Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Kẹta: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

Ohun Kẹta: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

Ohun Kẹta: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

“Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . Bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”—Oníwàásù 4:9, 10.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Àwọn tọkọtaya tí ìdílé wọn wà ní ìṣọ̀kan máa ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí tí Ọlọ́run là kalẹ̀ nínú Bíbélì. (Éfésù 5:22-24) Síbẹ̀, wọn kì í fi ojú “tèmi” wo ìgbéyàwó wọn, ṣe ni wọ́n máa ń wò ó bíi “tiwa.” Bí tọkọtaya bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọn ò ní máa ṣe nǹkan bí ìgbà tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó. Wọ́n ti di “ara kan” èyí tó túmọ̀ sí pé wọn ò gbọ́dọ̀ yara wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣera wọn lọ́kan.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kò bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan lè yára di ìṣòro ńlá débi tí ẹ̀yin méjèèjì á fi máa bára yín jà dípò tẹ́ ó fi yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀. Àmọ́, bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ńṣe lẹ máa dà bí awakọ̀ òfuurufú àti ìgbá kejì rẹ̀ tí èrò wọn jọra, ẹ ò sì ní dà bí àwọn awakọ̀ òfuurufú méjì tí wọ́n ń forí gbárí. Bí èdè yín ò bá yéra, ẹ yanjú rẹ̀ ní ìtùnbí ìnùbí dípò tí ẹ ó fi máa fàkókò ṣòfò níbi tẹ́ ẹ ti ń tahùn síra yín tẹ́ ẹ̀ sì ń dára yín lẹ́bi.

Gbìyànjú èyí wò. Lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti ṣàgbéyẹ̀wò bẹ́ ẹ ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tó.

Ǹjẹ́ mo máa ń wò ó bíi pé “tèmi ni” gbogbo owó tó ń wọlé fún mi, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èmi ni mò ń ṣiṣẹ́ fún un?

Ṣé mo jìnnà sáwọn ìbátan ọkọ tàbí aya mi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ tàbí aya mi sún mọ́ wọn?

Ṣé ìgbà tí ọkọ tàbí aya mi ò bá sí lọ́dọ̀ mi lára máa ń tù mí jù lọ?

Pinnu ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa ọ̀nà kan tàbí méjì tó o lè gbà fi hàn pé òótọ́ lò ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ.

O ò ṣe ní kí ọkọ tàbí aya rẹ mú àbá kan wá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ túmọ̀ sí pé ẹ̀yin méjèèjì dà bí awakọ̀ òfuurufú àti igbá kejì rẹ̀ tí èrò wọn jọra