Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tá ò Fi Ṣẹ́yún

Ìdí Tá ò Fi Ṣẹ́yún

Ìdí Tá ò Fi Ṣẹ́yún

VICTORIA tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ wa àkọ́kọ́, sọ fún ọ̀rẹ́kùnrin ẹ̀ Bill, pé òun ò ní ṣẹ́yún. Ó sọ pé: “Mo gbà pé ẹ̀dá alààyè ló wà nínú mi. Níwọ̀n bí mo sì ti mọ̀ pé bí èmi àti Bill bá ń bá ọ̀rẹ́ wa lọ, ó lè dá mi dá oyún náà, mo já a jù sílẹ̀.”

Nígbà tó ṣe, Bill yí èrò rẹ̀ pa dà ó sì ní kí Victoria fẹ́ òun. Àmọ́, bí òkè ńlá ni bíbójú tó ọmọ wọn jòjòló ṣe rí lójú wọn. Victoria ṣàlàyé pé: “A ò ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, kò sówó, ìwọ̀nba aṣọ díẹ̀ la ní, gbogbo ohun tá a ní ò tó nǹkan. Owó kékeré ló ń wọlé fún Bill, torí náà ilé olówó pọ́ọ́kú là ń gbé, àmọ́ a ò jẹ́ kó sú wa.”

Àwọn míì wà tí wọ́n ti kojú àwọn ipò líle koko nítorí oyún tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, àwọn pẹ̀lú kọ̀ láti ṣẹ́yún. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró láìyẹsẹ̀ tí wọ́n sì fàyà rán títọ́ ọmọ tí wọn ò múra sílẹ̀ fún tàbí tí wọn ò tiẹ̀ retí pàápàá? Ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé wọ́n fi ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ṣèwà hù.

Má Ṣe Kánjú Ṣèpinnu, Ṣètò Tó Bọ́gbọ́n Mu

Ohun tí Bíbélì sọ bọ́gbọ́n mu, ó ní: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.”Òwe 21:5.

Ní ti Connie, tó ní ọmọkùnrin mẹ́ta, tí ọ̀kan lára wọn jẹ́ abirùn, kò rọrùn fún un láti máa retí ọmọ míì. Ó sọ pé: “A ò retí àtigbọ́ bùkátà ọmọ míì báyìí. Torí náà, a ronú pé bóyá ká kúkú ṣẹ́yún ẹ̀.” Àmọ́, kó tó kánjú ṣèpinnu, ó kọ́kọ́ fọ̀rọ̀ lọ Kay, tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Kay jẹ́ kó yé e pé ẹ̀dá alààyè lọmọ tó lóyún ẹ̀ sínú, ìyẹn gan-an ló sì pe orí ẹ̀ wálé.

Àmọ́, Connie nílò ìrànlọ́wọ́ kó bàa lè mọ ibi tó máa gbé ọ̀ràn náà gbà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀gbọ́n ìyá Connie obìnrin wà ní àgbègbè yẹn, Kay dábàá pé kí Connie lọ bá a. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n màmá ẹ̀, inú ẹ̀ dùn láti ràn án lọ́wọ́. Ọkọ Connie náà wáṣẹ́ kún iṣẹ́ tó ń ṣe, wọ́n sì kó lọ sílé míì tówó ẹ̀ dín sí èyí tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Èyí ni ọgbọ́n tí wọ́n dá kí wọ́n lè bójú tó ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà.

Kay tún ran Connie lọ́wọ́ láti wá àwọn àjọ kan tó máa ń ran àwọn tó bá lóyún láìròtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́. Irú àjọ bẹ́ẹ̀ wà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ìyá ọmọ tí wọ́n bá nírú ìṣòro yìí. Èèyàn lè wá wọn kàn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí nípa lílo àwọn ìwé tí wọ́n kọ nọ́ńbà tẹlifóònù wọn sí, èyí tó máa ń wà láwọn ilé ìkàwé gbogbo gbòò. Ó lè gba ìsapá gan-an láti rí ìrànlọ́wọ́ gidi gbà, àmọ́ “àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn” ló máa ń yọrí sí rere.

