Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àwọn Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Rí Ìrànlọ́wọ́

Bí Àwọn Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Rí Ìrànlọ́wọ́

Bí Àwọn Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Rí Ìrànlọ́wọ́

Bí gbogbo nǹkan bá rí bó ṣe yẹ kó rí, ńṣe ni gbogbo òbí á máa fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́sọ́nà àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, wọ́n á sì máa fìfẹ́ ṣe é. Wọ́n á máa bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n á máa kàwé sí wọn létí, wọ́n á máa bá wọn jẹun, wọ́n á sì máa gbọ́ wọn yé. Àmọ́, kò sí òbí tó jẹ́ ẹni pípé. Bí Bíbélì se sọ gan-an ló rí, ó ní: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23.

Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ilé ò dùn mọ́ ẹ tó, ó sì lè jẹ́ pé bó ṣe rí nìyẹn lóòótọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó o lè ṣe kó o bàa lè dín àníyàn rẹ kù kí ayọ̀ rẹ sì pọ̀ sí i. Kíyè sí díẹ̀ lára ọ̀nà tí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Àbá Àkọ́kọ́

Wá Ẹni Bá Kẹ́gbẹ́ Dípò Kó O Máa Dá Wà

“Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Ara máa ń ti àwọn ọ̀dọ́ kan bí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn, torí náà ó máa ń tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n máa wo tẹlifíṣọ̀n tàbí kí wọ́n máa ṣeré orí kọ̀ǹpútà. Àwọn míì máa ń tijú gan-an, wọn kì í sì í fẹ́ yọjú síbi táwọn èèyàn bá wà rárá. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Elizabeth sọ pé ‘kò sígbà kan tóun kì í tijú.’ Ó sọ pé: “Ìtìjú ti di ìbẹ̀rù sí mi lára. Ó máa ń ṣòro fún mi láti tọ àwọn èèyàn lọ kí n sì bá wọn sọ̀rọ̀.”

Kí ló ran Elizabeth lọ́wọ́ láti borí ìtìjú rẹ̀? Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Elizabeth, ó sì máa ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọsìn rẹ̀. Elizabeth sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń tijú, mo fi ṣe àfojúsùn mi pé bí mo bá lọ sípàdé, màá bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Mi kì í rẹ̀wẹ̀sì lọ́jọ́ tí mi ò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àṣeyọrí mi ni mo máa ń gbájú mọ́. Mo ti jàǹfààní tó pọ̀ nínú mímọ àwọn ẹlòmíì.”

O ò ṣe kọ orúkọ èèyàn méjì tàbí mẹ́ta tó o máa fẹ́ láti mọ̀ dunjú? Fi ṣe àfojúsùn rẹ pé bó bá fi máa di ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ wàá mọ ohun tuntun nípa ọ̀kan lára wọn. Lẹ́yìn náà, ṣe àkọsílẹ̀ ohun dídára kan tó o lè ṣe fún olúkúlùkù wọn lóṣù tó ń bọ̀, kó o sì rí i pé o ṣe nǹkan náà.—Ìṣe 20:35.

Bí o kò bá wá nǹkan ṣe sáwọn ìṣòro rẹ, tó o sì ń sá fáwọn èèyàn, ó dájú pé ọ̀ràn ara rẹ á máa sú ẹ ju bó ṣe yẹ lọ. Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká má ṣe “máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [wa] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Bó o bá fàwọn ìlànà wọ̀nyẹn sílò nínú àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìdílé yín àtàwọn míì tó yí ẹ ká, wàá lè máa fi ojú tó tọ́ wo àwọn ìṣòro rẹ̀, á sì túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti yanjú àwọn ìṣòro náà.

Àbá Kejì

Sá fún Ìṣekúṣe

“Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí ènìyàn lè dá wà lóde ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Kí lo lè ṣe tí wọn ò fi ní máa fi ìbálòpọ̀ lọ̀ ẹ́, nígbà tó jẹ́ pé ohun tó gbilẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ tó kù nìyẹn?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kó o ronú dáadáa lórí ọ̀rọ̀ náà kí wọ́n tó fi lọ̀ ẹ́ tàbí kó tó di ìdẹwò fún ẹ. Òwe ọlọgbọ́n kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Mbali, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa, sọ pé: “Ọ̀dọ́mọkùnrin kan wà nínú kíláàsì mi nílé ìwé gíga, tó máa ń sọ fún mi ṣáá pé kí n jẹ́ ká jọ máa fẹ́ra. Àwọn ọmọbìnrin tó wà nínú kíláàsì ń sọ fún mi pé kí n gbà fún un torí pé ó wà pa, wọ́n máa ń fi àwòrán ẹ̀ polówó ọjà, ó sì tún ń gbá bọ́ọ̀lù fún iléèwé wa. Mo mọ̀ pé ó rẹwà lóòótọ́, àmọ́ mo ti pinnu pé mi ò ní fi ìlànà Bíbélì tí mò ń tẹ̀ lé báni dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ojúgbà mi rò pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn bá ẹni tó bá wù ú sùn. Àmọ́, mo mọ̀ pé ohun tí ò dáa ò dáa, mo sì ti pinnu ohun tí máa ṣe tipẹ́tipẹ́ kírú ọ̀rọ̀ yìí tó wáyé.”

Ohun kejì ni pé kó o gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀. Maggie, ọ̀dọ́ kan tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Àdúrà ló máa ń fún mi lókun láti kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ lọ̀ mí. Mi ò fìgbà kan rò pé agbára mi gbé e láti dá bójú tó ọ̀ràn náà. Mo máa ń fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn òbí mi létí, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi tó mọ ohun tó tọ́ tún máa ń jíròrò ìṣòro náà nígbà míì.”

