Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Témi Àtàwọn Òbí Mi Kì í Fi í Gbọ́ra Wa Yé?

Kí Nìdí Témi Àtàwọn Òbí Mi Kì í Fi í Gbọ́ra Wa Yé?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Témi Àtàwọn Òbí Mi Kì í Fi í Gbọ́ra Wa Yé?

Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tá a kọ sísàlẹ̀ yìí, ọ̀nà mẹ́ta ni Rachel gbà dá kún awuyewuye kan tó ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ o lè mọ àwọn ọ̀nà náà? Kọ ìdáhùn rẹ sí ìsàlẹ̀, kó o wá fi wé ohun tó wà nínú àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìdáhùn” ní ìparí àpilẹ̀kọ yìí.

Ní alẹ́ ọjọ́ Wednesday kan, Rachel, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ti parí àwọn iṣẹ́ ilé tó yẹ kó ṣe, ó sì fẹ́ sinmi! Ó tan tẹlifíṣọ̀n, ó sì jókòó sórí àga tó fẹ́ràn jù lọ.

Bó ṣe ń jókòó báyìí ni Mọ́mì ẹ̀ wọlé, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà, ó sì hàn lójú wọn pé inú wọn ò dùn. Wọ́n wá sọ pé: “Rachel! Kí ló dé tó fi jẹ́ pé ìdí tẹlifíṣọ̀n lo jókòó sí, nígbà tó yẹ kó o ran àbúrò ẹ lọ́wọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀? Kò sóhun téèyàn ní kó o ṣe tó o máa ń ṣe láyé tìẹ!”

Rachel wá bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn, ṣùgbọ́n mọ́mì ẹ̀ gbọ́ tó sọ pé: “Wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn!”

Mọ́mì ẹ̀ rìn síwájú díẹ̀. Wọ́n wá bi í pé: “Kí lo wí?”

Ọ̀rọ̀ náà ti sú Rachel, ó fèsì pé, “Mi ò sọ nǹkan kan,” ó wá mọ́ wọn lójú.

Inú bí Mọ́mì ẹ gan-⁠an. Wọ́n wá sọ pé: “Ṣémi lò ń bá sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn?”

Rachel wá dá wọn lóhùn pé: “Ṣé bí ẹ̀yin náà ṣe bá mi sọ̀rọ̀ yẹn dáa?”

Bí awuyewuye ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, Rachel ò sì ráyè sinmi mọ́.

1. ․․․․․

2. ․․․․․

3. ․․․․․

ǸJẸ́ irú ohun tá a sọ lókè yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Ṣé gbogbo ìgbà ni ìwọ àtàwọn òbí rẹ kì í gbọ́ra yín yé? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ronú nípa ohun tó máa ń fà á. Kí lohun tó sábà máa ń fa àìgbọ́ra-ẹni-yé? Sàmì sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tó sábà máa ń fa àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín yín tàbí kó o kọ àwọn nǹkan míì tó o rò pé ó ń fà á síwájú “Nǹkan míì.”

◯ Ìwà rẹ

◯ Iṣẹ́ ilé

◯ Aṣọ wíwọ̀

◯ Ìgbà tó yẹ kó o wọlé

◯ Eré Ìnàjú

◯ Àwọn ọ̀rẹ́

◯ Ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti obìnrin

◯ ◯ Nǹkan míì ․․․․․

Ohun yòówù kó máa fa àìgbọ́ra-ẹni-yé, ìdààmú ọkàn ló máa yọrí sí fún ìwọ àti àwọn òbí rẹ. O lè panu mọ́ kó o sì ṣe bíi pé o gba gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Àmọ́, ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó o ṣe nìyẹn? Rara o. Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé kó o “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfésù 6:2, 3) Àmọ́, ó tún gbà ọ́ níyànjú pé kó o mú “agbára láti ronú” dàgbà kó o sì máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ. (Òwe 1:1-4; Róòmù 12:1) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa dá ẹ lójú, àwọn ìpinnu kan tó o bá ṣe sì lè yàtọ̀ sí èrò àwọn òbí rẹ. Àmọ́, nínú ìdílé tí wọ́n ti ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, àwọn òbí àtàwọn ọmọ máa ń sọ̀rọ̀ láìsí ariwo, kódà bí èrò wọn bá tiẹ̀ dọ́gba lórí ọ̀rọ̀ kan.—Kólósè 3:13.

