Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwọn Obìnrin Kì í Fi í Gba Tèmi?

Kí Nìdí Táwọn Obìnrin Kì í Fi í Gba Tèmi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Táwọn Obìnrin Kì í Fi í Gba Tèmi?

Mò ń ṣe fọ́rífọ́rí fún un gan-an ni. Mo ti sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún un nípa mi, nǹkan tí mo ní, ibi tí mo ti dé rí, àwọn èèyàn tí mo mọ̀. Ìfẹ́ mi á ti máa pa á bí ọtí!

Ńṣe ló dà bíi pé kílẹ̀ lanu kó gbé mi mì! Ṣé kò yẹ kí nǹkan tí mò ń sọ ti yé e ni? Báwo ni màá ṣe wá paná ọ̀rọ̀ yẹn láì wọ́ ọ nílẹ̀?

O TI tó láfẹ̀ẹ́sọ́nà. Ẹni tó jojú ní gbèsè tí ẹ̀sìn yín sì pa pọ̀ ló máa wù ẹ́ kó o ní gẹ́gẹ́ bí àfẹ́sọ́nà. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ìgbà tó o bá fẹ́ wá ẹni tó o máa fẹ́, ó máa ń dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe.

Tó o bá fẹ́ mọ obìnrin kan dáadáa, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o gbé yẹ̀ wò? Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló sì yẹ kó o fi sọ́kàn?

Nǹkan Tó Yẹ Kó O Kọ́kọ́ Ṣe

Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí ronú àtifẹ́ ọmọ kan, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kó o mọ̀, ìyẹn á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lè bá ẹnikẹ́ni ṣọ̀rẹ́. Gbé àwọn wọ̀nyí yẹ̀ wò.

◼ Kọ́ bá a ṣe ń hùwà ọmọlúwàbí. Bíbélì sọ pé “ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:5, Ìròhìn Ayọ̀) Ìwà ọmọlúwàbí ò ní jẹ́ kó o máa yájú sáwọn ẹlòmíì, á sì mú kó o máa hùwà tó yẹ ká bá lọ́wọ́ ẹni tó jẹ́ Kristẹni. Àmọ́ ṣá o, ìwà ọmọlúwàbí kì í ṣe ohun tí wàá máa gbé wọ̀ bí ẹ̀wù kó o lè gbayì lójú àwọn èèyàn, kó o wá bọ́ ọ sílẹ̀ nígbà tó o bá délé. Torí náà, máa bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ìwà tó yẹ ọmọ gidi ni mo máa ń hù nínú ilé?’ Bí o kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ńṣe lò ń fagídí hùwà ọmọlúwàbí lójú àwọn ẹlòmíì. Torí náà, ó máa dáa kó o mọ irú ẹni tó o jẹ́, ọmọbìnrin tó lóye á kíyè sí bó o ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ.—Éfésù 6:1, 2.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Ó máa ń dá mi lọ́rùn tí bọ̀bọ́ kan bá níwà rere nínú ohun kékeré bíi kó ṣílẹ̀kùn fún mi, àti nǹkan ńlá bíi kó jẹ́ onínúure kó dẹ̀ máa gba tèmi àtàwọn ẹbí mi rò.”—Tina, ọmọ ogún ọdún. a

“Mo kórìíra kẹ́ni tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bá pàdé máa bi mí láwọn ìbéèrè bíi ‘Ṣó o ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́?’ tàbí ‘Kí làwọn àfojúsùn ẹ?’ Kò buyì kún mi ó sì máa n rí bákan lára mi!”—Kathy, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.

Jẹ́ kí ara ẹ mọ́ tónítóní. Ìmọ́tótó máa fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì àtara ẹ. (Mátíù 7:12) Bó o bá fọ̀wọ̀ wọra ẹ, àwọn míì á fọ̀wọ̀ wọ̀ ẹ́. Bó ò bá kí ń túnra ṣe, kò sí báwọn ọmọbìnrin á ṣe máa gba tìẹ.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Nǹkan tí ò jẹ́ kí n gba ti bọ̀bọ́ kan tó fìfẹ́ hàn sí mi ni pé ẹnu ẹ̀ máa ń rùn, mi ò dẹ̀ lè fara dà á rárá.”—Kelly, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún.

◼ Jẹ́ kí ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ ẹ túbọ̀ dára sí i. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó dán mọ́rán ni ìpìlẹ̀ fún àjọṣe tó máa pẹ́ títí. Èyí túmọ̀ sí pé ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ á máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó jẹ ẹ̀yin méjèèjì lógún.—Fílípì 2:3, 4.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Ó máa ń dá mi lọ́rùn tọ́rọ̀ bá yọ̀ mọ́ bọ̀bọ́ kan lẹ́nu, tó tètè ń rántí nǹkan tí mo sọ fún un, tó sì ń bi mí láwọn ìbéèrè tó ń mú kọ́rọ̀ tá à ń sọ máa dùn lọ.”—Christine, ọmọ ogún ọdún.