Àbá Kẹta

Máa Ro Tàwọn Òbí Rẹ

“Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” (1 Pétérù 3:8) Bí àwọn òbí ẹ bá yàn láti pínyà tàbí kọra wọn sílẹ̀, tàbí kẹ̀ kí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kò sí ohun tó o lè ṣe sí i. Àmọ́, ọwọ́ ẹ ló wà bóyá wàá jẹ́ kí ìṣòro tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fà ba àjọṣe tó o ní pẹ̀lú àwọn òbí ẹ jẹ́. Ọ̀nà kan tó o lè gbà dín àníyàn kù kó o sì mú kí ayọ̀ ẹ pọ̀ sí i ni pé kó o má ṣe dájú àwọn òbí ẹ, kó o sì gbìyànjú láti lóye àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra.

Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Amber ti fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Ó sọ pé nígbà míì àjọṣe àárín òun àti màmá òun máa ń yọrí sí àníyàn ọkàn, àìgbọ́ra-ẹni-yé àti ìjákulẹ̀. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni màmá mi ti fara dà sẹ́yìn. Òun nìkan ló dá tọ́ àwa ọmọ mẹ́rin. Òun ló ń sanwó ilé tá à ń gbé, tó ń wá jíjẹ mímu, tó sì ń dáṣọ sí wa lọ́rùn. Obìnrin bí ọkùnrin ni màmá mi, èmi náà sì múra tán láti ṣe bíi tiẹ̀ bí mo bá dojú kọ ìṣòro.”

Bó o bá ń sapá láti fira ẹ sípò àwọn òbí ẹ tó o sì ń sapá láti mọ bọ́ràn ṣe rí lára wọn, ìyẹn á jẹ́ kó o lè máa fojú tó yẹ wo ìṣòro ẹ. Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o mọ àwọn ànímọ́ rere táwọn òbí ẹ ní, wàá sì lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.

Ibi Tó O Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé

Àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ ká rí díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bó o bá sì ṣe ń mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni wàá máa mọrírì bí ìmọ̀ràn rẹ̀ tó ṣeé gbára lé ti ṣeyebíye tó. a

Ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì ni pé kó o máa pé jọ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o sì jẹ́ kí wọ́n máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín wọn lo ti máa rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí wọn kò ní dá ẹ dá ìṣòro ẹ, tí wọ́n sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò nígbèésí ayé ẹ. Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà inú Bíbélì. Àmọ́, bó o bá yàn láti jẹ́ kí ìlànà inú Bíbélì máa ṣamọ̀nà rẹ, títí ayé ni wàá máa jàǹfààní rẹ̀.—Aísáyà 48:17, 18.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wàá rí àwọn ìmọ̀ràn wíwúlò tá a gbé karí Bíbélì, nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra nínu ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. A tún ń gbé àwọn ìmọ̀ràn wíwúlò bí èyí jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wo ìkànnì wa, ìyẹn www.watchtower.org/ype.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ohun Tó Yẹ Káwọn Òbí Ṣe Fáwọn Ọ̀dọ́

Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tiwọn: Ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] òbí ni Jèhófà Ọlọ́run sọ fún nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo ‘tí wọ́n bá jókòó nínú ilé wọn àti nígbà tí wọ́n bá ń rìn ní ojú ọ̀nà.’ (Diutarónómì 6:6, 7) Èyí gba pé káwọn òbí máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù wá àkókò láti bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀ torí ó mọ̀ pé ó yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí “àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè fọwọ́ kàn wọ́n,” kí ló ṣe? “Ó . . . gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.” (Máàkù 10:13, 16) Àpẹẹrẹ rere mà lèyí jẹ́ fáwọn òbí o!

Ẹ Máa Bá Wọn Sòótọ́ Ọ̀rọ̀ ní Fàlàlà: Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Ó pọn dandan kí àwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ ìfinúkonú nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Àmọ́, ìgbà tó ṣe pàtàkì jù lọ ni àkókò tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, tí wọ́n sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọmọléèwé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn, tí wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé. Bí kò bá sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, táwọn òbí kì í bá àwọn ọmọ sòótọ́ ọ̀rọ̀ ní fàlàlà, àwọn ọmọ lè dà bí àjèjì nínú ilé.

Ìbáwí Yíyẹ: Ìbáwí túmọ̀ sí títọ́ni sọ́nà àti fífúnni ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè la ìfìyàjẹni lọ nígbà míì. Ìwé Òwe 15:5 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ òmùgọ̀ ń ṣàìbọ̀wọ̀ fún ìbáwí baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń ka ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sí jẹ́ afọgbọ́nhùwà.” Kò sí báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè ka “ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sí” bí wọn ò bá rí irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ gbà. Àmọ́ ṣá o, àwọn òbí ò gbọ́dọ̀ ki àṣejù bọ̀ ọ́ bí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wí. Wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ líle mú àwọn ọmọ débi tí wọ́n á fi kó ìdààmú bá wọn, bóyá kí wọ́n wá sọ wọ́n dẹni tí kò mọ̀ ọ́n ṣe. (Kólósè 3:21) Síbẹ̀, àwọn òbí ò gbọ́dọ̀ gbọ̀jẹ̀gẹ́ débi tí wọ́n á fi kùnà láti fún àwọn ọmọ ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe pàtàkì. Ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ máa ṣàkóbá fún wọn. b

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí kókó yìí, wo orí 5 àti 6 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.