Gbà Pé Ẹ̀dá Alààyè Ni

Bíbélì sọ pé: “Ní ti ọlọ́gbọ́n, ojú rẹ̀ wà ní orí rẹ̀; ṣùgbọ́n arìndìn ń rìn lọ nínú ògédé òkùnkùn.”Oníwàásù 2:14.

Obìnrin tó bá gbọ́n ò ní di ojú rẹ̀ sí bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an kó wá fira ẹ̀ sípò ẹni tó ń ‘rìn nínú òkùnkùn.’ Ńṣe lá á máa lo ‘ojú tó wà ní orí rẹ̀,’ èyí tó máa ràn án lọ́wọ́ láti lo agbára ìmòye rẹ̀. Èyí á ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ ibi tí ọ̀ràn máa já sí. Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ò ní dà bíi tàwọn tí wọ́n ṣe bíi pé wọn ò mọ̀ pé oyún ọmọ ló wà níkùn àwọn, obìnrin tó bá gbọ́n á fi àánú hàn sí ọlẹ̀ inú rẹ̀ á sì fẹ́ láti dáàbò bò ó.

Nígbà tí Stephanie, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó lóyún, ń gbèrò láti ṣẹ́ ẹ, wọ́n lo ẹ̀rọ láti jẹ́ kó mọ bí ọmọ oṣù méjì náà ṣe ń ṣe sí nínú ikùn rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo bú sẹ́kún. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Kí ló máa mú kí n gbẹ̀mí ọmọ tó wà láàyè?’”

Ọ̀dọ́mọbìnrin míì tóun náà gboyún, ìyẹn Denise, rí i gbangba gbàǹgbà pé ẹ̀dá alààyè ni ọmọ tóun lóyún ẹ̀. Nígbà tí ọ̀rẹ́kùnrin ẹ̀ fún un lówó pé kó “lọ wá nǹkan ṣe sí oyún náà,” ó dá a lóhùn pé: “Kí n ṣẹ́yún kẹ̀? Mi ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láé!” Torí náà, ó kọ̀ láti pa ọmọ náà.

Ohun Tí Ìbẹ̀rù Èèyàn Lè Múni Ṣe

Báwọn míì bá ní káwọn tó ti fẹ́ ṣẹ́yún tẹ́lẹ̀ kúkú lọ ṣẹ́ oyún náà, ó máa dáa kí wọ́n ronú lórí òwe Bíbélì tó sọ pé: ‘Ìbẹ̀rù ènìyàn ní í mú ìkẹkùn wá: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa ni a óò gbé lékè.’—Òwe 29:25, Bibeli Mimọ.

Bó ṣe kù díẹ̀ kí Monica tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ nípa ìṣòwò ni ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ fún un lóyún. Èyí ba màmá rẹ̀, tó jẹ́ opó tó ń tọ́mọ márùn-ún lọ́wọ́, lọ́kàn jẹ́ gidigidi. Ó wù ú pé kí Monica kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣòwò kóun náà má bàa tòṣì. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú ìyá Monica, ó sì sọ fún un pé àfi kó ṣẹ́yún. Monica sọ pé: “Nígbà tí dókítà bi mí pé ṣé mo fẹ́ láti ṣẹ́yún, mo sọ fún un pé, ‘Rárá!’”

Nígbà tí màmá Monica ro ti pé gbogbo ìsapá láti mú kọ́mọ òun má mòṣì ti fẹ́ wọgbó, tó sì tún ro wàhálà títọ́ ọmọ míì, ó lé e jáde kúrò nílé. Monica gba ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n màmá rẹ̀ obìnrin lọ. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, màmá ẹ̀ gbà pé kó padà wálé wá bímọ. Màmá ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti bá a tọ́jú ọmọ tuntun náà, ìyẹn Leon, ó sì fẹ́ràn ọmọ náà bí ojú.