“Nǹkan témi rò ni pé nǹkan táwọn ọkùnrin bá rí ló máa ń dá wọn lọ́rùn, àmọ́ nǹkan táwọn obìnrin bá gbọ́ ló máa ń wú wọn lórí.”—Laura, ọmọ ọdún méjìlélógún.

“Ẹ̀bùn dáa lóòótọ́. Àmọ́ ó ti máa lọ wà jù tọ́rọ̀ bá dá mọ́ ọmọkùnrin lẹ́nu, tó mọ bá a ṣe ń fọ̀rọ̀ tuni nínú tó sì mọ̀ọ̀yàn fún níṣìírí.”—Amy, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.

“Ó máa ń wú mi lórí tẹ́nì kan bá ń ṣàwàdà ní fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tó sì tún máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ láìjẹ́ pé ó kàn ń ṣe bíi tòótọ́.”—Kelly, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún.

Tó o bá ń fàwọn ìmọ̀ràn tá a sọ yìí ṣèwà hù, ìyẹn á jẹ́ kó o lè gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó dán mọ́rán. Ká wá sọ pé o ti ṣe tán láti láfẹ̀ẹ́sọ́nà, kí làwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe?

Nǹkan Tó Kàn Láti Ṣe

◼ Ìwọ ni kó o dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Tó o bá lọ́rẹ̀ẹ́ kan tó o gba tiẹ̀, tó o sì rí i pé ó ṣeé fi ṣaya, sọ fún un pé o fẹ́ fẹ́ ẹ. Sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ láìfi ìkan pe méjì. Lóòótọ́ ó lè má dùn-ún sọ. O ò sì ní í fẹ́ kó sọ pé òun ò gbà. Pé o tiẹ̀ gbẹ́nu lé e pé o fẹ́ fẹ́ ẹ lásán ti fi hàn pé ìwọ náà ti dọkùnrin.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Inú mi ni mo mọ̀, mi ò mọ tẹlòmíì. Tẹ́nì kan bá fẹ́ yọ sí mi, kó lanu sọ̀rọ̀.”—Nina, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún.

“Ìyípadà náà lè má rọrùn bó bá ti ṣe díẹ̀ tẹ́ ẹ ti ń bára yín bọ̀. Àmọ́, ẹni tó bá sọ fún mi pé òun fẹ́ ká jọ wà ju ọ̀rẹ́ lásán lọ ló máa gbayì lójú mi.”—Helen, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.

Ka ìpinnu ẹ̀ sí. Tí ọ̀rẹ́bìnrin ẹ bá wá sọ pé òun ò fẹ́ kẹ́ ẹ fẹ́ra ńkọ́? Bọ̀wọ̀ tiẹ̀ fún un tó bá lóun ò gbà. Tó o bá ní àforí àfọrùn kó ṣe tìẹ, a jẹ́ pé o ò tíì dọkùnrin nìyẹn. Tó ò bá kà á sí, tó o tún ń bínú torí pé kò gbà fún ẹ, ṣó máa lè sọ pé ò ń ro tòun mọ́ tìẹ?—1 Kọ́ríńtì 13:11.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Ó tiẹ̀ máa ń rí bákan lára mi bí mo bá sọ fún bọ̀bọ́ kan pé mi ò ṣe, tó wá ní dandan àfi kí n gbà.”—Colleen, ọmọ ogún ọdún.

“Mo sọ fún bọ̀bọ́ kan pé mi ò gba tiẹ̀, ńṣe ló kàn ń dààmú mi pé òun fẹ́ ní nọ́ńbà fóònù mi. Mo kàn dẹwọ́ fún un ni. Kò kúkú láyà láti sọ bó ṣe ń ṣe òun fún mi. Àmọ́ mo dúró lórí ìpinnu mi, mi ò sì gbà fún un.”—Sarah, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún.

Àwọn Nǹkan Tó Ò Gbọ́dọ̀ Ṣe

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan lérò pé kò lè ṣòro fáwọn láti fa ojú àwọn ọmọbìnrin mọ́ra. Kódà, wọ́n tún lè figa gbága pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn lórí ẹni tó lè mú àwọn sisí mọ́lẹ̀ jù. Àmọ́, irú ìfigagbága bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà òǹrorò ó sì lè sọ ẹ́ lórúkọ tí ò dáa. (Òwe 20:11) O lè mórí bọ́ nínú irú àbájáde bẹ́ẹ̀ tó o bá ṣe àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Má tage. Ẹni tó ń tage máa ń lo ọ̀rọ̀ dídùn, ó sì máa ń fara sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń ru ìbálòpọ̀ takọtabo sókè. Kò ní in lọ́kàn láti láfẹ̀ẹ́sọ́nà lọ́nà tó lọ́lá. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ò ka ọ̀rọ̀ Bíbélì sí pé ká máa bá ‘àwọn ọ̀dọ́bìnrin lò gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.’ (1 Tímótì 5:2) Àwọn tó ń tage kì í lọ́rẹ̀ẹ́ tó wúlò, ìgbékúgbèé ni wọ́n sì máa ń gbé sílé. Àwọn obìnrin tórí wọ́n pé mọ̀yẹn dájú.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Nǹkan tí ò dáa gbáà ni pé kí ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ dídùn fún ẹ tó o sì mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe sọ ọ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ kan lóṣù tó kọjá.”—Helen, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.

