Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?

“Mo gbọ́ tẹ́nì kan ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé béèyàn bá fẹ́ kí n wá síbì kan láago mẹ́rin, àfi kó sọ pé aago mẹ́ta ni kí n débẹ̀. Ìgbà yẹn ni mo tó gbà pé mo gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n lo àkókò mi!”—Ricky. a

BÁWO ni àkókò tó o lè rí lò sí i lójúmọ́ ṣe pọ̀ tó? Kí lo máa lo àkókò tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ náà fún?

□ Láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ

□ Láti sùn

□ Láti kàwé

□ Láti lọ dára yá

□ Òmíràn ․․․․․

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa wù ẹ́ pé kó o máa rí àkókò púpọ̀ sí i lò lójúmọ́, irú ẹ̀ ò jẹ́ ṣẹlẹ̀! Torí náà, kí lo lè ṣe? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń wá àkókò púpọ̀ sí i ní gbogbo ọ̀nà ti rí irú àkókò bẹ́ẹ̀ nípa fífọgbọ́n lo àkókò wọn. Wọ́n tún ti kíyè sí i pé báwọn ṣe ń fọgbọ́n lo àkókò àwọn ti dín wàhálà àwọn kù, ó ti mú káwọn túbọ̀ máa ṣe dáadáa nílé ìwé, ó sì ti mú káwọn òbí túbọ̀ fọkàn tán àwọn. Jẹ́ ká wo bíwọ náà ṣe lè jàǹfààní látinú fífọgbọ́n lo àkókò ẹ.

Ìṣòro Àkọ́kọ́ Bó O Ṣe Lè Ṣètò Àkókò

Ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́. Ṣíṣètò àkókò ẹ lè mú kó o máa ronú pé o ò ní í lómìnira láti ṣe ohun tó wù ẹ́! Torí ó lè jẹ́ pé ìgbà tí nǹkan bá wá sọ́kàn ẹ ló máa ń wù ẹ́ láti ṣe é, tó ò sì fẹ́ kí ètò kan tó o ṣe sílẹ̀ máa darí ohun tó o bá ń ṣe ní gbogbo ìṣẹ́jú.

Ìdí tó fi yẹ kó o ṣètò àkókò ẹ. Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5) Ọwọ́ Sólómọ́nì máa ń dí gan-an. Àfàìmọ̀ ni ò sì jẹ́ pé kó tó pé ọmọ ogún ọdún ló ti láya, tó lọ́mọ, tó sì tún di ọba! Ìyẹn sì tún mú kọ́wọ́ ẹ̀ dí gan-an. Ní báyìí, ọwọ́ tìẹ náà dí. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó máa dí sí i bó o ṣe ń dàgbà. Torí náà, ó sàn kó o tètè ṣètò àkókò ẹ báyìí, dípò kó o sún un síwájú!

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ. “Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fètò sí bí mo ṣe lè lo àkókò mi. Mò ń gbìyànjú láti mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn, ó sì dà bíi pé ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo ṣètò àkókò mi!”—Joey.

“Bí mo ṣe to àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe lẹ́sẹẹsẹ mú kó rọrùn fún mi láti tẹ̀ lé ètò tí mo ṣe. Bí àwọn nǹkan míì bá wà tí mo ní láti bójú tó, èmi àti mọ́mì mi á kọ ọ́ sílẹ̀, a ó sì jọ fètò sí bá a ṣe máa ran ara wa lọ́wọ́ táá fi di ṣíṣe.”—Mallory.

Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wò ó báyìí ná: Ká sọ pé ẹ fẹ́ gbé mọ́tò yín lọ sí ìrìn àjò. Olúkúlùkù yín wá ń ju báàgì tiẹ̀ sínú mọ́tò náà bó ṣe wù ú. Ó wá dà bíi pé àyè tó wà nínú mọ́tò náà ò tó láti gba ẹrù yín. Kí lo máa ṣe? Kó gbogbo ẹrù tó wà nínú mọ́tò náà kúrò, bẹ̀rẹ̀ sí tò wọ́n pa dà, àwọn àpò tó tóbi jù lọ ni kó o tò sísàlẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wàá rí ibi tó o máa ki àwọn àpò tó kéré sí.

