Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Póòpù Rọ Àwọn Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì Láti Máa Jẹ́rìí

Póòpù Rọ Àwọn Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì Láti Máa Jẹ́rìí

Póòpù Rọ Àwọn Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì Láti Máa Jẹ́rìí

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ

NÍ OṢÙ keje ọdún tó kọjá, àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì jákèjádò ayé kórí jọ sí ìlú Sydney, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, láti ṣayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé ti Ọdún 2008, èyí tó jẹ́ ayẹyẹ ìsìn tí Ìjọ Kátólíìkì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀.

Ìlú Sydney gbàlejò àwọn èèyàn láti àádọ́sàn-án [170] orílẹ̀-èdè. Wọ́n ń ju àsíá, wọ́n ń hó yèè, wọ́n ń kọrin, kùkùfẹ̀fẹ̀ ayẹyẹ náà sì gbilẹ̀ délé dóko nínú ìlú náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún òǹwòran tò sétí Èbúté Sydney kí wọ́n lè kófìrí Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún nígbà tó dé tòun tàwọn ọkọ̀ ojú omi méjìlá mèremère míì tí wọ́n jọ rìn. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mílíọ̀nù èèyàn jákèjádò àgbáyé ló ń wo ìran àrímáleèlọ náà lórí tẹlifíṣọ̀n, bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́.

Ààtò gbígba ara Olúwa tí wọ́n fi kásẹ̀ ayẹyẹ náà nílẹ̀ wáyé lórí pápá ìṣeré kan nílùú náà, àwọn èèyàn tó kóra jọ síbẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó [400,000], tó fi mọ́ ẹgbàajì [4,000] àwọn abẹnugan nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹgbàá [2,000] àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn àti ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn táwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ á kóra jọ sí ilẹ̀ Ọsirélíà, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kódà, wọ́n ju iye èèyàn tó kóra jọ síbi Ìdíje Òlíńpíìkì tó wáyé nílùú Sydney lọ́dún 2000 lọ fíìfíì.

Kí ló ń jẹ́ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé? Kí nìdí tó fi wáyé? Àwọn ìgbòkègbodò wo ló rọ̀ mọ́ ayẹyẹ náà? Kí ló sì jẹ́ ká mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àwọn ọ̀dọ́ tó wà nílùú Sydney?

‘Ìgbàgbọ́ ti Jó Rẹ̀yìn’

Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé jẹ́ ayẹyẹ táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì máa ń ṣe lọ́dọọdún láti sọ ìgbàgbọ́ àwọn ọ̀dọ́ ìjọ Kátólíìkì dọ̀tun. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó wà lábẹ́ àbójútó bíṣọ́ọ̀bù kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe àyájọ́ ayẹyẹ náà déédéé. Àmọ́, lọ́dún méjì méjì tàbí lọ́dún mẹ́ta mẹ́ta, ìlú ńlá kan máa ń gbàlejò ayẹyẹ náà, wọ́n á sì ké sí gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kárí ayé láti péjú síbẹ̀. Ìlú mẹ́wàá láti ilẹ̀ márùn-ún ló ti gbàlejò irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló sì ti lọ síbẹ̀.

Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn abẹnugan nínú ṣọ́ọ̀ṣì ti sọ, ìdí míì tí wọ́n fi ṣètò Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé ni kí wọ́n bàa lè wá nǹkan ṣe sí báwọn ọmọ Ìjọ Kátólíìkì ṣe ń pẹ̀dín. Àlùfáà àgbà ìjọ Kátólíìkì nílẹ̀ Ọsirélíà, George Cardinal Pell, sọ pé: “Ìṣòro tó dojú kọ wá báyìí ni pé àwọn ọmọ ìjọ wa ń pẹ̀dín, ìgbàgbọ́ wa náà sì ti jó rẹ̀yìn dé ìwọ̀n àyè kan. Torí ẹ̀ la ṣe ń ṣayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé, bóyá nǹkan á lè gbé pẹ́ẹ́lí sí i.”

Ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì fi hàn pé ńṣe ni àwọn àlùfáà wọn ń dín kù sí i. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn àlùfáà náà ló ti fi ipò wọn sílẹ̀ lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí kí wọ́n bàa lè gbéyàwó. Iye àwọn tó ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nílẹ̀ Ọsirélíà kí wọ́n lè di àlùfáà ti dín kù gan-an láàárín ọgbọ̀n ọdún tó kọjá. Ní báyìí, nínú èyí tó tóbi jù lọ lára àgbájọ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó wà lábẹ́ bíṣọ́ọ̀bù nílẹ̀ Ọsirélíà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àlùfáà tọ́jọ́ orí ẹ̀ dín sí ọgọ́ta [60] ọdún, èyí tó fi ogún [20] ọdún ju ọjọ́ orí àwọn tó sábà máa ń jẹ́ àlùfáà lọ́dún 1977.

Àwọn ọmọ ìjọ tó ń re ṣọ́ọ̀ṣì lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè pàápàá ti dín kù. Bá a bá kó ọgọ́rùn-ún èèyàn jọ nílẹ̀ Ọsirélíà, mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lára wọn ló máa sọ pé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì làwọn, àmọ́ mẹ́rìnlá lára wọn ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Àwọn ọ̀dọ́ tó sì wà lára àwọn wọ̀nyí ò tó mẹ́wàá. Àti pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni kì í pa òfin ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀, lílo oògùn máàjóyúndúró àti ìkọ̀sílẹ̀. Àwọn míì sì wà tí wọ́n ti ní ìjákulẹ̀ nítorí ìwà ẹ̀gàn táwọn àlùfáà abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ń hù.

Ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald, sọ pé Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé “gan-an ni ohun kan ṣoṣo tó kù tí ìjọ Kátólíìkì ń ṣe láti wá ojútùú sí ọ̀ràn àwọn ọmọ ìjọ tó ń pẹ̀dín náà. Àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà nílẹ̀ Ọsirélíà àti nílùú Róòmù ń wá bí wọ́n á ṣe lo àwọn ọ̀dọ́ láti ta ìgbàgbọ́ jí kí wọ́n sì sọ ọ́ dọ̀tun.” Ipa wo ni ìsapá àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń ní lórí wọn?

Pọ̀pọ̀ṣìnṣìn àti Àpèjẹ

Lára àwọn nǹkan tó wáyé nígbà ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé ti Ọdún 2008 ni pọ̀pọ̀ṣìnṣìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì, kíkóra jọ láti jíròrò, ìrìn àjò lọ síbi táwọn ẹlẹ́sìn kà sí ilẹ̀ mímọ́ àti àpéjọ ńlá láti ṣayẹyẹ gbígba ara Olúwa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbòkègbodò yìí wọ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́kàn, àwọn kan kíyè sí i pé ohun mìíràn kan wà tó mú kí ayẹyẹ náà gbádùn máwọn èèyàn. Ọ̀dọ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Alexandra, tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ nípa Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé pé, “Àpèjẹ ńlá kan ló jọ lójú tèmi.”

Àpéjọ ọlọ́jọ́-mẹ́fà tó wáyé nílùú Sydney náà ṣe àgbéjáde irínwó ó lé àádọ́ta [450] ìṣẹ̀lẹ̀ onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn bí orin àlùjó, fíìmù, onírúurú eré, ìpàtẹ àwọn iṣẹ́ ọnà, àti jíjó yí ìlú ká. Eré onítàn àti orin ẹ̀sìn nìkan kọ́ ló wáyé níbẹ̀, wọ́n tún kọ àwọn orin onílù kíkankíkan àti ọlọ́rọ̀ wótòwótò. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ràn fàájì àti àríyá ló gbádùn orin àlùjó tí wọ́n kọ níbẹ̀.

