Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Máa Ń Mú Ká Hùwà Rere Tàbí Búburú?

Kí Ló Máa Ń Mú Ká Hùwà Rere Tàbí Búburú?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ló Máa Ń Mú Ká Hùwà Rere Tàbí Búburú?

ÌKÓRÌÍRA àti ìpakúpa wọ́pọ̀ gan-an nínú ìtàn ìran èèyàn. Síbẹ̀, láwọn ibi tí ìjábá bá ti wáyé, àwọn èèyàn tún máa ń fi inúure hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Kí nìdí tí àwọn kan fi máa ń ya apààyàn tí kò láàánú lójú, tí àwọn míì sì jẹ́ onínúure? Kí nìdí tí àwọn èèyàn kan fi máa ń hùwà bí ẹranko nígbà míì?

Àìpé Ara Wa àti Ẹ̀rí Ọkàn Wa

Bíbélì sọ ojú abẹ níkòó, nígbà tó sọ pé: “Èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Abájọ tí àwọn ọmọdé fi sábà máa ń hùwàkiwà. (Òwe 22:15) Látìgbà tí wọ́n bá ti bí wa la ti máa ń fẹ́ hùwà tí kò tọ́. (Sáàmù 51:5) Bí ẹni tó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sí ibi tí omi ti ń ya bọ̀, a ní láti sapá gidigidi, ká tó lè máa hùwà rere.

Ọlọ́run tún fún wa ní ẹ̀rí ọkàn. Èrò tó máa ń jẹ́ ká mọ rere yàtọ̀ sí búburú yìí ló máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn fẹ́ láti hùwà ọmọlúwàbí. Èyí máa ń jẹ́ kí àwọn tí kò tiẹ̀ rí ẹni kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà ọmọlúwàbí pàápàá máa ṣe rere. (Róòmù 2:14, 15) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, èrò láti hùwà tí kò tọ́ máa ń ní ìforígbárí pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn wa. Àwọn nǹkan míì wo ló lè nípa lórí wa láti ṣe rere tàbí búburú?

Ìwàkiwà Tó Yí Wa Ká

Ẹranko tí wọ́n ń pè ní ọ̀gà sábà máa ń yí àwọ̀ ara rẹ̀ pa dà kí àwọ̀ rẹ̀ lè bá àyíká ibi tó bá wà mu. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ẹni tó bá ń ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkiwà. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.” (Ẹ́kísódù 23:2) Àmọ́, téèyàn bá ń bá àwọn olóòótọ́ èèyàn rìn, àwọn tí kì í fi dúdú pe funfun, tí wọ́n sì níwà ọmọlúwàbí, ìyẹn á jẹ́ kó rọrùn láti máa hùwà rere.—Òwe 13:20.

Síbẹ̀, a ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé ibi ò lè nípa lórí wa torí pé a ò bá àwọn oníwàkiwà rìn. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, èrò ibi lè fára sin nínú ọkàn wa, èyí sì lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́ nígbàkigbà. (Jẹ́nẹ́sísì 4:7) Yàtọ̀ síyẹn, ìwà búburú lè yọ́ wọ inú ilé wa nípasẹ̀ àwọn iléeṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde. Àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà, ètò orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù sábà máa ń gbé ìwà ipá àti ẹ̀mí ìgbẹ̀san lárugẹ. Kódà, téèyàn bá ń gbọ́ ìròyìn àgbáyé àtàwọn ìròyìn míì déédéé, ó lè mú kí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn àti làásìgbò tó ń bá wọn má jọ wá lójú mọ́.

Ta ni orísun ìwàkiwà tó yí wa ká yìí? Bíbélì dáhùn pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì Èṣù ni “ẹni burúkú” yìí, ó pè é ní òpùrọ́ àti apànìyàn. (Jòhánù 8:44) Ó ń tipasẹ̀ ayé rẹ̀ gbé ìwà ibi lárugẹ.

Torí gbogbo àwọn nǹkan tó ń nípa lórí ìṣe àti ìrònú wa yìí, àwọn kan lè ronú pé, àwọn ò jẹ̀bi táwọn bá hùwàkiwà. Òótọ́ ọ̀rọ̀ wo ló wá yẹ ká fi sọ́kàn? Ńṣe ni èrò ọkàn wa máa ń darí ara wa bí ìgbà tí awakọ̀ ń fi àgbá ìtọ́kọ̀ darí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí ọkọ̀ òkun sí ọ̀nà ibi tó máa gbà.

Ìwọ Lo Máa Pinnu Bóyá Rere Ló Fẹ́ Ṣe Tàbí Búburú

Gbogbo ohun téèyàn bá dìídì ṣe, yálà rere tàbí búburú, ló ti máa rò lọ́kàn tẹ́lẹ̀. Téèyàn bá ń ronú lọ́nà tó tọ́, tí ìrònú rẹ̀ sì bá ti ọmọlúwàbí mu, àǹfààní púpọ̀ ló wà ńbẹ̀. Àmọ́, tá a bá gba ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan láyè láti gbèrú nínú ọkàn wa, èyí lè mú ká hùwà ibi. (Lúùkù 6:43-45; Jákọ́bù 1:14, 15) Torí náà, a lè sọ pé ohun tó bá wu kálukú ló máa ṣe, ẹnì kan lè yàn láti máa hùwà rere tàbí búburú.

Inú wa dùn láti mọ ohun tí Bíbélì sọ pé, èèyàn lè kọ́ láti máa ṣe rere. (Aísáyà 1:16, 17) Torí pé “ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni,” ìfẹ́ ni ohun tó ń mú ká máa hùwà rere. (Róòmù 13:10) Tá a bá fi kọ́ra láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, èyí ò ní jẹ́ ká hùwà ibi sí ẹnikẹ́ni.

Ẹ̀kọ́ tí Ray, láti ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ́ nìyẹn. Láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ ọ láti máa jà, débi pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Punch, ìyẹn orúkọ ìnagijẹ kan tó fi hàn pé aríjàgbá ni. Ó tún máa ń bínú gan-an. Àmọ́, nígbà tó ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Síbẹ̀, ìyípadà yìí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Ìgbà míì wà tó máa ń nímọ̀lára bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹni tó sọ nínú Bíbélì pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” (Róòmù 7:21) Ní báyìí, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Ray ti ń sapá láti rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún un láti “fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:21.

Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti “rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere”? (Òwe 2:20-22) Ìdí ni pé, rere ló máa borí ibi nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Bíbélì sọ pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò . . . ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:9-11) Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ibi kúrò. Ẹ ò rí i pé ọjọ́ ọ̀la ológo ló ń dúró de àwọn tó bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa hùwà rere!

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ta ló máa ń pinnu irú ìwà tá a máa hù?—Jákọ́bù 1:14.

● Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti yí ìwà wa pa dà?—Aísáyà 1:16, 17.

● Ǹjẹ́ ìwà búburú máa dópin láé?—Sáàmù 37:9, 10; Òwe 2:20-22.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ohun tó bá wu kálukú ló máa ṣe, ẹnì kan lè yàn láti máa hùwà rere tàbí búburú