Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Ìwàláàyè Bẹ̀rẹ̀?

Ìgbà Wo Ni Ìwàláàyè Bẹ̀rẹ̀?

Ìgbà Wo Ni Ìwàláàyè Bẹ̀rẹ̀?

ỌMỌBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Gianna ṣàlàyé pé: “Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni màmá mi, oyún inú wọn sì ti pé oṣù méje ààbọ̀ kí wọ́n tó pinnu láti fi oògùn oníyọ̀ ṣẹ́ oyún náà. a Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi ni oyún tó ṣẹ́ náà. Àmọ́, mi ò kú o, mo ṣì wà láàyè.”

Gianna, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ló fẹnu ara ẹ̀ sọ pé bọ́ràn ṣe rí nìyí lọ́dún 1996, níwájú ìgbìmọ̀ ìjọba kan tó ń gbẹ́jọ́ oyún ṣíṣẹ́. Lẹ́yìn oṣù méje àtààbọ̀ tí ìyá Gianna ti lóyún ẹ̀, gbogbo ẹ̀yà ara ẹ̀ ti pé. Wàá sì gbà pé ó ti di odidi èèyàn kan nìyẹn, torí pé lẹ́yìn tí wọ́n bí i, ó ń wà láàyè nìṣó gẹ́gẹ́ bí èèyàn kan.

Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè sọ nípa Gianna nígbà tó pé ọ̀sẹ̀ márùn-ún nínú màmá ẹ̀, tí kò sì gùn ju nǹkan bí ìda mẹ́fà àtàǹpàkò lọ? Òótọ́ ni pé gbogbo ẹ̀yà ara ẹ lè máà tíì gbó, àmọ́ ó ti ní ọpọlọ àtàwọn iṣan tó ń jẹ́ kéèyàn mọ nǹkan lára. Ó ní ọkàn tó ń lù kìkì ní ọgọ́rin [80] ìgbà láàárín ìṣẹ́jú kan tó sì ń gbé ẹ̀jẹ̀ káàkiri inú àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú ara. Bá a bá wá gbà pé èèyàn ni Gianna lẹ́yìn tó ti pé oṣù méje àtààbọ̀ nínú oyún, kí ni ká sọ pó jẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ márùn-ún nínú oyún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀yà ara ẹ̀ ò tíì gbó?

Oyún Jẹ́ Ohun Àgbàyanu

Nígbà tí àtọ̀ láti ara ọkùnrin bá wọnú ẹyin tó wà nínú ilé ọlẹ̀ obìnrin, ni ìdàgbàsókè gbogbo ẹ̀yà ara máa ń bẹ̀rẹ̀. Àwọn àwárí tuntun nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti máa kíyè sí àwọn ìyípadà kíkàmàmà tó máa ń wáyé nínú ẹyin tí àtọ̀ ti sọ di ọlẹ̀ yìí. Àwọn ohun tín-tìn-tín tó ní apilẹ̀ àbùdá ti bàbá àti ti ìyá nínú á para pọ̀ di ọmọ tuntun kan tí kò tíì sírú ẹ̀ rí.

Látorí ẹyin tí àtọ̀ sọ di ọlẹ̀ yìí ni ìrìn-àjò ẹ̀dá tuntun tó máa di èèyàn ọ̀tọ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀ lọ́nà àgbàyanu. Ohun tó sì ń pinnu irú ẹ̀dá tí ọlẹ̀ yìí máa jẹ́ ni àwọn apilẹ̀ àbùdá tirẹ̀ fúnra rẹ̀. Àwọn ló ń pèsè ìsọfúnni fún ara nípa ohun tó yẹ kó ṣe, ìyẹn bí ẹ̀dá tuntun náà á ṣe ga tó, bójú ẹ̀ ṣe máa rí, àwọ̀ ẹyinjú àti irun ẹ̀, tó fi mọ́ àwọn àbùdá míì téèyàn máa ń ní.

Bó bá ṣe, ẹyin tí àtọ̀ kọ́kọ́ sọ dọmọ yẹn á bẹ̀rẹ̀ sí í pín sí sẹ́ẹ̀lì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, sẹ́ẹ̀lì tuntun kọ̀ọ̀kan á sì mú lára apilẹ̀ àbùdá náà, èyí tó máa fún un ní gbogbo ìsọfúnni tó nílò. Pabanbarì ibẹ̀ wá ni pé sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ti wà ní sẹpẹ́ láti di irú sẹ́ẹ̀lì tó máa wúlò fún ara, irú bíi sẹ́ẹ̀lì ọkàn, ti ọpọlọ, ti awọ ara, àti ti awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó bo ẹyinjú wa. Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé ohun àgbàyanu ni ìsọfúnni tó wà nínú apilẹ̀ àbùdá, èyí tó máa ń mú kí ẹ̀dá tí kò sírú ẹ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà.

