Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Kejì: Pa Àdéhùn Ìgbéyàwó Mọ́

Ohun Kejì: Pa Àdéhùn Ìgbéyàwó Mọ́

Ohun Kejì: Pa Àdéhùn Ìgbéyàwó Mọ́

“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Àwọn tọkọtaya tó wà ní ìṣọ̀kan máa ń wo ìgbéyàwó wọn gẹ́gẹ́ bí àjọṣe tó máa wà pẹ́ títí. Bí ìṣòro bá dé, wọ́n máa ń sapá láti yanjú rẹ̀ dípò kí wọ́n torí rẹ̀ fòpin sí ìgbéyàwó wọn. Bí tọkọtaya bá fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn ìgbéyàwó, mìmì kan ò ní mi ìgbéyàwó wọn. Ọkàn àwọn méjèèjì á balẹ̀ pé èyíkéyìí nínú àwọn kò ní jin ìgbéyàwó náà lẹ́sẹ̀.

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, pípa àdéhùn ìgbéyàwó mọ́ ni ohun tó lè mú kí ìgbéyàwó tọ́jọ́. Síbẹ̀, bí èdèkòyédè bá ń fìgbà gbogbo wáyé láàárín tọkọtaya, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n ń fi tipátipá pa àdéhùn ìgbéyàwó wọn mọ́. Bọ́rọ̀ bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, àdéhùn tí wọ́n ṣe pé, “títí ikú yóò fi yà wá,” á wá dà bí èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́, wọ́n á sì máa wá bí wọ́n ṣe lè fòpin sí àdéhùn náà. Wọ́n lè máà kó kúrò lọ́dọ̀ ara wọn, àmọ́ ọkàn àwọn méjèèjì á ti ‘ṣí kúrò lára ara wọn.’ Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa yan ara wọn lódì dípò kí wọ́n jọ jíròrò àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó.

Gbìyànjú èyí wò. Lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti ṣàgbéyẹ̀wò bó o ṣe ń pa àdéhùn ìgbéyàwó rẹ mọ́ tó.

Bí àríyànjiyàn bá wáyé, ǹjẹ́ mo máa ń ronú pé mo ti ṣi aya tàbí ọkọ fẹ́?

Ṣé ọ̀dọ̀ ẹlòmíì tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya mi ni ọkàn mi máa ń wà?

Ṣé mo máa ń sọ fún ọkọ tàbí aya mi nígbà míì pé, “Màá já ẹ jù sílẹ̀” tàbí “màá lọ wá ẹlòmíì tó mọyì mi”?

Pinnu ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa ohun kan tàbí méjì tó o lè ṣe kí àdéhùn ìgbéyàwó rẹ bàa lè túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Àbá díẹ̀ rèé: Máa kọ ọ̀rọ̀ ṣókí ránṣẹ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, fi fọ́tò ọkọ tàbí aya rẹ síbi tí ẹlòmíì ti lè rí i níbi iṣẹ́, tàbí kó o máa pe ọkọ tàbí aya rẹ lórí fóònù lójoojúmọ́ láti mọ bó ṣe ń ṣe sí níbi iṣẹ́.)

O ò ṣe mú onírúurú àbá wá, kó o wá ní kí ọkọ tàbí aya rẹ sọ èyí tó wù ú jù lọ nínú gbogbo rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bí irin ẹ̀gbẹ́ títì kì í ṣeé jẹ́ kí ọkọ̀ wọgbó, bẹ́ẹ̀ ni pípa àdéhùn ìgbéyàwó mọ́ ò ní jẹ́ kí ìgbéyàwó yín forí ṣánpọ́n

[Credit Line]

© Corbis/age fotostock