Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Kẹfà: Ìdáríjì

Ohun Kẹfà: Ìdáríjì

Ohun Kẹfà: Ìdáríjì

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.”—Kólósè 3:13.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Àwọn ìdílé tó wà níṣọ̀kan máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn kọjá; àmọ́ wọn kì í gbé aáwọ̀ tó ti kọjá sọ́kàn kí wọ́n sì wá lò ó láti máa ṣàròyé pé, “Gbogbo ìgbà lo máa ń pẹ́” tàbí “O kì í fetí sílẹ̀.” Ọkọ àti aya gbà pé “ẹwà ni ó . . . jẹ́ . . . láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”—Òwe 19:11.

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Ọlọ́run “ṣe tán láti dárí jini,” àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa ẹ̀dá ò rí bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 86:5) Bí tọkọtaya ò bá sì yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀, ó lè mú kí ẹ̀dùn ọkàn wọn pọ̀ débi pé wọn ò ní lè dárí ji ara wọn. Á wá di pé kí ọkọ àti aya máa bára wọn yan odì, kí wọ́n má sì ri ti ẹnì kejì wọn rò mọ́. Bí eré bí eré, ìfẹ́ ò ní ríbi gbé mọ́ nínú ìgbéyàwó wọn.

Gbìyànjú èyí wò. Wo fọ́tò tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ yà nígbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tàbí nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Gbìyànjú láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, kó tó di pé ìjà tó wáyé yí ojú tẹ́ ẹ fi ń wo ara yín pa dà. Lẹ́yìn náà, kó o wá ronú lórí àwọn ànímọ́ tó mú kó o fẹ́ràn ọkọ tàbí aya rẹ nígbà yẹn.

Ní báyìí, àwọn ànímọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ ní wo ló fà ẹ́ mọ́ra jù lọ?

Ronú nípa àwọn àbájáde rere tó lè tìdí ẹ̀ wá fáwọn ọmọ rẹ bó o bá túbọ̀ ń dárí jini.

Pinnu ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa ọ̀nà kan tàbí méjì tó ò fi ní máa fi èdè àìyedè tó ti wáyé láàárín yín nígbà kan hùwà bí èdè àìyedè míì bá wáyé láàárín ìwọ àti ẹni kejì rẹ nínú ìgbéyàwó.

O ò ṣe yin ọkọ tàbí aya rẹ nítorí àwọn ànímọ́ tó ń dá ẹ lọ́rùn lára rẹ̀?—Òwe 31:28, 29.

Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà díẹ̀ tó o lè gbà máa dárí ji àwọn ọmọ rẹ.

O ò ṣe bá àwọn ọmọ rẹ jíròrò nípa ìdáríjì àti àǹfààní tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé máa jẹ bí gbogbo yín bá ń dárí ji ara yín?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Bó o bá dárí ji ẹnì kan, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o wọ́gi lé gbèsè tí onítọ̀hún jẹ, o ò ní retí pé kó san gbèsè náà mọ́