Ìlúmọ̀ọ́ká onímọ̀ nípa àwọn ohun tín-tìn-tín inú ara, Ọ̀mọ̀wé David Fu-Chi Mark, sọ pé: “Látìgbà tí àtọ̀ bá ti sọ ẹyin di ọlẹ̀ ni gbogbo ohun tó lè mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà títí tó fi máa bàlágà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.” Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Kò tún sí iyè méjì kankan mọ́ pé látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú ilé ọlẹ̀ la ti jẹ́ ẹ̀dá èèyàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”

Ṣé Èèyàn Ni Wá Nínú Ilé Ọlẹ̀?

Látìgbà tí wọ́n bá ti lóyún ọmọ kan, lọmọ náà ti di ẹnì kan, kì í wulẹ̀ ṣe fọ́nrán iṣan lásán. Bí àjèjì ló ṣe máa ń rí nínú ikùn ìyá lọ́hùn-ún. Ńṣe ni ara ẹ̀ ì bá sì tì í síta bí kì í bá ṣe pé Ọlọ́run dáàbò bò ó lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ẹ̀dá èèyàn tuntun yìí, tó wà gẹ́gẹ́ bí alààyè nínú ikùn ìyá, jẹ́ ẹ̀dá kan tí apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ yàtọ̀.

Àlàyé táwọn kan ń ṣe ni pé bí nǹkan ò bá lọ déédéé nínú ara, oyún lè wálẹ̀, kí wá ló fà á tí dókítà ò fi ní í lè ṣẹ́yún? Síbẹ̀ náà, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín ikú òjijì àti kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ gbẹ̀mí ẹlòmíì. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù, nínú ẹgbẹ̀rún kan [1,000] àwọn ọmọdé, mọ́kànléláàádọ́rin [71] ló ń kú kí wọ́n tó pọ́mọ ọdún kan. Àmọ́, ṣé a wá lè torí pé àwọn ọmọ tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ń kú láìtọ́jọ́ ká máa dúńbú gbogbo ọmọ tí ò bá tíì pé ọdún kan? A ò gbọ́dọ̀ dánrú ẹ̀ wò!

Ní pàtàkì jù lọ, Bíbélì tiẹ̀ ṣàlàyé pé látinú ọlẹ̀ ni ìwàláàyè ti bẹ̀rẹ̀. Dáfídì, onísáàmù sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.” (Sáàmù 139:16) Dáfídì ò wulẹ̀ sọ pé “ọlẹ̀ kan” àmọ́ ó sọ pé “ọlẹ̀ MI,” èyí tó fi hàn lọ́nà títọ́ pé látìgbà tí wọ́n ti lóyún Dáfídì, kí wọ́n tiẹ̀ tó lálàá pé wọ́n máa bí i, ni ìwàláàyè rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. Ọlọ́run mí sí Dáfídì nígbà tó ń kọ Bíbélì, ó sì fi hàn án pé nígbà tó wà nínú oyún gbogbo ẹ̀yà ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́ni tó wà ní “àkọsílẹ̀,” èyí tó sọ ọ́ di irú ẹni tó jẹ́.

Jọ̀wọ́ kíyè sí i pé Bíbélì ò sọ pé obìnrin kan lóyún àwọn fọ́nrán iṣan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “A ti lóyún abarapá ọkùnrin kan!” (Jóòbù 3:3) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, èyí pẹ̀lú fi hàn pé látìgbà tí wọ́n bá ti lóyún ọmọ kan nirú ọmọ bẹ́ẹ̀ ti di ẹ̀dá alààyè. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìgbà yẹn gan-an ni ìwàláàyè bẹ̀rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Omi iyọ̀ tó ní májèlé nínú, èyí tí wọ́n máa ń rọ sínú abẹ́rẹ́ ni oògùn oníyọ̀ yìí, bí wọ́n bá gún ẹni tó lóyún ní abẹ́rẹ́ yìí, omiró náà á lọ sínú ilé ọlẹ̀, ọmọ náà á gbé e mì, á sì kú láàárín wákàtí méjì. Ọjọ́ kan lẹ́yìn náà ni aboyún náà á bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, táá sì bí ọmọ náà lókùú, tàbí bó ṣe máa ń rí nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, kó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán.

[Àwọ̀n Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 6, 7]

Ọlẹ̀ tó ti pé ọ̀sẹ̀ márùn-ún kì í wulẹ̀ ṣe fọ́nrán iṣan kan lásán, ó ní gbogbo ohun tó lè mú kó dàgbà di ẹ̀dá alààyè kan

(bó ṣe tó gan-an)