“Bọ̀bọ́ tó wà pa yìí bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi tage, kò mọ̀ ju kó máa pọ́n ara ẹ̀ lọ, ohun tó wá ṣẹlẹ̀ ni pé nǹkan kan náà ló ṣe sí ọmọbìnrin kan tó wá bá wa níbẹ̀, ìgbà tí ọmọbìnrin kẹta sì dé, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ síyẹn náà. Nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn ò ṣeé gbọ́ sétí!”—Tina, ọmọ ogún ọdún.

Má fàwọn ọmọbìnrin ṣeré. Ó yẹ kó o mọ̀ pé bíbá ọkùnrin bíi tìẹ ṣọ̀rẹ́ yàtọ̀ sí bíbá obìnrin ṣọ̀rẹ́ o. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò: Ọ̀rẹ́ ẹ ọkùnrin ò lè ronú pé ó ní láti jẹ́ pé o fẹ́ fẹ́ òun ni tó o bá ń yẹ́ ẹ sí pé aṣọ dáa lára ẹ̀ tàbí bó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ tó o sì ń finú hàn án. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rẹ́ ẹ obìnrin rò pé o fẹ́ fẹ́ òun ni tó o bá sọ fún un pé aṣọ dáa lára ẹ̀ tàbí tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ tó o sì ń finú hàn án.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan máa ń sọ: “Mi ò rò pé àwọn ọkùnrin mọ̀ pé báwọn ṣe ń ṣe síra wọn kọ́ ló yẹ kí wọ́n máa ṣe sóbìnrin.”—Sheryl, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

“Bọ̀bọ́ kan gba nọ́ńbà fóònù mi, ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù. Ẹ̀-ẹ́n, . . . kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ìgbà míì wà tẹ́ ẹ máa bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra yín lórí fóònù, débi pé ẹ̀ ẹ́ ti yófẹ̀ẹ́ fúnra yín gan-an, àmọ́ ọ̀rọ̀ mélòó lẹ fẹ́ kọ ránṣẹ́ síra yín lórí fóònù?”—Mallory, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.

“Mi ò rò pé ọ̀dọ́kùnrin kan máa ń mọ bí nǹkan ṣe tètè ń wọ obìnrin lára tó, àgàgà kí ọkùnrin yẹn lọ jẹ́ ẹni tó mọ obìnrin tọ́jú tó sì ṣeé bá sọ̀rọ̀. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé obìnrin yẹn ń wọ́kọ lójú méjèèjì. Mo kàn rò pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin máa ń fẹ́ yófẹ̀ẹ́ fọ́kùnrin tí wọ́n bá gba tiẹ̀ ni.’”—Alison, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.

Mọ Nǹkan Tó Ò Ń Ṣe

Ìwà ìjọra ẹni lójú ló máa jẹ́, kò sì ní í fi hàn pé o mọ nǹkan tó ò ń ṣe tó o bá rò pé gbogbo ọmọbìnrin ló máa gba tìẹ. Àmọ́, àwọn díẹ̀ lè gba tìẹ tó o bá ń rántí pé, irú ẹni tó o jẹ́ ní inú ṣe pàtàkì ju ìrísí òde ara ẹ lọ. Kò wá yẹ kó yà wá lẹ́nu nígbà tí Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ká máa fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” ṣèwà hù.—Éfésù 4:24.

Kate ọmọ ogún ọdún, sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́nà yìí: “Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa ń rò pé àwọn gbọ́dọ̀ múra lọ́nà kan káwọn tó lè fa ojú àwọn sisí mọ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn dé àwọn ipò kan, mo rò pé nǹkan tó ń fa àwọn sisí lójú mọ́ra jù ni ìwà ọmọlúwàbí.” b

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ò wọ́ ara ẹ nílẹ̀?

◼ Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ò fojú kéré nǹkan tí ọmọbìnrin kan ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lara ẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìwà ọmọlúwàbí kì í ṣe ohun tí wàá máa gbé wọ̀ bí ẹ̀wù kó o lè gbayì lójú àwọn èèyàn, kó o wá bọ́ ọ sílẹ̀ nígbà tó o bá délé