ìmọ̀lára ojú ẹsẹ̀ máa ń mú kéèyàn mọ nǹkan lára, bóyá nípa gbígbóòórùn, rírí nǹkan tàbí fífọwọ́ ba nǹkan. Ìrántí fún ìgbà díẹ̀ ni kéèyàn rántí ìwọ̀nba nǹkan fún àkókó kúkúrú, kó tó di pé ó gbàgbé ẹ̀. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ ká lè ro nọ́ńbà pọ̀, ká lè sáré há nọ́ńbà tẹlifóònù sórí títí tá a ó fi tẹ̀ ẹ́ sórí tẹlifóònù, ó sì máa ń mú ká rántí apá àkọ́kọ́ nínú gbólóhùn kan nígbà tá a bá ń ka apá kejì. Àmọ́, ohun kan ni pé, ó níbi tí agbára irú ìrántí yìí mọ.
Bó o bá fẹ́ máa rántí nǹkan títí gbére, àfi kó wà níbi tí ọpọlọ ẹ máa ń tọ́jú ìsọfúnni tó máa ń wà fún ìgbà pípẹ́ sí. Báwo lo ṣe lè fi ìsọfúnni síbẹ̀? Àwọn ìlànà wọ̀nyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́.
◼ Nífẹ̀ẹ́ sí Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ò ń kọ́, kó o sì máa rántí ìdí tó o fi ń kọ́ ọ. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti mọ̀ pé, tó o bá fọkàn sí ohun tó ò ń kọ́, wàá túbọ̀ máa rántí nǹkan ọ̀hún. Kókó yìí lè ran àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ gidigidi. Bí wọ́n bá ń ka Bíbélì kí wọ́n bàa lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa kọ́ àwọn èèyàn nípa rẹ̀, èyí á mú kí wọ́n máa rántí ohun tí wọ́n ń kọ́ dáadáa.—Òwe 7:3; 2 Tímótì 3:16.
◼ Fiyè sí Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Ìwé Mysteries of the Mind sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó sábà máa ń fà á téèyàn fi máa ń gbàgbé nǹkan ni pé onítọ̀hún ò fiyè sí ohun tó ń kọ́.” Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fiyè sí ohun tó ò ń kọ́? Nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ò ń kọ́, bó bá sì ṣeé ṣe kó o máa kọ àkọsílẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ṣíṣe àkọsílẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀, ó tún máa ń jẹ́ kéèyàn lè ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó kọ́ nígbà tó bá yá.
◼ Lóye Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Òwe 4:7 sọ pé: “Pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.” Tí ohun tó ò ń kọ́ ò bá yé ẹ, o ò ní rántí ẹ̀ dáadáa, tàbí kó o tiẹ̀ má rántí rárá. Béèyàn bá lóye ohun tó ń kọ́, ó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ bí èrò méjì ṣe jọra, èèyàn á sì mọ bó ṣe máa sọ wọ́n di ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ mẹkáníìkì kan bá lóye bí ẹ́ńjìnnì ṣe ń ṣiṣẹ́, á lè rántí ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ẹ́ńjìnnì náà.
◼ Mọ Béèyàn Ṣe Ń Ṣètò Nǹkan To àwọn èrò àtàwọn kókó ọ̀rọ̀ tó bá jọra pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá fẹ́ lọ ra nǹkan lọ́jà, á rọrùn láti rántí àwọn nǹkan náà, bó o bá to àwọn tó o lè rí níbì kan náà pa pọ̀ sójú kan. Irú bí ẹran, ẹ̀fọ́, èso àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kí wọ́n má bàa pọ̀ jù, o lè pín wọ́n sí ọ̀nà bíi márùn-ún sí méje. A sábà máa ń pín nọ́ńbà tẹlifóònù sí ọ̀nà mẹ́ta kí wọ́n bàa lè rọrùn láti rántí. Ó tún lè ṣèrànwọ́ tó o bá ṣètò àwọn nǹkan tó o fẹ́ rà lọ́nà tí wọ́n á fi tò tẹ̀ léra, bóyá lọ́nà ABD.
