Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kò Yẹsẹ̀ Lórí Ohun Tó Gbà Gbọ́

Kò Yẹsẹ̀ Lórí Ohun Tó Gbà Gbọ́

Kò Yẹsẹ̀ Lórí Ohun Tó Gbà Gbọ́

◼ Nígbà ọlidé kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ní káwọn ọmọ kíláàsì kan níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ka ìtàn nípa Kérésìmesì. Inú kíláàsì yìí ni Morgan, ọmọ ọdún méje wà, òun sì ni wọ́n yàn pé kó kà á. Ọmọbìnrin yìí sọ fún olùkọ́ rẹ̀ pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ayẹyẹ Kérésìmesì kò bá ohun tí Bíbélì fi kọ́ni mu. Olùkọ́ rẹ̀ wá ní kó ka ìtàn míì tí kò ní da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láàmù.

Nígbà tó yá, wọ́n pe ìdílé Morgan síbi ayẹyẹ kan tí wọ́n ti fẹ́ pín ẹ̀bùn fún àwọn ọmọléèwé. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún Morgan nígbà tí wọ́n fún un lẹ́bùn torí bó ṣe lo ìgboyà tí kò sì yẹsẹ̀ lórí ohun tó gbà gbọ́. Nígbà tí wọ́n bi í pé kí ló fún un ní irú ìgboyà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé òun àti ìdílé òun máa ń ka ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà pa pọ̀, àwọn sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù Kristi àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó wà nínú ìwé náà.

Ìwé olójú-ewé 256 tó kún fún àwòrán rírẹwà yìí á jẹ́ káwọn òbí lè máa ní ìjíròrò tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Lára àwọn àkòrí tó wà níbẹ̀ ni “Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́,” “Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí” àti “Ìrànlọ́wọ́ Láti Borí Ìbẹ̀rù.”

Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.