Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aṣọ Wo Ló Yẹ Kí N Wọ̀?

Aṣọ Wo Ló Yẹ Kí N Wọ̀?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Aṣọ Wo Ló Yẹ Kí N Wọ̀?

Ó ya àwọn òbí Heather lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí irú aṣọ ti ọmọ wọn fẹ́ wọ̀ jáde.

Dádì rẹ̀ bá kígbe mọ́ ọn pé: “Ṣé aṣọ tó o fẹ́ wọ jáde nìyí?”

Ó ya Heather lẹ́nu, ó wá fèsì pé: “Kí ló ṣe é? Ọjà ṣáà lèmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi ń lọ.”

Mọ́mì ẹ̀ wá sọ fún un pé: “Aṣọ tó wà lọ́rùn ẹ yẹn kọ́ ló máa wọ lọ ṣáá o!”

Heather wá sọ pé: “Aṣọ tó lòde nìyí, gbogbo ọ̀dọ́ ló ń wọ̀ ọ́, . . . àti pé, ó lóhun tó ń sọ!”

Dádì ẹ̀ dá a lóhùn pé: “Ohun yòówù kó máa sọ, kò tẹ́ wa lọ́rùn! Yáa lọ sókè kó o lọ wá aṣọ gidi wọ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ o ò lọ síbì kankan!”

ỌJỌ́ pẹ́ tí aṣọ wíwọ̀ ti máa ń dá ìṣòro sílẹ̀. Àwọn òbí rẹ náà ti lè ní irú ìṣòro kan náà pẹ̀lú àwọn òbí wọn nígbà ti wọ́n ṣì kéré bíi tìẹ. Ó sì lè jẹ́ pé bọ́ràn náà ṣe rí lára rẹ, náà ló ṣe rí lára wọn nígbà yẹn! Àmọ́ ní báyìí àwọn náà ti di òbí, ọ̀ràn irú aṣọ tó yẹ kó o wọ̀ sì ti wá ń dá wàhálà sílẹ̀ léraléra.

O sọ pé: Kò ni mí lára.

Wọ́n sọ pé: Ó ti ṣe gbàgẹ̀rẹ̀ jù.

O sọ pé: Ó wà pa gan-an!

Wọ́n sọ pé: Ó fi ara sílẹ̀, ó sì fún pinpin.

O sọ pé: Kò wọ́nwó rárá.

Wọ́n sọ pé: Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn. . . . Ṣé ìwọ̀ ò mọ̀ pé ìdajì aṣọ lo rà ni!

Ṣé nǹkan kan wà tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà? Bẹ́ẹ̀ ni! Megan, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] báyìí, mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ó sọ pé: “Kò sídìí tí wàá fi máa báwọn òbí rẹ jiyàn. Ẹ lè jọ fohùn ṣọ̀kan nípa irú aṣọ tó yẹ kó o wọ̀.” Kẹ́ ẹ fohùn ṣọ̀kan kẹ̀? Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé kó o máa múra bí arúgbó. Fọkàn ẹ balẹ̀! Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kíwọ àtàwọn òbí ẹ jọ fẹnu kò nípa irú aṣọ míì tó o lè wọ̀ tí ìwọ àti àwọn máa fara mọ́. Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀?

1. Ìmúra rẹ á dáa gan-an, wàá sì gbayì lójú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

2. Àwọn òbí ẹ ò ní máa fi bẹ́ẹ̀ rí sí aṣọ tó o bá wọ̀.

3. Bí àwọn òbí rẹ bá ti kíyè sí pé o ti lè dá pinnu aṣọ tó bójú mu, wọ́n á yọ̀ǹda fún ẹ́ láti máa ṣe àwọn nǹkan míì.

Jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ báyìí. Ronú nípa aṣọ “tó jojú ní gbèsè” tó o rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ní ṣọ́ọ̀bù kan. Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o . . .

