Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣẹ́yún Kì í Ṣe Ọ̀nà Àbáyọ Tí Kò Léwu

Ìṣẹ́yún Kì í Ṣe Ọ̀nà Àbáyọ Tí Kò Léwu

Ìṣẹ́yún Kì í Ṣe Ọ̀nà Àbáyọ Tí Kò Léwu

LÁTI kékeré ni Bill ti mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni kéèyàn ṣẹ́yún, béèyàn bá sì ṣẹ́yún ńṣe ló pààyàn. Àmọ́, lọ́dún 1975, nígbà tó di pé kó ṣèpinnu tó jẹ mọ́ oyún ṣíṣẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mikàn lórí ohun tó gbà gbọ́ yìí. Victoria tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lóyún mọ́ ọn lọ́wọ́, kò sì tíì ṣe tán láti gbéyàwó tàbí kó máa tọ́mọ. Bill sọ pé: “Kíá ni mo ti ronú ọ̀nà àbáyọ tó rọrùn jù lọ, mo sọ fún Victoria pé àfi kó yáa ṣẹ́ oyún náà.”

Bill kọ́ lẹni àkọ́kọ́ tó ka ṣíṣẹ́ oyún àìròtẹ́lẹ̀ yìí sí “ọ̀nà àbáyọ tó rọrùn.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe jákèjádò ayé lọ́dún 2007 fi hàn pé oyún táwọn èèyàn ṣẹ́ lọ́dún 2003 tó mílíọ̀nù méjìlélógójì [42]. Nínú onírúurú ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀sìn la ti ráwọn obìnrin tó ń ṣẹ́yún, yálà wọ́n lówó tàbí wọ́n tòṣì, yálà wọ́n kàwé tàbí wọ́n jẹ́ púrúǹtù, wọ́n ì báà sì jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Bí obìnrin bá lóyún mọ́ ẹ lọ́wọ́ tàbí tó o ṣàdédé lóyún fún ọkùnrin kan, kí lo máa ṣe? Kí ló fà á tọ́pọ̀ èèyàn fi máa ń yàn láti ṣẹ́yún?

“Ohun Kan Ṣoṣo Tí Mo Rò Pé Mo Lè Ṣe Nìyẹn”

Obìnrin ẹni ọdún márùndínlógójì [35] kan ṣàlàyé pé: “Oyún tí mo ní gbò mí gan-an, mo sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí mi ni, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò sówó lọ́wọ́, wàhálà sì pọ̀ lọ́rùn mi. Àmọ́ ọ̀sẹ̀ kẹfà lẹ́yìn tí mo bímọ ni mo tún lóyún míì. La bá kúkú pinnu láti ṣẹ́ ẹ. Mo mọ̀ pé kò dáa láti ṣẹ́yún, àmọ́ ohun kan ṣoṣo tí mo rò pé mo lè ṣe nìyẹn.”

Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìdí ló ń mú káwọn obìnrin ṣẹ́yún, bẹ̀rẹ̀ látorí àìríná-àìrílò tó fi dórí àjọṣe tó forí ṣánpọ́n, tàbí àìgbọ́ra-ẹni-yé tó lè mú kí obìnrin kan fárígá pé òun ò fẹ́ kí ohunkóhun da òun àti ọkùnrin náà pọ̀ mọ́. Tàbí kó jẹ́ pé oyún náà ta ko ohun tí obìnrin náà tàbí àwọn méjèèjì ń gbèrò àtiṣe.

Nígbà míì sì rèé, àwọn míì máa ń fi ìṣẹ́yún ṣe bojúbojú kí orúkọ wọ́n má bàa bà jẹ́. Bọ́ràn ṣe rí nìyẹn nínú àpẹẹrẹ kan tí Dókítà Susan Wicklund mú wá nínú ìwé rẹ̀ náà, This Common Secret—My Journey as an Abortion Doctor. Ẹnì kan tó wá ṣẹ́yún lọ́dọ̀ rẹ̀ jẹ́wọ́ fún un pé: “Ọwọ́ pàtàkì làwọn òbí mi fi mú ìjọsìn Ọlọ́run. . . . Bí mo bá bímọ láì ṣègbéyàwó, ó máa ba orúkọ wọn jẹ́. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wọn ló máa mọ̀ pé ọmọ wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”

Dókítà Wicklund wá béèrè pé: “Bó o bá rò pé wọ́n máa kà ẹ́ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ torí pé o lóyún, bó o bá wá ṣẹ́yún ńkọ́?” Ọmọbìnrin náà jẹ́wọ́ pé: “Bó bá jẹ́ toyún ṣíṣẹ́ ni, ẹ̀ṣẹ̀ tí ò ní ìdáríjì nìyẹn. Àmọ́, ìyẹn ṣeé fewé mọ́ torí pé kò sẹ́ni tó máa mọ̀. Bí mo bá ṣẹ́yún, àwọn ọ̀rẹ́ [àwọn òbí mi] tó wà ní ṣọ́ọ̀ṣì wa ò lè mọ̀ láéláé.”

Ohun yòówù tó lè mú kéèyàn pinnu pé òun á fẹ́ láti mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́yún, kì í ṣe ohun tó rọrùn. Ohun tó máa ń dunni wọra ni. Àmọ́, ṣé ọ̀nà àbáyọ tí kò léwu ni ìṣẹ́yún?

