Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Dádì Tàbí Mọ́mì Bá Kú?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Dádì Tàbí Mọ́mì Bá Kú?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Dádì Tàbí Mọ́mì Bá Kú?

“Nígbà tí Mọ́mì kú, ìdààmú bá mi, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi. Torí pé Mọ́mì ló so ìdílé wa pọ̀ ṣọ̀kan.”—Karyn. a

IKÚ òbí jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa ń dunni wọra gan-an. Béèyàn ṣe ń fara da ẹ̀dùn ọkàn nítorí ẹni téèyàn pàdánù, bẹ́ẹ̀ ni ominú á tún máa kọni pé ó ṣeé ṣe kí nǹkan máà rí béèyàn ṣe rò pé ó máa rí lọ́jọ́ iwájú.

Ó ṣeé ṣe kó o ti máa ronú pé mọ́mì tàbí dádì ẹ máa wà níbẹ̀ nígbà tó o bá ń gboyè jáde níléèwé tàbí nígbà tó o bá ríṣẹ́ tàbí nígbà tó o bá ń ṣègbéyàwó. Ó wá dà bíi pé ọ̀nà ò gba ibi tó o fojú sí mọ́, ọkàn rẹ bà jẹ́, gbogbo ẹ̀ tojú sú ẹ, tàbí kínú tiẹ̀ máa bí ẹ. Báwo lo ṣe lè fara da ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ téèyàn máa ń ní lẹ́yìn tí Dádì tàbí Mọ́mì bá kú?

‘Àbí Nǹkan Ń Ṣe Mí Ni?’

Nígbà tó o wá gbà pé lóòótọ́ ni Mọ́mì tàbí Dádì ti kú, ẹ̀dùn ọkàn lè mú kó o kọ́kọ́ fara ya lọ́nà tí kò tíì ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá péré ni Brian nígbà tí àrùn ọkàn pa dádì ẹ̀, ó sọ pé: “Gbàrà tá a mọ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé Dádì ti kú, ńṣe la kàn ń sunkún tá a sì ń dì mọ́ra wa.” Natalie, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa dádì ẹ̀ sọ pé: “Mo kàn ń wò ṣáá ni. Kò ṣe mí bíi kí n sunkún. Mi ò sì ní ìmọ̀lára kankan.”

Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ikú máa ń gbà nípa lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Kódà, Bíbélì sọ pé “olúkúlùkù” ní “ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀.” (2 Kíróníkà 6:29) Fìyẹn sọ́kàn, kó o wá ronú díẹ̀ lórí ipa tí ikú òbí ẹ ní lórí ẹ. Lórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí, ṣàlàyé (1) bó ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ nípa ikú Dádì tàbí Mọ́mì àti (2) bó ṣe rí lára ẹ báyìí. b

(1) ․․․․․

(2) ․․․․․

Bó o bá lè ṣàlàyé bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára ẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀dùn ọkàn tó o ní nípa ikú Dádì tàbí Mọ́mì ti ń dín kù nìyẹn. Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Ìyẹn ò fi hàn pé o ti gbàgbé àwọn òbí ẹ. Ohun mìíràn sì tún ni pé, ó ṣeé ṣe kó ṣì máa dùn ẹ́, tàbí kó tiẹ̀ máa dùn ẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ẹ̀dùn ọkàn ẹ ń wá tó sì tún ń lọ bí ìgbà tí omi ń ṣàdédé ru gùdù. Bó ṣe máa ń rí nìyẹn, kódà ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú àwọn òbí ẹ. Ìbéèrè tó wá yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni pé, Ọ̀nà yòówù kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ máa gbà wá, báwo lo ṣe lè kojú rẹ̀?

Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Kojú Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ

Bí ẹkún bá ń gbọ̀n ẹ́, sun ún! Ikú èèyàn ẹni máa ń bani lọ́kàn jẹ́ gan-an, ẹkún sì lè dín irú ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ kù. Àmọ́, ó lè máa ṣe ìwọ náà bíi ti Alicia, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] nígbà tí mọ́mì rẹ̀ kú. Ó sọ pé, “Ó ṣe mí bíi pé bí mo bá fi ẹ̀dùn ọkàn hàn ju bó ṣe yẹ lọ, lójú àwọn ẹlòmíì, ńṣe ló máa dà bíi pé mi ò nígbàgbọ́.” Àmọ́, jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ẹni pípé tó ní ìgbàgbọ́ yíyè kooro nínú Ọlọ́run ni Jésù Kristi. Síbẹ̀, ó “da omijé” lójú nígbà tó gbọ́ pé Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. (Jòhánù 11:35) Torí náà, má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ láti sunkún. Ìyẹn ò fi hàn pé o nígbàgbọ́! Alicia sọ pé: “Nígbà tó ṣe mo bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. Ojoojúmọ́ ni mò ń wa ẹkún mu bí omi.” c

Sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Karyn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, nígbà tí mọ́mì ẹ̀ kú, sọ pé: “Ní alaalẹ́ tí mo bá fẹ́ lọ sùn, mo sábà máa ń lọ sí yàrá òkè láti fẹnu ko mọ́mì lẹ́nu. Àmọ́, alẹ́ ọjọ́ kan wà tí mi ò ṣe bẹ́ẹ̀. Àárọ̀ ọjọ́ kejì sì ni Mọ́mì kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé rírí tí mi ò rí Mọ́mì kí n tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ikú wọn, síbẹ̀, ọkàn mi ń dá mi lẹ́bi pé mi ò lọ wò wọ́n, mo sì tún ń dará mi lẹ́bi torí gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì. Ìdí ni pé Dádì lọ ṣiṣẹ́ níbì kan, wọ́n sì ní kémi àti àǹtí mi máa lọ wo Mọ́mì. Àmọ́, a pẹ́ ká tó sùn, a ò sì tètè jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Ìgbà tí mo sì máa lọ wo Mọ́mì, wọ́n ti kú. Ọkàn mi dà rú, torí pé kò sí nǹkan tó ṣe wọ́n nígbà tí Dádì jáde nílé!”

Bíi ti Karyn, ọkàn ẹ lè máa dá ẹ lẹ́bi torí àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe àmọ́ tó ò ṣe. Kó o wá máa kábàámọ̀ pé, ‘Ká ní mo ti sọ pé kí Dádì lọ rí dókítà ni.’ ‘Ká ní mo ti lọ wo Mọ́mì ṣáájú ìgbà yẹn ni.’ Bírú èrò yẹn bá ń da ọkàn ẹ láàmú, ohun tó o gbọ́dọ̀ rántí rèé: Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn kábàámọ̀ nítorí pé kò ṣe ohun tó yẹ kó ṣe. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ká ló o mọ̀ pé ibi tọ́rọ̀ máa já sí nìyẹn ni, ọ̀tọ̀ ni nǹkan tó ò bá ṣe. Àmọ́, o kò mọ̀. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ kó o dára ẹ lẹ́bi. Ìwọ kọ́ lo pa dádì tàbí mọ́mì ẹ! d

Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún àwọn ẹlòmíì. Òwe 12:25 sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ rere máa ń múni yọ̀.” Bó o bá pa bó ṣe ń ṣe ẹ́ mọ́ra, ó lè mú kó ṣòro fún ẹ láti borí ẹ̀dùn ọkàn ẹ. Ohun míì ni pé, bó o bá jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹnì kan tó o fọkàn tán, wàá láǹfààní láti gbọ́ “ọ̀rọ̀ rere” tí ń gbéni ró nígbà tí ọkàn ẹ bá bà jẹ́. Torí náà, o ò ṣe gbìyànjú ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn àbá wọ̀nyí?

Bá òbí ẹ tó wà láàyè sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò tí kò rọgbọ lèyí jẹ́ fún dádì tàbí mọ́mì ẹ tó wà láàyè, òun náà ṣì máa fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Torí náà, jẹ́ kó mọ bó ṣe ń ṣe ẹ́. Ó dájú pé irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ á dín ẹ̀dùn ọkàn ẹ kù á sì mú kí ìwọ àti dádì tàbí mọ́mì ẹ̀ tó wà láàyè túbọ̀ mọwọ́ ara yín.