Báwo lo ṣe lè sọ èrò rẹ jáde láìjẹ́ pé ọ̀rọ̀ di awuyewuye? Ó lè yá ẹ lára láti sọ pé: “Àwọn òbí mi ló níṣòro. Ó ṣe tán àwọn ni ò fi mí lọ́rùn sílẹ̀!” Àmọ́, rò ó wò ná: Ẹni mélòó lo lè pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, títí kan àwọn òbí rẹ? Ohun tó dájú ni pé, ara rẹ nìkan lo lè yí pa dà. Ibi tó wá dáa sí ni pé, tó o bá yẹra fún bíbá wọn jiyàn, àwọn òbí rẹ náà á lè fara balẹ̀ gbọ́ tìẹ, tó o bá lóhun tó o fẹ́ sọ fún wọn.

Jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o lè ṣe tí ọ̀rọ̀ yín á fi máa yé ara yín. Tó o bá tẹ̀ lé àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí, ó lè ya ìwọ àtàwọn òbí rẹ lẹ́nu láti rí i pé o ti wá mọ bá a ṣe ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀.

(Àbá: Fi àmì sí àwọn àbá tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí.)

Ronú kó o tó fèsì. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” (Òwe 15:28) Táwọn òbí rẹ bá sọ̀rọ̀ tó bí ẹ nínú, má ṣe sọ ohun tó bá kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, bí mọ́mì ẹ bá sọ pé: “Kí ló dé tí o kò fọ abọ́? Kò síṣẹ́ téèyàn fún ẹ tó o máa ń ṣe láyé tìẹ!” Ìdáhùn tó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn ni pé: “Kí ló dé tẹ́ ẹ fi máa ń rí sí mi ṣáá?” Àmọ́, ńṣe ni kó o ronú jinlẹ̀. Gbìyànjú láti ronú nípa ohun tó mú kí mọ́mì ẹ sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀, ìgbà tí wọ́n bá lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “gbogbo ìgbà” tàbí “láyé tìẹ,” kì í ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn gan-an nìyẹn. Àmọ́, èyí fi hàn pé ohun kan ń dùn wọ́n lọ́kàn. Kí ló lè máa dùn wọ́n lọ́kàn?

Ó lè máa dun mọ́mì ẹ pé iṣẹ́ ilé tí ò ń fi sílẹ̀ fún wọn ti pọ̀ jù. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn fẹ́ kó o fi dá àwọn lójú pé wàá máa ran àwọn lọ́wọ́. Tíwọ náà bá sì rò ó dáadáa, ó lè jẹ́ pé ó ti di àṣà rẹ láti máa yẹ iṣẹ́ ilé sílẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, tó o bá sọ pé: “Kí ló dé tẹ́ ẹ fi máa ń rí sí mi ṣáá?,” ìyẹn kò ní yanjú ìṣòro náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dojú ọ̀rọ̀ rú! Torí náà, o ò ṣe fi mọ́mì ẹ lọ́kàn balẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Mọ́mì, ẹ má bínú, màá lọ fọ àwọn abọ́ yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” Àkíyèsí: Má ṣe fèsì lọ́nà tó máa pẹ̀gàn wọn. Tó o bá sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé o mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ṣeé ṣe kí èyí yanjú ìṣòro náà.

Kọ ohun tó o rò pé dádì tàbí mọ́mì lè sọ tó lè mú kí inú bí ẹ, tí o kò bá mú un mọ́ra.

․․․․․

Wá ronú nípa bó o ṣe lè rọra fèsì lọ́nà tó máa mú kí ìbínú àwọn òbí rẹ lọ sílẹ̀.