Gbé Ewu Tó Wà Ńbẹ̀ Yẹ̀ Wò

Àbájáde ìwádìí kan tó wáyé lọ́dún 2004, èyí tó dá lórí òjì-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́sàn-án [331] obìnrin láti ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti igba ó lé mẹ́tàdínlógún [217] obìnrin láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé nǹkan bí ìdajì lára àwọn tí ìwádìí náà dá lé lórí ni wọ́n kábàámọ̀ pé àwọn ṣẹ́yún. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ará Amẹ́ríkà àti ìdajì lára àwọn ará Rọ́ṣíà ni oyún ṣíṣẹ́ ń da ẹ̀rí ọkàn wọn láàmú. Mẹ́fà nínú mẹ́wàá àwọn obìnrin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọn ‘ò lè dárí ọ̀rọ̀ náà ji ara wọn.’ Bó bá wá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọkàn àwọn tó ń ṣẹ́yún ṣe ń dá wọn lẹ́bi tó, kódà àwọn tí wọn ò kara wọn sẹ́ni tó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn, kí ló fà á tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin ṣì ń ṣẹ́yún?

Ohun táwọn èèyàn máa ń sọ sí wọn létí ló sábà máa ń mú kí wọ́n ṣẹ́yún. Àwọn òbí, ọkọ, tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ agbọ̀ràndùn fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ló sábà máa ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n kúkú ṣẹ́yún. Èyí sì lè mú kí wọ́n fi ìkùgbù ṣe ìpinnu, láìro ẹ̀yìn ọ̀rọ̀ wò. Ọ̀mọ̀wé Priscilla Coleman, tó jẹ́ ògbógi lórí ọ̀ràn ìdààmú-ọkàn tó máa ń bá ìṣẹ́yún rìn ṣàlàyé pé: “Àmọ́, lẹ́yìn tí ìpinnu tó nira náà bá ti kọjá lọ tán tí wọ́n sì ti ṣẹ́ oyún náà, orí àwọn obìnrin máa ń pé wálé, wọ́n á máa dára wọn lẹ́bi, inú wọ́n á bà jẹ́, wọ́n á sì máa kábàámọ̀.”

Àbámọ̀ yìí sábà máa ń dá lórí ìbéèrè náà: Bí mo bá ṣẹ́yún, ṣé ẹ̀mí ọmọ tó ti di alààyè ni mo dá légbodò? Àbájáde ìwádìí kan tí àwọn tó ń wádìí nípa ìṣẹ́yún, ìyẹn South Dakota Task Force to Study Abortion, ṣe lórí kókó yìí parí èrò pé ọ̀pọ̀ aboyún tó ń ronú nípa ìṣẹ́yún “ni wọ́n ṣì lọ́nà nípa mímú kí wọ́n rò pé ‘fọ́nrán iṣan’ lásán ni wọ́n fọ̀ dà nù kúrò nínú ara, wọ́n sì sọ pé báwọn bá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, àwọn ò ní ṣẹ́yún.”

Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàgbéyẹ̀wò bí ẹgbàá dín ọgọ́ta [1,940] obìnrin tó ṣẹ́yún “ṣe jẹ́wọ́ láìfìkan pe méjì àmọ́ lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n banú jẹ́ gidigidi,” ìwádìí náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn obìnrin wọ̀nyí ni ìbànújẹ́ dorí wọn kodò pé àwọn dá ẹ̀mí ọmọ tí wọ́n sọ fáwọn pé kò tíì di alààyè légbodò.” Ó tún fi kún un pé “bí obìnrin bá ń rántí pé òun fọwọ́ ara òun pa ọmọ òun, ńṣe lọ́kàn ẹ̀ á máa gbọgbẹ́ ṣáá.”

Àmọ́, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an? Ṣé òótọ́ ni pé fọ́nrán iṣan lásán ni wọ́n ń fọ̀ dà nù lára obìnrin tó bá ṣẹ́yún? Ṣé òótọ́ ni pé alààyè ni ọmọ tó bá ṣì wà nínú oyún?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ójú ìwé 4]

ÈWO LÈWO: ÌBÍMỌ ÀBÍ ÌṢẸ́YÚN?

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2006 dá lórí ìtàn ìgbésí ayé àwọn obìnrin tí wọ́n lóyún nígbà tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún. Ìdajì lára wọn bí ọmọ náà, ìdajì yòókù sì ṣẹ́yún. Àbájáde ìwádìí náà ni pé “àwọn tó bímọ ò fi bẹ́ẹ̀ nílò ìmọ̀ràn torí ìdààmú ọkàn, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìṣòro oorun sísùn, kò sì jọ pé ó ń ṣe wọ́n bíi kí wọ́n mugbó, èyí tí kò rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn àwọn tó ṣẹ́yún.”—Ìwé ìròyìn Journal of Youth and Adolescence.

Ìròyìn míì sọ “àbájáde ìwádìí mẹ́rin tó gbòòrò jù lọ tó dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.” Kí làwọn ìwádìí náà fi hàn? “Àwọn obìnrin tó ti ṣẹ́yún rí ní ìdààmú ọkàn ńláǹlà lónírúurú ọ̀nà bá a bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú àwọn tí kò ṣẹ́yún rí.”—Report of the South Dakota Task Force to Study Abortion—2005.