Ayẹyẹ yìí rí bákan lára àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì. Àlùfáà Peter Scott sọ fún Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn ABC ti Ilẹ̀ Ọsirélíà pé ńṣe ni ayẹyẹ náà wá “di àríyá onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn, ọ̀sẹ̀ tí àríyá ń ṣàn, tí ìlú àti orin ń kọ lálá, láìsí ohun kan tá a lè tọ́ka sí pó jẹ́ mímọ́ tó sì jẹ́ ti ìsìn níbẹ̀.” Kódà, lọ́dún 2000, Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún, tó ń jẹ́ Kádínà Ratzinger nígbà yẹn, kọ̀wé pé: “[Orin] tó ń fi ìfẹ́ gbígbóná fún ohun tara hàn ní orin ‘rọ́ọ̀kì,’ àwọn tó bá sì ti sọ orin yìí di ọlọ́run wọn ló máa ń fà mọ́ra, èyí tó lòdì pátápátá sí ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni fi ń kọ́ni.”Ìwé The Spirit of the Liturgy.

A wá lè béèrè pé, “Ṣé ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń yí ìgbé ayé ẹni pa dà ni Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé?” Àlùfáà tẹ́lẹ̀rí, Paul Collins sọ pé: “Àfi bó bá máa yí ìgbé ayé ìwọ̀nba èèyàn kéréje pa dà.” Ó wá fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ á máa gbé ìgbé ayé tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ lọ ni. Kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ló ń múni ṣe ìyípadà ńlá, bí kò ṣe àròjinlẹ̀, ìwéwèé àfẹ̀sọ̀ṣe àti ìmúratán láti yanjú ìṣòro tó nípọn.”

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”

Èyí gan-an lọ̀rọ̀ tó ń jà ràn-ìn láàárín àwọn aṣáájú ẹ̀sìn. Torí náà, ẹṣin ọ̀rọ̀ tí ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé ti Ọdún 2008 dá lé lórí ni: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá ti bà lé yín; ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi.” a

Àwọn bíṣọ́ọ̀bù rọ àwọn tó rìnrìn àjò wá sílùú Sydney láti “gbé ìtara bíi tàwọn àpọ́sítélì wọ̀ kí wọ́n lè wàásù Ìhìn Rere ní kíkún sí i lóde òní.” Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún rọ àwọn arìnrìn-àjò náà pé kí wọ́n di “ẹ̀yà ìran tuntun ti àwọn àpọ́sítélì” bó sì ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tan “Ìhìn Rere kálẹ̀ láàárín àwọn ará, ọ̀rẹ́ àti gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń bá pàdé.”

Ọ̀rọ̀ yìí gún díẹ̀ lára àwọn tó wá síbi ayẹyẹ náà ní kẹ́ṣẹ́. Ramido, ọmọ ogún ọdún tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ fún oníròyìn kan pé: “Ọwọ́ pàtàkì ni mo fi mú jíjẹ́ ẹlẹ́rìí.” Àmọ́, Beatrice, ọmọ ọdún méjìdínlógún kan tó wá láti ìlú Ítálì, sọ ní tiẹ̀ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ òde òní kì í sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Kò rọrùn láti jẹ́ ẹlẹ́rìí lákòókò tá a wà yìí.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá sí Sydney lèrò wọ́n dọ́gba pẹ̀lú tàwọn ọmọbìnrin méjì kan tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún, tí wọ́n wá láti ìpínlẹ̀ Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan la mọ̀ tí wọ́n máa ń jẹ́rìí níbi tá a ti wá!”

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Jẹ́rìí

Kò sírọ́ ńbẹ̀, tàgbà tèwe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn èèyàn mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń fìtara wàásù. Kí ló fà á tí wọ́n fi ń wàásù? Sotir, ọmọ ọdún méjìlélógún kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó wá láti ìlú Sydney sọ pé: “Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run, fáwọn èèyàn àti fún Bíbélì ló ń mú kí wọ́n wàásù.”

Bí ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé ti Ọdún 2008 ṣe ń lọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí láti ìlú Sydney, tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó irínwó [400] ń ṣe ohun kan. Wọn ò dara pọ̀ mọ́ àwọn Kátólíìkì níbi ayẹyẹ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lọ́wọ́ nínú àkànṣe ìgbétáásì láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn tí ìlú Sydney gbà lálejò. Travas, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sọ pé: “Inú mi dùn gan-an láti bá àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì yìí, tí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run, pàdé. Ọ̀pọ̀ lára wọn béèrè àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání nípa Bíbélì, ó sì dùn mọ́ mi láti fún wọn ní ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn.”