Bó o bá gbìyànjú ohun tá a kọ sísàlẹ̀ yìí wò, ó máa jẹ́ kó o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò: Kọ ohun méjì tàbí mẹ́ta tí ì bá ti wù ẹ́ kó o mọ̀ nípa dádì tàbí mọ́mì ẹ tó kú, kó o sì sọ fún òbí ẹ tó wà láàyè pé wàá fẹ́ láti jíròrò wọn pẹ̀lú rẹ̀. e

․․․․․

Bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ la “bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Alicia sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ẹni tó ò ronú kàn rárá ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Torí náà, má bẹ̀rù láti sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ síta.” Bí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yẹn, ẹ lè má mọ ohun tó yẹ kẹ́ ẹ sọ. Àmọ́, bó bá yá, wàá rí i pé ó dáa tó o sọ tinú ẹ fún wọn. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré ni David nígbà tí àrùn ọkàn pa bàbá rẹ̀. Ó sọ pé: “Ńṣe ni mo bo ẹ̀dùn ọkàn mi mọ́ra. Ká ní mo sọ tinú mi jáde ni, ara ì bá tù mí gan-an. Ìyẹn ì bá sì ti mú kí n kápá ẹ̀dùn ọkàn mi.”

Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Bóyá, ohun tí ì bá fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ jù lọ ni pé kó o ‘tú ọkàn-àyà ẹ jáde’ fún Jèhófà Ọlọ́run nínú àdúrà. (Sáàmù 62:8) Èyí kì í wulẹ̀ ṣe nítorí kára lè tù ẹ́ o. Ṣó o rí i, bó o bá gbàdúrà, ńṣe lò ń bẹ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń pèsè ìtùnú ni nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ó lè fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” kó o lè fara da ìrora tí ẹ̀dùn ọkàn máa ń fà. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ọlọ́run tún máa ń pèsè “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́.” (Róòmù 15:4) Torí náà, bẹ Ọlọ́run pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó o sì wá àkókò láti fi ka àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (2 Tẹsalóníkà 2:16, 17) O tiẹ̀ lè kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o rí i pé ó máa ń tù ẹ́ nínú síbì kan, kó o sì máa mú un rìn nígbà gbogbo. f

Ṣé Ẹ̀dùn Ọkàn Yẹn Máa Lọ?

Ẹ̀dùn ọkàn kì í ṣe ohun tó máa ń kúrò lọ́sàn-án kan òru kan. Brianne, tí màmá ẹ̀ kú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé: “Kò dà bí ohun kan tó o lè ‘pinnu láti fòpin sí.’ Àwọn ọjọ́ míì wà tí mo máa ń sunkún títí tí oorun á fi gbé mi lọ. Láwọn ìgbà míì, mo máa ń gbé ikú Mọ́mì kúrò lọ́kàn, màá sì máa ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe, èyí tá jẹ́ kémi àti Mọ́mì gbádùn ara wa nínú Párádísè.”

Nínú Párádísè tí Brianne ń sọ yìí, Bíbélì mú kó dá wa lójú pé, “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Ìwọ pẹ̀lú lè rí i pé bó o bá ń ṣàṣàrò lórí irú àwọn ìlérí yìí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ikú dádì tàbí mọ́mì rẹ.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

b Bí kò bá tíì rọrùn fún ẹ láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, o lè dáhùn wọn bó bá yá.

c Má ṣe rò pé dandan ni kó o sunkún kó o tó lè fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn. Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà fi ẹ̀dùn ọkàn hàn yàtọ̀ síra. Ohun kan tó dájú ni pé: “Bí ẹkún bá ń gbọ̀n ẹ́, kó o mọ̀ pé “ìgbà sísunkún” tó nìyẹn.—Oníwàásù 3:4.

d Bí irú èrò yẹn ò bá yé dà ẹ́ láàmú, sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún òbí ẹ tó ṣì wà láàyè tàbí àgbàlagbà mìíràn. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, o ò ní máa dára ẹ lẹ́bi mọ́.

e Bó bá jẹ́ pé òbí kan ṣoṣo ló tọ́ ẹ dàgbà tàbí tó bá jẹ́ pé torí bí ipò nǹkan ṣe rí, ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n lo máa ń fojú kan òbí ẹ tó wà láàyè, o lè fọ̀rọ̀ lọ àgbàlagbà míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀.

f Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ gan-an rèé: Sáàmù 34:18; 102:17; 147:3; Aísáyà 25:8; Jòhánù 5:28, 29.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Èwo lo máa lò lára àwọn àbá inú àpilẹ̀kọ yìí? ․․․․․

◼ Bó bá di pé ẹ̀dùn ọkàn ń pọ̀ jù, kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan tó máa tù ẹ́ nínú síbí. ․․․․․

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

KÒ BURÚ LÁTI SUNKÚN . . . ÀWỌN NÁÀ SUNKÚN!

