Kí Lẹ Lè Ṣe Tí Ìgbéyàwó Yín Ò Fi Ní Tú Ká?
Kí Lẹ Lè Ṣe Tí Ìgbéyàwó Yín Ò Fi Ní Tú Ká?
Àwọn tó ni ilé náà rí i pé ó ti di ahẹrẹpẹ, àmọ́ wọ́n pinnu láti ṣàtúnṣe rẹ̀.
ṢÉ Ó wu ìwọ náà pé kó o ṣàtúnṣe ìgbéyàwó rẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ibo lo ti máa bẹ̀rẹ̀? Gbìyànjú àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí.
1 Pinnu ohun tó o máa ṣe.
Kí ẹ̀yin méjèèjì jọ fohùn ṣọ̀kan pé ẹ máa mú kí àlàáfíà jọba nínú ìgbéyàwó yín. Ẹ gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìpinnu yín. Bí ẹ̀yin méjèèjì bá fohùn ṣọ̀kan láti yanjú àwọn ìṣòro yín, ńṣe lẹ jùmọ̀ ń ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí ìgbéyàwó yín tú ká.—Oníwàásù 4:9, 10.
2 Mọ ohun tó ń fa ìṣòro.
Kí ni kò jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìgbéyàwó yín? Ní gbólóhùn kan, kọ ohun tó o rò pé ó ń fa ìṣòro tàbí ohun tó wù ẹ́ pé kó yí pa dà. (Éfésù 4:22-24) Má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bí ohun tí ìwọ sọ pé ó ń fa ìṣòro bá yàtọ̀ sí ohun tí ẹnì kejì rẹ sọ.
3 Ní àfojúsùn.
Báwo lo ṣe fẹ́ kí ìgbéyàwó yín rí ní oṣù mẹ́fà sí àkókò yìí? Àwọn àyípadà pàtó wo lo máa fẹ́ láti rí? Ṣàkọsílẹ̀ àfojúsùn rẹ. Tó o bá mọ àwọn nǹkan tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìgbéyàwó yín dáadáa, á rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn ohun tó o ní lọ́kàn.—1 Kọ́ríńtì 9:26.
4 Máa fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò.
Tó o bá ti mọ àwọn nǹkan tó ń fa ìṣòro, tó o sì ti pinnu àwọn àyípadà tó o máa fẹ́ láti ṣe, ńṣe ni kó o wá ìmọ̀ràn látinú Bíbélì. Kò sígbà táwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì kì í wúlò, ó sì máa ń gbéṣẹ́ gan-an ni. (Aísáyà 48:17; 2 Tímótì 3:17) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì gba ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ níyànjú pé kẹ́ ẹ máa dárí ji ara yín. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Ẹwà ni ó . . . jẹ́ . . . láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”—Òwe 19:11; Éfésù 4:32.
Pẹ̀lú gbogbo ìsapá rẹ, bí nǹkan ò bá tiẹ̀ kọ́kọ́ rí bó o ṣe fẹ́, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! Ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní The Case for Marriage sọ ohun tó wúni lórí nípa ìwádìí táwọn kan ṣe, ó ní: “Ó yani lẹ́nu pé, ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tọkọtaya tí wọn ò láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn, síbẹ̀ tí wọn ò kọ ara wọn sílẹ̀, ló jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún márùn-ún, àárín wọn túbọ̀ tòrò.” Kódà, àwọn tọkọtaya tí wọ́n máa ń sọ pé kò tiẹ̀ sí ayọ̀ kankan nínú ìgbéyàwó àwọn ló ti wá dẹni tó láyọ̀ báyìí.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tìẹ náà rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí, ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti rí i pé Bíbélì fún àwọn tọkọtaya láwọn ìmọ̀ràn tó gbẹ́ṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ayọ̀ túbọ̀ máa ń wà nínú ìdílé, bí tọkọtaya bá jẹ́ onínúure, tí wọ́n ń fi àánú hàn sí ara wọn, tí wọ́n sì ń dárí ji ara wọn fàlàlà. Àwọn aya ti rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa fi “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” hàn, àwọn ọkọ pẹ̀lú sì ti rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣàì máa bínú lọ́nà kíkorò sáwọn aya wọn.—1 Pétérù 3:4; Kólósè 3:19.
Àwọn ìlànà Bíbélì yìí wúlò gan-an ni, torí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. A rọ̀ ẹ́ pé kó o béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa bí Bíbélì ṣe lè mú kí ìgbéyàwó rẹ tòrò. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ìwé olójú ewé 192 kan tó lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́, orúkọ ìwé náà ni Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Bó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, lo àdírẹ́sì tó bá a mu lára àwọn tá a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí wa.