◼ Àkàtúnkà Tó o bá ń ka àwọn ohun tó o fẹ́ máa rántí sókè lákàtúnkà (bóyá ọ̀rọ̀ èdè àjèjì kan tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀), ó máa mú káwọn nǹkan
tín-tìn-tín tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nínú ọpọlọ túbọ̀ lágbára. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, bó o ṣe ń pe àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ń mú kó o pọkàn pọ̀ dáadáa. Ẹ̀ẹ̀kejì, olùkọ́ ẹ lè gbọ́ bó o ṣe ń pe àwọn ọ̀rọ̀ yẹn kó sì sọ ibi tó kù díẹ̀ sí tàbí kó sọ bó o ṣe ṣe dáadáa sí. Ẹ̀ẹ̀kẹta, tó o bá ń fetí ara ẹ gbọ́ ohun tó ò ń sọ, ńṣe ló ń mú káwọn apá ibòmíì nínú ọpọlọ rẹ máa ṣiṣẹ́.◼ Fojú Inú Yàwòrán Máa fojú inú yàwòrán ohun tó o bá fẹ́ rántí. Ó tún lè ṣèrànwọ́ tó o bá ń yàwòrán ohun tó ò ń rò lọ́kàn sórí ìwé kan. Bíi ti àkàtúnkà, fífojú inú yàwòrán nǹkan máa ń jẹ́ káwọn apá ibi tó yàtọ̀ síra nínú ọpọlọ ẹ máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Bó o bá ṣe ń lo ọpọlọ ẹ tó bẹ́ẹ̀ ni ohun tó ò ń kọ́ á ṣe máa wọ̀ ẹ́ lórí tó.
◼ Máa Ṣe Ìfiwéra Tó o bá ń kọ́ nǹkan tuntun, máa fi wé àwọn tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Bó o bá ń so àwọn ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rò mọ́ àwọn nǹkan tó ti wà nínú ọpọlọ tẹ́lẹ̀, ó máa mú kó rọrùn fún ọpọlọ láti gbà á wọlé, ó tún máa ń rọrùn láti rántí àwọn ìsọfúnni náà. Fífi nǹkan tuntun wé àwọn tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, á jẹ́ kí ọpọlọ mọ̀ pé o ṣì nílò àwọn ìsọfúnni náà. Bí àpẹẹrẹ, kó o lè máa rántí orúkọ ẹnì kan, ńṣe ni kó o so ó mọ́ àwọn nǹkan kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìrísí onítọ̀hún tàbí kó o so ó mọ́ nǹkan míì tó máa jẹ́ kó o tètè rántí orúkọ náà. Bí ohun tó o so orúkọ náà mọ́ bá ṣe ń dẹ́rìn-ín pani tó tàbí bó ṣe dà bí i pé tí kò nítumọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa tètè rántí sí. Ní kúkúrú ṣá, a gbọ́dọ̀ máa ronú nípa àwọn èèyàn àtàwọn nǹkan tá a bá fẹ́ máa rántí.
Ìwé kan tó ní àkọlé náà, Searching for Memory, sọ pé: “Bá a bá kàn ń gbé ayé, tá ò láròjinlẹ̀ tá ò sì ronú nípa àyíká wa àtàwọn nǹkan tá a ti là kọjá, a lè má ní òye kíkún nípa àwọn ibi tá a ti dé àtàwọn ohun tá a ti gbé ṣe láyé.”
◼ Mú Káwọn Nǹkan Tó O Ti Kọ́ Fìdí Múlẹ̀ Jẹ́ káwọn nǹkan tó o ti kọ́ yẹn silẹ̀ sínú ọpọlọ ẹ, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dáa jù lọ tó o lè gbà ṣe èyí ni pé kó o ṣàtúnyẹ̀wò àwọn nǹkan tó o ti kọ́, bóyá kó o máa tún un sọ fáwọn ẹlòmíì. Bó o bá ní ìrírí kan tó gbádùn mọ́ni tàbí o kà nípa nǹkan kan tó ń gbéni ró nínú Bíbélì tàbí nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, sọ ọ́ fún ẹnì kan. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin méjèèjì lẹ máa jàǹfààní. Ìyẹn ò ní jẹ́ kó o gbàgbé òun tó o kọ́, á sì fún ẹni tó o sọ ọ́ fún ní ìṣírí. Abájọ tí wọ́n fi máa ń sọ pé “iṣu àtẹnumọ́rọ̀ kì í jóná.”
Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kéèyàn Tètè Rántí Nǹkan
Nílẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù ayé ọjọ́un, àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ máa ń sọ àwọn àsọyé tó gùn láìwòwé. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Wọ́n máa ń ta ọgbọ́n táá mú kí wọ́n lè tètè rántí nǹkan. Irú ọgbọ́n yìí máa ń mú kéèyàn gba ìsọfúnni sínú ọpọlọ, èyí tó lè mú kéèyàn rántí ẹ̀ fúngbà pípẹ́, kó sì wá sí ọpọlọ nígbà téèyàn bá fẹ́ lò ó.
Irú èyí táwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Gíríìkì àtijọ́ máa ń lò ni ohun tó máa ń jẹ́ kí wọ́n rántí ibi tí nǹkan wà, ọ̀gbẹ́ni Simonides ará Ceos tó jẹ́ akéwì ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ló kọ́kọ́ ṣàlàyé irú ọ̀nà yìí lọ́dún 477 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Irú ọ̀nà yìí ní í ṣe pẹ̀lú ìṣètò, “Fojú Inú Yàwòrán.”
fífojú inú yàwòrán àti fífi àwọn ohun tó jọra wé ara wọn, irú bí ohun pàtàkì kan tó gbàfiyèsí lójú ọ̀nà ibì kan tàbí nǹkan kan tó wà nínú yàrá tàbí ilé ẹnì kan. Àwọn tó máa ń lo irú ọgbọ́n yìí máa ń fojú inú yàwòrán nǹkan, wọ́n sì máa ń fi gbogbo nǹkan tí wọn ò bá fẹ́ gbàgbé wé àwọn ohun pàtàkì tó wà níbi pàtó kan tàbí nǹkan míì. Bí wọ́n bá wá fẹ́ rántí nǹkan kan, ńṣe ni wọ́n á kàn tún fojú inú yàwòrán nǹkan ọ̀hún.—Wo àpótí náà,Ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa àwọn tó fakọ yọ nínú ìdíje àwọn tó ní ọpọlọ tó jí pépé jù lọ lágbàáyé, tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún fi hàn pé, kì í ṣe torí pé ọpọlọ wọn pé lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ló mú kí wọ́n tètè rántí nǹkan lọ́nà tó jáfáfá ju tàwọn yòókù lọ. Nǹkan míì tún wá ni pé, ọjọ́ orí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó kópa nínú ìdíje náà wà láàárín ogójì [40] sí àádọ́ta [50]. Kí ló mú kí wọ́n fakọ yọ? Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sọ pé lílo àwọn ohun tó máa ń mú kéèyàn tètè rántí nǹkan lọ́nà tó jáfáfá ló ran àwọn lọ́wọ́.
Tó o bá fẹ́ rántí àwọn ọ̀rọ̀ kan, kí lo lè ṣe? Ohun kan tó gbéṣẹ́ tó lè mú kó o rántí ni lílo ìkékúrú orúkọ, ìyẹn mímú àwọn lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ kan láti fi ṣe ọ̀rọ̀ tuntun. Ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ káàárọ̀-o-ò-jíire máa ń rántí àwọn nǹkan nípa kíkọ ọ́ lórin. Irú bí àwọn ọjọ́ tó wà nínú ọ̀sẹ̀, oṣù tó wà nínú ọdún, àtàwọn ìwé inú Bíbélì. Òmíràn ni lílo àwọn ìlà tí wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ àdìtú sí, àwọn Hébérù ayé ọjọ́un lo ọ̀nà yìí dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀pọ̀ sáàmù inú Bíbélì, ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ ní ẹsẹ kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ẹsẹ kan bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà èdè Hébérù kan. (Wo Sáàmù 25, 34, 37, 111, 112 àti 119.) Ọ̀nà tó wúlò téèyàn lè gbà rántí nǹkan yìí mú káwọn akọrin lè mọ gbogbo ẹsẹ mẹ́rìndínlọ́gọ́sàn-án [176] tó wà nínú Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà [119]!
Ohun tó dájú ni pé o lè ṣe ohun táá mú kó o túbọ̀ máa rántí nǹkan. Ohun tí ìwádìí fi hàn ni pé, bí iṣan ara ni agbára tá a ní láti máa rántí nǹkan ṣe rí. Bá a bá ṣe ń lò ó tó, bẹ́ẹ̀ láá ṣe máa lágbára tó, kódà, títí dọjọ́ ogbó.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
ÀWỌN NǸKAN TÓ O TÚN LÈ ṢE
◼ Tó o bá fẹ́ máa rántí nǹkan dáadáa, kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan, kọ́ èdè tuntun, tàbí kó o kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò ìkọrin.