Gbé Àwọn Ìlànà Bíbélì Yẹ̀ Wò

Ó lè yani lẹ́nu pé Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa aṣọ wíwọ̀. Kódà, o lè ka gbogbo ìtọ́ni tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa aṣọ wíwọ́ láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan! Síbẹ̀, láàárín àkókò yẹn, wàá ti rí ìtọ́ni tó wúlò tó o lè tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ:

◼ Bíbélì fún àwọn obìnrin nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ “pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” a1 Tímótì 2:9, 10.

Ọ̀rọ̀ náà “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà” lè má fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. O lè máa ronú pé: ‘Ṣé kí n kúkú kó sínú àpò kí ẹnikẹ́ni má bàa rí ara mi?’ Rárá o! Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn ohun tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà túmọ̀ sí ni pé, kí aṣọ tó o wọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn fọ̀wọ̀ ẹ wọ̀ ẹ́, kó sì fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn ẹlòmíì. (2 Kọ́ríńtì 6:3) Ọ̀pọ̀ aṣọ ló bá ohun tá à ń sọ yìí mu. Danielle ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún sọ pé: “Ó lè ṣòro lóòótọ́, àmọ́ o múra lọ́nà tó wuni láì wọ aṣọ tó fi ara sílẹ̀ tàbí èyí tó fún pinpin.”

◼ Bíbélì sọ nípa ìmúra pé, “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” ló yẹ ká fún láfiyèsí tá a bá ń múra.—1 Pétérù 3:4.

Lóòótọ́, bó o bá wọ aṣọ tó fara sílẹ̀ tàbí èyí tó fún pinpin, àwọn kan lè gba tìẹ, àmọ́ irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló máa jẹ́ káwọn àgbà àtàwọn ojúgbà ẹ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Àwọn ojúgbà ẹ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn pẹ̀lú lè rí i pé wíwọ aṣọ tó fara sílẹ̀ tàbí èyí tó fún pinpin kò ṣeni láǹfààní kankan. Brittany tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: Ó kóni nírìíra láti rí báwọn obìnrin ṣe máa ń tara wọn lọ́pọ̀ fáwọn ọkùnrin nípa irú aṣọ tí wọ́n bá wọ̀!” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kay náà gbà pẹ̀lú Brittany. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà kan, ó ní: “Aṣọ tí kò ní jẹ́ káwọn ọkùnrin lè gbójú kúrò lára ẹ̀ ló máa ń wọ̀ nígbà gbogbo. Torí ó fẹ́ káwọn ọkùnrin máa wo òun ṣáá, aṣọ tó jojú ní gbèsè jù lọ ló máa ń wọ̀.”

Irú Aṣọ Tó Yẹ Kó O Yàn: Yẹra fún aṣọ tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe. Wọ́n máa jẹ́ kó dà bíi pé ò ń wá ọkùnrin lójú méjèèjì àti pé tara ẹ nìkan lo mọ̀. Irú aṣọ bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè jẹ́ káwọn ọkùnrin máa fi ìbálòpọ̀ fìtínà ẹ tàbí kí wọ́n ṣe ohun tó burú jùyẹn lọ. Àmọ́, aṣọ tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì á jẹ́ kí ìmúra rẹ wuyì, ó sì máa fi àwọn ànímọ́ tó dáa tó o ní hàn.

Jẹ́ Káwọn Òbí Rẹ Tọ́ Ẹ Sọ́nà

dára kó o máa fi aṣọ tí kò bójú mu sínú àpò ilé ìwé rẹ, kó o wá wọ̀ ọ́ níléèwé. Àwọn òbí rẹ á túbọ̀ fọkàn tán ẹ bí o kò bá fọ̀rọ̀ pa mọ́ tó o sì ń sọ òótọ́ fún wọn, tó fi mọ́ àwọn ọ̀ràn tó o rò pé wọn ò lè mọ̀. Ohun tó dáa jù ni pé tó o bá fẹ́ ra aṣọ, kọ́kọ́ mọ èrò wọn nípa rẹ̀ kó o tó rà á.—Òwe 15:22.

Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n mọ̀ sí i? Ṣé kì í ṣe pé àwọn òbí rẹ kò ní jẹ́ kó o wọ aṣọ tó wù ẹ́ báyìí? Bóyá ni. Lóòótọ́, èrò ti Dádì àti Mọ́mì lè yàtọ̀ sí tìẹ. Àmọ́, ohun tó o nílò gan-an nìyẹn nígbà míì. Nataleine tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Mo mọrírì ìmọ̀ràn àwọn òbí mi, torí mí ò fẹ́ káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tó máa tì mí lójú tàbí kí wọ́n torí aṣọ tí mo wọ̀ máa sọ̀rọ̀ sí mi.”

Bọ́ràn ṣe rí gan-an ni pé: Títí tó o fi máa kúrò nílé, abẹ́ àṣẹ àwọn òbí rẹ lo ṣì wà. (Kólósè 3:20) Síbẹ̀, tó o bá ti lóye ohun tí wọ́n ń fẹ́, táwọn náà sì mọ ohun tí ò ń fẹ́, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu pé lọ́pọ̀ ìgbà ẹ ò ní máa jiyàn. Èyí sì lè yanjú ìṣòro tẹ́ ẹ ní lórí irú aṣọ tó yẹ kó o máa wọ̀!

Irú Aṣọ Tó Yẹ Kó O Yàn: Bó o bá ń yẹ aṣọ kan wò, ohun tó o rí nínú jígí lè ṣàì tó láti pinnu bóyá aṣọ náà dáa tó. Aṣọ tó dà bíi pé ó wà létòlétò lè má dáa mọ́ tó o bá jókòó tàbí tó o bẹ̀rẹ̀ láti mú nǹkan. O lè ní kí òbí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tí òótọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ sọ ohun tó rò nípa aṣọ náà.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ni Bíbélì darí ìtọ́ni yìí sí, ó kan àwọn ọkùnrin náà. Wo àpótí náà  “Àwọn Ọkùnrin Ńkọ́?”

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Ronú nípa irú aṣọ tó o máa fẹ́ rà. Kó o wá bi ara rẹ pé:

◼ Irú èèyàn wo ni aṣọ yìí “ń sọ” fáwọn èèyàn pé mo jẹ́?

◼ Irú èrò wo ló máa mú káwọn èèyàn ní nípa mi?

◼ Ṣé èrò tí mo fẹ́ kí wọ́n ní nípa mi nìyẹn, ṣé mo sì ṣe tán láti fara mọ́ ohun tó bá tìdí rẹ̀ yọ?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bó o ṣe lè yan aṣọ tó tọ́

Ìtọ́ni: Ṣe ẹ̀dà ojú ìwé yìí. Ní káwọn òbí ẹ kọ ọ̀rọ̀ kún àlàfo tó wà lápá ọ̀tún, kí ìwọ sì kọ ọ̀rọ̀ kún àlàfo tó wà lápá òsì. Lẹ́yìn náà, gba èyí táwọn òbí ẹ kọ, kó o sì fún wọn ní èyí tí ìwọ náà kọ, kẹ́ ẹ wá jọ jíròrò àwọn ìdáhùn yín. Ǹjẹ́ o rí ohun tó yà ẹ́ lẹ́nu nínú àwọn ìdáhùn náà? Àwọn nǹkan wo tẹ́ ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa ojú tí ọ̀kọ̀ọ̀kan yín fi ń wo nǹkan lẹ́ ti wá mọ̀ báyìí?

KỌ Ọ̀RỌ̀ SÍ ÀLÀFO YÌÍ KÍ ÒBÍ KỌ Ọ̀RỌ̀ SÍ ÀLÀFO YÌÍ

Ronú nípa aṣọ kan tó o fẹ́ wọ̀ ronú nípa aṣọ kan tí ọmọ yín tó

tàbí tó o fẹ́ rà. ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà fẹ́ wọ̀ tàbí tó fẹ́ rà.

