Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Bínú Sódì?

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Bínú Sódì?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Bínú Sódì?

Báwo ni inú ṣe máa ń bí ẹ sódì tó?

□ Kò ṣẹlẹ̀ rí

□ Oṣooṣù

□ Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀

□ Ojoojúmọ́

Ta ló ṣeé ṣe kó múnú bí ẹ?

□ Kò sí

□ Àwọn ọmọléèwé mi

□ Àwọn òbí mi

□ Tẹ̀gbọ́ntàbúrò mi

□ Àwọn míì

Ṣàlàyé ohun kan tó máa ń múnú bí ẹ sórí ìlà yìí.

□ ․․․․․

BÓ O bá fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ “Kò ṣẹlẹ̀ rí,” “Kò sí,” tí o kò sì kọ ohunkóhun sínú àlàfo tó kẹ́yìn, a bá ẹ yọ̀, a jẹ́ pé o kì í bínú sódì nìyẹn!

Àmọ́ ṣá o, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára olúkúlùkù yàtọ̀, gbogbo èèyàn ló sì máa ń ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó lọ́nà kan tàbí òmíràn. Jákọ́bù, òǹkọ̀wé Bíbélì, sọ pé: “Gbogbo wa ni a ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà.” (Jákọ́bù 3:2, Ìròhìn Ayọ̀) Kódà, lórí ọ̀rọ̀ ìbínú tá à ń sọ yìí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti Serena, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. a Ó sọ pé: “Ara mi máa ń gbẹ̀kan, bí ẹnì kan bá sì tọ́ mi pẹ́nrẹ́n, màá fìkanra mọ́ ọn ni. Ì báà jẹ́ Dádì, Mọ́mì, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi, ó sì lè jẹ́ ajá mi pàápàá!”

Bá A Ṣe Lè Mọ Irọ́ Yàtọ̀ sí Òótọ́

Ṣé gbogbo ìgbà lo máa ń bínú sódì? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ mọ àwọn ohun kan tí kò rí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́.

Irọ́: “Mi ò lè ṣe kí n máà bínú sódì, a máa ń tètè bínú nílé wa!”

Òótọ́: Ó lè jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé, ibi tó ò ń gbé tàbí àwọn nǹkan míì ló fà á tó fi máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fi “ìhónú” hàn. Àmọ́, ìwọ lo máa pinnu bóyá wàá máa gba ìbínú láyè tàbí o kò ní máa gbà á láyè. (Òwe 29:22) Ìbéèrè tó wá yẹ kó o bi ara ẹ ni pé, Ṣé èmi ni màá máa darí ìbínú ni, àbí ìbínú lá máa darí mi? Àwọn míì ti kọ́ láti máa darí ìbínú wọn, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!—Kólósè 3:8-10.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Éfésù 4:31.

Irọ́: “Bí inú bá ń bí mi, ó sàn kí n fara ya dípò kí n pa á mọ́ra.”

Òótọ́: Kò séyìí tó dáa fún ìlera ẹ nínú méjèèjì. Lóòótọ́, àkókò wà tó yẹ kó o “tú” ìdàníyàn ẹ “jáde.” (Jóòbù 10:1) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kí ìbínú wá sọ ẹ́ di àgbá ẹ̀tù tó ń wá iná kiri. O mọ béèyàn ṣe ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn láì fara ya.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, . . . tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.”—2 Tímótì 2:24.

Irọ́: “Bí mo bá jẹ́ ‘ẹni pẹ̀lẹ́ sí ẹni gbogbo,’ àwọn èèyàn, á máa rí mi fín.”

Òótọ́: Àwọn èèyàn mọ̀ pé kì í ṣe ohun tó rọrùn láti máa kóra ẹni níjàánu, bí wọ́n bá wá rí i tó ò ń kóra ẹ níjàánu, wọ́n á bọ̀wọ̀ fún ẹ.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.

Bó O Ṣe Lè Kọwọ́ Ìbínú Rẹ Bọlẹ̀

Bó bá jẹ́ pé o máa ń tètè bínú, ó ṣeé ṣe kó o ti máa di ẹ̀bi ru àwọn míì pé àwọn ló ń jẹ́ kó o fara ya. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o ti sọ ọ́ rí pé, “Ó múnú bí mi” tàbí “Ó jẹ́ kí n bínú sódì”? Bó o bá ti sọ bẹ́ẹ̀ rí, ohun tó ò ń sọ nígbà náà ni pé àwọn ẹlòmíì ló ń darí ẹ síbi tí wọ́n bá fẹ́. Báwo ni ìwọ fúnra rẹ ṣe lè máa darí ara rẹ? Gbìyànjú àwọn ohun tá a fẹ́ sọ yìí ná.

Ìwọ ni kó o máa darí ara rẹ. Èyí bẹ̀rẹ̀ látorí mímọ̀ pé ìwọ nìkan lo lè ‘múra’ ẹ bínú. Torí náà, má ṣe dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi pé àwọn ló ń mú ẹ bínú mọ́. Dípò tí wàá fi sọ pé, “Ó múnú bí mi,” gbà pé, ‘èmi ni mo jẹ́ kí inú bí mi.’ Dípò tí wàá fi sọ pé, “Ó jẹ́ kí n bínú sódì,” gbà pé, ‘èmi ni mo yàn láti bínú sódì.’ Bó o bá ti gbà pé ọwọ́ ẹ lọ̀rọ̀ wà, ó máa rọrùn fún ẹ láti ṣe ìyípadà.—Gálátíà 6:5.