Ohun tó fa ìṣòro tí abilékọ míì kan tó ń jẹ́ Robin ń bá yí yàtọ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo lóyún, dókítà mi kọ́kọ́ bá mi tọ́jú àìsàn kíndìnrín tó ń ṣe mí, kó tó wá rí i pé mo lóyún. Ó sọ fún mi pé màá bí ọmọ náà, ṣùgbọ́n àfàìmọ̀ kó má ya abirùn.” Ni dókítà bá ní kó ṣẹ́yún. Àmọ́, Robin sọ pé: “Mo ṣàlàyé ojú tí Bíbélì fi wo ìwàláàyè fún un. Mo sọ fún un pé kò sóun tó máa mú kí n ṣẹ́yún.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ dókítà náà ò ṣeé kó dà nù, oyún náà ò tíì ṣèpalára kankan fún ìwàláàyè Robin. a Robin sọ síwájú sí i pé: “Nígbà tí mo fi oyún náà bí obìnrin tí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀, wọ́n rí i pé àìsàn fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ibi tó ń darí iṣan ara nínú ọpọlọ ló ń ṣe é. Ara ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ó ti pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún báyìí, ìwé kíkà ẹ̀ sì ń já gaara sí i. Mi ò jẹ́ kóyán ẹ̀ kéré, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lóòjọ́ pó jẹ́ kí n bí ọmọ náà.”

Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run Máa Ń Múni Ṣe Ohun Tó Tọ́

Bíbélì sọ pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”Sáàmù 25:14.

Ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ tó kọ̀ láti ṣẹ́yún ṣe irú ìpinnu tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n gbé ojú tí Ẹlẹ́dàá wọn fi wo ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò. Ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n ṣe máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run àti bí wọ́n á ṣe máa ṣe ohun tó wù ú. Irú èrò yìí nípa gan-an lórí ohun tí Victoria tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe. Ó sọ pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé Ọlọ́run ló ń fúnni ní ìwàláàyè, mi ò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ̀mí.”

Nígbà tí Victoria bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ìpinnu tí mo ṣe pé mi ò ní ṣẹ́yún ọmọ mi mú kí n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyẹn sì ń mú kí n fẹ́ láti tẹ́ ẹ lọ́rùn nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe. Nígbàkigbà tí mo bá gbàdúrà pé kó ràn mí lọ́wọ́, gbogbo nǹkan yòókù kàn máa ń bọ́ sí i ni.”

Àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, tó jẹ́ Orísun ìyè, máa mú kí ọ̀wọ̀ tá a ní fún ẹ̀dá alààyè tó wà nínú oyún jinlẹ̀ sí i. (Sáàmù 36:9) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọ́run lè fún obìnrin kan àtàwọn aráalé rẹ̀ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè fàyà rán ìṣòro oyún tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Bá a bá wẹ̀yìn wò, ibo lọ̀rọ̀ àwọn tó bọ̀wọ̀ fún ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwàláàyè já sí?

A Ò Kábàámọ̀

Ọkàn àwọn òbí wọ̀nyí ò máa dá wọn lẹ́bi, wọn ò máa kárí sọ, wọn ò sì máa banú jẹ́ nítorí òfò ọmọ. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, wọ́n ń rí i pé òótọ́ làwọn “èso ikùn” jẹ́ èrè, wọ́n kì í ṣe ègún! (Sáàmù 127:3) Wákàtí méjì péré lẹ́yìn tí Connie, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, bímọ ló ti mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn! Inú ẹ̀ dún, ó sì ké sí Kay, tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ láti sọ fún un pé inú òun dùn bóun ṣe ń fojú sọ́nà fún títọ́ ọmọbìnrin òun. Tayọ̀tayọ̀, Connie fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn tó bá ń ṣe ohun tó fẹ́.”

Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní púpọ̀ pé ká máa fojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwàláàyè wò ó? Ìdí ni pé gẹ́gẹ́ bí Orísun ìyè, “ire [wa],” làwọn òfin àtàwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì wà fún.—Diutarónómì 10:13.