◼ Kí nìdí tó o fi fẹ́ràn irú aṣọ ◼Kí lẹ rò pé ó mú kí ọmọ yín

yìí? Kọ nọ́ńbà síwájú àwọn ohun tó fẹ́ràn aṣọ yìí? Ẹ kọ nọ́ńbà síwájú

wà nísàlẹ̀ yìí bí wọ́n ti ṣe àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí níbàámu

pàtàkì sí ẹ tó. pẹ̀lú bẹ́ ẹ ṣe ronú pé wọ́n ṣe

pàtàkì sí ọmọ yín jù lọ.

․․․․․ Ilé iṣẹ́ tó ṣe é Ilé iṣẹ́ tó ṣe é

․․․․․ Bó ṣe máa fa obìnrin tàbí ․․․․․ Bó ṣe máa fa obìnrin tàbí

ọkùnrin mọ́ra tó ọkùnrin mọ́ra tó

․․․․․ Báwọn ọ̀rẹ́ mi á ṣe gba tiẹ̀ ․․․․․ Báwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe máa gba ti aṣọ náà tó

․․․․․ Bó ṣe máa rí lára ․․․․․ Bó ṣe máa rí lára

․․․․․ Iye owó ẹ̀ ․․․․․ Iye owó ẹ̀

․․․․․ Nǹkan míì ․․․․․ ․․․․․ Nǹkan míì ․․․․․

◼ Ohun tó ṣeé ṣe káwọn òbí mi Ohun tí màá sọ tí mo bá rí i ni pé

sọ bí wọ́n bá rí aṣọ yìí ni pé

“O ò gbọ́dọ̀ wọ̀ ọ́!” “O ò gbọ́dọ̀ wọ̀ ọ́!”

“Mi ò lè sọ.” “Mi ò lè sọ.”

“Ó dáa.” “Ó dáa.”

◼ Ohun tó lè mú kí wọ́n má gba ◼ Ohun tó lè mú kí n má gba

ti aṣọ náà ni pé ti aṣọ náà ni pé

“Ó fi ara sílẹ̀, ó sì “Ó fi ara sílẹ̀, ó sì fún pinpin.”

fún pinpin.”

“Ó rí gbàgẹ̀rẹ̀.” “ Ó rí gbàgẹ̀rẹ̀.”

“Aṣọ táyé gba wèrè ẹ̀ ni” “ Aṣọ táyé gba wèrè ẹ̀ ni.”

“Kò pọ́n àwa òbí ẹ lé.” “ Kò pọ́n àwa òbí ẹ lé.”

“Ó ti wọ́n jù.” “Ó ti wọ́n jù.”

Nǹkan míì ․․․․․ Nǹkan míì ․․․․․

ǸJẸ́ A LÈ JỌ WÁ NǸKAN ṢE SÍ I?

◼ Kí ló mú kí ohun táwọn òbí ◼ Ṣé torí pé aṣọ yìí ò wù wá la

mi sọ ṣe pàtàkì? ò ṣe gba ti aṣọ náà?

․․․․․ Bẹ́ẹ̀ ni Ó jọ bẹ́ẹ̀ Rárá

◼ Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tí mo lè ◼ Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tá a lè ṣe

ṣe sí aṣọ yìí táá fi ṣeé wọ̀? ◼ sí aṣọ yìí táá mú kó ṣeé wọ̀?

ṢÉ KÍ N RÀ Á ÀBÍ KÍ N MÁ RÀ Á?

․․․․․ ․․․․․

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

“Kò burú láti wọṣọ tó gbayì, bí kò bá ṣáà ti ta ko ìlànà Bíbélì. Ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ò ní kọminú sí ló wà, tó o lè rà.”—Derrick.

