Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Àkọ́kọ́: Fi Ohun Tó Yẹ Sípò Àkọ́kọ́

Ohun Àkọ́kọ́: Fi Ohun Tó Yẹ Sípò Àkọ́kọ́

Ohun Àkọ́kọ́: Fi Ohun Tó Yẹ Sípò Àkọ́kọ́

“Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Kí ìdílé bàa lè wà ní ìṣọ̀kan, tọkọtaya gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnì kejì wọ́n jẹ wọ́n lógún ju ara wọn, ohun ìní wọn, iṣẹ́ wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtàwọn èèyàn wọn míì lọ. Nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, ọkọ àti aya máa ń lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú ara wọn àti pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Àwọn méjèèjì máa ń múra tán láti yááfì àwọn nǹkan fún àǹfààní ìdílé wọn.—Fílípì 2:4.

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Ọwọ́ pàtàkì ni Bíbélì fi mú ọ̀ràn ìdílé. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ẹni tí kò bá pèsè fún ìdílé rẹ̀ “burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Síbẹ̀, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ohun téèyàn kà sí pàtàkì lè yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìdílé kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbi àpérò tí òun ṣe ló dà bíi pé iṣẹ́ ló jẹ wọ́n lógún ju ìdílé wọn lọ. Ó sọ pé ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń fẹ́ láti mọ “ọ̀nà àbùjá” tí wọ́n á fi lè tètè máa yọrùn kúrò nínú ìṣòro ìdílé kí wọ́n bàa lè gbàgbé nípa rẹ̀ kí wọ́n sì pa dà sídìí iṣẹ́ wọn. Kí la rí kọ́ nínú èyí? Ó rọrùn láti sọ pé ọ̀rọ̀ ìdílé ẹni jẹni lógún, àmọ́ kì í rọrùn láti fi hàn pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn.

Gbìyànjú èyí wò. Lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti ṣàgbéyẹ̀wò bí ìdílé ẹ ti ṣe pàtàkì sí ẹ tó.

Bí ọkọ, aya tàbí ọmọ mi bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ mo máa ń tètè dá a lóhùn?

Nígbà tí mo bá ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe, ṣé mo sábà máa ń sọ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìdílé mi?

Bí àkókò tí mò ń lò pẹ̀lú ìdílé mi ò bá pọ̀ tó, ṣé mo lè kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àwọn ojúṣe kan tí wọ́n bá fi lọ̀ mí (lẹ́nu iṣẹ́ tàbí níbòmíì)?

Bó o bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a jẹ́ pé ò ń fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́ nìyẹn. Àmọ́, kí ni ọkọ, aya, tàbí àwọn ọmọ rẹ máa sọ nípa rẹ? Ojú tá a fi ń wo ara wa nìkan kọ́ ló yẹ ká fi pinnu bóyá à ń fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́. Ìlànà kan náà yẹn sì ṣeé fi sílò nípa àwọn ohun mìíràn tó lè mú kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan, èyí tá a máa jíròrò láwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí.

Pinnu ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa ọ̀nà kan tàbí méjì tó o lè gbà fi hàn pé ìdílé rẹ lo fi sípò àkọ́kọ́. (Bí àpẹẹrẹ: Ronú nípa bó o ṣe lè dín àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó máa gba àkókò tó yẹ kó o lò pẹ̀lú ọkọ, aya, tàbí àwọn ọmọ rẹ kù.)

O ò ṣe jíròrò ibi tó o bá parí èrò sí pẹ̀lú ìdílé rẹ? Nígbà tí ẹnì kan nínú ìdílé bá múra tán láti ṣe àwọn ìyípadà, ó ṣeé ṣe káwọn yòókù náà fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Tọkọtaya tó bá fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ara wọn àti tàwọn ọmọ wọn, máa ń ṣàṣeyọrí