Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?

Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?

Ẹ̀yà kan tó ń jẹ́ Annang lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbà gbọ́ pé béèyàn ò bá sin àwọn òkú tìlù tìfọn, ẹ̀mí wọn á pa dà wá dààmú àwọn aráalé, á sì mú àwọn náà lọ. Àwọn kan nílẹ̀ Ṣáínà náà gbà gbọ́ pé béèyàn ò bá sìnkú gẹ́gẹ́ bí àṣà, ẹ̀mí irú àwọn òkú bẹ́ẹ̀ á pa dà wá jà, wọ́n á sì mú àwọn míì lọ.

ÌGBÀGBỌ́ pé béèyàn bá kú ọkàn ẹ̀ tàbí ẹ̀mí ẹ̀ á jáde kúrò nínú ara á sì gba ibòmíì lọ wọ́pọ̀ gan-an nínú onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ jákèjádò ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì tún gbà gbọ́ pé ọkàn tàbí ẹ̀mí yìí tún lè ran àwọn ìdílé tàbí ọ̀rẹ́ òkú lọ́wọ́ tàbí kó pa wọ́n lára.

Àmọ́, ṣóòótọ́ ni pé ohun kan wà tó máa ń jáde nínú ara tá á sì máa wà láàyè nìṣó lẹ́yìn téèyàn bá ti kú? Bó bá sì wà, ṣóòótọ́ ni pé ó lè pa àwọn alààyè lára? Kí ni ojú tí Bíbélì fi wo ọ̀ràn náà?

Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Mọ Ohunkóhun?

Bíbélì sọ gbangba gbàǹgbà pé àwọn òkú ò “mọ nǹkan kan rárá.” Ó sì tún sọ pé àwọn òkú jẹ́ “aláìlè-ta-pútú nínú ikú.” (Oníwàásù 9:5; Aísáyà 26:14) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé nípa ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.”Jẹ́nẹ́sísì 2:7.

Kíyè sí i pé Ọlọ́run dá Ádámù gẹ́gẹ́ bí ọkàn kan, ìyẹn ni pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá alààyè kan. Torí náà, Bíbélì ò sọ pé Ọlọ́run fún Ádámù ní ọkàn, èyí tó lè máa dá gbé nígbà tí ara bá ti kú. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó kú. Ó di “òkú ọkàn.” (Númérì 6:6) Bíbélì tún sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Gbogbo wa la jogún ẹ̀ṣẹ̀, tàbí àìpé, látọ̀dọ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù. Torí náà, nígbà tá a bá kú, ọkàn wa ti kú nìyẹn.—Róòmù 5:12.

Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé ipò táwọn òkú wà, kò lo àdììtú èdè, ṣùgbọ́n ó lo àwọn gbólóhùn tá a lè lóye, bíi “sùn lọ nínú ikú.” (Sáàmù 13:3) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù sọ nípa ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan pé: “Kò kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni.” Àwọn èèyàn “bẹ̀rẹ̀ sí fi í rẹ́rìn-ín tẹ̀gàn-tẹ̀gàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé ó ti kú.” Síbẹ̀, Bíbélì ṣàlàyé pé Jésù jí i dìde kúrò nínú oorun ikú.—Lúùkù 8:51-54.

Bọ́ràn ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí Lásárù kú. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun ń lọ sọ́dọ̀ Lásárù láti lọ “jí i kúrò lójú oorun.” Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn, torí náà “Jésù wí fún wọn láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ pé: ‘Lásárù ti kú.’” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ nípa àwọn “tí ó ti sùn nínú ikú,” ó sì sọ pé bí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, ó máa mú kí wọ́n pa dà wà láàyè.—Jòhánù 11:11-14; 1 Tẹsalóníkà 4:13-15.

Bíbélì ò fi kọ́ni níbikíbi pé ohun kan tó jáde nínú ara máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn téèyàn bá ti kú. Torí náà, kò sídìí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù àwọn òkú. Kí ló wá mú káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, ohun kan tó jáde lára ẹ̀ á máa wà láàyè nìṣó? Kí ló fà á táwọn èèyàn fi máa ń bẹ̀rù pé àwọn òkú lè pa alààyè lára?

Irọ́ Paraku

Àwọn ẹ̀sìn èké ló ń ṣagbátẹrù èrò náà pé ẹní bá kú ṣì ń wà láàyè nìṣó níbòmíì. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn jákèjádò ayé ti gba ti ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn. Nítorí èyí, nígbà táwọn alákòóso kan bá kú, irú bí àwọn Fáráò tó máa ń jẹ ní Íjíbítì àtijọ́, wọ́n máa ń pa àwọn ẹrú wọn kí wọ́n bàa lè máa sìn ọ̀gá wọn nìṣó nínú ayé míì.

Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn ẹ̀mí tàbí ọkàn tí wọ́n sọ fún wọn pó jẹ́ tẹni tó ti kú ń fòòró. Àwọn náà sì gbà gbọ́ pé aájò àti ètùtù táwọn ò ṣe fẹ́mìí àwọn tó kú fáwọn àti òkú àwọn tí ò fẹ́ràn àwọn ló mú kí wọ́n máa fòòró àwọn. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe mú kó ṣe kedere, irọ́ paraku nìyẹn. Àwọn agbára àìrí tó ń jẹ́ ẹ̀mí èṣù ló ń fòòró èèyàn, ó sì máa ń wù wọ́n kí wọ́n máa fìyà jẹ àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa kó ìpayà bá wọn.—Lúùkù 9:37-43; Éfésù 6:11, 12.

Ìwé Mímọ́ pe Sátánì ní “baba irọ́,” tó ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” Òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Jòhánù 8:44; 2 Kọ́ríńtì 11:14; Ìṣípayá 12:9) Kódà, Sátánì ló wà nídìí irọ́ paraku náà pé ọkàn ò lè kú, àti pé àwọn òkú lè pa àwọn alààyè lára.

Àmọ́ ṣá o, kò sẹ́ni tó lè firú irọ́ bẹ́ẹ̀ tan àwọn tó gba Bíbélì gbọ́ jẹ. Wọ́n ti mọ ohun tó fà á tí Sátánì fi ń tan àwọn èèyàn jẹ́ kí wọ́n bàa lè gbà gbọ́ pé àwọn òkú lè bá àwọn alààyè sọ̀rọ̀. Bí Bíbélì ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Dájúdájú, àwọn òtítọ́ tó lè sọ wá di òmìnira nípa bọ́rọ̀ àwọn tó ti kú ṣe jẹ́ gan-an wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!—Jòhánù 8:32.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ǹjẹ́ àwọn òkú mọ ohunkóhun?—Oníwàásù 9:5; Aísáyà 26:14.

◼ Ta ló wà nídìí ìgbàgbọ́ tó wọ́pọ̀ náà pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, apá kan lára ẹ̀ á ṣì máa wà láàyè nìṣó?—Jòhánù 8:44.

◼ Ibo la lè yíjú sí bá a bá fẹ́ mọ bọ́rọ̀ àwọn tó ti kú ṣe jẹ́ gan-an? —Jòhánù 8:32; 17:17.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Àwọn ẹ̀mí èṣù tó jẹ́ olubi ló fẹ́ràn láti máa fòòró àwọn èèyàn kì í ṣe àwọn tó ti kú