Bí ìgbésí ayé ẹ ṣe rí náà nìyẹn. Bó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí kò tó nǹkan lo kọ́kọ́ dáwọ́ lé, bóyá lo máa rí àkókò fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Kọ́kọ́ wáyè fáwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù, ìyàlẹ́nu ló sì máa jẹ́ fún ẹ láti rí i pé o ní àkókò tó pọ̀ tó fáwọn nǹkan tó kù!—Fílípì 1:10.

Àwọn nǹkan wo ló ṣe pàtàkì jù tó o gbọ́dọ̀ ṣe?

․․․․․

Ohun tó kàn báyìí ni pé kó o fàwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ṣáájú nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ. Bó o bá kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì, wà á rí i pé àkókò tó pọ̀ á ṣẹ́ kù fún ẹ láti fi ṣe àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Àmọ́, rántí pé bó o bá ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn, àkókò ò ní tó!

Ohun tó o lè ṣe. Wá ohun kan tí wàá máa kọ ohun tó o bá fẹ́ ṣe sí, kó o sì tò wọ́n bí wọ́n ti ṣe pàtàkì sí. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan míì tá a tò síbí yìí sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

□ Kàlẹ́ńdà inú fóònù

□ Ìwé kékeré

□ alágbèéká

□ Kàlẹ́ńdà kékeré

□ Kàlẹ́ńdà orí kọ̀ǹpútà téèyàn lè kọ ìsọfúnni sí

Ìṣòro Kejì Títẹ̀lé Ètò Tó O Ṣe

Ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́. Nígbà tó o tilé ìwé dé, ó kàn wù ẹ́ pé kó o sinmi kó o sì wo tẹlifíṣọ̀n fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé o ti wéwèé láti kàwé, àmọ́ ẹnì kan fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ké sí ẹ̀ pé kẹ́ ẹ jọ lọ wo fíìmù. O ò lè dá fíìmù dúró dìgbà míì, àmọ́ o sún ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ sọ́wọ́ alẹ́. O tiẹ̀ lè máa dára ẹ nínú dùn pé, ‘Bí ohun kan bá ń lé mi léré gan-an ni mo máa ń ṣe dáadáa jù.’

Ìdí tó fi yẹ kó o ṣètò àkókò ẹ. O lè gba máàkì tó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí ohunkóhun ò gbé ẹ lọ́kàn sókè. Ó ṣe tán, kò rọrùn fún ẹ láti máa tẹ̀ lé ètò tó o ṣe láti fọgbọ́n lo àkókò ẹ. Kí ló fà á tí wàá fẹ́ láti dá kún ìyẹn nípa sísáré kàwé lóru láti múra sílẹ̀ fún ìdánwò tó o máa ṣe níléèwé? Báwo lára ẹ ṣe máa rí tó o bá jí láàárọ̀? O lè sùn kọjá àkókò, kí ara wó ẹ, kó o sáré jáde nínú ilé, kó o sì pẹ́ délé ìwé.—Òwe 6:10, 11.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ. “Mo fẹ́ràn láti máa wo tẹlifíṣọ̀n, kí n máa ta gìtá, kí n sì máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Kò sóhun tó burú nínú gbogbo àwọn nǹkan yìí; àmọ́ nígbà míì, wọn kì í jẹ́ kí n tètè bójú tó àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, á wá di pé kí n máa kánjú ṣe wọ́n bó bá yá.”—Julian.

Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má fi ètò tó ò ń ṣe mọ sórí àwọn nǹkan tó o gbọ́dọ̀ ṣe, máa fètò sáwọn nǹkan tó o gbádùn láti máa ṣe pẹ̀lú. Julian sọ pé: “Ó máa ń rọrùn fún mi láti ṣe ohun tí mo bá mọ̀ pó pọn dandan, níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé mo máa ṣe àwọn ohun tó gbádùn mọ́ mi bó bá yá.”

Ohun míì tún rèé: Ní ohun tí wàá máa fojú sùn, kó o tún wá ṣe àwọn ètò kéékèèké tí ò ní í jẹ́ kó o gbàgbé àfojúsùn ẹ̀. Joey, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Màá fẹ́ láti máa lo èyí tó pọ̀ nínú àkókò mi láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àfojúsùn yẹn ń ràn mí lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ètò tí mò ń ṣe báyìí, kí n lè múra sílẹ̀ de ìgbà tọ́wọ́ mi á túbọ̀ dí.”

Ohun tó o lè ṣe. Kí ni ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn àfojúsùn pàtó tí wàá fẹ́ láti lé bá láàárín oṣù mẹ́fà?