Gẹ́gẹ́ bí ìrírí Victoria àti Bill, tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tá a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, ṣe fi hàn, ìpinnu tí wọ́n ṣe pé àwọn ò ní ṣẹ́yún ló yí ìgbésí ayé wọn pa dà. Bí wọ́n ṣe ṣàlàyé ara wọn rèé, wọ́n ní: “À ń kó egbòogi jẹ, à bá sì ti kú ká sọ pé a ò jáwọ́ nínú ẹ̀ ni. Àmọ́, ọ̀wọ̀ tá a ní fún ẹ̀mí ọmọ tá a lóyún ẹ̀ ló mú káwa náà tún inú rò nípa ìwàláàyè tiwa alára. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́ láti yí pa dà.”

Lance, ọmọ wọn, tí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n báyìí, ọdún kejìlá sì nìyí tó ti ṣègbéyàwó. Lance ṣàlàyé pé: “Látìgbà ọmọdé làwọn òbí mi ti kọ́ mi láti máa gbé àwọn ìpinnu mi karí Bíbélì. Èyí ti ṣàǹfààní gan-an fún èmi, ìyàwó mi àti ọmọ mi débi tá a fi lérò pé kò sóhun tó tún lè mú wa láyọ̀ tóyẹn.” Bàbá Victoria, tó ti fẹ́ kọ́mọ òun ṣẹ́yún tẹ́lẹ̀, sọ pé: “A máa ń wárìrì tá a bá rántí pé díẹ̀ ló kù ká ṣẹ́yún ọmọkùnrin wa ọ̀wọ́n dà nù.”

Tún ronú nípa Monica, tó kọ̀ láti ṣẹ́yún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé màmá rẹ̀ hàn án léèmọ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí mo bí ọmọkùnrin mi làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tọ̀ mí wá tí mo sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí mo ṣe lè máa gbé ìgbé ayé mi ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run. Kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Leon, ọmọ mi, bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Bọ́jọ́ sì ti ń gorí ọjọ́, òun náà dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an. Leon ti di ìránṣẹ́ arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí.”

Bí Leon ṣe ń ronú lórí ohun tí màmá rẹ̀ ṣe, ó sọ pé: “Níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ mi gan-an débi tó fi dá mi sí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé nira fún un, ìyẹn máa ń jẹ́ kó wù mí láti gbé ìgbé ayé mi lọ́nà tó dára jù lọ kí n lè fi ìmọrírì mi hàn fún Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn àgbàyanu ti ìwàláàyè.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti wá mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwàláàyè kì í kábàámọ̀ pé àwọn pinnu láti pa ìwàláàyè ọmọ táwọn ń gbé gẹ̀gẹ̀ báyìí mọ́. Látinú ọkàn wọn tó kún fún ọpẹ́, wọ́n lè sọ pé, “A ò ṣẹ́yún!”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó bá ṣẹlẹ̀ pé nígbà ìbímọ ẹ̀mí ọmọ tàbí ti ìyá wà nínú ewu, àwọn tọ́ràn bá kàn gbọ̀ngbọ̀n ló máa pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Àmọ́, irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ kì í sábàá wọ́pọ̀ nítorí ibi tí ìtẹ̀síwájú ti bá ìtọ́jú ìṣègùn dé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Stephanie pinnu pé òun ò ṣẹ́yún nígbà tí wọ́n jẹ́ kó rí bí ọmọ oṣù méjì náà ṣe ń ṣe sí nínú ikùn rẹ̀

(Àwa la fa ìlà yípo ẹ̀)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Victoria àti Lance rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Victoria àti Bill rèé báyìí pẹ̀lú Lance àti ìdílé ẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Monica kún fọ́pẹ́ gidigidi póun ò ṣẹ́yún ọmọ òun lọ́dún mẹ́rìndínlógójì sẹ́yìn; Leon ọmọ rẹ̀ náà kún fọ́pẹ́