Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Máa Finá Sun Àwọn Èèyàn Búburú ní Ọ̀run Àpáàdì?

Ṣé Ọlọ́run Máa Finá Sun Àwọn Èèyàn Búburú ní Ọ̀run Àpáàdì?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Máa Finá Sun Àwọn Èèyàn Búburú ní Ọ̀run Àpáàdì?

ONÍWÀÁSÙ ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Gertrude ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn gba-Jésù, ó sì fi gbogbo ara gbà pé iná ọ̀run àpáàdì wà. Bí ẹnì kan bá sì sọ lójú ẹ̀ pé kò sí ọ̀run àpáàdì, ńṣe ló máa dà bíi pé onítọ̀hún fẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà. Èrò ẹ̀ ni pé láìsí iná ọ̀run àpáàdì, àṣegbé ni gbogbo ìwà ọ̀daràn bíburú jáì máa jẹ́. Gertrude ò gbà kí ohunkóhun yí èrò tó ní yìí pa dà. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Mi ò rò pé màá fẹ́ láti sin Ọlọ́run bó bá jẹ́ pé àwọn ẹni ibi ò ní lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.”

Ṣóòótọ́ ni pé Ọlọ́run á fi iná sun àwọn èèyàn búburú ní ọ̀run àpáàdì? Bí kò bá ní fi iná sun wọ́n, ìyà wo ló máa fi jẹ wọ́n?

Ìgbà Àkọ́kọ́ Tí Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ẹ̀dá Aláìṣòótọ́

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́ ní pípé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Diutarónómì 32:4) Ó fi wọ́n sínú ọgbà párádísè, ó sì fún wọn láǹfààní láti máa wà láàyè títí láé. Àmọ́, ohun kan wà tó sọ pé àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ náà, Ádámù àti Éfà, ò gbọ́dọ̀ ṣe. Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17.

Ó ṣeni láàánú pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ò yege nínú ìdánwò tí kò nira yìí, èyí tó béèrè pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn. Torí náà, ó di dandan pé kí Ẹlẹ́dàá dájọ́ ikú fún wọn. Ó sọ fún wọn pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

Bó bá jẹ́ pé ọ̀run àpáàdì ni Ọlọ́run fẹ́ rán Ádámù àti Éfà lọ, ṣé kò ti ní kìlọ̀ fún wọn nípa ìyà tí wọ́n máa jẹ níbẹ̀? Òtítọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé kò sọ pé wọ́n máa jìyà lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Báwo ni ìyà tiẹ̀ ṣe máa jẹ wọ́n? Ó ṣe tán, wọn ò ní ọkàn tí kò lè kú, tá máa wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú. Bíbélì sì mú ìyẹn ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.”Ìsíkíẹ́lì 18:4. a

Gẹ́gẹ́ bí Olùfúnni ní ìyè, Ẹlẹ́dàá wa mọ gbogbo ohun tó yẹ ní mímọ̀ nípa ìwàláàyè àti ikú. Ó sọ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “àwọn òkú . . . kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Ádámù àti Éfà kò fi lè jìyà nínú iná ọ̀run àpáàdì kan lẹ́yìn tí wọ́n kú. Ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ pa dà sínú ilẹ̀ tí wọn ò sì wà láàyè mọ́. Wọn kò “mọ nǹkan kan rárá.”

Ṣé A Lè Jìyà Lẹ́yìn Tá A Bá Kú?

Bíbélì sọ fún wa nínú Róòmù 5:12 pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.” Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣó wá bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn èèyàn á máa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ nínú iná ọ̀run àpáàdì kan, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni Ádámù tó fà á tí gbogbo aráyé fi ń kú wulẹ̀ pa dà sínú erùpẹ̀ lẹ́yìn tó kú?—1 Kọ́ríńtì 15:22.

Òfin tó mú Ádámù ló mú àwa náà. “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” Àti pé béèyàn bá ti kú, “a ti dá [a] sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7, 23) Bó bá wá jẹ́ pé àti ẹni rere àti ẹni búburú ló ń kú, tí èyíkéyìí nínú wọn kì í sì í jìyà, báwo ni Ọlọ́run ṣe wá ń fìyà jẹ àwọn ẹni ibi nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn?

Ìdájọ́ Òdodo Ọlọ́run

Ète Ọlọ́run fún aráyé onígbọràn ò tíì yí pa dà látìgbà tó ti dá tọkọtaya àkọ́kọ́ tó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n bímọ kí wọ́n sì máa bójú tó ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó ṣe kedere pé ète rẹ̀ náà ṣì nìyẹn, níwọ̀n bó ti polongo lẹ́yìn náà pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

Kíyè sí i pé lórí ilẹ̀ ayé ńbí ni àwọn olódodo á máa gbé. Àìlera èyíkéyìí kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́, wọ́n á sì máa láyọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí fún Ádámù àti Éfà. Ètè Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí ayé kún fún ìran èèyàn olódodo á sì ní “àṣeyọrí sí rere tí ó dájú.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti fi ayé tuntun òdodo rọ́pò ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí ni ìlérí yìí máa tó nímùúṣẹ.—Aísáyà 55:11; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:4.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ti kú láìmọ bí wọ́n ṣe lè ṣèfẹ́ Ọlọ́run máa jíǹde, wọ́n á sì gba ìtọ́ni tó máa mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti wàláàyè títí láé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀. (Aísáyà 11:9; Jòhánù 5:28, 29) Àmọ́ ṣá o, bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ láti fara mọ́ àwọn òfin Ọlọ́run, Jèhófà máa fìyà “ikú kejì” jẹ ẹ́, ìyẹn ikú tí kò ní àjíǹde nínú.—Ìṣípayá 21:8; Jeremáyà 51:57.

Ó dájú pé, Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ ò ní fi iná dá àwọn èèyàn lóró ní ọ̀run àpáàdì. (1 Jòhánù 4:8) Kò sì ní fàyè gba ìwà búburú títí gbére. Ìyẹn ni Sáàmù 145:20 fi mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni burúkú ni òun yóò pa rẹ́ ráúráú.” Ǹjẹ́ ìyẹn ò mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ìfẹ́ àti onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú Bíbélì, “ọkàn” túmọ̀ sí odidi èèyàn kan, kì í ṣe ohun kan tó dá wà nínú ara. Jẹ́nẹ́sísì 2:7 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Ọlọ́run kò fún Ádámù ní ọkàn tó ń gbé nínú ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ádámù fúnra rẹ̀ ni alààyè ọkàn.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ṣé a ní ọkàn tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú?—Ìsíkíẹ́lì 18:4.

◼ Ipò wo làwọn òkú wà?—Oníwàásù 9:5.

◼ Báwo ní Ọlọ́run ṣe máa fìyà jẹ àwọn ẹni ibi?—Sáàmù 145:20.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

“Àwọn òkú . . . kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5

[Àwòrán Credit Line tó wà lójú ìwè 26]

Fọ́tò: www.comstock.com