◼ Máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ.
◼ Mọ àwọn nǹkan tó lè tètè mú kéèyàn rántí nǹkan.
◼ Máa mu omi dáadáa. Bí omi ò bá pọ̀ tó nínú ara, kì í jẹ́ kí ọpọlọ jí pépé.
◼ Máa sùn dáadáa. Nígbà téèyàn bá ń sùn, ọpọlọ máa ń tọ́jú àwọn ìsọfúnni pa mọ́.
◼ Jẹ́ kára ẹ balẹ̀ dáadáa tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Bí ọkàn èèyàn ò bá balẹ̀, ó máa ń mú kí omi inú ara tó ń jẹ́ kí agara dáni sun jáde, èyí kì í sì í jẹ́ kí àwọn iṣan ara ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.
◼ Má ṣe máa mutí lámujù, má ṣe mu sìgá pẹ̀lú. Ọtí kì í jẹ́ kéèyàn tètè rántí nǹkan. Béèyàn bá sì ti sọ ọtí mímu di bárakú, kì í jẹ́ kí èròjà fítámì inú ara tó máa ń jẹ́ kéèyàn tètè rántí nǹkan lágbára dáadáa. Sìgá mímu máa ń dín afẹ́fẹ́ oxygen tó ń dénú ọpọlọ kù. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Inú ìwé ìròyìn orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ Brain & Mind la ti rí ìsọfúnni yìí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
FOJÚ INÚ YÀWÒRÁN
Báwo lo ṣe lè rántí àwọn nǹkan tó o fẹ́ lọ rà lọ́jà, bíi búrẹ́dì, ẹyin, mílíìkì àti bọ́tà? Tó o bá lo ọgbọ́n tó máa ń jẹ́ kéèyàn rántí ibi tí nǹkan wà, ńṣe ló máa dà bíi pé ò ń rí àwọn nǹkan náà, bó o bá fọkàn yàwòrán wọn látinú yara ẹ.
Fojú inú wò ó pé búrẹ́dì ni tìmùtìmù tó wà lórí àga rẹ,
ẹyin tí adìyẹ ń sàba lé lórí wà lábẹ́ àtùpà onígò
ẹja ń lúwẹ̀ẹ́ nínú mílíìkì
wọ́n fi bọ́tà rá ojú tẹlifíṣọ̀n
Báwọn nǹkan náà bá ṣe pani lẹ́rìn-ín tó tàbí bó ṣe ṣàjèjì tó ló ṣe máa mú kó o rántí tó! Bó o bá wá débi tó o ti fẹ́ rajà, kó o tún fojú inú yàwòrán àwọn nǹkan náà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
MÁA DÚPẸ́ PÉ O LÈ GBÀGBÉ NǸKAN!
Ká sọ pé gbogbo nǹkan pátá lo máa ń rántí, àtèyí tó ṣe pàtàkì àtèyí tí ò ṣe pàtàkì, báwo ni ìgbésí ayé ì bá ṣe rí ná? Àwọn nǹkan tí kò wúlò ni ì bá kúnnú ọpọlọ ẹ, àbí kì í ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé obìnrin kan wà tó jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí i pátá ló máa ń rántí. Obìnrin náà “ṣàlàyé pé àwọn nǹkan náà ‘kì í yé wá sọ́pọlọ òun, kò sí nǹkan tóun lè ṣe láti dáwọ́ ẹ̀ dúró, ó máa ń tán òun lókun’ àti pé ‘ẹrù ìnira’ ló jẹ́ fóun.’” A dúpẹ́ pé kì í ṣe gbogbo wa la nírú ìṣòro yìí. Àwọn olùwádìí sọ pé ìdí tí a kì í fi í rántí gbogbo nǹkan ni pé ohun kan wà tó máa ń palẹ̀ àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì mọ́ kúrò nínú ọpọlọ wa. Ìwé ìròyìn New Scientist tún sọ pé “téèyàn bá ń gbàgbé àwọn nǹkan tó yẹ kó gbàgbé bó ṣe yẹ, ó jẹ́ ara àmì pàtàkì tó fi hàn pé ọpọlọ ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Téèyàn bá gbàgbé nǹkan tó ṣe pàtàkì, . . . ohun tí èyí ń fi hàn ni pé ohun tó máa ń palẹ̀ àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì mọ́ nínú ọpọlọ kò ṣiṣẹ́ dáadáa tó.”