Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀tá Ẹni?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀tá Ẹni?
Jésù Kristi sọ pé: “Mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”—Mátíù 5:44, 45.
LÓJÚ tìẹ ṣé ìsìn máa ń mú kí àwọn èèyàn fìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa gbé lálàáfíà àbí ńṣe ló ń fa ìkórìíra àti ìwà ipá? Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìsìn máa ń fa ìkórìíra àti ìwà ipá, pàápàá jù lọ bí wọ́n bá ti dà á pọ̀ mọ́ ìṣèlú, ìfẹ́ ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè ẹni. Àmọ́, bí Jésù ṣe sọ, àwọn tó jẹ́ ‘ọmọ Ọlọ́run’ lóòótọ́ máa ń fi ìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run, èyí sì kan bí wọ́n ṣe ń ṣe sí àwọn ọ̀tá wọn pàápàá.
Ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì sọ pé: “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu . . . Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:20, 21) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí? Gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ó ṣeé ṣe! Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò.
Wọ́n Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Wọn
Jésù kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an, ara sì máa ń tù wọ́n láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn kan dìídì ta kò ó, àìmọ̀kan mọ̀kàn ló sì jẹ́ káwọn míì ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 7:12, 13; Ìṣe 2:36-38; 3:15, 17) Síbẹ̀, Jésù ò yé sọ ọ̀rọ̀ tó lè fúnni ní ìyè fáwọn èèyàn, títí kan àwọn alátakò rẹ̀. (Máàkù 12:13-34) Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù mọ̀ pé àwọn kan ṣì lè yí ìwà wọn pa dà, kí wọ́n wá mọ̀ pé òun ni Mèsáyà, kí wọ́n sì jẹ́ kí òtítọ́ tẹ̀mí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ wọn sọ́nà.—Jòhánù 7:1, 37-46; 17:17.
Ní alẹ́ tí àwọn ọ̀tá tó dìhámọ́ra wá mú Jésù láìtọ́, Jésù ṣe ohun tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Kódà, nígbà tí Pétérù fi idà gé etí ọ̀kan lára àwọn tó wá mú Jésù, ńṣe ni Jésù mú ọkùnrin náà lára dá. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Jésù fi ìlànà kan lélẹ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ ń tẹ̀ lé dòní olónìí. Ó sọ pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:48-52; Jòhánù 18:10, 11) Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, Pétérù kọ̀wé pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. . . . Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ [Ọlọ́run].” (1 Pétérù 2:21, 23) Ó ṣe kedere pé, Pétérù ti wá mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ kì í gbẹ̀san, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ń fi ìfẹ́ hàn.—Mátíù 5:9.
Gbogbo àwọn tó ń ‘tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí’ máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì, wọ́n sì máa ń lẹ́mìí ìṣoore. Nínú 2 Tímótì 2:24 a kà pé: “Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, . . . tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.” Ọ̀nà tí Kristẹni gbà ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ máa fi hàn pé ó ní àwọn ànímọ́ yẹn, torí á máa wá àlááfíà kò sì ní lọ́ tìkọ̀ láti yanjú aáwọ̀.
Gẹ́gẹ́ Bí ‘Ikọ̀ fún Kristi’ Wọ́n Ń Wá Àlááfíà
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀, ó ní: “Nítorí náà, àwa jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi . . . Gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’” (2 Kọ́ríńtì 5:20) Àwọn ikọ̀ kì í lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú àti ti ológun ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n rán wọn lọ ṣe ni wọ́n máa ń gbájú mọ́. Iṣẹ́ wọn ni láti ṣojú kí wọ́n sì gbẹnu sọ fún ìjọba tó rán wọn níṣẹ́.
Bọ́ràn àwọn ikọ̀ àti aṣojú ikọ̀ fún Kristi ṣe rí náà nìyẹn. Wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba, wọ́n sì ń gbẹnu sọ fún Ìjọba tó máa ṣàkóso látọ̀run nípa pípòkìkí ìhìn rere láì fipá mú ẹnikẹ́ni. (Mátíù 24:14; Jòhánù 18:36) Ìdí nìyí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí wọ́n jọ gbáyé pé: “A kò ja ogun gẹ́gẹ́ bí ohun tí a jẹ́ nínú ẹran ara. Nítorí àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n [jẹ́] alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run fún dídojú . . . àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run . . . dé.”—2 Kọ́ríńtì 10:3-5; Éfésù 6:13-20.
Àkókò tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ká ní wọ́n fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, wọn ì bá gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn àti láti sọ̀rọ̀ tó máa pẹ̀tù sí wọn nínú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopedia of Religion and War sọ pé: “Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù kọ̀ láti jagun tàbí wọṣẹ́ ológun,” torí wọ́n mọ̀ pé ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kò bá ìlànà ìfẹ́ tí Jésù fi lélẹ̀ mu bẹ́ẹ̀ sì ni ó ta ko àṣẹ tó pa pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa.” a
Bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Jésù ni Ọba àwọn. Wọ́n tún gbà pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tó máa ṣàkóso látọ̀run, tó sì máa mú àlááfíà àti ààbò tó wà pẹ́ títí wá sórí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Torí náà, gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ àti aṣojú ikọ̀, wọ́n ń kéde àwọn ọ̀nà tí Ìjọba yẹn gbà ta yọ fáyé gbọ́. Bákan náà, wọ́n tún máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè rere níbi tí wọ́n bá ń gbé, nípa sísan owó orí àti ṣíṣègbọràn sí òfin tí kò bá tako òfin Ọlọ́run.—Ìṣe 5:29; Róòmù 13:1, 7.
Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, nígbà míì wọn kì í lóye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń bà wọ́n lórúkọ jẹ́, wọ́n sì máa ń ṣe inúnibíni sí wọn. Síbẹ̀, wọn kì í gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń gbìyànjú láti jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,” wọ́n á sì ní in lọ́kàn pé àwọn alátakò kan lè “padà bá Ọlọ́run rẹ́” kí wọ́n sì máa fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun. b—Róòmù 12:18; Jòhánù 17:3.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopedia of Religion and War sọ pé: “Gbogbo àwọn tó ń kọ̀wé nípa ẹ̀sìn Kristẹni ṣáájú ìgbà Constantine [Olú ọba ilẹ̀ Róòmù láàárín 306 sí 337 Sànmánì Kristẹni], dẹ́bi fún ìpànìyàn lójú ogun. Ìgbà tí ìpẹ̀yìndà tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni ìwà àwọn èèyàn yí pa dà.—Ìṣe 20:29, 30; 1 Tímótì 4:1.
b Bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi òfin gbèjà òmìnira tí wọ́n ní láti máa sin Ọlọ́run.—Ìṣe 25:11; Fílípì 1:7.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Báwo ló ṣe yẹ káwọn Kristẹni ṣe sáwọn ọ̀tá wọn?—Mátíù 5:43-45; Róòmù 12:20, 21.
◼ Kí ni Jésù ṣe nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí i?—1 Pétérù 2:21, 23.
◼ Kí nìdí táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kì í fi í lọ́wọ́ sí ogun jíjà?—2 Kọ́ríńtì 5:20; 10:3-5.