Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Níyì Lójú Ara Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Níyì Lójú Ara Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Níyì Lójú Ara Mi?

BẸ́Ẹ̀ NI BẸ́Ẹ̀ KỌ́

Bó o bá wo ara rẹ nínú dígí,

ṣé o máa ń nífẹ̀ẹ́ sí bó o ṣe rí?

Ṣé o gbà pé o lè ṣe àwọn nǹkan kan

táá mú káwọn ẹlòmíì gbóríyìn fún ẹ?

Ṣé o lè ṣe ìpinnu tó tọ́ nígbà táwọn

ojúgbà rẹ bá fẹ́ kó o ṣohun tí kò dáa?

Bí ẹnì kan bá sọ ohun tí kò

dáa tó o ṣe, ṣé o ò ní bínú?

Báwọn ẹnì kan bá ń sọ̀rọ̀ tí kò

dáa nípa rẹ, ṣé o ò ní fara ya?

Ǹjẹ́ o tiẹ̀ rò pé àwọn ẹlòmíì nífẹ̀ẹ́ rẹ?

Ṣé o máa ń bójú tó ìlera rẹ?

Ǹjẹ́ inú rẹ máa ń dùn táwọn ẹlòmíì bá ṣàṣeyọrí?

Ṣó o lè sọ pé ìwọ gan-an ti ṣàṣeyọrí?

Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ sí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìbéèrè yìí, o ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ojú ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan tó o fi ń wo ara rẹ ni kò jẹ́ kó o rí àwọn ibi tó o dáa sí. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ àwọn ibi tó o dáa sí!

Ọ̀PỌ̀ ọ̀dọ́ ni ọkàn wọn kì í balẹ̀ nípa ìrísí wọn àti àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe, ẹ̀rù sì máa ń bà wọ́n láti fi àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe wéra pẹ̀lú ti àwọn ojúgbà wọn. Ṣé ohun tá a sọ yìí máa ń ṣe ìwọ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lo ní irú èrò yìí.

“Inú mi kì í dùn torí pé mi kì í ṣe àwọn nǹkan bó ṣe tọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé, èmi ni mo máa ń rí sí ara mi jù.”—Leticia. a

“Kò sí bó o ṣe lè dáa lọ́kùnrin tàbí kó o dá a lóbìnrin tó, wàá tún rí àwọn ẹlòmíì tó rẹwà jù ẹ́ lọ.”—Haley.

“Ṣe ni mo máa ń ṣọ́ra mi bí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn, ẹ̀rù máa ń bà mí pé kò sóhun tí mo lè ṣe tó máa dáa lójú wọn.”—Rachel.

Bí ìwọ náà bá ń ronú bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ yìí, fọkàn ẹ balẹ̀. O rí ìrànlọ́wọ́. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè jẹ́ kó o túbọ̀ máa fojú iyì wo ara rẹ, tó sì máa jẹ́ kó o mọ àwọn ibi tó o dáa sí.

1. Yan Ọ̀rẹ́

Ohun tí Bíbélì sọ. “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Ohun tó túmọ̀ sí. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń dúró tini gbágbáágbá lọ́jọ́ ìṣòro. (1 Sámúẹ́lì 18:1; 19:2) Tó o bá ń rántí pé ẹnì kan wà tí kì í fọ̀rọ̀ rẹ ṣeré, èyí lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 16:17, 18) Torí náà, sún mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tó máa nípa rere lórí rẹ.

“Àwọn ọ̀rẹ́ gidi ò ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bò ẹ́ mọ́lẹ̀.”—Donnell.

“Nígbà míì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kó o ṣáà ti mọ̀ pé ẹnì kan wà tí kì í fọ̀rọ̀ ẹ ṣeré rárá. Èyí lè jẹ́ kó o níyì lójú ara ẹ.”—Heather.

Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má fi irú ẹni tó o jẹ́ pa mọ́, má ṣe máa díbọ́n torí kó o má bàa yàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. (Òwe 13:20; 18:24; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Tó o bá ń ṣe àwọn ohun tí kò bójú mu kínú àwọn ẹlòmíì lè dùn sí ẹ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ò ń fira ẹ wọ́lẹ̀ àti pé ṣe làwọn èèyàn kàn ń lò ẹ́ bó ṣe wù wọ́n.—Róòmù 6:21.

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́. Kọ orúkọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó lè jẹ́ kó o máa fojú iyì wo ara rẹ sórí ìlà yìí.

․․․․․

O ò ṣe ṣètò láti lo àkókò pẹ̀lú ẹni tó o kọ orúkọ rẹ̀ yìí? Fi sọ́kàn pé: Kì í ṣe ọ̀ranyàn kí ẹni náà jẹ́ ojúgbà rẹ.

2. Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́

Ohun tí Bíbélì sọ. “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Ohun tó túmọ̀ sí. Tó o bá ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, ara rẹ lo ràn lọ́wọ́ yẹn. Lọ́nà wo? Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra, ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.” (Òwe 11:25) Ká sòótọ́, inú wa máa ń dùn tá a bá ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. b

“Mo ronú nípa ohun tí mo lè ṣe fáwọn ẹlòmíì, mo sì gbìyànjú láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ nínú ìjọ wa. Ara mi máa ń yá gágá, nígbà tí mo bá fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì, tí mo sì jẹ́ kọ́rọ̀ wọn jẹ mí lógún.”—Breanna.

“Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú lílọ́wọ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, torí pé kò ní jẹ́ kó o máa ronú nípa ara rẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn ẹlòmíì.”—Javon.

Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má ṣe ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ torí kó o lè rí nǹkan gbà látọ̀dọ̀ wọn. (Mátíù 6:2-4) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní ṣe ẹ́ láǹfààní kankan. Ó sábà máa ń hàn pé ẹ̀tàn lò ń ṣe!—1 Tẹsalóníkà 2:5, 6.

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́. Ronú nípa ẹnì kan tó o ti ràn lọ́wọ́ nígbà kan rí. Ta ni ẹni yẹn, kí lo sì ṣe fún onítọ̀hún?

․․․․․

Báwo lohun tó o ṣe yẹn ṣe rí lára rẹ lẹ́yìn náà?

․․․․․

Tún ronú nípa ẹlòmíì tó o lè ràn lọ́wọ́, kó o sì ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́.

․․․․․

3. Má Ṣe Jẹ́ Kí Àwọn Àṣìṣe Rẹ Mú Ẹ Rẹ̀wẹ̀sì

Ohun tí Bíbélì sọ. “Nítorí gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23.

Ohun tó túmọ̀ sí. Má ṣe gbàgbé pé, aláìpé ni ẹ́. Ìyẹn á jẹ́ kó o máa rántí pé àwọn ìgbà kan máa wà tó o máa sọ ohun tí kò tọ́ tàbí tí wàá ṣe ohun tí kò dáa. (Róòmù 7:21-23; Jákọ́bù 3:2) Òótọ́ ni pé, o ò lè ṣe kó o má ṣàṣìṣe, síbẹ̀, o kọ́ ara rẹ láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe nígbà tí àṣìṣe bá wáyé. Bíbélì sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.”—Òwe 24:16.

“Nígbà míì, a lè bèrẹ̀ sí í fojú ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan wo ara wa, tá a bá ń fi ibi tá a kù sí wéra pẹ̀lú ibi tí àwọn ẹlòmíì dáa sí.”—Kevin.

“Gbogbo èèyàn ló ní ibi tí ìwà ẹ̀ dáa sí àti ibi tó kù sí. Ó yẹ kínú wa máa dùn nítorí ibi tí ìwà wa dáa sí, ká sì ṣàtúnṣe sí àwọn ibi tá a kù sí.”—Lauren.

Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má ṣe torí pé o jẹ́ aláìpé, kó o wá máa fi ẹ̀ṣẹ̀ ṣomi mu. (Gálátíà 5:13) Tó o bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o ní ìtẹ́wọ́gbà ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run!—Róòmù 1:24, 28.

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́. Kọ ànímọ́ tó wù ẹ́ pé kó o túbọ̀ ní sórí ìlà yìí.

․․․․․

Kọ déètì òní sí ẹ̀gbẹ́ ànímọ́ tó o kọ yìí. Ṣe ìwádìí lórí bó o ṣe lè túbọ̀ ní ànímọ́ náà, kó o sì wá wo bó o bá ti ṣe sí lẹ́yìn oṣù kan.

Bó O Ṣe Níye Lórí Tó

Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ.” (1 Jòhánù 3:20) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn nǹkan kan lè wà tí Ọlọ́run mọyì rẹ̀ lára rẹ, tí ìwọ̀ fúnra rẹ kò sì ronú kàn. Àmọ́, ṣé ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ẹ́ ti yí pa dà torí o jẹ́ aláìpé? Fojú inú wò ó pé o ní ₦100.00 odindi lọ́wọ́, àmọ́ owó yẹn ti ya létí. Ṣé wàá torí ìyẹn sọ ọ́ nù tàbí kó o máa wò ó bíi pé kò wúlò mọ́? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! O ṣì ní ₦100.00 lọ́wọ́, yálà ó ya létí tàbí kò ya.

Èyí fara jọ bó o ṣe níye lórí tó lójú Ọlọ́run. Ó ń kíyè sí bó o ṣe ń sapá láti múnú rẹ̀ dùn, ó sì mọyì rẹ̀, bí àwọn ìsapá rẹ bá tiẹ̀ dà bí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ! Kódà, Bíbélì fi dá wa lójú pé, “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Tó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ronú nípa bí inú rẹ ṣe máa ń dùn tó nígbà tó o bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíì.—Aísáyà 52:7.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Kí lo máa ṣe bí inú rẹ ò bá dùn torí pé

● Àwọn ojúgbà rẹ ń rí sí ẹ?

● Ò ń ronú pé o ò mọ nǹkan ṣe bíi tàwọn ojúgbà rẹ?

● Ó dà bíi pé àwọn àṣìṣe rẹ nìkan lò ń rí?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

“Èèyàn lè rẹwà gan-an, kó sì máa rò pé òun burẹ́wà. Èèyàn sì lè má fi bẹ́ẹ̀ rẹwà, síbẹ̀, kó máa rò pé òun lòún rẹwà jù lọ níbi tóun wà. Ó kù sọ́wọ́ irú ojú tí kálukú bá fi ń wo ara ẹ.”—Alyssa

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Àwọn ọ̀rọ̀ tó tura tí àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ, ẹ̀rín músẹ́ wọn tàbí bí wọ́n ṣe gbá mi mọ́ra máa ń fún mi lókun.”

“Dípò kéèyàn máa banú jẹ́ torí àwọn ànímọ́ rere táwọn ẹlòmíì ní, a lè jàǹfààní látinú àwọn ànímọ́ rere wọn, bí àwọn náà ṣe lè jàǹfààní látinú tiwa.”

[Àwọn àwòrán]

Aubrey

Lauren

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ìníyelórí owó kò dín kù torí pé ó fà ya. Bákan náà, ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ẹ́ kò dín kù torí pé o jẹ́ aláìpé