Fọkàn ro ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Torí náà, ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o fọkàn ro ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé. Bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo ló ṣeé ṣe kí n fara ya?’ Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Megan sọ pé: “Iṣẹ́ alẹ́ ni mò ń ṣe, nígbà tí mo bá fi máa parí iṣẹ́, ó máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Irú ìgbà yẹn ni ohunkóhun lè mú orí mi gbóná kí n sì fara yà.”

Ìbéèrè: Àwọn ìgbà wo ló ṣeé ṣe kó o fara ya?

․․․․․

Múra láti fèsì lọ́nà tó sàn jù. Tí inú bá bí ẹ, mí sínú kó o sì tún mí síta kára ẹ lè silé, dẹ ohùn ẹ wálẹ̀, kó o wá fohùn jẹ́jẹ́ sọ̀rọ̀. Dípò kó o fẹ̀sùn kan ẹlòmíì (“Ìwọ olè yìí! O mú súẹ́tà mi láì kọ́kọ́ béèrè ẹ̀ lọ́wọ́ mi!”) ṣe ni kó o gbìyànjú láti sọ ọ̀nà tí ohun tẹ́ni yẹn ṣe gbà kàn ẹ́. (“Mo wá súẹ́tà mí títí nígbà tí mo fẹ́ wọ̀ ọ́, àmọ́ mi ò mọ̀ pé ìwọ lo wá ‘yá’ a láìsọ fún mi.”)

Àṣedánrawò: Ronú nípa ohun kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí tó mú kó o bínú sódì.

1. Kí ló bí ẹ nínú?

․․․․․

2. Kí lo ṣe?

․․․․․

3. Kí ni ì bá ti sàn jù kó o sọ?

․․․․․

Ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ìlànà Bíbélì ló wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ:

Òwe 12:18: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” Ọ̀rọ̀ máa ń dunni, bó o bá sì bínú sódì, àfàìmọ̀ kó o má sọ ohun tó o máa kábàámọ̀ bó bá yá.

Òwe 29:11: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” Béèyàn bá ń bínú sódì, ńṣe ló máa rí ara ẹ̀ bí òmùgọ̀ nígbà tí ojú ẹ̀ bá dá.

Òwe 14:30: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” Ìbínú ò dáa fún ìlera rẹ! Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Anita sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ ríru ń yọ wá lẹ́nu nínú ìdílé mi, mo sì máa ń rò ó dáadáa kí n tó bínú, torí pé mo máa ń ní ìdààmú ọkàn.”

Kí lèyí kọ́ wa? Máa ro ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ àti ìwà tó o bá hù máa já sí. Heather, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé: “Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Bí mo bá bínú sí ẹni yìí, kí ló máa rò nípa mi? Ṣé kò ní ba àjọṣe wa jẹ́? Báwo ló ṣe máa rí lára mi béèyàn bá ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi?’ ” O lè bi ara rẹ nírú ìbéèrè yìí kó o tó kọ lẹ́tà ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ alágbèéká tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ìbéèrè: Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí ẹnì kan bá múnú bí ẹ tó o sì kọ lẹ́tà ìbínú ránṣẹ́ sí i, yálà lórí ẹ̀rọ alágbèéká tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

․․․․․

Wá ìrànlọ́wọ́. Òwe 27:17 sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” O ò ṣe ní kí Dádì, Mọ́mì, tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan tó dàgbà dénú kọ́ ẹ bó ṣe máa ń fiyè dénú?

Máa kíyè sí ibi tó o tẹ̀ síwájú dé. Ní àkọsílẹ̀ kan, kó o sì máa kíyè sí ibi tó o tẹ̀ síwájú dé. Ní gbogbo ìgbà tó o bá bínú sódì, ṣe àkọsílẹ̀ (1) ohun tó ṣẹlẹ̀, (2) ohun tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe, àti (3) ohun tó sàn jù kó o ṣe. Bó bá yá, wàá rí i pé ohun tó sàn jù kó o ṣe yẹn gan-an lá kọ́kọ́ máa wá sọ́kàn ẹ!

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Ìgbà míì tiẹ̀ wà táwọn tá a rò pé wọn ò jẹ́ bínú sódì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo lo rò pé a lè rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí?

◼ Mósè—Númérì 20:1-12; Sáàmù 106:32, 33.

◼ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà—Ìṣe 15:36-40.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Bí mo ṣe máa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó ń bí mi nínú tàbí kí n sọ ọ́ fún Mọ́mì, máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.”—Alexis, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Bó bá ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu, mo máa ń sáré kúṣẹ́kúṣẹ́ kára mi lè nà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ìrònú mi já gaara.”—Elizabeth, láti orílẹ̀-èdè Ireland.

“Mo máa ń gbọ́kàn kúrò nínú ohun tó ṣẹlẹ̀, màá wá bi ara mi pé, ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí mo bá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo?’ Mo sábà máa ń rí i pé ariwo kọ́ ló máa yanjú ọ̀ràn náà!”—Graeme, láti ilẹ̀ Ọsirélíà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń bínú. Síbẹ̀, orí ẹ̀tọ́ ló máa ń bínú lé, kì í sì í ṣàṣejù. Kò bínú sódì rí!—Wo Ẹ́kísódù 34:6; Diutarónómì 32:4; àti Aísáyà 48:9.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ìwọ lo máa pinnu yálà wàá jẹ́ kí inú bí ẹ sódì tàbí kó má ṣe bí ẹ sódì