Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Àpótí Tí Jèhófà Nìkan Lè Ṣí’

‘Àpótí Tí Jèhófà Nìkan Lè Ṣí’

‘Àpótí Tí Jèhófà Nìkan Lè Ṣí’

◼ Lọ́dún 2007, bàbá àwọn ọmọ ọdún mẹ́fà kan tó ń jẹ́ Erika àti ọmọ ọdún mẹ́rin kan tó ń jẹ́ Mattia, kú. Ní báyìí, ìrètí àjíǹde ti pẹ̀tù sáwọn ọmọ méjì yìí lọ́kàn.—Ìṣe 24:15.

Erika fẹ́ràn láti máa sọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ ọ nípa àjíǹde fáwọn ẹlòmíì, pàápàá níléèwé rẹ̀ tó wà ní erékùṣù Sísílì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Beatrice, ọ̀rẹ́ Erika sọ pé ọ̀run ni bàbá Erika wà báyìí, Erika fara balẹ̀ ṣàlàyé fún un pé Bíbélì ò sọ pé ọ̀run ni bàbá òun lọ. Beatrice wá bi í pé: “Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ibo ló wà?”

Erika fèsì pé: “Nínú ibojì.” Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, Beatrice fẹ́ láti mọ ohun tó ń jẹ́ ibojì.

Erika ṣàlàyé fún un pé: “Ibojì dà bí àpótí kan tó ṣeé ṣí, tó sì tún ṣeé tì. Àmọ́ gbàrà tí àpótí náà bá ti tì, kò sí ẹ̀dá tó lè ṣí i. Jèhófà nìkan ló lè ṣí i nínú ayé tuntun tó ń bọ̀.”

Lẹ́yìn yẹn ni Erika wá ṣàlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, pé ó máa mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé, kò ní sí àìsàn mọ́, àwọn òkú á sì jíǹde. Erika wá ní kí Beatrice béèrè lọ́wọ́ mọ́mì rẹ̀ bóyá ó máa jẹ́ kí òun fún un ní ẹ̀bùn ìwé kan tó ṣàlàyé àwọn nǹkan wọ̀nyí.

Lẹ́yìn tí Erika mọ̀ pé mọ́mì Beatrice ò ní sọ pé kó má gba ìwé náà, ó fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ní ẹ̀dà kan ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Erika ń bá a nìṣó láti máa sọ àwọn ohun tó ń kọ́ látinú Bíbélì fáwọn ẹlòmíì, ó sì ti fún olùkọ́ rẹ̀ ní ẹ̀dá kan ìwé yìí pẹ̀lú.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ikú bàbá Erika ṣì máa ń ba òun àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin nínú jẹ́, ìrètí àjíǹde máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Bíi tàwọn ọmọdé mìíràn níbi gbogbo lágbàáyé, àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, Ọlọ́run tó ń fún wa ní ojúlówó ìtùnú.—Mátíù 21:16; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan lára ìwé olójú ewé 256, tó ní àwòrán rírẹwà tó sì fẹ̀ tó ìwé ìròyìn yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ìwé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sí ojú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.