․․․․․

Sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Michelle ti jẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti mọ bó ṣe yẹ kó máa bá mọ́mì ẹ̀ sọ̀rọ̀. Michelle sọ pé: “Ohun yòówù ká fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí, ohun tó sábà máa ń fa ìṣòro ni pé Mọ́mì máa ń sọ pé ohùn mi ti máa ń le jù.” Tó bá jẹ́ pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà nìyẹn, kọ́ béèyàn ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ láìpariwo, kó o sì yẹra fún fífojú kó wọn mọ́lẹ̀ tàbí ṣíṣe àwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú ń bí ẹ. (Òwe 30:17) Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fara ya, gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Ọlọ́run, nínú ọkàn rẹ. (Nehemáyà 2:4) Kì í ṣe káwọn òbí rẹ má bàa máa bá ẹ wí ló ṣe yẹ kó o gbàdúrà, àmọ́ àdúrà yẹn á jẹ́ kó o lè kó ara rẹ níjàánu, kó o máa bàa dá kún ìṣòro náà.—Jákọ́bù 1:26.

Kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ kó o máa sọ àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kó o máa ṣe sí ìsàlẹ̀ yìí.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń sọ:

․․․․․

Àwọn ohun tó o máa ń ṣe:

․․․․․

Máa fetí sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ninu ọ̀rọ̀ pupọ, a kò lè fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù.” (Owe 10:19, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Má máa já lu ọ̀rọ̀ dádì tàbí mọ́mì ẹ, kó o sì máa fetí sílẹ̀ dáadáa tí wọ́n bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá ti ń bá ẹ sọ̀rọ̀, pa orin tó ò ń gbọ́, pa ìwé tó ò ń kà tì, kó o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Má ṣe gbó wọn lẹ́nu. Ṣáà fetí sílẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sọ̀rọ̀ tán, o lè bi wọ́n ní ìbéèrè tàbí kó o ṣàlàyé èrò rẹ fún wọn. Àmọ́, tó o bá fàáké kọ́rí, tó o ní àfi kí wọ́n gbọ́ tìẹ dandan, ńṣe ni gbogbo nǹkan á dojú rú. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan pọ̀ tó o ṣì fẹ́ sọ, ó lè jẹ́ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” nìyí.”—Oníwàásù 3:7.

Múra tán láti tọrọ àforíjì. Ó yẹ kó o lè sọ pé, “Ẹ má bínú” nígbàkigbà tó o bá ṣe ohun tó fa awuyewuye. (Róòmù 14:19) O lè ní kí wọ́n má ṣe bínú pé ẹ ò gbọ́ra yín yé. Tó bá ṣòro fún ẹ láti tọrọ àforíjì lójú kojú, o lè kọ ọ́ síwèé kan kó o wá fún wọn. Yàtọ̀ síyẹn, tún sapá láti yẹra fún ohun yòówù tó o ṣe tó dá kún awuyewuye náà. (Mátíù 5:41) Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ ilé tó o pa tì ló fa awuyewuye yẹn, o ò ṣe jọ àwọn òbí rẹ lójú nípa ṣíṣe iṣẹ́ náà? Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ yẹn ò wù ẹ́ ṣe, ṣé kò ní dáa kó o ṣe é dípò tíyẹn á fi dá wàhálà sílẹ̀ nígbà táwọn òbí rẹ bá rí i pé o ò ṣe é?—Mátíù 21:28-31.

Tó bá yá, wàá rí i pé bó o ṣe ń sapá láti yanjú ìṣòro tàbí bó o tiẹ̀ ṣe ń dènà rẹ̀ á jẹ́ kí ọkàn rẹ túbọ̀ balẹ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ẹni “tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.” (Òwe 11:17) Ronú nípa àǹfààní tó o máa rí tó o bá ṣe ipa tìrẹ láti dín awuyewuye tó ń wáyé láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ kù.

Àwọn ìdílé tó wà níṣọ̀kan pàápàá máa ń ní ìṣòro, àmọ́ wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro wọn láìsí ariwo. Gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, o lè wá rí i pé wàá máa bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ láìsí awuyewuye, títí kan àwọn ọ̀rọ̀ tí kò rọrùn láti jíròrò pàápàá!

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● Kí nìdí táwọn ojúgbà ẹ kan fi máa ń sọ pé ó dáa kéèyàn máa jiyàn?

● Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fojú òmùgọ̀ wo ẹni tó bá ń fa awuyewuye?​—Òwe 20:3.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mò ń ṣiṣẹ́, mo sì ti ń gbọ́ bùkátà ara mi, mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí mọ́mì lẹ́nu, torí ilé wọn ni mo ṣì ń gbé. Àwọn ló tọ́ mi dàgbà, torí náà bí wọ́n bá tiẹ̀ fẹ́ mọ ohun tí mò ń ṣe, bíi kí wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá àkókò tó yẹ kí n wọlé ni mo wọlé, mo mọ̀ pé ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe ni wọ́n ń ṣe.”

