Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Àwọ̀ Ara Rẹ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn

Jẹ́ Kí Àwọ̀ Ara Rẹ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn

Jẹ́ Kí Àwọ̀ Ara Rẹ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn

● Àwọn èèyàn kan ní ilẹ̀ Áfíríkà, Gúúsù Éṣíà, àgbègbè Caribbean àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn gbà pé èèyàn pàtàkì ni ẹni tó bá ní àwọ̀ pupa àti pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ló mọ àṣà ìgbàlódé. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin láwọn ibi tá a mẹ́nu bà yìí máa ń lo onírúurú ìpara láti fi bóra, èyí sì sábà máa ń ṣàkóbá púpọ̀ fún ìlera wọn.

Àwọn ìpara kan tí àwọn èèyàn máa fi ń bóra ní èròjà hydroquinone nínú, èròjà yìí máa ń ṣí àwọn ohun kan kúrò ní awọ ara, kì í sì í jẹ́ kí ara lè mú èròjà melanin tó máa ń dáàbò bo ara lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn jáde. Èròjà hydroquinone máa ń gba awọ ara wọlé sínú ara, ó sì lè ba àwọn ẹran inú ara jẹ́ lọ́nà tí kò gbóògùn. Èyí á sọ ẹni náà di arúgbó ọ̀sán gangan. Èròjà yìí tún lè fa àrùn jẹjẹrẹ. Àwọn ìpara míì tún máa ń ní èròjà mercury tóun náà jẹ́ májèlé nínú.

Láfikún sí i, àwọn ìpara yìí lè mú kí nǹkan sú síni lára, ó lè mú kí àwọ̀ apá ibì kan nínú ara yàtọ̀ sí ìyókù, ó sì lè mú kí awọ ara rọ̀ débi pé kò ní ṣeé rán tí èèyàn bá fara pa. Bí àwọn kẹ́míkà tó wà nínú àwọn ìpara yìí bá sì wọ inú ara lọ, wọ́n lè ba ẹ̀dọ̀, kíndìnrín tàbí ọpọlọ jẹ́ tàbí kí wọ́n mú kí àwọn ẹ̀yà ara kan daṣẹ́ sílẹ̀.

Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé, bí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú ṣe ń fẹ́ sọra wọn di aláwọ̀ pupa, ńṣe ni àwọn aláwọ̀ pupa tàbí aláwọ̀ funfun kan máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àwọ̀ wọn lè dúdú. Òótọ́ ni pé, ìwọ̀nba oòrùn fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ṣàǹfààní fún ìlera ara. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí ara lè mú èròjà fítámì-D jáde. Àmọ́ bí èèyàn bá pẹ́ jù nínú oòrùn ọ̀sán gangan, ó lè ṣèpalára fún ara. Bí àwọ̀ ará bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í dúdú ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn fi hàn pé ìtànṣán Ultra Violet, tó ń wá látinú oòrùn ti ṣàkóbá fún awọ ara nìyẹn, awọ ara náà sì wá ń gbìyànjú láti dáàbò bo ara rẹ. Àmọ́ ìwọ̀nba ni awọ ara lè dáàbò ba ara rẹ̀ mọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ìpara tó máa ń dáàbò bo awọ ara lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn lè ṣèrànwọ́, kò lè dáàbò bo awọ ara pátápátá lọ́wọ́ àwọn àkóbá tí oòrùn lè ṣe àtàwọn oríṣi àrùn jẹjẹrẹ kan, títí kan àwọn kókó ọlọ́yún dúdú tí wọ́n ń pè ní melanoma.

Ìdí nìyẹn tí Àjọ Ìlera Àgbáyé fi ń fẹ́ “kí àwọn èèyàn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọ̀ ara tí Ọlọ́run dá mọ́ wọn, èyí sì ṣe pàtàkì, bí wọ́n bá fẹ́ dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn ‘ìpalára tí ìtànṣán oòrùn máa ń ṣe.’” Àmọ́ ṣá o, àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ máa ń fún ohun tí Bíbélì pè ní “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” ní àfiyèsí, kí wọ́n lè mú un sunwọ̀n sí i dípò awọ ara tó ń hun jọ!—1 Pétérù 3:3, 4; Òwe 16:31.