Tarsha, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún sọ pé: “Wẹ́rẹ́ báyìí ni mo máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi. Mo fẹ́ láti kí wọn káàbọ̀ sílùú Sydney, kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún mi.” Frazer, ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Bí àyè ẹ̀ bá yọ, mo máa ń fún àwọn àlejò náà ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? b Inú gbogbo àwọn tí mo bá pàdé dùn láti gba ìwé náà.”

Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò yìí ló gbádùn ìjíròrò tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Suzanne wá láti erékùṣù Fíjì, ó bi Belinda, ìyẹn ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, nípa ohun tó fà á tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Belinda dábàá pé kó jẹ́ káwọn jíròrò ìdáhùn tó wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Nígbà tí wọ́n parí ìjíròrò náà, Suzanne sọ pé: “Ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ fún mi ni pé àwámárìídìí niṣẹ́ Ọlọ́run. Mo ti wá rí ìdáhùn tí mò ń wá báyìí!” Nígbà tí Belinda fún un ní ìwé náà, Suzanne fìtara sọ̀rọ̀ pé: “Ṣe ni mò ń gbìyànjú láti há gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ sórí. Mi ò tiẹ̀ mọ̀ pé wà á fún mi ní ìwé yẹn!”

Àlejò kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Philippines ní kí Marina, Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, ya òun ní fọ́tò níwájú ibi pàtàkì kan nílùú Sydney. Bí ìjíròrò tó lárinrin ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, Marina sì fún obìnrin náà ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Obìnrin náà wá sọ pé: “Ìwòyí alẹ́ àná rèé tí mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n lè túbọ̀ lóye Bíbélì. Ó ní láti jẹ́ pé ìwé yìí ni Ọlọ́run máa lò láti dáhùn ìbéèrè mi!”

Levi, Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú màmá kan àti ọmọ ẹ̀ obìnrin tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Panama. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Levi lo àǹfààní yẹn láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ tó jíire látinú Bíbélì. Àwọn méjèèjì gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Lẹ́yìn náà ni Levi béèrè pé, “Kí lohun tó gbádùn mọ́ ọn yín jù lọ nínú ìrìn àjò yìí?” Ọmọbìnrin tóun àti màmá ẹ̀ jọ gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? yẹn, gbá ìwé náà máyà, ó sì fèsì pé, “Bíbá tá a bá ẹ pàdé.”

Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Kátólíìkì ni wọ́n fẹ́ láti túbọ̀ lóye Bíbélì. Ìwọ ńkọ́? Ṣó wù ẹ́ kó o túbọ̀ lóye Bíbélì? O ò ṣe ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa bá ẹ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́? Inú wọn máa dùn láti ran ìwọ náà lọ́wọ́!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ látinú Ìṣe 1:8, nínú ìtumọ̀ The Jerusalem Bible.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

“Ìṣòro tó dojú kọ wá báyìí ni pé àwọn ọmọ ìjọ wa ń pẹ̀dín, ìgbàgbọ́ wa náà sì ti jó rẹ̀yìn dé ìwọ̀n àyè kan.”—George Cardinal Pell ti Ìjọ Kátólíìkì

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ójú ìwé 17]

ÌPOLONGO OJÚṢE Ẹ̀SÌN

Níbi Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé ti Ọdún 2008 ni ìpolongo ojúṣe ẹ̀sìn tí ò tíì sírú ẹ̀ rí nílẹ̀ Ọsirélíà ti wáyé. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] àjọ àti onírúurú aṣojú ìjọ Kátólíìkì tó rọ àwọn tó lé ní ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ láti ronú sí i bóyá wọ́n á lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ nínú Ìjọ Kátólíìkì gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tàbí àwọn iṣẹ́ míì tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn.

[Àwòrán tó wà lójú ewé 16, 17]

Àwọn àlejò tó wọṣọ mèremère ń wọ́ káàkiri àdúgbò

[Àwòrán tó wà lójú ewé 18]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn àlejò tó ń rìn yí ká ìlú Sydney

[Àwòrán Credit Line tó wà lójú ìwè 16]

Àwòrán tí Getty Images yà