“Tí ọ̀rọ̀ èmi àtàwọn òbí mi ò bá ti yé ara wa lórí kókó ọ̀rọ̀ kan, a máa ń fi sínú àdúrà, àá ṣe ìwádìí, àá sì jíròrò rẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ ká dórí ìpinnu tí gbogbo wa máa fọwọ́ sí. Bá a bá jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ọ̀rọ̀ máa ń níyanjú.”

[Àwọn àwòrán]

Daniel

Cameron

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

ÌDÁHÙN

1. Ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tó sọ (“Wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn!”) mú kí inú túbọ̀ bí Mọ́mì rẹ̀.

2. Bí Rachel ṣe ṣojú (ìyẹn bó ṣe mọ́ wọn lójú) dá kún ìṣòro náà.

3. Ọ̀rọ̀ àrífín tó sọ (“Ṣé bí ẹ̀yin náà ṣe bá mi sọ̀rọ̀ yẹn dáa?”) sábà máa ń dá wàhálà sílẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Wo ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tí ìyá Rachel ṣe tó dá kún awuyewuye náà? Kí lo lè ṣe láti yẹra fún awuyewuye láàárín ìwọ àti ọmọ rẹ? Fi àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí sọ́kàn:

Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ àsọrégèé bíi “Gbogbo ìgbà lo máa ń” tàbí “Láyé tìẹ.” Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí ọmọ rẹ fẹ́ gbèjà ara rẹ̀. Ó ṣe tán, àwọn ọ̀rọ̀ bí ìwọ̀nyí lè jẹ́ àsọdùn, ọmọ rẹ náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ìbínú ló jẹ́ kó o máa sọ irú ọ̀rọ̀ àsọdùn bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé òun ò mọṣẹ́ òun níṣẹ́.

Ohun tó dùn ẹ́ nínú ìwà ọmọ rẹ ló yẹ kó o sọ, má ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìwọ,” tó máa fi hàn pé ńṣe lo dájú sọ ọmọ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Tó o bá ṣe báyìí báyìí, ó máa ń ṣe mí bíi pé . . . . ” Fi sọ́kàn pé, báwọn ọmọ rẹ bá mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ, wọn ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́. Tó o bá jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ bí ìwà wọn ṣe rí lára rẹ, wọ́n á lè túbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ.

Ó lè má rọrùn lóòótọ́ o, àmọ́ gbìyànjú láti ní sùúrù títí dìgbà tí ìbínú rẹ á fi rọlẹ̀. (Òwe 10:19) Bí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ilé bá wà lára ohun tó ń fa awuyewuye, pe ọmọ rẹ jókòó kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe gan-an sílẹ̀, tó bá sì pọn dandan, sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí kò bá ṣiṣẹ́ náà. Fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí ọmọ rẹ ní í sọ, bí ohun tó ń sọ ò bá tiẹ̀ tọ̀nà lójú rẹ. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń gbọ́ tẹni tó bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn ju ti ẹni tó bá kàn ń da ìtọ́ni bolẹ̀ lọ.

Kó o tó yára pinnu pé ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe tó wọ́pọ̀ nínú ayé ló ń da ọmọ rẹ láàmú, mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù nínú ìwà tó o rí lára ọmọ rẹ ló jẹ́ ara nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń dàgbà. Ọmọ rẹ lè má fara mọ́ ohun tó o sọ torí ó fẹ́ fi yé ẹ pé òun ti ń dàgbà. Má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ náà di awuyewuye. Má gbàgbé pé àwọn ọmọ rẹ ń kíyè sí ohun tó o máa ń ṣe nígbà tínú bá ń bí ẹ. Bó o bá ní sùúrù àti ìpamọ́ra, wàá lè fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún ọmọ rẹ láti tẹ̀ lé.—Gálátíà 5:22, 23.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Tó o bá ń bá àwọn òbí rẹ ṣe awuyewuye, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń sáré lójú kan náà, kò sí bó o ṣe lè sapá tó, o ò lè kúrò níbi tó o wà