Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òbí Tó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Tí Wọ́n sì Mọṣẹ́ Wọn Níṣẹ́

Àwọn Òbí Tó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Tí Wọ́n sì Mọṣẹ́ Wọn Níṣẹ́

Àwọn Òbí Tó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Tí Wọ́n sì Mọṣẹ́ Wọn Níṣẹ́

◼ Ojú ọjọ́ tutù nini lọ́jọ́ tá à ń wí yìí níbi títẹ́jú pẹrẹsẹ kan tó wà lápá ibi gíga fíofío láàárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè South Africa. Mo bojú wòta láti àjà kẹta nínú ọ́fíìsì mi tó lọ́ wọ́ọ́wọ́, mo sì rí igi kan tí kò léwé lórí, tí ẹ̀fúùfù ìgbà òtútù ń bì síwá sẹ́yìn. Mo rí ẹyẹ àdàbà kan láàárín méjì ẹ̀ka igi náà. Ó kó àwọn ọmọ ẹ̀ méjì tí wọn ò tíì ju ọmọ ọjọ́ mẹ́ta lọ sábẹ́, kó bàa lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ otútù.

Kí abo àdàbà yìí tó yé ẹyin àkọ́kọ́, òun àti èyí akọ kọ́kọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe ìtẹ́. Akọ ń fẹnu gbé igi kéékèèké wá, èyí abo sì ń tò ó pọ̀ láti fi ṣe ìtẹ́ náà. Ìtẹ́ náà lágbára débi pé ẹ̀fúùfù ìgbà òtútù ò lè tú u ká. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìtẹ́ náà tán, èyí abo yé ẹyin méjì sínú rẹ̀. Abo àdàbà náà máa ń sàba lé àwọn ẹ̀yin méjì yìí lálẹ́; èyí akọ á sì gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, wọ́n pa ẹyin náà. Kí ọ̀sẹ̀ méjì míì tó pé, àwọn ọmọ àdàbà yìí á ti tóbi wọ́n á sì ti lágbára tó láti fò.

Fetí sílẹ̀! Ṣó ò ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ kú-ku kú-ku bí ìgbà téèyàn rọra ń rẹ́rìn-ín? Abo àdàbà ló dé yẹn, ó ti lọ fi ẹnu gbé oúnjẹ wá fáwọn ọmọ wọn tébi ń pa, ó sì tún ṣe tán láti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ èyí akọ. Nígbà tó ṣe, àwọn ọmọ àdàbà yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í fò, síbẹ̀ àwọn òbí wọn ṣì ń wá oúnjẹ fún wọn títí dìgbà tí wọ́n fi dàgbà tó láti wá oúnjẹ sẹ́nu ara wọn.

Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi báwọn àdàbà yẹn ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tí wọ́n sì bójú tó àwọn ọmọ wọn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Bí ọgbọ́n àdámọ́ni yẹn á sì ṣe máa wà nínú àwọn ọmọ wọn láti ìran dé ìran nìyẹn. Èyí mú mi rántí àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 86:8, tó sọ pé: “Jèhófà, kò sí ẹni tí ó dà bí rẹ . . . , bẹ́ẹ̀ ni kò sí iṣẹ́ kankan tí ó dà bí tìrẹ.”

Nínú Bíbélì Mímọ́ tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Jèhófà fún àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ òbí ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé bí irú ọgbọ́n àdámọ́ni tó fáwọn ẹyẹ àdàbà yìí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì rọ àwọn òbí pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.” (Títù 2:4) Ó sọ fún àwọn baba pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4; 1 Tímótì 5:8) Ó dájú pé àwọn òbí tó bá ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ yìí ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run.