Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ó dáhùn àwọn ìbéèrè wa’

‘Ó dáhùn àwọn ìbéèrè wa’

‘Ó dáhùn àwọn ìbéèrè wa’

◼ ‘Ó dáhùn àwọn ìbéèrè wa.’ Ohun táwọn ọ̀dọ́ ń sọ nípa ìwé tuntun náà, Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, nìyí. Jessicah, tó wà ní ìpínlẹ̀ Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ara mi ò yé mi tẹ́lẹ̀ torí mi ò mọ nǹkan tó yẹ kí n ṣe, àmọ́ ìwé yìí fún mi níṣìírí gan-an ni. Ọkàn mi wá balẹ̀ nígbà tí mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bíi tèmi tó fẹ́ sin Ọlọ́run ni kì í rọrùn fún láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìbéèrè tó wà lọ́kàn mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ ni ìwé náà dáhùn.”

Breann, tó wà ní ìpínlẹ̀ Colorado sọ pé: “Ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kí ìwé náà ṣe ló ń ṣe. Ó túbọ̀ ń jẹ́ káwọn òbí àtàwọn ọmọ máa fọ̀rọ̀ wérọ̀. Tí mo bá ti fẹ́ bá mọ́mì mi sọ̀rọ̀, ṣe ni mo máa ń ka apá tí mo fẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìwé náà sí wọn létí. Ọ̀rẹ́ mi kan tóun náà ka ìwé náà ti wá ṣe tán báyìí láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fáwọn òbí ẹ̀.”

Àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé náà dáhùn àwọn ìbéèrè tó sábà máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn, ìyẹn ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti obìnrin. Katrina tó wà ní ìpínlẹ̀ New Jersey kọ̀wé pé: “Ìwé náà ti jẹ́ kí ìpinnu mi pé mi ò tíì fẹ́ lẹ́ni tí mò ń fẹ́ lágbára si. Mi ò ní torí ohun táwọn èèyàn ń sọ tọrùn bọ̀ ọ́. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ nǹkan lèèyàn lè ṣe bí ò bá tíì lẹ́ni tó ń fẹ́! Mí ò sì tíì fẹ́ dáwọ́ ṣíṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ dúró báyìí. Bó bá wá tó àkókò láti lẹ́ni tí màá fẹ́, màá ti mọ irú ìwà tí mo fẹ́ kónítọ̀hún ní, màá sì mọ ọ̀nà tó yẹ kí n gbé e gbà.”

Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ìwé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Jessicah

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Breann

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Katrina