“Nígbà tí mi ò tíì pé ọmọ ogún ọdún, mo fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wù mí. Mi ò fẹ́ kí wọ́n máa sọ irú aṣọ tó yẹ kí n wọ̀ fún mi. Àmọ́, nígbà tó yá, mo wá rí i pé èyí kì í jẹ́ káwọn èèyàn máa fọ̀wọ̀ fún mi bó ṣe yẹ. Àfi ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohun táwọn òbí mi àti àwọn tó jù mí lọ ń sọ ni nǹkan tó yí pa dà.”—Megan.

“Bí mo bá rí àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n wọ aṣọ tó ṣí ara sílẹ̀, wọn kì í níyì lójú mi. Àmọ́, bí mo bá rí ẹni tó wọ aṣọ tó bójú mu tó sì tún fani mọ́ra, mo máa ń sọ lọ́kàn mi pé: ‘Bó ṣe wù mí kí n máa rí nìyí.’”—Nataleine.

 [Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

ÀWỌN ỌKÙNRIN ŃKỌ́?

Ìlànà Bíbélì tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí kan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú. Ẹ jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Ẹ jẹ́ káwọn èèyàn lè tipasẹ̀ ìmúra yín mọ ẹni tẹ́ ẹ jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Kó o tó ra aṣọ kan, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé: ‘Kí ló máa sọ nípa irú ẹni tí mo jẹ́? Ṣé ohun tí aṣọ náà máa “sọ” nípa mi bá irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an mu?’ Rántí pé, bá a ṣe rìn là á koni. Máa wọṣọ tó máa mú káwọn èèyàn máa ní èrò tó dáa nípa rẹ!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Ronú nípa àpèjúwe tá a fí bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì wò ó pé ọmọ rẹ ni Heather. Ńṣe lo kàn rí i tó wọ aṣọ péńpé kan tó fi ara sílẹ̀. O wá sọ fún un pé, “Yáa lọ sókè kó o lọ wá aṣọ gidi wọ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ o ò lọ síbì kankan!” Ó ṣeé ṣe kí ohun tó o ṣe yẹn ran ọmọ ẹ lọ́wọ́. Ó ṣe tán, kò yẹ kí ọmọ rẹ kọ ọ̀rọ̀ sí ẹ lẹ́nu. Àmọ́, báwo lo ṣe lè kọ́ ọ láti tún èrò rẹ̀ ṣe, kì í ṣe ìmúra rẹ̀ nìkan?

◼ Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rántí pé ọmọ rẹ náà mọ ohun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ tó bá múra lọ́nà tí kò bójú mu, ó tiẹ̀ lè rí i bí ohun pàtàkì láti múra lọ́nà tó bójú mu ju bí ìwọ ṣe rò lọ. Ká sòótọ́, ọmọ rẹ to ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà náà kò ní fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú òmùgọ̀ wo òun torí bó ṣe múra, kò sì ní fẹ́ pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara rẹ̀. Ńṣe ni kó o fi sùúrù ṣàlàyé fún un pé kò túmọ̀ sí pé èèyàn fẹ́ fa ojú ẹlòmíì mọ́ra tó bá wọ aṣọ tí kò bójú mu. b Sọ aṣọ míì tó o ronú pé ó lè wọ̀.

◼ Ohun kejì ni pé, “jẹ́ kí ìfòyebánilò [rẹ] di mímọ̀.” (Fílípì 4:5) Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ aṣọ yìí ta ko ìlànà Bíbélì kan, àbí kò kàn wù mí ni?’ (2 Kọ́ríńtì 1:24) Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni aṣọ náà ò kàn wù ẹ́, ṣó o lè jẹ́ kí ọmọ rẹ wọ̀ ọ́?

◼ Má kàn máa sọ fún ọmọ rẹ pé aṣọ kan dáa. Ńṣe ni kó o bá a wá àwọn aṣọ tó bójú mu. Níkẹyìn, wàá rí i pé ìsapá tó o ṣe àti àkókò tó o lò tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ajíṣefínní ni ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà yìí, torí náà, sọra kó o máa lọ sọ ohun tó máa mú kó rò pé ìrísí òun kò dáa rárá.