Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kó O Máa San Owó Nítorí Àwọn Ààtò Ìsìn?

Ṣó Yẹ Kó O Máa San Owó Nítorí Àwọn Ààtò Ìsìn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Kó O Máa San Owó Nítorí Àwọn Ààtò Ìsìn?

NÍ Ọ̀PỌ̀ ilẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn tó pera wọn ní Kristẹni àti tàwọn onísìn tí kì í ṣe Kristẹni máa ń gba owó nítorí àwọn ààtò ìsìn tí wọ́n ń ṣe. Lára àwọn ààtò ìsìn tí wọ́n ń gba owó fún ni ìbatisí, ìgbéyàwó àti ìsìnkú. Owó tí wọ́n sì máa ń gbà máa ń tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún owó dọ́là, ó tiẹ̀ máa ń pọ̀ tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là nígbà míì pàápàá.

Àwọn aṣáájú ìsìn kan tiẹ̀ máa ń gba owó oṣù lọ́dọ̀ ìjọba fún àwọn ààtò ìsìn tí wọ́n bá ṣe lórúkọ ìjọba àti fún fífi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lè mọyì àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí, àwọn owó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì sì wà tí ṣọ́ọ̀ṣì ní láti san. Àmọ́, ṣé Bíbélì fọwọ́ sí àṣà gbígba owó nítorí àwọn ààtò ìsìn tàbí sísọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn èèyàn láti sanwó nítorí ààtò ìsìn?

Ṣé “Ilé Ọjà Títà” Ni?

Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn aṣáájú ìsìn àwọn Júù àtàwọn ẹlòmíì máa ń fi àkókò ààtò ìsìn pa owó rẹpẹtẹ, pàápàá jù lọ nígbà Ìrékọjá. Ṣé inú Jésù dùn sí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí? Rárá o! Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, ó “da ẹyọ owó àwọn olùpààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì sojú àwọn tábìlì wọn dé.” Ó wá sọ pé: “Ẹ dẹ́kun sísọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà!”—Jòhánù 2:14-16.

Nígbà ayé wòlíì Míkà, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ohun tí àwọn aṣáájú ìsìn ṣe jọ ti àwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí. Bíbélì ròyìn pé, àwọn aṣáájú ìsìn ní Ísírẹ́lì “ṣe họ́ọ̀ sí ìdájọ́ òdodo,” àwọn àlùfáà sì “ń fúnni ní ìtọ́ni kìkì fún iye kan.” Síbẹ̀, wọ́n ní Ọlọ́run ni alátìlẹyìn àwọn, wọ́n ń sọ pé: “Jèhófà kò ha wà ní àárín wa?” (Míkà 3:9, 11) Àmọ́, Jèhófà kò tì wọ́n lẹ́yìn rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó kórìíra ohun tí wọ́n ń ṣe, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ èyí dáadáa nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn máa ń dá irú ọgbọ́n oníwọra yìí, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ àwọn ibi ìjọsìn wọn di “ilé ọjà títà.” Kódà, àwọn àjọ ìsìn máa ń ṣòwò, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ta àwọn ère àtàwọn nǹkan táwọn èèyàn fi ń jọ́sìn lóríṣiríṣi láti fi jèrè gọbọi. a1 Jòhánù 5:21.

“Ọ̀fẹ́ Ni Ẹ̀yín Gbà, Ọ̀fẹ́ Ni Kí Ẹ Fi Fúnni”

Nígbà tí Jésù ń gbé iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́, tó ní kí wọ́n mú àwọn aláìsàn lára dá, kí wọ́n sì jí òkú dìde, ó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:7, 8) Èyí fi hàn pé, kò yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ máa bu owó lé àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù fúnra rẹ̀ fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ ní ti pé ó wàásù fún àwọn èèyàn láìgba owó lọ́wọ́ wọn.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tẹ̀ lé àwòkọ́ṣe Jésù, ó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ “láìgba owó.” (1 Kọ́ríńtì 9:18) Nígbà tó nílò owó, ó fọwọ́ ara rẹ̀ ṣiṣẹ́, ìyẹn iṣẹ́ àgọ́ pípa. (Ìṣe 18:1-3) Èyí mú kó lè sọ nípa ara rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì pé: “Àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 2:17) Àmọ́, tí ìjọ bá nílò owó ńkọ́, bóyá owó tí wọ́n máa san fún ibi tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn tàbí owó tí wọ́n máa fi rà á?

“Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”

Látinú ọrẹ àtinúwá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń rí àwọn owó tí wọ́n bá nílò. Ìlànà Bíbélì yìí ni wọ́n máa ń fi sílò: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ta àwọn ìwé wọn, wọn kì í sì í gba owó nígbà tí wọ́n bá ṣe ààtò ìsìn, irú bí ìrìbọmi, ìgbéyàwó àti ìsìnkú. Wọn kì í gba ìdámẹ́wàá, wọn kì í sì í gbégbá ọrẹ ní àwọn ìpàdé wọn. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe kárí ayé lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífowó sínú àwọn àpótí ọrẹ tí wọ́n gbé síbi tó yẹ nínú àwọn ibi ìjọsìn wọn.

Yíká ayé, ọrẹ àtinúwá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò láti fi kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn ilé ìtẹ̀wé wọn, ọrẹ àtinúwá yìí náà ni wọ́n sì ń lò láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá. Bíi ti obìnrin opó tí Jésù gbóríyìn fún, ohun tí àwọn kan lè fi ṣètìlẹ́yìn kò pọ̀ rárá. (Lúùkù 21:2) Àwọn míì sì lè fi ọrẹ tó pọ̀ dáadáa ṣètìlẹyìn. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Bíbélì, tí wọ́n sì ń fi ohun tí agbára wọn gbé ṣètọrẹ máa ń ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ìbùkún Ọlọ́run àti ojúlówó ayọ̀.—Ìṣe 20:35; 2 Kọ́ríńtì 8:12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ṣó Yẹ Ká Máa Fi Ère Jọ́sìn Ọlọ́run?” nínú Jí! October–December 2008.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ni Jésù sọ fún àwọn tó ń ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì?—Jòhánù 2:14-16.

● Ǹjẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún iṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣe?—2 Kọ́ríńtì 2:17.

● Irú ìtọrẹ wo ni inú Jèhófà dùn sí?—2 Kọ́ríńtì 9:7.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

“Ẹ dẹ́kun sísọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà!”—Jòhánù 2:14-16