․․․․․

Àwọn àfojúsùn pàtó wo lo lè lé bá láàárín ọdún méjì, kí ló sì yẹ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí, kọ́wọ́ rẹ lè ba àfojúsùn náà?

․․․․․

Ìṣòro Kẹta Mọ́ Tónítóní Kó O sì Wà Létòlétò

Ohun tó lè dí ẹ̀ lọ́wọ́. Kò dá ẹ lójú bí wíwà ní mímọ́ tónítóní àti wíwà létòlétò ṣe kan fífọgbọ́n lo àkókò ẹ̀. Ó ṣe tán, ó rọrùn láti jẹ́ ẹni tí kò wà létòlétò. Béèyàn ò gbálẹ̀ ilé lónìí, ó lè gbá a lọ́la, tàbí kó má tiẹ̀ gbá a rárá! Bó ṣe wu èèyàn ló lè ṣe yàrá ẹ̀, ìyẹn ò sì fàjà. Àbó la ìjà lọ ni?

Ìdí tó fi yẹ kó o ṣètò àkókò ẹ. Bí gbogbo nǹkan bá mọ́ tónítóní tó sì wà létòlétò, ó máa dín àkókò tí wàá fi máa wá nǹkan kù. Ìyẹn ni ò sì ní í jẹ́ kó o máa gbéra ẹ lọ́kàn sókè.—1 Kọ́ríńtì 14:40.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ. “Kì í rọrùn fún mi nígbà míì láti ká àwọn aṣọ mi kúrò nílẹ̀, bí gbogbo ilé ṣe rí jákujàku kì í sì í jẹ́ kí n rí ohun tí mo bá ń wá!”—Mandy.

“Ọ̀sẹ̀ kan ni mo fi wá pọ́ọ̀sì mi tí mi ò rí i. Mo dààmú gan-an ni. Ìgbà tí mò ń tún yàrá mi ṣe ni mo wá rí i.”—Frank.

Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bó o bá mú ohun kan, rí i pé o tètè dá a pa dà síbi tó o ti mú un. Ó máa rọrùn, á sì yá ẹ láti tún yàrá ẹ ṣe bó o bá ń ṣe é déédéé ju kó o máa dúró dìgbà tí gbogbo yàrá bá ti dà rú.

Ohun tó o lè ṣe. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa jẹ́ káwọn nǹkan wà ní mímọ́ tónítóní. Bí ohun kan bá ti wà ní mímọ́, jẹ́ kó túbọ̀ mọ́ sí i, kó o wá wò ó bóyá á jẹ́ káwọn nǹkan túbọ̀ rọrùn.

Ibi kékeré ni kó o ti bẹ̀rẹ̀, àmọ́ máà jẹ́ kó dọ̀la! Àwọn ìmọ̀ràn wo ló wúlò fún ẹ jù lọ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

․․․․․

Màá gbìyànjú àwọn àbá yìí fún ọ̀sẹ̀ ․․․․․ kí n lè rí i bóyá wọ́n á ràn mí lọ́wọ́.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Báwo ló ṣe yẹ kó o sùn pẹ́ tó kára ẹ lè yá gágá?

◼ Ta lo lè sọ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè fètò sí àkókò ẹ?

◼ Bó o bá ti ṣètò àkókò ẹ tẹ́lẹ̀, àwọn àtúnṣe wo ló máa pọn dandan pé kó o ṣe?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 30, 31]

Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, àwọn ọmọ ọdún mẹ́jọ sí méjìdínlógún lo àkókò wọn lọ́nà yìí:

17

pẹ̀lú àwọn òbí wọn

30

níléèwé

44

láti wo tẹlifíṣọ̀n, tayò orí fídíò, fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí gbọ́ orin

KÍ NI MÒ Ń FI GBOGBO ÀKÓKÒ MI ṢE?

Ka iye wákàtí tó ò ń lò lọ́sẹ̀ láti

wo tẹlifíṣọ̀n: ․․․․․

tayò orí fídíò: ․․․․․

lo kọ̀ǹpútà: ․․․․․

gbọ́ orin: ․․․․․

Àròpọ̀: ․․․․․

Iye wákàtí tó yẹ kí n ti lò fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù: ․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 30]

Bó o bá kọ́kọ́ kó àwọn ohun tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sọ́kọ̀, àyè ò ní sí fáwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì gan-an