Ábúráhámù—Jẹ́nẹ́sísì 23:2.

Jósẹ́fù—Jẹ́nẹ́sísì 50:1.

Dáfídì—2 Sámúẹ́lì 1:11, 12; 18:33.

Màríà, arábìnrin Lásárù —Jòhánù 11:32, 33.

Jésù—Jòhánù 11:35.

Màríà Magidalénì—Jòhánù 20:11.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

NÍ ÀKỌSÍLẸ̀

Bó o bá ń kọ ohun tó ò ń rò nípa dádì tàbí mọ́mì rẹ tó kú sílẹ̀, wàá lè fara da ẹ̀dùn ọkàn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó o lè kọ nípa Mọ́mì tàbí Dádì. Àwọn àbá díẹ̀ rèé.

◼ Kọ díẹ̀ sílẹ̀ lára àwọn nǹkan tó jẹ́ mánigbàgbé nípa dádì tàbí mọ́mì rẹ.

◼ Kọ ohun tí wàá fẹ́ láti bá dádì tàbí mọ́mì rẹ sọ ká ní wọ́n ṣì wà láàyè.

◼ Ronú pé o ní àbúrò kan tó ṣì ń dára rẹ̀ lẹ́bi nítorí ikú dádì tàbí mọ́mì yín. Ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wàá sọ láti tù ú nínú. Èyí lè mú kó o ní èrò tó tọ́ nípa bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ìwọ alára.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

ÒBÍ ALÁṢẸ̀YÌNDÈ, Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O

Ikú ọkọ tàbí aya ẹni máa ń dunni gan-an. Síbẹ̀, lákòókò tó ṣẹlẹ̀ sí yìí, ọmọ ẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ lójú méjèèjì. Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kó má ṣe banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ, kí ìwọ náà sì gbọ́ tara ẹ?

Má fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ pa mọ́. Ọ̀dọ̀ rẹ lọmọ ẹ ti kọ́ ọ̀pọ̀ lára ohun ṣíṣeyebíye tó mọ̀. Ọ̀dọ̀ rẹ náà ló ti máa kọ́ bó ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn. Torí náà, má ṣe rò pé o gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ pa mọ́ kó o tó lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́. Ńṣe ló máa jẹ́ kí òun náà máa díbọ́n. Àmọ́, bó o bá fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn, ìyẹn á jẹ́ kó mọ̀ pé ó sàn kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀ ju kó máa pa á mọ́ra lọ, àti pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn banú jẹ́, kí nǹkan tojú súni, tàbí kéèyàn bínú pàápàá.

Gba ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà níyànjú láti sọ tinú ẹ̀ jáde. Láìfi ipá mú ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, gbà á níyànjú láti bá ẹ jíròrò ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Bó bá dà bíi pé ó ń lọ́ tìkọ̀, ẹ ò ṣe jọ jíròrò àpilẹ̀kọ yìí? Kẹ́ ẹ tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ń wù yín nípa olóògbé náà. Jẹ́ kó mọ bí nǹkan á ṣe máa ṣòro fún ẹ tó ní báyìí tí ẹrù ẹ̀yin méjì ti di ti ìwọ nìkan. Bó bá rí i pé ò ń sọ tinú ẹ jáde, òun náà á mọ̀ pé kò burú bóun náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Mọ ibi tágbára rẹ mọ. Òótọ́ ni pé o kò ní fẹ́ láti já ọmọ ẹ kulẹ̀ lákòókò ìṣòro yìí. Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé ikú ọkọ tàbí aya rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣì ń dun ìwọ náà. Torí náà, ó ṣì lè máa bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, kó má rọrùn fún ẹ láti ronú ohun tó yẹ láti ṣe, kí ara ẹ má sì yá gágá. (Òwe 24:10) Torí náà, o lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó dàgbà nínú ìdílé yín tàbí sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn míì. Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”

Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó lè fún ẹ ní ìtìlẹ́yìn tó dára jù lọ, torí ó ṣèlérí fáwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísáyà 41:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ẹ̀dùn ọkàn lè dà bí ìgbà tí omi bá ń ṣàdédé ru gùdù